Báwo ni o ṣe nítara sí? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 05, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàra 2025. Mo gbadura pe ki Ọlọrun pese ohun yowu ti o ṣe alaini anito rẹ ni ti itara rẹ lati jẹ ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu Iwe Mimọ, ọkan lara awọn nkan ti yoo sọ boya a o da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki a da tabi jẹ igbadun awọn ipese rẹ fun wa ni itara wa. Ti a ba ni itara ti o peye to lati jẹ ohun ti O fẹ ki a jẹ tabi lati jẹ igbadun awọn nkan ti O fẹ ki a jẹ igbadun, yoo ri daju pe oju ko ti wa. Idi si ni pe bibeli sọ wipe Olusẹṣan ni O jẹ fun awọn ti o ba farabalẹ tabi fi itara wa a (Hébérù 11:6).

Ṣugbọn ti a ko ba ni itara rara tabi ti o peye to lati jẹ ohun ti O fẹ ki a jẹ tabi lati ni awọn nkan ti O fẹ ki a ni, a le ma jẹ igbadun didara rara tabi bi o ti yẹ ki a jẹ, ti a ko ba ṣaanu fun wa. Nitorina, ti o ba ni adura kan ti o yẹ ki a ma a gba lore-koore, oun naa ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ jẹ ki itara wa fun un ati fun awọn nkan ti O ni nipamọ fun wa peye.

Fun apẹrẹ, nigba ti Wolii Eliṣa sọ fun Ọba Jehoasi Isiraẹli pe ki o ta ọfa iṣẹgun lori awọn ara Aramu, ẹmẹta pere ni o ta a. Eyi si bi wolii yi ninu. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹgun ẹmẹta lori awọn ara Aramu ko to lati fun Isiraẹli ni ominira patapata kuro lọwọ wọn. Wọn yoo nilo to iṣẹgun ẹmẹfa lori wọn ki wọn to le bọ patapata kuro lọwọ imunisin wọn. (Wo: 2Àwọn Ọ̀ba 13:14-19)

Ki wa lo fa ti ọba wọn fi ta ọfa iṣẹgun mẹta pere ni ọjọ naa? Idi ni pe ko ni itara to peye to lati bọ kuro ninu ajaga ika awọn ara Aramu. O kan ro wipe ti oun ba le ṣẹgun wọn ni igba mẹta, o yẹ ki iyẹn naa to. Nitorina, o padanu anfaani kan ṣoṣo ti o ni lati gba ominira ti o peye fun awọn eniyan rẹ kuro lọwọ awọn ti o n pọn wọn loju. O ma ṣe o!

Amọ wo Namani. Bi o tilẹ jẹ wipe Eliṣa jẹ wolii orilẹ-ede ti o jẹ ọta rẹ, itara rẹ lati gba iwosan fun ẹtẹ rẹ jẹ ki o wa si ọdọ rẹ. Bi o si tun tilẹ jẹ wipe ipo ọgagun ẹgbẹ-ogun orilẹ-ede rẹ ni o wa, o gbe igberaga rẹ ju si ẹgbẹ kan lati ṣe nkan ti wolii sọ fun pe ki o ṣe. Ki ni idi? Idi ni pe o ni itara lati gba iwosan rẹ. Ṣe o wa ri gba tabi ko ri gba? O ri gba! (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ko ki i fi igba gbogbo wo itara wa ki O to ṣe nkan fun wa, awọn nkankan wa ni aye yi ti ko ni lailai ṣe fun wa tabi jẹ ki a jẹ igbadun rẹ, ti a ko ba ni itara to fun wọn. Bawo wa ni a ṣe ni itara si lati jẹ ohun ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ ati lati ṣe awọn nkan ti O fẹ ki a ṣe? Eyi yoo han lati ara iha ti a kọ si ọrọ Ọlọrun, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn Kiristiẹni bi ti wa.

Ti a ba mu awọn nkan wọnyi ni ọkunkundun, a jẹ wipe a ni itara nitootọ fun Ọlọrun ati fun awọn nkan ti O ni ni ipamọ fun wa niyẹn. Ṣugbọn ti a ko ba mu wọn ni ọkunkundun, nṣe ni a n fi han pe imuṣẹ ete rẹ fun aye wa ko ka wa lara pupọ tabi rara. Nitorina, a le e ma lailai ni iriri imuṣẹ ete rẹ fun aye wa. Njẹ eyi yo wa suwọn bi? Rara!

Nitorina, gbadura pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ ma fi ojoojumọ pese ohun gbogbo ti o kudiẹ-kaato ninu itara rẹ fun un. Nipa ṣiṣe eyi, ete rere rẹ fun aye rẹ yoo le jẹ mimuṣẹ lẹkunrẹrẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *