Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀wàrà 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọkan rẹ ni okun lati gbe aye rẹ pẹlu otitọ inu ni ipo yowu ti o le ba ara rẹ, yala awọn eniyan n wo ọ tabi wọn ko wo ọ, ki aye rẹ ba a le ma a fi igba gbogbo jẹ ki awọn eniyan yin orukọ mimọ rẹ. Amin.
Ki ni idi ti Pọtifari ṣe fi Josẹfu ṣe alakoso ohun gbogbo ti o ni, yatọ si aya rẹ? Idi ni pe o jẹ ẹnikan ti o ṣe e fọkan tan lati ṣe ohun ti o tọ, yala ẹnikẹni n wo tabi wọn ko wo. Eyi ja si pe Josẹfu ko ki ṣe ẹnikan ti o fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe. Dipo bẹ ẹ, o jẹ ẹnikan ti yoo ṣe nkan ti o tọ ati ti o lere lori fun oluwa rẹ, yala o wa nibẹ o tabi ko si nibẹ. Abalajọ ti ohun gbogbo ti oluwa rẹ ni ṣe gberu labẹ amojuto rẹ. (Wo: Jẹ́nẹ́sísì 39:1-6)
Wayi o, irufẹ eniyan wọnyi ni Ọlọrun fẹ ki ọkọọkan ninu awọn ọmọ rẹ jẹ. O fẹ ki a jẹ ẹni ti awọn ti o wa ninu aye wa le fi ọkan tan lati ṣe ohun ti o yẹ, yala wọn wa nibẹ pẹlu wa tabi wọn ko si nibẹ. Wo awọn ọrọ Iwe mimọ wọnyi:
“Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan.” (Fílípì 1:27)
“Ẹyin ẹru, ẹ gbọ ti awọn olowo yin nipa ti ara ni ohun gbogbo; ki i ṣe ni arọjuṣe, bi awọn alaṣehan; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹru Ọlọrun. Ohunkohun ti ẹyin ba n ṣe, ẹ maa fi tọkantọkan ṣe e fun Oluwa, ki i ṣe fun eniyan; ki ẹ mọ pe lọwọ Oluwa ni ẹyin o gba ere, nitori ẹyin n sin Oluwa Kirisiti. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yoo gba a pada nitori aiṣododo naa ti o ti ṣe: ko si si ojuṣaaju.” (Kólósè 3:22-25)
Ki ni awọn ọrọ Iwe mimọ wọnyi n sọ fun wa? Wọn n sọ fun wa pe a ni lati jẹ ẹni ti Ọlọrun ati eniyan le fọkantan lati ṣe ohun ti o tọ ni ipokipo ti a le wa, yala a n wo wa tabi a ko wo wa. Ki ni idi? Idi ni pe kiki awọn ti o ba n gbe aye wọn ni ọna yi ni yoo pada gba oriyin lọdọ Ọlọrun, bi wọn ko tilẹ ni anfaani lati di ipo ti o ga kankan mu laye ti a wa yi.
Njẹ mo wa jẹ irufẹ eniyan ti Ọlọrun ati awọn eniyan le fi ọkan tan lati ṣe ohun ti o tọ ati ti o dara ninu gbogbo awọn ibaṣepọ mi, yala a n wo mi tabi a ko wo mi? Njẹ iwọ naa jẹ irufẹ eniyan yi bi? Ṣe awọn ti a n ba gbele, ti a n ba ṣiṣẹ, ti a n ṣiṣẹ fun tabi ti a jọ wa ninu ijọ kan naa le fi ọkan tan wa lati ma a fi igba gbogbo ṣe ohun ti o yẹ ati ti o dara, yala wọn wa pẹlu wa tabi wọn ko si pẹlu wa?
Wo o, aye yi ko fi igba kankan ṣe alaini anito awọn alaṣehan. Nitorina, ti o ba jẹ ẹnikan ti ko fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe ṣugbọn ti o n fi igba gbogbo ṣe ohun ti o dara ati ti o yẹ, yala awọn eniyan n wo o tabi wọn ko wo o, awọn ti o n ba ọ ni ajọsepọ yoo ma a fi gbogbo igba ri ara wọn bi alabukunfun. Idi si ni pe wọn yoo mọ wipe awọn ko ni lati yọnu lori ohunkohun ti wọn ba fi si abẹ isakoso rẹ – wọn ti mọ wipe wa a mojuto pẹlu ifarabalẹ.
Ṣugbọn ti o ba jẹ ẹnikan ti o fi ara rẹ fun oju-aye ṣiṣe, ko ni pẹ rara ti awọn ti o wa ni ayika rẹ yoo fi da ọ mọ fun ẹni ti o jẹ gan an. Bi wọn ko tilẹ wa bẹnu atẹ lu ọ ni gbangba, wọn yoo fi si ọkan pe o ko le lailai ṣoju wọn bi o ti ṣe tọ lori ọrọ kankan, ayafi ti wọn ba wa nibẹ. Bi eyi yoo ṣe wa pa ọ lara si jẹ ohun ti ẹnikẹni ko le e sọ. Nitorina, bẹrẹ si ni mọ-ọn-mọ gbadura si Ọlọrun lati ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu oju-aye ati lati fun ọkan rẹ ni okun lati ma a fi igba gbogbo jẹ oninukan ati ẹni ti o jafafa. Nipa bayi, iwọ yoo le de awọn ibi giga ti O fẹ ki o de laye.
Kí o ní ọ̀ṣẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)