October 2025

Ṣíṣí ilẹ̀kùn ìpèsè rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 26

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2025. Mo gbadura pe ki gbogbo ilẹkun ipese Ọlọrun ti a ti mọ ọ jẹ ṣiṣi fun ọ ninu ọsẹ naa, ki ayọ rẹ ba a le kun akunwọsilẹ ninu ọṣẹ naa ati ni gbogbo awọn ọjọ ti o ku ninu ọdun yi. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n ṣi ilẹkun ipese Ọlọrun fun awọn eniyan rẹ ni ilawọ si awọn iranṣẹ rẹ ti o n sin wa ninu ọrọ rẹ ati ninu adura. Fun apẹrẹ, ki ilẹkun ipese Ọlọrun ba a le ṣi fun opo ti Elija pade ni Sarefati, o ni lati lawọ si i. Bi o tilẹ wa jẹ wipe asiko iyan ni, ko wa awawi. Dipo eyi, nṣe ni o fifun un lati ara diẹ ti o ni. Nitorina, Ọlọrun ri daju pe ebi ko pa oun ati ọmọkunrin rẹ rara titi iyan ti o wa ni ilẹ naa fi lọ. (Wo: 1Àwọn Ọba 17)

Ki wa ni idi ti o fi jẹ wipe obinrin yi ni Ọlọrun ran Elija si ni asiko naa? Bi Jesu ti ṣe sọ fun wa, ọpọlọpọ opo ni o wa ni ilẹ Isiraẹli ni igba naa. Sibẹsibẹ, Ọlọrun ko ran Elija si ọkankan ninu wọn. Ki ni idi? Idi ni pe O mọ ọkan wọn. O mọ wipe ti Oun ba tilẹ sọ fun wọn pe ki wọn tọju Elija, wọn ko ni gbọ ti Oun. (Wo: Lúùkù 4:25-26)

O ti wa le jẹ wipe Ọlọrun ba awọn melokan sọrọ lara wọn lati tọju Elija. Ṣe wọn wa tẹti si nkan ti O sọ? Ti wọn ba tẹti si nkan ti O sọ ni, ko tun ni nilo lati ran ọkunrin naa lọ si ọdọ opo yi ni Sarefati. Ṣugbọn niwọn igba ti O ti ran-an lọ si Sarefati, kedere ni o han si wa pe opo yowu ti O tilẹ le ba sọrọ ni Isiraẹli lori titọju rẹ ko tẹti si ọrọ rẹ.

Amọ opo ti o wa ni Sarefati yi tẹti si Ọlọrun, O si tun gbọran si lẹnu. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ti kọkọ ba a sọrọ nipa Elija ki O to ran lati lọ wa a. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọrọ Ọlọrun si Elija nipa rẹ ni pe: “Mo ti paṣẹ fun pe ki o tọju rẹ.” Nigba ti Elija si wa kan, o ṣe ifẹ Ọlọrun. Nitorina, a ṣi ilẹkun ipese ti a ko ṣi fun awọn opo yoku fun oun ati ọmọkunrin rẹ.

Ka wa sọ wipe ko tẹti si Ọlọrun tabi gbọran si lẹnu nkọ? Nṣe ni Ọlọrun ko ba ran Elija lọ si ọdọ ẹlomiran ti yoo gbọran si lẹnu. Ẹni naa si wa ni awọn ilẹkun ipese rẹ lati bori asiko iyan naa yo jẹ ṣiṣi fun.

Nibakanna, kiki awa ti a ba n gbọran si Ọlọrun lẹnu lori ohunkohun ti O ba n sọ fun wa lori lilawọ si awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ ati ti wọn n gbadura fun wa ni awọn ilẹkun ipese rẹ kan yoo jẹ ṣiṣi fun. Awọn ti o n fi gbogbo igba ṣe awawi lati ma ṣe ohun ti O palasẹ fun wa ko ni ri nkan miran jẹ ju awawi wọn lọ. Nitorina, ronupiwada bayi, ki o si dẹkun lati ma ṣe awawi fun pipa ifẹ Ọlọrun lori fifun awọn iranṣẹ rẹ ti o n jiṣẹ fun ọ ti. Aijẹbẹ, awọn ipese rẹ kan wa ti ko ni lailai jẹ tirẹ laye yi.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣíṣí ilẹ̀kùn ìpèsè rẹ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 26 Read More »

Má gbé ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ nínú rẹ̀ sọnù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 25

