Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fi okun fun ọkan rẹ lati mu ọrọ rẹ ni pataki, ki o ba a le ma fi igba gbogbo ṣe aṣeyọri ninu ohun gbogbo ti o ba n ṣe, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, irufẹ ẹni yowu ti a le jẹ laye, Ọlọrun fẹ ki a mu ọrọ rẹ ni pataki. Ki ni idi? Idi ni pe nipasẹ ọrọ rẹ nikan ni a ṣe le ṣe aṣeyọri lotitọ laye, ki a si tun jẹ igbadun aṣeyọri wa. Nitorina, bi o ba tilẹ jẹ ọba lori awọn eniyan, o nilo ọrọ Ọlọrun lati jẹ ọba alaṣeyọri, ọba ti awọn ti o wa labẹ iṣakoso rẹ yoo ma a gberu si.
Wo ọrọ ilana ti Mose fun ẹnikẹni ti yoo ba jẹ ọba lori awọn eniyan Isiraẹli:
“Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.” (Ditarónómì 17:18-20)
Ki ni nkan akọkọ ti ẹnikẹni ti o ba di ọba lori awọn eniyan Isiraẹli gbọdọ ṣe? O gbọdọ gba ẹda iwe ofin Ọlọrun kan fun ara rẹ. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni ki o ba a le fi ara rẹ jin fun kika ati ṣiṣe aṣaro ninu rẹ ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Ekeji, idi ni ki o ba a le kiyesi lati ma a gbe ile aye rẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ti o ba si ṣe eyi, gẹgẹ bi Mose ti ṣe fi han, oun ati awọn arọmọdọmọ rẹ yoo ṣe rere, wọn yoo si tun jọba fun asiko ti o pẹ lori ilẹ naa.
Ṣe o wa ri bayi pe fun ẹnikẹni ti o jẹ ọba ni Isiraẹli gan lati ṣoriire ati lati ni ọpọlọpọ arọmọdọmọ rẹ gẹgẹ bi ọba lẹyin rẹ, o gbọdọ mu ọrọ Ọlọrun ni pataki. Ko le pa ọrọ rẹ ti tabi ki o sọ wipe oun ko raaye fun un. Aijẹbẹ, ijọba rẹ ko ni tọjọ.
O wa ṣeni laanu, gẹgẹ bi a tun ṣe ri ninu bibeli, pe ọpọ awọn ti o jọba lori awọn ọmọ Isiraẹli ni ko mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun. Nitorina, ijọba wọn ko tojọ. Dipo bẹ ẹ, nigba ti o to asiko kan, nṣe ni Ọlọrun ni lati ran gbogbo awọn eniyan naa lọ si igbekun nitori wọn. A si tun wa ri pe nkan kanna ni o n ṣẹlẹ laye ti a wa ninu rẹ loni. Ibikibi ti awọn adari ko ba ti mu ọrọ Ọlọrun ni pataki, wọn ko le ṣoriire. Dipo eyi, dandan ni ki wọn dari awọn eniyan wọn sinu oniruuru igbekun.
Ka mọ fọrọgun, koko nkan ti mo n sọ ni pe niwọn igba ti awọn ọba gan nilo lati mu ọrọ Ọlọrun ni pataki fun wọn lati ṣoriire laye, awa ti a ko wa ki i ṣe ọba ko gbọdọ ro wipe a le ṣoriire laye lalai mu ọrọ rẹ ni pataki. Nitorina, ti o ko ba i ti ma mu ọrọ Ọlọrun ni pataki, o nilo lati ronupiwda fun anfaani ara rẹ. Lọna wo? Akọkọ, wa ẹda bibeli fun ara rẹ ti o le ka yekeyeke. Ekeji, fi ara rẹ jin lati ma a ka a ati lati ma ṣe aṣaro ninu rẹ. Bi o ba si ṣe n ṣe eyi, ko ni pẹ rara ti iwọ naa yoo fi ri wipe o n gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun n sọ fun ọ.
Wayi o, ẹnikẹni ti o ba n fi ojoojumọ gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun sọ di dandan ki o ṣe aṣeyọri laye. O le bẹrẹ ni ibi kekere laye bi Dafidi. Sibẹsibẹ, Ọlọrun yoo ri daju pe o ṣoriire. O si tun le ba ọpọlọpọ idojukọ pada laye bi Josefu tabi Jobu. Ọlọrun yoo si tun ri daju pe o ṣoriire. Nitorina, irufẹ ipo yowu ti o le wa laye lọwọlọwọ yi, mu ọrọ Ọlọrun ni pataki. Iṣoriire otitọ ati eyi ti o n bani kalẹ yoo si jẹ tirẹ.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)