September 2025

Ìran aláíníkan-án-ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 28, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 22

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaaifa jẹ tirẹ lalai ni odiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òwewè ati Ọ̀wàrà 2025 mọ ara wọn. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ kọ ọkan rẹ lati ma tun lailai ṣe awawi mọ fun aitẹwọgba ìfẹ́ rẹ̀ fun aye rẹ, ki ohun gbogbo ba a le dara fun ọ ati fun ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe iran wa jẹ iran eyi ti o fi ara rẹ jin fun awawi ṣiṣe lati ma ṣe ohun ti o tọ, gẹgẹ bi Jesu Kirisiti Oluwa wa ti ṣe tọkasi fun wa. Ti awa ti a si jẹ ọmọ Ọlọrun ko ba kiyesi ara wa, awa naa yoo kan ri wipe nṣe ni a n ṣe awawi ni gbogbo igba fun aigbe ninu ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Iwọ naa wo nkan ti Jesu sọ lori eyi:

“Ṣugbọn kili emi iba fi iran yi wé? O dabi awọn ọmọ kekeke ti njoko li ọjà ti nwọn si nkọ si awọn ẹgbẹ wọn, Ti nwọn si nwipe, Awa fun fère fun nyin ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun. Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu. Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.” (Mátíù 11:16-19)

Ki ni nkan ti a ri nibiyi nipa iran yi? A ri wipe o jẹ iran aláíníkan-án-ṣe. Idi si ni yi ti o fi kun fun awawi ṣiṣe lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun. Bi Oluwa wa ti fi han wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yẹn, bi o tilẹ jẹ wipe Oun ati Johanu Onitẹbọmi ko gba ọna kanna ṣe iṣẹ iranṣẹ wọn, awọn mejeeji ni Ọlọrun ran lati bukunfun araye. Eyi si n fi han wa pe ki a ma ṣe ṣe agbeyẹwo iṣẹ iranṣẹ ẹnikẹni lori awọn nkan ti ode; dipo bẹ ẹ, nṣe ni ki a ṣe e ni ibamu pẹlu eso ti o n so. Ti o ba n so eso ododo Ọlọrun, a jẹ wipe ti Ọlọrun ni. Ṣugbọn ti ko ba so eso ododo rẹ, bi o tilẹ dabi ẹni wipe o jẹ mimọ ni ode, ko ki i ṣe ti Ọlọrun. Ki o si dakun fi eleyi si ọkan.

Ni kukuru, a ri wipe awọn Juu aye igba Jesu Kirisiti Oluwa wa ko tẹwọgba ati Oun ati Johanu Onitẹbọmi, bi o tilẹ jẹ wipe ọna ọtọtọ ni wọn gba ṣe iṣẹ iranṣẹ wọn. Ki ni idi? Wọn ko níkan-ań-ṣe ni. Bi a tun ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yẹn, ọna ti Johanu n gba ṣe iranṣẹ rẹ fi han pe ko bikita pupọ nipa ounjẹ, aṣọ, ilegbe tabi ibaṣepọ pẹlu awọn eniyan. O kan ṣa fẹ polongo ọrọ Ọlọrun si gbogbo orilẹ-ede ni, ki o si pese wọn fun Mesaya wọn. Boya wọn wa gbọ si lẹnu tabi wọn ko gbọ si lẹnu, ko bikita rara. Nitorina, awọn eniyan n pe ni aṣiwin ọkunrin. Eyi jasi pe, awawi wọn lati ma tẹwọ gba a ati ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa ni pe ko ma a ṣe bi eniyan gidi. (Wo: Máítù 3:4; Máàkù 1:6)

Ṣugbọn nigba ti Jesu de, ti O si bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ tirẹ, gbogbo nkan ti Johanu kọ lati ṣe ni Oun ṣe. O jẹun. O mu. O ba awọn eniyan, pẹlupẹlu awọn ẹlẹṣẹ, ṣe pọ. A o wa ro wipe wọn yoo tẹwọgba nitoripe Oun ṣe bi eniyan gidi. Ṣugbọn dipo ti wọn yoo fi tẹwọgba ati ọrọ Ọlọrun ti O mu wa, nṣe ni awọn eniyan n pe ni alajẹbanu ati ọmutipara.

