June 2026

Ṣe o wa ni iha ti Ọlọrun? | Láti ọwọ́: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 28, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 09

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òkúdù ati Agẹmọ ọdun 2026 papọ mọ ara wa. Adura mi si ni pe ohunkohun laye yi ko ni ṣe aṣeyọri lati tan ọ lati ma fi ara rẹ jin fun Ọlọrun mọ, ki o si wa tipasẹ eyi bọ si abẹ idajọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ Iwe Mimọ yi ti o sọ pe:

“Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀.” (Ẹ́kísódù 32:26)

Wayi o, Ọlọrun si n bere ibeere kaana ni oni: “Tani o wa ni iha ti Oluwa?” Ninu aye ti o kun fun ẹṣẹ, aiṣododo ati airoju, onigbagbọ kọọkan gbọdọ yan iha ẹni ti yoo wa, yala iha ti Oluwa ni tabi iha ti aye yi.

Ki wa ni o tunmọ si lati wa ni iha ti Oluwa? Akọkọ, o tunmọ si yiyan igbọran dipo aigbọran. Jòhánù 14:15 sọ wipe, “Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.” Ekeji, o tunmọ si diduro fun ododo. Róòmù 12:2 sọ wipe, “Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi…”

Ẹkẹta, wiwa ni iha ti Oluwa tunmọ si titẹle Kirisiti tọkan-tọkan. Lúùkù 9:23 sọ wipe, “O si wi fun gbogbo wọn pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati mã tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀ ni ijọ gbogbo, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.” Ẹkẹrin, wiwa ni iha ti Oluwa tunmọ si jijẹ olododo ni sisin Ọlọrun. Jóṣúà 24:15 sọ wipe, “…Sugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn.”

Ọlọrun n wa awọn ọkunrin ati obinrin ti yoo duro digbi fun un, lalai kọbiara si nkan ti ṣiṣe eyi yoo na wọn. Wiwa ni iha ti Oluwa ko ki i wa fi gbogbo igba jẹ nkan ti ọpọ eniyan n fẹ, ṣugbọn iha iṣẹgun ni o ma fi igba gbogbo jẹ. Nitorina, Ọlọrun n bere lọwọ ọkọọkan wa loni, “Njẹ o wa ni iha temi?” Nṣe si ni ki a jẹ ki idahun wa dabi ti Joṣua, ti o sọ wipe, “Bi o ṣe ti emi ati ile me, Oluwa ni awa o ma a sin.”

Adura mi ni pe ki Ọlọrun, Baba wa, ma a fi ojoojumọ ran ọ lọwọ lati duro ṣinṣin ni iha tirẹ. Mo si tun gbadura pe ki O fun ọ ni igboya lati ma a gbọran si lẹnu, lati ma a sin in ati lati ma a tẹle pẹlu otitọ ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Amin.

Kí O ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣe o wa ni iha ti Ọlọrun? | Láti ọwọ́: Omotola Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 28, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 09 Read More »

Bíbá àwọn adarí ìjọ wa ṣe pọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 21, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 08

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọsu Òkúdù 2026. Adura mi si pe ki a ya aye rẹ ya ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun awọn ibukun rẹ ti a ti tu sori aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o ma n ṣaba di ifarahan awọn ibukun Ọlọrun ninu aye awọn eniyan rẹ lọwọ ni ki wọn ma ba awọn adari ti a yan le wọn lori ninu ijọ lo pọ ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni ifẹ rẹ lori bi a ṣe n ba awọn adari ti o wa lori wa ninu ijọ ṣe pọ? Ifẹ rẹ ni a sọ fun wa ni kukuru ninu awọn ẹsẹ Iwe mimọ wọnyi:

“Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin.” (1 Tẹsalóníkà 5:12-13)

“Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin.” (Hébérù 13:17)

“Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.” (1 Kọ́ríntì 9:14)

Ki ni a ri nibiyi? Akọkọ, a ri wipe ifẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a bu ọla ti o ga fun awọn ti O yan gẹgẹ bi adari fun wa ninu ijọ. Eyi si gbọdọ farahan ninu bi a ti ṣe n ba wọn sọrọ ati bi a ti ṣe n ba wọn ṣe pọ. Ki ni idi? Ṣe nitoripe wọn san ju wa lọ niwaju Ọlọrun ni? Rara? Dipo bẹẹ, nitori iṣẹ rẹ ti wọn n ṣe ni aarin wa ni.

