Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹ́nà 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu ki ọsẹ naa dara jọjọ fun iwọ ati idile rẹ. Amin.
Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati jẹ ẹnikan ti yoo ma fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ni ayika rẹ ni iwuri lati ṣe ifẹ rẹ nipa ọrọ ati iṣe rẹ. Wo o, nkan ti awọn eniyan kan nilo lati fi ara wọn jin lẹkunrẹrẹ fun ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ko ju ọrọ iwuri lati ẹnu ẹnikan lọ. Bẹẹ si ni, nkan ti awọn elomiran nilo lati wa awawi lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun ko ju ẹnikan ti yoo ko irẹwẹsi ba wọn, yala nipa ọrọ tabi iṣe rẹ. Ti o ba wa fi aaye gba eṣu lati lo ọ lati ko irẹwẹsi si ba ẹnikẹni lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun, mo daju pe Ọlọrun yoo ba ọ wi ni ibamu pẹlu nkan ti o ṣe.
Fun apẹrẹ, nigba ti o ku diẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli wọ Ilẹ Ileri, lẹyin igba ti wọn ti ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun, awọn ara Rubẹni ati awọn ara Gaadi wa sọdọ Mose pẹlu ẹbẹ kan. Oun naa si ni pe ki o gba wọn laaye lati ma sọda odo Jọdani si ilẹ awọn ara Kenani. Ki ni idi? Idi ni pe ibi ti o wa ṣaaju Jọdani dara pupọ fun awọn nkan ọsin. Awọn si wa ni agbo aguntan ati maalu ti o pọ. (Wo: Númérì 32:1-5)
Iha wo wa ni Mose kọ si ẹbẹ wọn? Wo nkan ti a kọ lori eyi ninu bibeli:
“Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi? Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn? Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na.” (Númérì 32:6-8)
Njẹ o ri bayẹn? Mose sọ fun awọn eniyan wọnyi pe nkan ti wọn ṣe jẹ nkan ti yoo ko irẹwẹsi si ba ọkan awọn ọmọ Isiraẹli yoku lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun nipa sisọda Jọdani lati gba Ilẹ Ileri. O tilẹ fi asiko yi ran wọn leti pe idi ti gbogbo wọn ṣe ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun ni pe awọn obi wọn ko irẹwẹsi ba ara wọn lati ma gba Ilẹ Ileri naa. Awọn ara Rubẹni ati awọn ara Gaadi yi wa nilo lati fi da Mose loju pe awọn yoo kọkọ sọda Jọdani lati ran awọn ọmọ Isiraẹli yoku lọwọ lati gba Ilẹ Ileri ki awọn to pada wa do si ilẹ ti ara wọn ki o to di pe o tẹwọgba ẹbẹ wọn.
Ki ni eyi n kọ wa? Oun naa ni pe Ọlọrun ko ki i fi oju rere wo ẹnikẹni ti o ba n fi irẹwẹsi si ọkan awọn miran lati ma ṣe ifẹ rẹ. Dipo bẹẹ, nṣe ni O ma n ṣe idajọ wọn. Niwọn igba ti a ko wa le sọ ọna ti yoo gba ṣe idajọ wa ti a ba lọ ko irẹwẹsi ba ẹnikẹni lati ma ṣe ifẹ rẹ, a ni lati kiyesara lati ma jẹ idi ti ẹnikẹni ko fi ni ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ tabi jẹ igbadun ipese rẹ fun aye wọn nipa ohun ti a n sọ tabi ṣe. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ma a fi igba gbogbo ran wa lọwọ lati wuwa ni ibamu plẹu awọn nkan wọnyi. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)