Ṣe iwọ naa wa ri wipe wọn ko níkan-ań-ṣe? Bẹẹni, wọn ko níkan-án-ṣe, wọn ko si tun ni lọkan lati mu Ọlọrun ni pataki. Nitorina, wọn le lo ohunkohun gẹgẹ bi awawi wọn fun sisa jina si ifẹ rẹ fun wọn, eyi ti yoo si pada jẹ ki wọn pa ara wọn run.

O wa ṣeni laanu pe ọrọ ko ti yipada loni rara. Iran wa ko ti yipada rara. A ko si níkan-ań-ṣe sibẹsibẹ. Nitorina, a le lo ohunkohun gẹgẹ bi awawi wa fun kikọ Ọlọrun silẹ. Fun apẹrẹ, mo ka ninu iroyin laipẹ yi nipa gbajumọ ọdọmọkunrin kan ti o sọrọ lori idi ti oun fi juwọ si ijọ ninu ifọrọjomitoro-ọrọ kan. Ki si ni idi rẹ? Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, nigba ti o wa ọkọ ayọkẹlẹ rẹ de ile-ijọsin rẹ ni kutukutu owurọ ọjọ isinmi kan, wọn dari rẹ lati lọ fidi ọkọ naa gunlẹ si ita. Ṣugbọn bi o ti ṣe n ṣe eyi lọwọ ni o ri wipe, nṣe ni wọn n dari awọn kan lara awọn ti o de lẹyin rẹ lati fi idi ọkọ ti wọn gunlẹ sinu ile. Ki ni idi? Idi ni wipe awọn ọkọ ti awọn wọnyi lowo-lori ju tirẹ lọ. Nitorina, dipo ti yoo fi gbe ọkọ rẹ si ita, nṣe ni o kan wa nkan rẹ pada lọ si ile. Lati igba yi, ẹwẹ, naa si ni ko ti lọ si ipade ijọ kankan mọ.

Ṣe o wa tọna lati ṣe bi eleyi si ẹnikẹni ninu ijọ kankan? Rara o! Ṣugbọn ti o ba jẹ wipe Ọlọrun ati igbala ọkan rẹ ni o n lepa, o ko ni fi aye gba irufẹ nkan bi eyi lati le ọ jina si ijọ. Amọ ṣa o, ti o ko ba níkan-ań-ṣe, ti o ko si ṣetan lati ṣẹ ifẹ Ọlọrun, o le lo ohunkohun, pẹlupẹlu nkan ti ko ni itumọ bi ọna ti a gba to awọn aga inu ijọ kan, gẹgẹ bi awawi rẹ lati sa jina si ijọ tabi lati ma paarọ ijọ bi ẹni n paarọ aṣọ.

Ki a ma fọrọgun, ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa bayi, o si n kilọ fun ọ pe ki o dẹkun lati ma a ṣe awawi fun àínikan-án-ṣe rẹ ni ti ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. Idi si ni pe ko si awawi rẹ kankan ti yoo le yọ ọ kuro ninu ewu ni ọjọ ti Oluwa ba de lati ṣe idajọ gbogbo araye. Nitorina, kilọ fun ara rẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìran aláíníkan-án-ṣe | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 28, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 22 Read More »

Ṣé nkàn tí o nílò láti gbọ́ ni? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 21, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 21

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu Owewe 2025. Adura mi ni pe ki eti rẹ ma tun lailai di si ohùn Ẹmi Ọlọrun, ki o ma ba a ṣegbe pẹlu aye okunkun yi.

Bi a ti ṣe ri ninu iwe Ifihan, ọkan lara awọn nkan ti Jesu Oluwa wa n sọ fun awọn ijọ rẹ ti O kọ lẹta si ni pe ẹnikẹni ti o ba ni eti ki o gbọ nkan ti Ẹmi Ọlọrun n sọ fun awọn ijọ. Eyi n sọ fun wa pe ko ki i ṣe gbogbo eniyan naa ni o ni eti lati gbọ ohun Ẹmi Ọlọrun, yala fun igbega tabi fun aabo wọn. Nkan ti awọn kan ni eti lati gbọ ni ohùn ara wọn tabi ohùn eṣu. Nitorina, irufẹ nkan yowu ti Ọlọrun le ma a sọ fun wọn nipasẹ Ẹmi rẹ, wọn ko le e gbọ.

