October 2026

Yoò yí nkàn padà sí rere fún ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 01, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 27

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu Belu 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun yi ohun gbogbo ti a ti ṣe lodi si ọ ninu ọdun yi pada si rere fun ọ, bi o ti ṣe n la oṣu naa kọja, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin iku Jakọbu, awọn arakurin Josẹfu bẹrẹ si ni bẹru wipe o le fẹ jẹ wọn niya fun gbogbo awọn nkan buruku ti wọn ti ṣe si i. Nitorina, wọn ran iṣẹ si lati sọ fun pe baba wọn fi ọrọ silẹ fun lati bẹbẹ pe ki o dariji wọn fun gbogbo awọn ipalara ti wọn ti ṣe si i. Nigba ti Josẹfu gbọ eyi, o sọkun. Eyi ni akọsilẹ nkan ti o sọ fu wọn:

“Ṣugbọn Josẹfu wi fun wọn pe, “Ẹ ma ṣe bẹru, emi ha wa ni ipo Ọlọrun bi? Bi o tilẹ jẹ pe ẹ gbero lati ṣe mi ni ibi, ṣugbọn Ọlọrun gbero lati fi ṣe rere ti n ṣe lọwọ yii; ni gbigba ẹmi ọpọlọpọ Eniyan la.”” (Jẹ́nẹ́sísì 50:19-20)

Njẹ o ri bayẹn? Josẹfu ko ṣetan lati jẹ awọn arakunrin rẹ niya tabi fi ibi san ibi ti wọn ṣe si i. Ki ni idi? Idi ni pe o ri wipe Ọlọrun ṣiṣẹ ninu ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ si i. O ri bi O ti ṣe yi gbogbo nkan ti awọn arakunrin rẹ ṣe lati palara pada si rere fun un. Nitorina, ko ri idi kankan lati jẹ wọn niya fun iwa ika wọn. Ijiya yowu ti Ọlọrun ati ẹri-ọkan wọn n fun wọn ti to.

Nibakana, Ọlọrun le yi wọn pada si rere fun ọ gbogbo ibi ti awọn Eniyan ti ṣe tabi ti wọn n ṣe si ọ. Nkan ti o ṣe pataki ju ni ki o ma a fi igba gbogbo fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ. Bibeli sọ fun wa pe ẹnikẹni ti o ba fi igbẹkẹle rẹ sinu rẹ oju ko ni ti (Róòmù 10:11). Nitorina, niwọn igba ti igbẹkẹle rẹ ba ti wa ninu rẹ, oju ko ni ti ọ, bi o ti wu ki ipalara ti awọn eniyan ṣe si ọ ti le to.

Wayi o, Ọlọrun si tun n san awọn Eniyan lẹsan fun iṣẹ aṣekara ati iṣẹ afọkansi wọn pẹlu igbega ati iṣoriire, bi o ti wu ki awọn ipo ti wọn ba ara wọn ninu rẹ ti le nira to. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ipo ti ko rọgbọ ni o ti ba ara rẹ laye, nṣe ni ki o tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ karakara ati pẹlu tọkantọkan. Nigba ti asiko ba si to, Ọlọrun yoo san ọ lẹsan fun iṣẹ aṣekara rẹ pẹlu igbega ati iṣoriire ni awọn ọna ti o kọja ireti rẹ.

Ni akotan, o gbọdọ tẹsiwaju lati ma a rin ninu ododo. Aijẹbẹ, o le fi aaye silẹ fun ọta lati sọ eto Ọlọrun fun aye rẹ di asan. Josẹfu ko fi aaye silẹ fun awọn iwa ika awọn arakunrin rẹ lati ran an. Ko fi aaye silẹ fun awọn iwa ika ti wọn wu si lati sọ oun naa di ika Eniyan. Dipo eyi, nṣe ni o mura si rinrin ninu ibẹru Ọlọrun. Nitorina, Satani ko ri aaye lati sọ eto Ọlọrun fun aye rẹ di asan.