Wayi o, ko ki i wa ṣe kiki igba ti wọn ba n ṣe daradara si wa nikan ni a ni lati bọwọ fun wọn ni ọna yi; a ni lati bọwọ fun wọn pẹlu ni igba ti wọn ba n ba wa wi. Ọkan lara awọn idi ti Ọlọrun fi fi idi ijọba Dafidi mulẹ ni pe ko dẹkun lati ma a bọwọ fun Ọba Sọọlu gidigidi, bi o tilẹ jẹ wipe ọkunrin na ti ṣina. Ko yan asiko ti yoo bọwọ fun ati asiko ti ko ni bọwọ fun. Ti awa naa ba fẹ ki ibukun Ọlọrun fi idi mulẹ ninu aye wa, a ko gbọdọ yan igba ti a o ma bọwọ fun awọn adari ijọ wa. Dipo eyi, gbogbo igba ni a gbọdọ fi ọwọ ti o ga han fun wọn, nitoripe eyi ni ifẹ Ọlọrun fun wa. Ti a ba si wa ri eyi ti o n ṣiwawu ninu wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a n bọwọ fun un, Ọlọrun yoo ṣe idajọ onitọun funrarẹ ni ọna tirẹ.

Nkan keji ti a fi han wa lori ifẹ Ọlọrun fun wa ni biba awọn adari wa ṣe pọ ni i ṣe pẹlu ki a tẹriba fun aṣẹ wọn. Ki ni eyi tunmọ si? O tunmọ si pe niwọn igba ti adari ijọ kan ba ti n dari rẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, nṣe ni ki o fi tọkantọkan ma a tẹle aṣẹ rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun yoo bere lọwọ rẹ bi o ti ṣe n ṣe. Irufẹ ijiyin wo ni yoo wa fun un nipa rẹ?

Nigbati Kora, Datani, Abiramu ati Oni gbimọ pọ lodi si Mose ati Aroni, Mose sọ fun Ọlọrun pe ki O ma tẹwọgba ọrẹ wọn. Ọlọrun ko si tẹwọgba. Yatọ fun iyẹn, O tun jẹ ki ilẹ lanu lati gbe ati awọn ati awọn ẹbi wọn mi laaye. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe awọn naa ni ibukun Ọlọrun lori aye wọn, awọn ibukun wọnyi ko le pa wọn mọ kuro lọwọ idajọ rẹ. Eyi si waye nitori iha ti ko dara ti wọn kọ si awọn adari wọn. Ṣe iwọ naa wa ri idi ti a ṣe sọ fun wa pe ainitẹriba fun awọn adari ijọ wa ko le ṣiṣẹ gbe wa? (Wo: Númérì 16)

Siwaju si, ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ran awọn adari ijọ wa lọwọ pẹlu owo wa ati awọn nkan ti ara miran. Eyi ko si ki i ṣe nkan ti a o ma ṣe ni ẹkọọkan tabi nigbati a ba n woye pe ki wọn gba awọn akanṣe adura kan fun wa. Dipo eyi, o gbọdọ jẹ nkan ti a o fi ara wa jin lati ma a ṣe. Ọkankan ninu wa ko si ni awawi lati ma ṣe e. Idi si ni pe bi o tilẹ jẹ wipe ife omi kan pere ni a le ma a fun wọn loorekoore, Ọlọrun yoo tẹwọgba fun wa, yoo si tun pin wa lere fun un.

O wa ṣeni laanu pe, bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni a ti kọ ni awọn nkan wọnyi leralera, wọn ko ko ki i ṣiṣẹ le wọn lori. Ọkan lara awọn idi si ni yi ti ifarahan ìṣẹ́, ìjákulẹ̀ ati ailera ṣe wọpọ ninu ọpọ ijọ awọn eniyan Ọlọrun. Awa ni a n ṣiṣẹ lodi si ibukun rẹ ninu aye wa.

Wo o, ti o ko ba ri adari ijọ kan gẹgẹ bi ẹni ti ko lẹtọ si ọwọ, igbọran ati iranlọwọ rẹ, kuro ninu ijọ rẹ, ki o si lọ si ibi ti o ti le fi tọkan-tọkan bọwọ fun, gbọran si ati ṣe iranlọwọ fun adari ibẹ. Aijẹbẹ, nṣe ni iwọ yoo ma ṣiṣẹ lodi si iṣoriire ara rẹ. Adura mi si ni pe ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ sinu ironupiwada nibikibi ti o ba ti n kuna lori ọrọ yi ni kiakia. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Bíbá àwọn adarí ìjọ wa ṣe pọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 21, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 08 Read More »

Ohun gbogbo wà ní àkọsílẹ̀ | Láti ọwọ́: Ọmọtọla Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 14, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 07

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ma a fi ojoojumọ gbe aye pẹlu afiyesi pe a o ṣe idajọ ọrọ rẹ ati iṣẹ ọwọ rẹ ni ọjọ kan, ki o ba a le fi ara rẹ jin lati ma a gbe igbe aye ti o buyi kun un. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ inu bibeli ti o sọ pe:

“Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” (Málákì 3:16)

Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ ohun gbogbo ti a n ṣe. Gbogbo ọrọ wa, iṣe wa, ẹbọ tabi ifarada wa, adura wa ati iṣẹ isin wa ni O n ri, ti ko si le e gbagbe. Ọpọ ni o lero wipe niwọn igba ti awọn eniyan ko ti ri awọn nkan ti wọn n ṣe, ohun yowu ti wọn ba ṣe ko ja mọ nkankan. Ṣugbọn bibeli kọ wa pe Ọlọrun ri ohun gbogbo ati wipe yoo mu ohun gbogbo wa si abẹ idajọ.

Oníwàásù 12:14 sọ wipe, “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.” Eyi ja si pe ati iṣẹ rere wa ati iṣẹ ti ko dara wa ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Ko si nkankan ti oju rẹ foru.

Lafikun, Mátíù 12:36 sọ wipe, “Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.” Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo ọrọ ti a n sọ ni o wa ninu akọsilẹ. Nitorina, awọn onigbagbọ gbọdọ ṣọra ṣe pẹlu ọrọ, iwa ati ibaṣepọ wọn pẹlu awọn miran. Idi si ni pe a o mu wọn jiyin rẹ ni ọjọ kan.

Iroyin ayọ wa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ iṣododo, adura, ififunni ati laala wa ninu ijọba rẹ naa pẹlu. Hébérù 6:10 sọ wipe, “Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀…” Nitorina, ti o ba n ti sin Ọlọrun lotitọ, ti o si dabi ẹni pe awọn eniyan ko ka ọ si, ma jẹ ki o su ọ. Ohun gbogbo ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Yoo si pin gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ti o jẹ olododo lere ni asiko tirẹ.

Niwọn igba ti ohun gbogbo si wa ni akọsilẹ bi eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma a gbe igbe aye iwa mimọ, ki a ma a sin Ọlọrun pẹlu ọkan ti o tọ, ki a si duro ṣinṣin gẹgẹ bi olododo. Ọlọrun ti o n ṣe akọsilẹ iṣẹ gbogbo ko ni ṣalai pin gbogbo awọn olododo lere, ki o si ṣe idajọ iṣẹ kọọkan ni ibamu pẹlu idajọ-ododo rẹ ti o peye.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ohun gbogbo wà ní àkọsílẹ̀ | Láti ọwọ́: Ọmọtọla Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 14, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 07 Read More »

Gbàdúrà fún orílẹ̀-èdè wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 07, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 06

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. O fun mi idunnu ti o ga lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati ma jẹ ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ lugbadi awọn ibi awọn ọjọ ikẹyin yi. Amin.

Ọkan lara awọn aṣẹ ti Ọlọrun pa fun awọn eniyan rẹ ni pe ki wọn ma a fi igba gbogbo gbadura fun alaafia ati iṣoriire ibikibi ti wọn ba n gbe. Ko ba wa jẹ pe ilu abinibi ni wọn wa tabi ile okere, niwọn igba ti o ba ti jẹ wipe ibẹ ni wọn n gbe, Ọlọrun fẹ ki wọn ma a gbadura fun-un. Ki ni idi? Idi ni pe iṣoriire ati alaafia ti wọn naa da le lori ni iwọn kan tabi omiran.

Fun apẹrẹ, eyi ni Ọlọrun sọ fun awọn Juu ti a mu lẹru lọ si ilẹ Babiloni ni asiko Ọba Nebukadinesari:

“Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.” (Jeremáyà 29:7)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe a ko awọn Juu wọnyi ni igbekun lọ si Babiloni lodi si ifẹ wọn, sibẹsibẹ Ọlọrun pa a lasẹ fun wọn lati wa alaafia ibẹ ati lati ma gbadura fun un. Ki ni idi? Idi ni pe odiwọn alaafia ati iṣoriire ti wọn yoo jẹgbadun ni ibẹ da lori bi ibẹ ba ṣe wa ni alaafia si ati bi o ba ṣe ṣoriire si.

Nibakana, ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu wa ko ṣe ma jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire ti o ga ju eyi ti a n jẹ lọwọlọwọ yi ni pe orilẹ-ede wa ko wa ni ipo alaafia ati iṣoriire to bi o ti ṣe yẹ. Ti ko ba si ṣe pe Ọlọrun da si ọrọ wa, ti O si mojuto ohun gbogbo ti o n di alaafia ati iṣoriire orilẹ-ede naa lọwọ, ọpọ ninu wa ko ni kuro ni ipo ainilọsiwaju ati ibanujẹ titi lai.

Nitorina, ko to fun ọ lati ma a gbadura fun ara rẹ; o tun ṣe pataki ki o ma gbadura fun orilẹ-ede yi pẹlu. Adura rẹ fun orilẹ-ede naa ko si gbọdọ jẹ ẹkọọkan; dipo bẹẹ, o gbọdọ jẹ eyi ti iwọ yoo ma a gba ni gbogbo igba. Idi si ni pe ti orilẹ-ede naa ba a wa ni alaafia, ti o si tun n ṣoriire, iwọ naa yo jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire rẹ.

Amọ ṣa o, ti o ba jẹ wipe o ya ọlẹ ni gbigbadura fun ara rẹ, bawo ni a ṣe le lero pe iwọ yoo ma gbadura fun orilẹ-ede naa? Tabi ti o ba jẹ wipe o ya amọtara-ẹni-nikan ninu igbe-aye adura gbigba rẹ tabi ti o jẹ wipe ọrọ alaafia ati iṣoriire ara tirẹ nikan ti o jẹ o logun ti o ba n gbadura, bawo ni a ṣe le lero pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede yi lọkunkundun?

Ni kukuru, ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa bayi, o si n sọ fun ọ pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede wa ni ọkunkundun, dipo ti o o fi tẹwọgba ainilọsiwaju ti o n fi kọ ọ lọrun tabi ti o o fi ma a fi igba gbogbo ronu bi iwọ yoo ṣe salọ si orilẹ-ede miran. Ranti pe awọn eniyan kan ni wọn sọ awọn orilẹ-ede ti o n ronu lati salọ di giga. Iwọ naa si le wa lara awọn ti yoo sọ orilẹ-ede wa di giga nipa adura pẹlu itara ti o ba n gba fun un. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Gbàdúrà fún orílẹ̀-èdè wa | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Okudu 07, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 06 Read More »