Fun apẹrẹ, pẹlu gbogbo ikilọ ti Wolii Mikaiah fun Ahabu, ọba yi ko gbọran si lẹnu. Ọrọ rẹ ko tilẹ ri aye wọ eti rẹ lati yi i lọkan pada, ki a ba a le pa mọ kuro ninu iku ti o n duro de e ni oju ogun. Amọ ṣa o, ọrọ awọn wolii Ahabu wọ eti rẹ, o si ki i laya lati lọ si oju ogun ti yoo gba ẹmi rẹ. Ki ni idi? Awọn wolii wọnyi sọ nkan ti o fẹ gbọ fun un. (Wo: 1Awọn Ọba 22; 2Kironika 18)

Nitorina, ọkan lara awọn idi ti eti awọn eniyan ṣe ma n di si ohùn Ẹmi Ọlọrun ni pe kiki nkan ti wọn fẹ gbọ naa ni wọn fẹ gbọ. Ti wọn ba si nilo lati san owo fun ẹnikan lati sọ nkan ti wọn fẹ gbọ fun wọn, wọn yoo fi tayọtayọ san an. Abalajọ ti bibeli ṣe sọ wipe:

“Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn.” (2Tímótì 4:3)

Wayi o, o wa ṣeeṣe ki iwọ naa jẹ ọkan lara awọn ti a n sọrọ nipa. Gbogbo awọn oniwaasu ati eniyan ti o n gbọ ọrọ wọn jẹ kiki awọn ti yoo sọ nkan ti o fẹ gbọ fun ọ. Ṣugbọn ṣe nkan ti o fẹ gbọ yi gan ni o nilo lati gbọ? Ti nkan ti o fẹ gbọ ko ba ki i ṣe nkan ti o nilo lati gbọ, a jẹ wipe o ko yatọ si Ahabu niyẹn. Nitorina, o ti n ṣi ilẹkun aye rẹ silẹ fun ewu. Ti o ba si kọ lati ronupiwada lasiko, o di dandan ki o run aye ati ọkan rẹ lọjọkan.

Nitorina, ki o to kọ ẹyin si ohun yowu ti ẹnikẹni le ma a sọ fun ọ, kọkọ bere lọwọ ara rẹ naa boya nkan ti ẹni na n sọ jẹ nkan ti o nilo lati gbọ tabi eyi ti o ko nilo lati gbọ. Ti o ba si jẹ ohun ti o nilo lati gbọ ni, ti o jẹ ohun ti yoo ṣe aye rẹ ni anfaani, ti yoo si tun darí rẹ̀ si ọna ti o yẹ, mọ wipe ohùn Ẹmi Ọlọrun ni o n ba ọ sọrọ. Nitorina, tẹwọgba, bi o tilẹ dun ọ. Eyi yio si jẹ ọgbọn fun ọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣé nkàn tí o nílò láti gbọ́ ni? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 21, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 21 Read More »

Bí o bá tilẹ̀ jẹ́ ọba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 14, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fi okun fun ọkan rẹ lati mu ọrọ rẹ ni pataki, ki o ba a le ma fi igba gbogbo ṣe aṣeyọri ninu ohun gbogbo ti o ba n ṣe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, irufẹ ẹni yowu ti a le jẹ laye, Ọlọrun fẹ ki a mu ọrọ rẹ ni pataki. Ki ni idi? Idi ni pe nipasẹ ọrọ rẹ nikan ni a ṣe le ṣe aṣeyọri lotitọ laye, ki a si tun jẹ igbadun aṣeyọri wa. Nitorina, bi o ba tilẹ jẹ ọba lori awọn eniyan, o nilo ọrọ Ọlọrun lati jẹ ọba alaṣeyọri, ọba ti awọn ti o wa labẹ iṣakoso rẹ yoo ma a gberu si.