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2025. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun naa, mojuto ajaga yowu ti o le ma a rin ọ mọlẹ, ki O si tun tu ọ lara ni ibi yowu ti ara ti le ma a ni ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi o tilẹ jẹ wipe otitọ ni pe Ọlọrun le mojuto gbogbo ajaga wa, ki O si tun tu wa lara, o tun ṣe pataki ki a ma gbe igbẹkẹlẹ wa ninu rẹ ju sọnu nitori ohun yowu ti a le ma a la kọja. Ṣe o ri, pe Ọlọrun n mojuto ọrọ wa ko tunmọ si pe lẹsẹkẹsẹ naa ni a o ni iriri itura. A le ma a ni iriri itura lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn ti a ko ba gbe igbẹkẹle wa ninu rẹ sọnu, o di dandan ki a ni iriri ominira ti o peye kuro lọwọ ohun yowu ti Satani le ma gbiyanju lati lo lati fi pa wa run.

Fun apẹrẹ, nigba ti Ọlọrun ran Mose lọ si Ijibiti lati tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ, ko ki i ṣe lẹsẹkẹsẹ naa ni wọn ri itura gba. Dipo eyi, nṣe ni Farao mu nkan le si fun wọn. Ki a ti lẹ sọ otitọ, Mose ni lati pada sọdọ Ọlọrun lati sọ wipe:

“OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi? Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.” (Ẹ́kísódù 5:22-23)

Ṣe lotitọ wa ni pe Ọlọrun ko gbe igbesẹ kankan lati tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ? Rara o! O ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ fun itusilẹ wọn ni asiko naa. Amọ ṣa o, Mose ati awọn eniyan naa nilo lati fi suuru tẹsiwaju lati ma a gbẹkẹ le e, ki wọn ba a le jẹgbadun ere gbogbo nkan ti O n ṣe lati gba wọn la lẹkunrẹrẹ. Njẹ wọn wa ṣe eyi? Bẹẹni. Nitorina, a papa tu wọn silẹ kuro ni Ijibiti, a si tun dari wọn wọ inu Ilẹ-Ileri.

Nibakana, awa naa nilo lati ma a fi suuru tẹsiwaju ni gbigbẹkẹle Ọlọrun, ki a ba a le ni iriri ẹkunrẹrẹ ere gbogbo nkan ti O n ṣe lati ṣe ohun gbogbo ti o n ṣe ti wa ni aṣepe. Nitorina, bibeli sọ eyi fun wa:

“Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla. Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na.” (Hébérù 10:35-36)

Njẹ o ri bayẹn? Lakọkọ, a sọ wipe ki a ma ṣe gbe igbẹkẹle wa ninu Ọlọrun sọnu. Kini idi? Idi naa ni pe a o pin wa ni ere ti o ga lori rẹ. Eyi jasi pe, Ọlọrun ko ni lailai ja awọn ti ko ba gbe igbẹkẹle wọn ninu rẹ ju sọnu kulẹ. Ekeji, a sọ wipe ki a ni ifarada ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ni asiko idojukọ aye wa. Eyi tunmọ si pe ki a ma ṣe dẹkun lati ma gbadura, lati ma ṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun, lati ma sọ ọrọ Ọlọrun si awọn idojukọ wa ati lati ma rin ninu ododo. Kini idi? Eyi nikan ni ọna fun wa lati ri imuṣẹ ifẹ rẹ ninu aye wa.

Wayi o, awọn idojukọ ti a n koju le jẹ ki o dabi ẹni pe ifasiko-ṣofo ni fun wa lati tẹsiwaju lati ma gbadura ati lati ma gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun, paapaa julọ ti nkan ba n buru si fun wa dipo ki wọn ma a san si. Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun ti sọ fun wa pe oju ko ni ti awọn ti ko ba gbe igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun ju sọnu. Nitorina, tẹsiwaju lati ma gbadura ati lati ma ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun,. Nigba ti asiko ba si to, iwọ yoo kore didara ati igbala rẹ ninu aye rẹ lọna ti o ga.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má gbé ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ nínú rẹ̀ sọnù | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 19, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 25 Read More »

Májẹ́ ká lò ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 12, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwàrà 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ pa ọ mọ lati ma jẹ irinṣẹ ti Satani le ri lo lọnakọna, ki o ma ba a ṣilẹkun aye rẹ silẹ fun idajọ rẹ. Amin.