Iwọ naa ko gbọdọ fi aaye gba awọn iwa ika ti a wu si ọ lati sọ ọ di ika Eniyan. Dipo eyi, nṣe ni ki o tẹsiwaju lati ma a rin ni ipa ọna ododo. Nigba ti asiko ba si to, Ọlọrun yoo yi ohun gbogbo pada si rere fun ọ, yoo si tun gbe ọ ga. Adura mi wa ni pe ki Ọlọrun fi okun fun ọkan rẹ lati pa awọn ọrọ yi mọ sinu ọkan rẹ, bi o ti ṣe n la oṣu yi kọja, ati lati ṣiṣẹ tọ wọn. Amin.

Kí o ní oṣù Belu 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Yoò yí nkàn padà sí rere fún ọ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 01, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 27 Read More »

Fi ayé rọ̀ wọ́n lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 25, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 26

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o gbẹyin oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi ni pe a ko tun ni lailai fi awọn nkan ti o nilo fun iṣerere rẹ laye pamọ fun ọ mọ ni abala yowu ti o le wa laye, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ti Ọlọrun ko ba ṣi oju awọn eniyan si awọn nkan ti wọn ni lati ṣe lati ni iriri alaafia ati iṣerere, ki wọn ba a le bẹrẹ si ni ṣe wọn, wọn le fi gbogbo ọjọ aye wọn ma a tiraka, ki wọn si ma ni iriri alaafia ati iṣerere. Fun apẹrẹ, ti Ọlọrun ko ba ṣi oju Ruutu ni asiko, lẹyin igba ti o ti padanu ọkọ rẹ, lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ ti yoo yọri si imupadabọsipo ati igbe aye alaafia ati iṣoriire fun-un, a le ma lailai gbọ nkankan nipa rẹ. (Wo: Rúùtù 1)

Ṣugbọn Ọlọrun ṣi oju rẹ, lakọkọ, lati kọ awọn oriṣa awọn eniyan rẹ silẹ ati lati tẹwọgba a gẹgẹ bi Ọlọrun rẹ. Lafikun, nigba ti o dabi ẹni pe ko mu ọgbọn lọwọ lati tẹle iya-ọkọ rẹ ati lati ma a toju rẹ, Ọlọrun ṣi oju ọkan rẹ lati ri wipe ṣiṣe bẹẹ gẹgẹ ni o tọ fun un. O si ṣe bẹẹ.

Wayi o, nitoripe o fi si ọkan rẹ lati tẹle iya-ọkọ rẹ, Naomi, pada wa si ilẹ Isiraẹli lati le ma a sin Ọlọrun ati lati mojuto iya arugbo yi i, Ọlọrun ru ọkan iya naa soke lati dari rẹ lati gbe igbesẹ ti yoo yi ohun gbogbo pada si rere fun un. Wo diẹ lara nkan ti bibeli sọ lori eyi:

“Ni ọjọ kan, Naomi, iya ọkọ Rutu wi fun un pe, ‘Ọmọbinrin mi, njẹ ko yẹ ki emi ba ọ wa ile ọkọ miiran, nibi ti wọn yoo ti le e maa tọju rẹ?” (Rutu 3:1)

Njẹ o ri bayẹn? Naomi fi si ọkan rẹ lati ri daju pe Ruutu, ẹni ti o ti padanu ọkọ rẹ ni rewerewe ati ẹni ti ko ti lọmọ laye, gba imupadabọsipo ati pe a fi a fi idi rẹ mulẹ sinu ile ifẹ, ayọ, alaafia ati iṣerere. Ọlọrun si fun un ṣe. Nitorina, Ruutu di ọkan lara awọn iya-nla Dafidi ati Jesu Oluwa wa. (Wo: Ruutu 3-4)

Ṣugbọn ki ni o fa ti Naomi ṣe fi si ọkan lati ṣe eyi fun Ruutu? Idi ni pe Ruutu funrarẹ gan dara si i. Yatọ si pe Ruutu ti gba Ọlọrun Isiraẹli gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ, ti o si ti ṣetan lati sin in fun iyoku ọjọ aye rẹ, o tun boju aanu wo Naomi, ẹni ti o ti padanu ọmọkunrin rẹ meji, ti ko si tun ni ọmọ-ọmọ kankan ti o le ma a mojuto o. Idi ni yi ti o ṣe duro ti i nigba ti wọn pada de ilẹ Isiraẹli, ti o si n tọju rẹ, dipo ti yoo fi lọ fẹ ọkunrin miran lẹsẹkẹsẹ. Niwọn igba ti Naomi funrarẹ naa ko si ki ṣe ẹnikan ti o mọ tara rẹ nikan, ko pẹ rara ti o fi bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori bi inu Ruutu naa yoo ṣe pada dun.

Ki wa ni koko nkan wọnyi? Oun naa ni pe nipa fifi tọkan-tọkan ran awọn ti o wa ninu aye wa ti wọn nilo iranlọwọ lotitọ lọwọ, a le ma a la ọna fun aye awa tikara wa lati fi idi mulẹ sinu alaafia ati iṣerere. Awọn ti a n ran lọwọ le ma dabi ẹni ti o le gbe nkankan ti o ṣe pataki ṣe lori aṣeyọri ati ibalẹ-ọkan wa laye, gẹgẹ bi Naomi ko ṣe dabi ẹni ti o le gbe nkan rere kankan ṣe lori aye Ruutu. Ki a tilẹ sọ otitọ, oun funrarẹ sọ fun Ruutu ki wọn to kuro ni ilẹ Moabu pe oun ko ni nkan rere kankan ti oun le ṣe fun mọ. Sibẹsibẹ, Ruutu tẹle. Ki ni idi? Idi ni pe ko fi ọkan si nkan ti iya yi le ṣe fun oun bikoṣe nkan ti oun le ṣe lati mu aye rọrun fun iya naa. Bi Ọlọrun si ti wa jẹ ki ọrọ lọ, Naomi yi ni o wa papa dari rẹ sinu ile alaafia, ayọ ati ọpọlọpọ ohun rere gbogbo.

Nitorina, ma di oju rẹ si awọn nkan ti Ọlọrun n fi han ọ nipa awọn ti o wa ni ayika rẹ ti o le ran lọwọ, ti o le jẹ ki aye rọrun si fun wọn. Awọn wọnyi le jẹ awọn agbalagba kan ti o wa ni ayika rẹ, awọn ọmọde adugbo, awọn kan ninu ẹbi tabi ninu ijọ tabi awọn akẹgbẹ rẹ lẹnu iṣẹ tabi ni ile iwe. Irufẹ ẹni yowu ti wọn le jẹ, ṣe amulo ti o peye awọn anfaani ti Ọlọrun n fun ọ lati jẹ ki aye rọrun si fun wọn. Idi si ni pe o le ma a mọ ọna ti Ọlọrun le gba lo awọn nkan ti o n ṣe wọnyi lati mu aye rọrun fun iwọ naa pẹlu, yala loni tabi ni ọjọ iwaju.

Lafikun, ti Ọlọrun ba n lo ẹnikẹni lati mu aye rọrun fun ọ, ma ya alanikanjọpọn ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu wọn. Ma fi oju si kiki nkan ti o le ti ara wọn jere. Nṣe ni ki iwọn naa ma a ronu nipa nkan ti awọn naa le ti ara rẹ jere. Ma a ronu nipa awọn nkan ti iwọ naa le ṣe lati mu aye rọrun si fun wọn. Aijẹbẹ, ti o ba to asiko kan, Ọlọrun le ti iẹlkun iranwọ ti o n rigba nipasẹ wọn. Eyi si le e pa ọ lara lọna ti o ga. Nitorina, jẹ ki igbayegbadun awọn ti igbayegbadun rẹ jẹ logun jẹ iwọ naa logun. Njẹ ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo kun aye rẹ pẹlu isinmi. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Fi ayé rọ̀ wọ́n lọ́rùn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 25, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 26 Read More »

Ìtara fún iṣẹ́ rere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 18, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 25

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ tun ọ ṣe ni okun lati fi otitọ ṣe gbogbo iṣẹ rere ti O tun ọ da lati ṣe, ki o ba a le ri ere rẹ gba lọwọ rẹ lẹkunrẹrẹ. Amin.

Ninu iwe Pọọlu si awọn ara Efesu, o sọ eyi fun wa:

“Nitori awa ni iṣẹ ọwọ rẹ ti a da ninu Kristi Jesu fun awọn iṣẹ rere, eyi ti Ọlọrun ti pese tẹlẹ, fun wa lati ṣe.” (Éfésù 2:10)

Ki ni Ọlọrun tun wa da fun, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? O tun wa da lati ṣe awọn iṣẹ rere ti O ti pese silẹ ṣaaju asiko ti a wa yi lati ṣe. Nitorina, awọn iṣẹ rere wa ti Ọlọrun fẹ ki ẹnikọọkan wa ṣe pẹlu asiko wa ni aye yi. Njẹ a wa mọ wọn? Ti a ko ba mọ wọn, a ni lati bẹrẹ si ni gbadura si i pe ki O ma a fi ojoojumọ kun ọkan wa pẹlu ifihan nipa wọn, ki a ba a le fi ara wa jin fun ṣiṣe wọn.

Ki ni idi ti eyi ṣe ṣe pataki? O ṣe pataki nitoripe kiki awọn iṣẹ rere ti Ọlọrun ba yan fun wa ni yoo san wa ni ẹsan fun. Ki a tilẹ sọ otitọ, dandan ni ki a pade ifooro ati ikuna, ti a ma ba n lọ gbe igbesẹ lati ṣe awọn iṣẹ rere ti ko yan fun wa lati ṣe. Kiki awọn iṣẹ rere ti O yan fun wa ni a le reti lati ṣe aṣeyọri ninu wọn ati lati gba ere le lori. Nitorina, o ṣe pataki ki ẹnikọọkan wa mọ gbogbo iṣẹ rere ti Ọlọrun fẹ ki o ṣe ni ojoojumọ. Nipa bayi, a o le fi ara wa jin fun ṣiṣe wọn.

Amọ ṣa o, mimọ awọn iṣẹ rere ti Ọlọrun n fẹ ki a ṣe ko ma to; a tun ni lati ni itara lati ṣe wọn. Nigba ti a ba ni itara lati ṣe awọn iṣẹ rere ti O fẹ ki a ṣe ni a le ni iwuri lati kọ ẹkọ ninu Iwe mimọ lori wọn ati lati gbadura lori ki a ṣe aṣeyọri ni ṣiṣe wọn. Ọkan lari idi ti Ọlọrun fi wa wẹ wa mọ ninu Kiristi Jesu ni ki a ba a le ni itara lati ṣe iṣẹ rere. Wo nkan ti Pọọlu sọ nipa eyi:

“Ẹni ti o fi ara rẹ fun wa lati irapada kuro ninu iwa buburu gbogbo ati ki o si le wẹ awọn eniyan kan mọ fun ara rẹ fun ini ohun tikara rẹ, awọn to n ni itara fun iṣẹ rere.” (Títù 2:14)