Wo ọrọ ilana ti Mose fun ẹnikẹni ti yoo ba jẹ ọba lori awọn eniyan Isiraẹli:

“Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.” (Ditarónómì 17:18-20)

Ki ni nkan akọkọ ti ẹnikẹni ti o ba di ọba lori awọn eniyan Isiraẹli gbọdọ ṣe? O gbọdọ gba ẹda iwe ofin Ọlọrun kan fun ara rẹ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni ki o ba a le fi ara rẹ jin fun kika ati ṣiṣe aṣaro ninu rẹ ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Ekeji, idi ni ki o ba a le kiyesi lati ma a gbe ile aye rẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ti o ba si ṣe eyi, gẹgẹ bi Mose ti ṣe fi han, oun ati awọn arọmọdọmọ rẹ yoo ṣe rere, wọn yoo si tun jọba fun asiko ti o pẹ lori ilẹ naa.

Ṣe o wa ri bayi pe fun ẹnikẹni ti o jẹ ọba ni Isiraẹli gan lati ṣoriire ati lati ni ọpọlọpọ arọmọdọmọ rẹ gẹgẹ bi ọba lẹyin rẹ, o gbọdọ mu ọrọ Ọlọrun ni pataki. Ko le pa ọrọ rẹ ti tabi ki o sọ wipe oun ko raaye fun un. Aijẹbẹ, ijọba rẹ ko ni tọjọ.

O wa ṣeni laanu, gẹgẹ bi a tun ṣe ri ninu bibeli, pe ọpọ awọn ti o jọba lori awọn ọmọ Isiraẹli ni ko mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun. Nitorina, ijọba wọn ko tojọ. Dipo bẹ ẹ, nigba ti o to asiko kan, nṣe ni Ọlọrun ni lati ran gbogbo awọn eniyan naa lọ si igbekun nitori wọn. A si tun wa ri pe nkan kanna ni o n ṣẹlẹ laye ti a wa ninu rẹ loni. Ibikibi ti awọn adari ko ba ti mu ọrọ Ọlọrun ni pataki, wọn ko le ṣoriire. Dipo eyi, dandan ni ki wọn dari awọn eniyan wọn sinu oniruuru igbekun.

Ka mọ fọrọgun, koko nkan ti mo n sọ ni pe niwọn igba ti awọn ọba gan nilo lati mu ọrọ Ọlọrun ni pataki fun wọn lati ṣoriire laye, awa ti a ko wa ki i ṣe ọba ko gbọdọ ro wipe a le ṣoriire laye lalai mu ọrọ rẹ ni pataki. Nitorina, ti o ko ba i ti ma mu ọrọ Ọlọrun ni pataki, o nilo lati ronupiwda fun anfaani ara rẹ. Lọna wo? Akọkọ, wa ẹda bibeli fun ara rẹ ti o le ka yekeyeke. Ekeji, fi ara rẹ jin lati ma a ka a ati lati ma ṣe aṣaro ninu rẹ. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, ko ni pẹ rara ti iwọ naa yoo fi ri wipe o n gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun n sọ fun ọ.

Wayi o, ẹnikẹni ti o ba n fi ojoojumọ gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ di dandan ki o ṣe aṣeyọri laye. O le bẹrẹ ni ibi kekere laye bi Dafidi. Sibẹsibẹ, Ọlọrun yoo ri daju pe o ṣoriire. O si tun le ba ọpọlọpọ idojukọ pada laye bi Josefu tabi Jobu. Ọlọrun yoo si tun ri daju pe o ṣoriire. Nitorina, irufẹ ipo yowu ti o le wa laye lọwọlọwọ yi, mu ọrọ Ọlọrun ni pataki. Iṣoriire otitọ ati eyi ti o n bani kalẹ yoo si jẹ tirẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Bí o bá tilẹ̀ jẹ́ ọba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 14, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 20 Read More »

Yóò sọ ète wọn di asán | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 07, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 19

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu ọsu Òwewè 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun fooro gbogbo ete eṣu lodi si ọ ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun naa, ki gbogbo ete rere rẹ fun aye rẹ fun ọdun naa ba a le jẹ mimuṣẹ lẹkunrẹrẹ. Amin.

Nigba ti Abusalomu bẹrẹ ọtẹ rẹ, ọkunrin kan ti a n pe ni Ahitofeli darapọ mọ. Ta si wa ni ọkunrin yi? Ọrẹ Dafidi, iyẹn baba Abusalomu, ni. Yatọ si pe o jẹ ọrẹ Dafidi, o tun wa jẹ ọkan lara awọn ti o n gba a nimọran. Amọ ṣa o, ọkunrin yi kọja ẹni ti o kan ma n gba eniyan nimọran. O jẹ ẹnikẹni ti Ọlọrun diidi fun ni ẹbun lati gba awọn eniyan nimọran. Wo nkan ti a sọ ninu bibeli nipa rẹ:

“Imọ̀ Ahitofeli ti ima gbà nijọ wọnni, o dabi ẹnipe enia mbere nkan li ọwọ́ Ọlọrun: bẹ̃ni gbogbo ìmọ Ahitofeli fun Dafidi ati fun Absalomu si ri.” (2Sámúẹ́lì 16:23)

Njẹ o ri bayẹn? Lilọ si ọdọ Ahitofeli fun imọran ni awọn ọjọn wọnni dabi lilọ si ọdọ Ọlọrun funrarẹ fun imọran. Iyẹn jasi pe, o ko le gbe nkan gbagi tabi ki o kuna niwọn igba ti o ba n tẹle imọran rẹ. Abalajọ ti ara Dafidi ko ṣe balẹ nigba ti o gbọ wipe ọkunrin yi ti darapọ mọ Abusalomu lati ditẹ mọ ọn. O mọ wipe niwọn igba ti Abusalomu ba si n gbọran si i lẹnu, oun ni yoo ma a bori. Ka si to wi, ka to fọ, yoo ti fi idi ara rẹ mulẹ ṣinṣin gẹgẹ bi ọba lori Isiraẹli.

Nitorina, Dafidi gbadura si Ọlọrun lori ọrọ naa. Wo nkan ti a sọ ninu bibeli lori eyi:

“Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan.” (2Sámúẹ́lì 15:31)

Ki ni Dafidi ni ki Ọlọrun ṣe? O ni ki O sọ imọran Ahitofeli di ọrọ omugọ ni eti Abusalomu. Ki ni idi? Idi ni wipe ọna kan ṣoṣo fun Abusalomu lati fidirẹmi niyẹn. Ṣe Ọlọrun wa da a lohun tabi ko da lohun? O da a lohun. O lo ọkunrin kan ti a n pe ni Huṣai lati sọ imọran Ahitofeli di ọrọ omugọ ni eti Abusalomu ati awọn agbaagba Isiraẹli ti o wa pẹlu rẹ. Nitorina, Abusalomu pada kuna ninu ija fun itẹ-ọba naa. Ahitofeli funrarẹ naa si pada pokunso. (Wo: 2Samuẹli 17&18)

O wa yẹ ki o ṣakiyesi pe Dafidi ko gbadura pe ki Ọlọrun pa Ahitofeli tabi Abusalomu, bi o tilẹ jẹ wipe awọn mejeeji ni wọn n lepa ẹmi ati itẹ rẹ. Dipo eyi, nṣe ni o gbadura pe ki Ọlọrun fooro ete wọn. Nigba ti Ọlọrun si fooro ete wọn, nṣe ni wọn padanu ẹmi wọn.

Nibakanna, a ko nilo lati gbadura pe ki Ọlọrun pa ẹnikẹni ti o n ṣiṣẹ lodi si wa. Nṣe ni a nilo lati sọ fun pe ki O fooro ete wọn, ki O sọ nkan ija yowu ti wọn n lo lodi si wa di korofo. Yoo si da wa lohun. Ti ẹnikẹni ba wa ku tabi jẹ iya gidigidi nigba ti Ọlọrun n dahun adura wa, a ko ni bi wa lere ẹjẹ wọn.

Nitorina, ma ṣe iyọnu nitori awọn ti wọn n ṣiṣẹ lodi si o, ti wọn n tiraka lati re ọ jabọ tabi lati pa ọ run, bi o ti wu ki iye wọn pọ to. Dipo eyi, nṣe ni ko gbadura pe ki Ọlọrun so ohun yowu ti wọn ba n sọ tabi ṣe lodi si ọ di asan. Yoo si da ọ lohun, yoo si tun ri daju pe a ko doju ti ọ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Yóò sọ ète wọn di asán | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 07, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 19 Read More »