Jesu Oluwa wa sọ awọn ọrọ wọnyi si awọn ọmọ ẹyin rẹ nigbakan ri:

“Egbé ni fun aiye nitori ohun ikọsẹ̀! ohun ikọsẹ̀ ko le ṣe ki o ma de; ṣugbọn egbé ni fun oluwarẹ̀ na nipasẹ ẹniti ohun ikọsẹ̀ na ti wá!” (Mátíù 18:7)

Wayi o, ki ni a ri kọ lati ara awọn ọrọ Oluwa wọnyi? Akọkọ, a ri kọ pe aye wa ninu ijangbọn ati labẹ idajọ Ọlọrun. Ki ni idi? Idi ni pe awọn nkan ti o n mu awọn eniyan kọsẹ wa ninu rẹ. Lotitọ, gbogbo eniyan ni a bi pẹlu ẹṣẹ ninu wọn. Ṣugbọn ti a ko ba fun awọn eniyan ni anfaani lati dẹṣẹ si Ọlọrun, awọn iwa-aidara kan wa ti wọn le ma lailai wu laye.

Amọ ṣa o, anfaani lati dẹṣẹ si Ọlọrun pọ jantirẹrẹ ninu aye. Nitorina, bi enikan ko tilẹ fẹ dẹṣẹ, o le ma ni okun to lati gbogun ti ọpọlọpọ itanjẹ lati dẹṣẹ ti o rọgba yi ka. Ta wa ni o n tan awọn eniyan jẹ lati dẹṣẹ? Esu ni. Oun ni o tan Efa jẹ lati ṣẹ si Ọlọrun. Oun yi kanna ni o si tun n tan ẹnikọọkan wa jẹ lati ṣẹ si Ọlọrun loni. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 3)

O wa yẹ ki iwọ naa ri bayi idi ti Jesu ṣe sọ wipe awọn nkan ti o n jẹ ki awọn eniyan dẹṣẹ ko le ṣalai ma waye. Wọn ko le ṣalai ma waye nitoripe Satani n bẹ ninu aye. Eyi jasi pe, niwọn igba ti Satani ati awọn iwin rẹ ba ninu aye yi, o di dandan ki a ma a dojukọ awọn iṣẹlẹ ti o le jẹ ki a kọsẹ, ki a si ṣubu sinu ẹṣẹ. Njẹ eyi wa tunmọ si pe a ko le ṣalai ma kọsẹ, ki a si ṣubu sinu ẹṣẹ? Rara o! A le yago fun eyi nipa oore-ọfẹ Ọlọrun. Ṣugbọn a ko le yago fun idanwo lati dẹṣẹ. Nitorina, a gbọdọ kọ lati ma a fi ojoojumọ duro sinu oore-ọfẹ Ọlọrun. Aijẹbẹ, oniruuru idanwo ni yoo bori wa.

Amọ ṣa o, Oluwa ko wa ma reti pe ki a kan ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati ma ko sinu ẹṣẹ nikan. O tun n reti pe ki a ṣe amulo rẹ lati ma jẹ ki eṣu lo wa lati jẹ ki awọn miran ṣubu sinu ẹṣẹ. Ranti pe O ti sọ fun wa pe awọn nkan ti o n jẹ ki awọn eniyan dẹṣẹ ko le ṣalai ma waye. Ṣugbọn awọn nkan wọnyi ko ki n ṣaba wa lati ọdọ eṣu taara-taara. Lati ọdọ awọn eniyan bi ti wa ni wọn ti ma n ṣaba wa. Ti awa funrawa ko ba si wa kiyesara, a le da irinṣẹ ti Satani yoo lo lati jẹ ki awọn miran kọsẹ, ki wọn si tun ṣubu.

Njẹ ibi ti eyi ba ti wa ṣẹlẹ, gẹgẹ bi Jesu Kirisiti Oluwa wa ti fi han wa, a o gba ibawi ti o gbópọn lọdọ Ọlọrun ju ẹni ti a ti ṣinu ẹṣẹ lọ. Ranti pe ibawi Efa gbópọn ju ti Adamu lọ. Idi si ni pe nipasẹ rẹ ni Satani ṣe ṣe aṣeyọri lati gbe Adamu ṣubu. Eyi jasi pe eṣu lo lo o. Ti awa naa ba si fi aye gba a lati lo wa lati dari ẹnikẹni siniu ẹṣẹ, ti Ọlọrun si ni lati ba wa wi, ibawi tiwa di dandan ki o pọ ju ti ẹni naa lọ. Nitorina, ma ṣe jẹ ki eṣu lo ọ. Ki Ọlọrun ran ọ lọwọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó suwọ̀n.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Májẹ́ ká lò ọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 12, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 24 Read More »

Báwo ni o ṣe nítara sí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 05, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàra 2025. Mo gbadura pe ki Ọlọrun pese ohun yowu ti o ṣe alaini anito rẹ ni ti itara rẹ lati jẹ ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, ọkan lara awọn nkan ti yoo sọ boya a o da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki a da tabi jẹ igbadun awọn ipese rẹ fun wa ni itara wa. Ti a ba ni itara ti o peye to lati jẹ ohun ti O fẹ ki a jẹ tabi lati jẹ igbadun awọn nkan ti O fẹ ki a jẹ igbadun, yoo ri daju pe oju ko ti wa. Idi si ni pe bibeli sọ wipe Olusẹṣan ni O jẹ fun awọn ti o ba farabalẹ tabi fi itara wa a (Hébérù 11:6).