Njẹ o ri bayẹn? Iṣẹ iwẹnumọ Ẹmi Mimọ ninu aye wa yẹ ki o mojuto ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu iwa ailakasi yowu ti o le wa ninu wa si ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. Nitorina, ti o ba ṣakiyesi pe o ko ni itara lati sin Ọlọrun tabi lati ṣe oore fun awọn ti o wa ni ayika rẹ, tabi ti o ba ri wipe o ma n fi igba gbogbo ṣaroye tabi ṣe awawi ni igbakugba ti a ba pe ọ lati ṣe oore fun awọn miran, o le jẹ wipe nṣe ni o n fi orikunkun di iṣẹ Ẹmi Mimọ lọwọ ninu aye rẹ. Idi si ni pe ko si bi yoo ṣe ma ṣiṣẹ ninu rẹ ni ọna ti kun, ti o ko ni ni itara lati ṣe iṣẹ rere yowu ti Ọlọrun le ma a pe ọ lati ṣe, yala ninu ẹbi rẹ, adugbo rẹ, ile-iwe rẹ, ibi-iṣẹ rẹ, ijọ rẹ tabi ibi yowu ti o ti le ba ara rẹ.

Ni kukukuru, koko nkan ti mo n sọ ni pe kiki awọn ti o ba ni itara lati ṣe iṣẹ rere ni yoo rọrun fun Ẹmi Ọlọrun lati dari wọn lati ṣe gbogbo iṣẹ rere ti Ọlọrun le fẹ ki wọn ṣe ni aye yi. Ti o ba wa ri wipe o ṣe alaini itara ti o to ni ṣiṣẹ rere, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu ainitara lati ṣe ohun rere. Nipa bayi, a o le dari iwọ naa lati bẹrẹ si ni ṣe gbogbo iṣẹ rere ti Ọlọrun yoo fẹ ki o ṣe ki asiko rẹ laye yi to tan. Nigba ti o ba si wa duro niwaju rẹ ninu ijọba ayeraye rẹ, ere nla ni iwọ yoo ri gba.

Ki o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìtara fún iṣẹ́ rere | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 18, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 25 Read More »

Ojú-ayé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 11, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 24

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati gbe aye rẹ pẹlu otitọ inu ni ipo yowu ti o le ba ara rẹ, yala awọn eniyan n wo ọ tabi wọn ko wo ọ, ki aye rẹ ba a le ma a fi igba gbogbo jẹ ki awọn eniyan yin orukọ mimọ rẹ. Amin.

Ki ni idi ti Pọtifari ṣe fi Josẹfu ṣe alakoso ohun gbogbo ti o ni, yatọ si aya rẹ? Idi ni pe o jẹ ẹnikan ti o ṣe e fọkan tan lati ṣe ohun ti o tọ, yala ẹnikẹni n wo tabi wọn ko wo. Eyi ja si pe Josẹfu ko ki ṣe ẹnikan ti o fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe. Dipo bẹ ẹ, o jẹ ẹnikan ti yoo ṣe nkan ti o tọ ati ti o lere lori fun oluwa rẹ, yala o wa nibẹ o tabi ko si nibẹ. Abalajọ ti ohun gbogbo ti oluwa rẹ ni ṣe gberu labẹ amojuto rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 39:1-6)

Wayi o, irufẹ eniyan wọnyi ni Ọlọrun fẹ ki ọkọọkan ninu awọn ọmọ rẹ jẹ. O fẹ ki a jẹ ẹni ti awọn ti o wa ninu aye wa le fi ọkan tan lati ṣe ohun ti o yẹ, yala wọn wa nibẹ pẹlu wa tabi wọn ko si nibẹ. Wo awọn ọrọ Iwe mimọ wọnyi:

“Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan.” (Fílípì 1:27)

“Ẹyin ẹru, ẹ gbọ ti awọn olowo yin nipa ti ara ni ohun gbogbo; ki i ṣe ni arọjuṣe, bi awọn alaṣehan; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹru Ọlọrun. Ohunkohun ti ẹyin ba n ṣe, ẹ maa fi tọkantọkan ṣe e fun Oluwa, ki i ṣe fun eniyan; ki ẹ mọ pe lọwọ Oluwa ni ẹyin o gba ere, nitori ẹyin n sin Oluwa Kirisiti. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yoo gba a pada nitori aiṣododo naa ti o ti ṣe: ko si si ojuṣaaju.” (Kólósè 3:22-25)

Ki ni awọn ọrọ Iwe mimọ wọnyi n sọ fun wa? Wọn n sọ fun wa pe a ni lati jẹ ẹni ti Ọlọrun ati eniyan le fọkantan lati ṣe ohun ti o tọ ni ipokipo ti a le wa, yala a n wo wa tabi a ko wo wa. Ki ni idi? Idi ni pe kiki awọn ti o ba n gbe aye wọn ni ọna yi ni yoo pada gba oriyin lọdọ Ọlọrun, bi wọn ko tilẹ ni anfaani lati di ipo ti o ga kankan mu laye ti a wa yi.

Njẹ mo wa jẹ irufẹ eniyan ti Ọlọrun ati awọn eniyan le fi ọkan tan lati ṣe ohun ti o tọ ati ti o dara ninu gbogbo awọn ibaṣepọ mi, yala a n wo mi tabi a ko wo mi? Njẹ iwọ naa jẹ irufẹ eniyan yi bi? Ṣe awọn ti a n ba gbele, ti a n ba ṣiṣẹ, ti a n ṣiṣẹ fun tabi ti a jọ wa ninu ijọ kan naa le fi ọkan tan wa lati ma a fi igba gbogbo ṣe ohun ti o yẹ ati ti o dara, yala wọn wa pẹlu wa tabi wọn ko si pẹlu wa?

Wo o, aye yi ko fi igba kankan ṣe alaini anito awọn alaṣehan. Nitorina, ti o ba jẹ ẹnikan ti ko fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe ṣugbọn ti o n fi igba gbogbo ṣe ohun ti o dara ati ti o yẹ, yala awọn eniyan n wo o tabi wọn ko wo o, awọn ti o n ba ọ ni ajọsepọ yoo ma a fi gbogbo igba ri ara wọn bi alabukunfun. Idi si ni pe wọn yoo mọ wipe awọn ko ni lati yọnu lori ohunkohun ti wọn ba fi si abẹ isakoso rẹ – wọn ti mọ wipe wa a mojuto pẹlu ifarabalẹ.

Ṣugbọn ti o ba jẹ ẹnikan ti o fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe, ko ni pẹ rara ti awọn ti o wa ni ayika rẹ yoo fi da ọ mọ fun ẹni ti o jẹ gan an. Bi wọn ko tilẹ wa bẹnu atẹ lu ọ ni gbangba, wọn yoo fi si ọkan pe o ko le lailai ṣoju wọn bi o ti ṣe tọ lori ọrọ kankan, ayafi ti wọn ba wa nibẹ. Bi eyi yoo ṣe wa pa ọ lara si jẹ ohun ti ẹnikẹni ko le e sọ. Nitorina, bẹrẹ si ni mọ-ọn-mọ gbadura si Ọlọrun lati ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu oju-aye ati lati fun ọkan rẹ ni okun lati ma a fi igba gbogbo jẹ oninukan ati ẹni ti o jafafa. Nipa bayi, iwọ yoo le de awọn ibi giga ti O fẹ ki o de laye.

Kí o ní ọ̀ṣẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ojú-ayé | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 11, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 24 Read More »

Takété sí àwọn oníwàásù èké | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 04, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 23

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapda wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi si nipe nibikibi ti o ba lọ Ọlọrun ko ni jẹ ki o lugbadi ẹtan awọn oniwaasu eke awọn ọjọ ikẹyin wọnyi. Amin.

Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, awọn ọjọ ikẹyin yi jẹ awọn ọjọ ninu eyi ti a o ri ọpọ eke oniwaasu. Awọn wọnyi si ni eṣu yoo ma a lo lati tan ọpọ eniyan jẹ ati lati dari wọn kuro ninu otitọ. Nitorina, a fun wa ni awọn aṣẹ wọnyi ninu bibeli lori wọn:

“Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn…” (Mátíù 7:15-16)

“OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.” (1 Jòhánù 4:1)

Ki ni awọn aṣẹ ti a fun wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli wọnyi? Akọkọ, a ni lati kiyesi awọn eke oniwaasu. Ki si ni idi ti a ṣe ni lati kiyesi wọn? Idi ni pe alarekereke ni wọn. Wọn ko ni fi ete inu wọn han wa lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba tọ wa wa. Dipo bẹẹ, nṣe ni wọn yoo fi ara wọn han bi ẹni ti o fẹran wa, ti o si fẹ ki a ṣe rere. Ṣugbọn bi wọn yoo ṣe jẹ aye wa run nipasẹ ojukokoro, iṣekuṣe ati awọn iwa ika miran ni wọn n wa.

Aṣẹ keji ti a gba ni pe ki a ma a dan gbogbo awọn oniwaasu ti o n tọ wa wa wo. Ki ni idi? Idi ni pe eyi ni yoo jẹ ki a le da awọn eke ti o wa ni aarin wọn mọ. Bi a ti ṣe ri ninu awọn ẹsẹ bibeli yẹn, ọpọ eke oniwaasu ni wọn ti jade lọ sinu aye. Lati ibo si ni wọn ti jade lọ sinu aye? Lati inu ijọ ni! Nitorina, ki a to fi ara wa jin lati ma a tẹle oniwaasu kankan, a sọ fun wa pe ki a kọkọ dan wọn wo naa.

Bawo wa ni ki a ṣe dan wọn wo? Ọrọ Ọlọrun ni a o lo lati dan wọn wo. Ọrọ Ọlọrun fi han wa kedere bi a ti ṣe le mọ iyatọ laarin awọn ojulowo oniwaasu ati awọn eke. Fun apẹrẹ, ọrọ Ọlọrun sọ wipe nipa eso wọn ni a o fi mọ wọn. Nitorina, oniwaasu yowu ti ko ba ti so eso Ẹmi, eso ifẹ, ayọ, alaafia, iwa-pẹlẹ, suuru, irẹlẹ, ikora-ẹni-nijanu ati awọn wọn iwa rere miran ti a mẹnuba ninu bibeli, ko ki i ṣe ti Ọlọrun. Nitorina a gbọdọ takete si i.

Lafikun, oniwaasu yowu ti iṣọwọ ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko ba ti wa ni ibamu pẹlu nkan ti a ri ninu bibeli ko ki i ṣe ti Ọlọrun. A si ni ọpọ wọn loni ti wọn n ṣe oniruuru nkan ti ko wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Awọn wọnyi a ma a yan adura ti o takọ ọrọ Ọlọrun. Wọn a ma a bu awọn ẹda ọrun. Wọn a ma a ta ororo, omi ati awọn nkan miran. Wọn a tun ma ṣe iṣẹ oṣọ, pẹlu iboju pe awọn n ṣe akanṣe eto itusilẹ fun awọn eniyan.

Wayi o, ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe a gbọdọ takete si irufẹ awọn eniyan wọnyi, bi o ti wu ki awọn iṣẹ amin, iṣẹ iyanu ati iṣẹ ara ti wọn n ṣe le ga to. Aijẹbẹ, Satani yo o lo wọn lati pa aye wa run. Lafikun, nipa dida ara wa pọ mọ wọn, awọn naa le di alajọpin ninu idajọ Ọlọrun yowu ti o ba wa sori wọn. Nitorina, takete si awọn eke oniwaasu. Fun anfaani rẹ si ni lati ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Takété sí àwọn oníwàásù èké | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwàrà 04, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 23 Read More »