Àwọn ọlọ́lá Tẹ́kóà | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Sẹrẹ 18, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, oṣu Sẹ́rẹ́ 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n di ọ lọwọ lati wulo fun un, ki o ma ba padanu ipo rẹ tabi ere rẹ ninu ijọba rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ru ọkunrin kan ti a n pe ni Nehemáyà soke ni asiko kan lati dari awọn eniyan Juda lati tun odi Jerusalẹmu mọ. Nigba ti o si ba wọn eniyan yi sọrọ nipa rẹ, gbogbo wọn bẹrẹ si ni ṣiṣẹ, ẹnikọọkan n ṣe iṣẹ yi ni ibi ti o ti sunmọ-ọn ju. Ki ni idi? Idi ni pe iṣẹ yi pe gbogbo wọn – iṣẹ yi wa fun anfaani gbogbo awọn eniyan Juda. (Wo: Nehemáyà 2&3)

Amọ ṣa o, awọn kan laarin wọn kọ lati darapọ mọ wọn lati ṣe iṣẹ yi. Wo nkan ti a sọ nipa wọn:

“Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.” (Nehemáyà 3:5)

Ki ni idi ti awọn ọlọla Tẹkoa ko ṣe darapọ mọ awọn yoku lati tun odi Jerusalẹmu mọ? A ko fun wa ni idahun kankan si eyi ninu akọsilẹ naa. O le je igberaga ni o fa a. Tabi kẹ, o le jẹ wipe awọn naa n jere lati ara bi nkan ti ṣe ri fun odi yi ni asiko naa, ki wọn ma a jere lati ara idamu awọn eniyan wọn. A ko mọ idi ni pato.

Amọ ṣa o, a mọ odi Jerusalẹmu, a si tun pari rẹ ni kiakia, laarin ọjọ meji-le-ni-aadota (Nehemáyà 6:15). A pari awọn odi yi, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọta awọn eniyan Juda n gbogun ti wọn. Bẹẹni, a mọ awọn odi yi tan lalai si ọwọ awọn ọlọla Tẹkoa nibẹ. Ṣugbọn yoo wa ninu akọsilẹ titi lailai pe nigba ti awọn eniyan Ọlọrun n ṣiṣẹ lati tun odi ilu Ọlọrun, Jerusalẹmu, mọ ati lati fi opin si iriri ẹgan ti wọn n ni, awọn ọlọla Tẹkoa ko kopa nibẹ.

Wayi o, ẹkọ wo ni a ri kọ lati ara eyi? Ohun naa ni pe yala a dara mọ awọn eniyan Ọlọrun yoku, paapaa julọ awọn ti ijọ wa, lati ṣe iṣẹ Ọlọrun tabi a ko dara pọ mọ wọn, iṣẹ rẹ yoo jẹ ṣiṣe. Lotitọ, o le ni oniruuru idi tabi awawi lati ma ko ipa tirẹ ni ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun. Iṣẹ rẹ yoo jẹ ṣiṣe, sibẹsibẹ. Amọ yoo wa ninu akọsilẹ pe o ko yọju nigba ti awọn yoku n ṣe iṣẹ rẹ.

Ṣe Ọlọrun, yoo wa pin ọ lere fun iṣẹ ti o ko ṣe fun un bi? Rara o! Nitorina, gbe gbogbo awawi ti o n ṣe lati ma ko ipa tirẹ ni ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun ju sọnu, ki o si bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ naa tọkan-tọkan. Njẹ ki O ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe iṣẹ rẹ ni ọna ti yoo gba pin ọ ni ere. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *