Àkórí: Àlàáfíà wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 25, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 39

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu yi, oṣu Sẹrẹ 2026. Adura mi ni pe ki alaafia Ọlọrun ti o kọja gbogbo oye eniyan ma a fi igba gbogbo jọba ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti yoo jẹ ki alaafia Ọlọrun jọba ninu aye rẹ ni ki o fi tọkan-tọkan tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ awọn adari ti O yan le ọ lori ninu ijọ rẹ. Ni igba kan ti Jesu Oluwa wa n ran awọn ọmọ ẹyin rẹ lati lọ waasu, O sọ eyi fun wọn:

“Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi. Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin. Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.” (Lúùkù 10:5-7)

Ki ni yoo jẹ ki alaafia awọn iranṣẹ Kirisiti sọkalẹ sori awọn ti wọn n waasu si ati ti wọn n gbadura fun? Iha ti awọn eniyan naa ba kọ si wọn ni! Iha wo si ni o yẹ ki wọn kọ si wọn? Nṣe ni o yẹ ki wọn fi tọkan-tọkan tẹwọgba wọn ati iṣẹ iranṣẹ wọn.

Bawo wa ni a ṣe le fi han pe a tẹwọgba enikan ati iṣẹ iranṣẹ ẹni naa tọkan-tọkan? Akọkọ, a le ṣe eyi nipa mimu ọrọ Ọlọrun ti ẹni naa n kọ wa ni ọkunkundun. Ti a ko ba mu ọrọ Ọlọrun ti ẹni naa n kọ wa ni ọkunkundun, a ko le sọ wipe a tẹwọgba irufẹ ẹni naa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ.

Ekeji, a le fi han pe a tẹwọgba awọn iranṣẹ Kirisiti ti a ran si wa tọkan-tọkan nipa ṣiṣe ‘Amin’ si adura wọn. Bi Jesu ti ṣe fi han wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, gbolohun adura awọn iranṣẹ rẹ ko ni ṣadede ṣiṣẹ ninu aye wa, nitoripe wọn kan gbadura fun wa. Gbolohun adura wa yoo ṣiṣẹ ninu aye wa ni ibamu pẹlu bi a ba ti ṣe fi tọkan-tọkan ṣe ‘Amin’ si adura naa too. Aijẹbẹ, alaafia wọn, alaafia ti o n ba awọn adura wọn fun wa rin ko ni sọkalẹ sori aye wa.

Nitorina, ti o ba ri pe adura awọn adari ijọ rẹ ko ma ṣiṣẹ fun ọ rara tabi to, o le jẹ wipe ọkan rẹ ko tọ si wọn ni. Nse ni ki o wa ba ara rẹ sọrọ lori eyi, ki o si jẹ ki ọkan rẹ wa ni pipe pẹlu wọn lati le ma a fi igba gbogbo ri alaafia wọn gba, alaafia ti o n ba iṣẹ iranṣẹ wọn rin. Aijẹbẹ, wa ijọ miran lati darapọ mọ.

Nkan ikẹta ti yoo fi han pe a tẹwọgba awọn iranṣẹ Kirisiti ti O ran si wa ni ki a ma a fi nkan ini wa gbe wọn ni igbọnwọ. Bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yẹn, Jesu ṣe apejuwe ẹnikẹni ti o ba bọ awọn iranṣẹ rẹ, ti o si tun fun wọn ni ile gbe, gẹgẹ bi ẹni alaafia. Nitorina, ko ki i ṣe nipa ṣiṣe ‘Amin’ si adura awọn adari ijọ wa nikan ni a le gba jẹ ki alaafia Ọlọrun ti wọn n polongo sọkalẹ sori aye wa. A tun le jẹ ki o sọkalẹ sori aye wa nipa titọju wọn. Ibi ti a ba si ti n ṣe eyi, awọn adura ti wọn gba ni kẹlẹkẹlẹ ati ikọkọ paapaa yoo wa wa kan, yoo si ṣe wa loore.

Wayi o, ko si ẹnikẹni ti o le sọ bi iha ti a kọ si awọn iransẹ Kirisiti ti a ran si wa yoo ṣe ran alaafia ati iṣoriire re wa laye to si. Ka nkan ti a sọ lori arabinrin Ṣunemu ti o tọju Eliṣa ati lori bi ṣiṣe eyi ṣe ran idile rẹ lọwọ (2Àwọn Ọba 4&8). Eyi yoo la ọ lọyẹ lori bi alaafia Ọlọrun ti awọn iranṣẹ rẹ n pe sinu aye wa nipasẹ awọn iṣẹ iranṣẹ wọn ṣe le yi itan aye wa pada titi lailai. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun fun ọkan rẹ ni okun lati bẹrẹ si ni mu ọrọ yi ni ọkunkundun, ki ọkankan ninu awọn ohun rere ti O fẹ ki O ni laye yi ma ba a fo ọ ru, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *