O kò lè jẹ́ kòṣeku-kòṣẹyẹ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 21, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 34

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2025. Mo gbadura pe ki Ọlọrun tẹsiwaju lati ma a fun ọ ni okun lati pọ si ni iwulo ni ọwọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, mo fẹ ran ọ leti awọn ọrọ Jesu kan ti o lọ bayi:

“Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka.” (Mátíù 12:30)

Wayi o, ki ni koko nkan ti Jesu fẹ mujade nipa sisọ awọn nkan wọnyi? Oun naa ni pe a ko le jẹ kòṣeku-kòṣẹyẹ ninu aye yi tabi ninu ijọba rẹ. Ti a ko ba si ni iha tirẹ, a jẹ wipe a lodi si niyẹn. A si ri awọn kan ti wọn ma n sọ wipe awọn ko ni nkankan lodi si Jesu ati igbe aye Kirisitiẹni ṣugbọn ti wọn ko fẹ da Kirisitiẹni. Awọn miran lara wọn tilẹ ma n lọ si ipade ijọ awọn eniyan Ọlọrun nigba miran pẹlu awọn ọrẹ wọn tabi awọn ẹbi wọn. Ṣugbọn ni ti Jesu o, gbogbo wọn lo lodi si. Nitorina, wọn ko ni ri gẹgẹ bi ọrẹ wọn ṣugbọn bi onidajọ ati ọta wọn ni ọjọ idajọ.

Lafikun, a tun ri awọn ti wọn n pe ara wọn ni Kirisitiẹni ṣugbọn ti wọn ko ni darapọ mọ awọn yoku ninu ijọ wọn lati ṣe ohunkohun fun Ọlọrun. Ki si ni idi ti wọn ko ki i fi darapọ mọ awọn miran lati ṣe nkankan fun Oluwa? Wọn le sọ wipe iṣẹ pọ ju fun awọn lati ṣe bẹẹ. Wọn si le sọ wipe oju n ti awọn ni tabi wipe ẹru n ba awọn lati ṣe bẹẹ ni. Wọn tilẹ le sọ wipe nkan ti wọn ṣe ninu ijọ wọn ko nitumọ si awọn, paapaa julọ ti ko ba ki i ṣe wipe awọn ni wọn mu aba lati ṣe nkan naa wa.

Ni kukuru, ni ti Jesu o, nṣe ni gbogbo irufẹ awọn bayi ti ko ba ṣe akojọ n tu iṣẹ rẹ ka. Wọn le ma fi oju eyi wo nkan ti wọn n ṣe o. Ṣugbọn nkan ti wọn n ṣe niyẹn. Ọjọ kan si n bọ ti a o jẹ wọn niya fun pipa iṣẹ Ọlọrun run. Ti a o ba si sọ otitọ, a tilẹ ti n jẹ awọn kan niya lọwọlọwọ yi fun pipa iṣẹ Ọlọrun run lalai mọ. Awọn ni ko kan mọ pe a n jẹ awọn niya.

Nitorina, o ko le jẹ kòṣeku-kòṣẹyẹ ninu ijọba Ọlọrun. Ti o ba fẹ wa ninu ile, kuku duro sinu ile, ki o si fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o wulo. Aijẹbẹ, nṣe ni ki o duro si ita ki ẹnikẹni ma ba a ro wipe ti Jesu ni o n ṣe, bi o tilẹ jẹ wipe o ko ki i ṣe tirẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *