Kọ́ wa láti má fi ayé wa ṣòfò | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ọ̀pẹ 14, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 33

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọ̀pẹ 2025. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki ọsẹ naa dun fun iwọ ati ẹbi rẹ ni gbogbo ọna, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe n wọ inu awọn ọjọ ti o gbẹyin ọdun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ adura Mose yi:

“Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.” (Sáàmù 90:12)

Ki ni eyi tunmọ si? Njẹ o tunmọ si pe ki Ọlọrun kọ wa ni bi a ti ṣe le mọ ọjọ ori wa bi? Rara o! A ko nilo Ọlọrun lati kọ wa lati mọ iye ọjọ ori wa. Awọn obi wa ati awọn mọlẹbi wa ti o wa nibẹ nigba ti a bi wa le ṣe eyi. Ki a tilẹ sọ otitọ, wọn o ti ṣe eyi ti o ba jẹ wipe wọn ni imọ-ẹkọ diẹ.

Lafikun, mimọ iye ọjọ ori wa kọ ni yo jẹ ki a ma a gbe igbe aye ọgbọn, nitori a ri ọpọ awọn ti o jẹ agbalagba ti wọn n gbe igbe aye omugọ. Dipo eyi, mimọ bi a ti ṣe le ṣe amulo ti o peye ọjọ kọọkan ti Ọlọrun ba fun wa ni yoo jẹ ki a le gbe igbe aye ọlọgbọn. Eyi gan-an si ni adura Mose yi dale lori. O jẹ igbe si Ọlọrun lati kọ wa lati ma fi aye wa ṣofo.

Lati ara nkan ti a ri ninu Iwe Mimọ, o ṣeeṣe ki a fi aye wa ṣofo. A o si fi aye wa ṣofo, ti a ba n fi awọn ọjọ wa ṣofo. Idi ni yi ti a fi nilo Ọlọrun lati kọ wa bi a ti le lo ọjọ kọọkan lati ṣe kiki awọn nkan ti o lere lori.

Wayi o, mi o mọ bi o ti ṣe lo awọn ọjọ ti Ọlọrun fun ọ ni ọdun yi. Mi o mọ boya o fi wọn ṣofo lori awọn nkan ti ko lere ni tabi boya o lo wọn lati ṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki Ọlọrun gboriyin fun ọ. Ṣugbọn mo fẹ ki o mọ wipe o ko nilo lati fi ojọ kankan ṣofo mọ lori awọn nkan ti ko lere. O ko si ni fi ọjọ kankan ṣofo mọ lori awọn nkan ti ko lere, ti o ba le bere lọwọ Ọlọrun pe ki O kọ ọ bi o ti ṣe le ṣe amulo ti o peye ọjọ kọọkan.

Nitorina, bi o ti ṣe n wọ awọn ọjọ ti o gbẹyin ọdun yi, fi sinu adura rẹ lojoojumọ pe ki Ọlọrun ma kọ ọ ni bi o ko ṣe ni fi aye rẹ ṣofo. Nipa bayi, a o le gbe ọ ro lati gbe iyoku ọjọ aye rẹ ninu ọgbọn dipo ninu omugọ. Njẹ ki o gba okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *