Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. O fun mi idunnu ti o ga lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati ma jẹ ki iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ lugbadi awọn ibi awọn ọjọ ikẹyin yi. Amin.
Ọkan lara awọn aṣẹ ti Ọlọrun pa fun awọn eniyan rẹ ni pe ki wọn ma a fi igba gbogbo gbadura fun alaafia ati iṣoriire ibikibi ti wọn ba n gbe. Ko ba wa jẹ pe ilu abinibi ni wọn wa tabi ile okere, niwọn igba ti o ba ti jẹ wipe ibẹ ni wọn n gbe, Ọlọrun fẹ ki wọn ma a gbadura fun-un. Ki ni idi? Idi ni pe iṣoriire ati alaafia ti wọn naa da le lori ni iwọn kan tabi omiran.
Fun apẹrẹ, eyi ni Ọlọrun sọ fun awọn Juu ti a mu lẹru lọ si ilẹ Babiloni ni asiko Ọba Nebukadinesari:
“Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.” (Jeremáyà 29:7)
Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe a ko awọn Juu wọnyi ni igbekun lọ si Babiloni lodi si ifẹ wọn, sibẹsibẹ Ọlọrun pa a lasẹ fun wọn lati wa alaafia ibẹ ati lati ma gbadura fun un. Ki ni idi? Idi ni pe odiwọn alaafia ati iṣoriire ti wọn yoo jẹgbadun ni ibẹ da lori bi ibẹ ba ṣe wa ni alaafia si ati bi o ba ṣe ṣoriire si.
Nibakana, ọkan lara awọn idi ti ọpọ ninu wa ko ṣe ma jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire ti o ga ju eyi ti a n jẹ lọwọlọwọ yi ni pe orilẹ-ede wa ko wa ni ipo alaafia ati iṣoriire to bi o ti ṣe yẹ. Ti ko ba si ṣe pe Ọlọrun da si ọrọ wa, ti O si mojuto ohun gbogbo ti o n di alaafia ati iṣoriire orilẹ-ede naa lọwọ, ọpọ ninu wa ko ni kuro ni ipo ainilọsiwaju ati ibanujẹ titi lai.
Nitorina, ko to fun ọ lati ma a gbadura fun ara rẹ; o tun ṣe pataki ki o ma gbadura fun orilẹ-ede yi pẹlu. Adura rẹ fun orilẹ-ede naa ko si gbọdọ jẹ ẹkọọkan; dipo bẹẹ, o gbọdọ jẹ eyi ti iwọ yoo ma a gba ni gbogbo igba. Idi si ni pe ti orilẹ-ede naa ba a wa ni alaafia, ti o si tun n ṣoriire, iwọ naa yo jẹ igbadun alaafia ati iṣoriire rẹ.
Amọ ṣa o, ti o ba jẹ wipe o ya ọlẹ ni gbigbadura fun ara rẹ, bawo ni a ṣe le lero pe iwọ yoo ma gbadura fun orilẹ-ede naa? Tabi ti o ba jẹ wipe o ya amọtara-ẹni-nikan ninu igbe-aye adura gbigba rẹ tabi ti o jẹ wipe ọrọ alaafia ati iṣoriire ara tirẹ nikan ti o jẹ o logun ti o ba n gbadura, bawo ni a ṣe le lero pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede yi lọkunkundun?
Ni kukuru, ọrọ Ọlọrun n tọ ọ wa bayi, o si n sọ fun ọ pe ki o mu adura gbigba fun orilẹ-ede wa ni ọkunkundun, dipo ti o o fi tẹwọgba ainilọsiwaju ti o n fi kọ ọ lọrun tabi ti o o fi ma a fi igba gbogbo ronu bi iwọ yoo ṣe salọ si orilẹ-ede miran. Ranti pe awọn eniyan kan ni wọn sọ awọn orilẹ-ede ti o n ronu lati salọ di giga. Iwọ naa si le wa lara awọn ti yoo sọ orilẹ-ede wa di giga nipa adura pẹlu itara ti o ba n gba fun un. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati mu ọrọ yi ni pataki, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)