Ṣugbọn ti a ko ba ni itara rara tabi ti o peye to lati jẹ ohun ti O fẹ ki a jẹ tabi lati ni awọn nkan ti O fẹ ki a ni, a le ma jẹ igbadun didara rara tabi bi o ti yẹ ki a jẹ, ti a ko ba ṣaanu fun wa. Nitorina, ti o ba ni adura kan ti o yẹ ki a ma a gba lore-koore, oun naa ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki itara wa fun un ati fun awọn nkan ti O ni nipamọ fun wa peye.

Fun apẹrẹ, nigba ti Wolii Eliṣa sọ fun Ọba Jehoasi Isiraẹli pe ki o ta ọfa iṣẹgun lori awọn ara Aramu, ẹmẹta pere ni o ta a. Eyi si bi wolii yi ninu. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹgun ẹmẹta lori awọn ara Aramu ko to lati fun Isiraẹli ni ominira patapata kuro lọwọ wọn. Wọn yoo nilo to iṣẹgun ẹmẹfa lori wọn ki wọn to le bọ patapata kuro lọwọ imunisin wọn. (Wo: 2Àwọn Ọ̀ba 13:14-19)

Ki wa lo fa ti ọba wọn fi ta ọfa iṣẹgun mẹta pere ni ọjọ naa? Idi ni pe ko ni itara to peye to lati bọ kuro ninu ajaga ika awọn ara Aramu. O kan ro wipe ti oun ba le ṣẹgun wọn ni igba mẹta, o yẹ ki iyẹn naa to. Nitorina, o padanu anfaani kan ṣoṣo ti o ni lati gba ominira ti o peye fun awọn eniyan rẹ kuro lọwọ awọn ti o n pọn wọn loju. O ma ṣe o!

Amọ wo Namani. Bi o tilẹ jẹ wipe Eliṣa jẹ wolii orilẹ-ede ti o jẹ ọta rẹ, itara rẹ lati gba iwosan fun ẹtẹ rẹ jẹ ki o wa si ọdọ rẹ. Bi o si tun tilẹ jẹ wipe ipo ọgagun ẹgbẹ-ogun orilẹ-ede rẹ ni o wa, o gbe igberaga rẹ ju si ẹgbẹ kan lati ṣe nkan ti wolii sọ fun pe ki o ṣe. Ki ni idi? Idi ni pe o ni itara lati gba iwosan rẹ. Ṣe o wa ri gba tabi ko ri gba? O ri gba! (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ko ki i fi igba gbogbo wo itara wa ki O to ṣe nkan fun wa, awọn nkankan wa ni aye yi ti ko ni lailai ṣe fun wa tabi jẹ ki a jẹ igbadun rẹ, ti a ko ba ni itara to fun wọn. Bawo wa ni a ṣe ni itara si lati jẹ ohun ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ ati lati ṣe awọn nkan ti O fẹ ki a ṣe? Eyi yoo han lati ara iha ti a kọ si ọrọ Ọlọrun, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn Kiristiẹni bi ti wa.

Ti a ba mu awọn nkan wọnyi ni ọkunkundun, a jẹ wipe a ni itara nitootọ fun Ọlọrun ati fun awọn nkan ti O ni ni ipamọ fun wa niyẹn. Ṣugbọn ti a ko ba mu wọn ni ọkunkundun, nṣe ni a n fi han pe imuṣẹ ete rẹ fun aye wa ko ka wa lara pupọ tabi rara. Nitorina, a le e ma lailai ni iriri imuṣẹ ete rẹ fun aye wa. Njẹ eyi yo wa suwọn bi? Rara!

Nitorina, gbadura pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ ma fi ojoojumọ pese ohun gbogbo ti o kudiẹ-kaato ninu itara rẹ fun un. Nipa ṣiṣe eyi, ete rere rẹ fun aye rẹ yoo le jẹ mimuṣẹ lẹkunrẹrẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Báwo ni o ṣe nítara sí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 05, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 23 Read More »