Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹ́nà 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣe ọ ni onirẹlẹ ati oniwapẹlẹ ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn ti o wa ni ayika rẹ, ki o ma ba sọ tabi ṣe ohunkohun si wọn ti yoo fi ọ si abẹ idajọ rẹ. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ọkan lara awọn nkan ti o ma n jẹ ki a bọ si abẹ idajọ Ọlọrun ni ki a ma fi ẹnu tẹnbẹlu awọn miran. Lotitọ, ko si ẹni ti o peye to ni iwuwasi ni aye yi. Ọlọrun nikan ni Ẹni naa ti O peye. Nitorina, awọn eniyan le ṣe aṣiṣe. Nibi ti eyi ba si ti ri bẹ, o di dandan ki a gbe igbesẹ lati fi nkan ti o tọ han wọn.
Amọ ṣa o, yala awọn eniyan ṣe aṣiṣe nitootọ tabi a kan ro wipe wọn ṣe aṣiṣe ni, ọna ti a gba da si ọrọ wọn ni yoo sọ boya wọn yo gbọ ti wa tabi wọn ko ni gbọ. Oun naa ni yoo tun sọ boya a o gba oriyin lọdọ Ọlọrun tabi a ko ni i gba a.
Fun apẹrẹ, nigba ti awọn ọrẹ Joobu wa si ọdọ rẹ ni asiko inira rẹ, o ro wipe wọn wa lati tu u ninu ni. Ṣugbọn dipo ti wọn yoo fi tu u ninu, nṣe ni gbogbo wọn pada n fi ẹnu tẹnbẹlu rẹ, ti wọn n fi ẹsun kan pe o ṣe awọn nkan ti ko ṣe. Ṣe o wa gbo ti wọn? Rara o, ko gbọ ti wọn. Ṣe o tẹwọgba gbogbo irọ ti wọn n pa mọ-ọn? Rara o, ko tẹwọ gba a. (Wo: Jóòbù 2:11-13)
Ki ni idi ti Joobu ko ṣe gbọ ti wọn? Akọkọ, idi ni pe wọn ko wadi daju awọn iroyin buburu ti wọn gbọ nipa rẹ ki wọn to ma fi ẹsun kan pe o n wuwa ika. Idi keji ni pe gbogbo wọn ni wọn n sọrọ kobakungbe si dipo ọrọ itunu, ti wọn ko si tilẹ kọbiara si pe o wa ninu iroro ti o ga ati wipe o ti padanu gbogbo awọn ọmọ rẹ ati ọrọ̀ rẹ. Nitorina, ki a tilẹ sọ wipe otitọ ni ọrọ wọn, ko si bi ẹni ti o wa ninu irora bi tirẹ yoo ṣe tẹti gbọ awọn ọrọ kobakungbe ati ibanininujẹ ti wọn n sọ si.
Wayi o, bawo wa ni Ọlọrun ṣe da si ọrọ naa? O da si pẹlu ibinu. Ta si ni O binu si? Awọn ọrẹ Joobu ni! Ki ni idi? Akọkọ, idi ni pe wọn ṣi imọ rẹ ti wọn ni lo lati fẹnu tẹnbẹlu Joobu. Idi keji ni pe wọn ko tu ọkunrin na lara rara; nṣe ni wọn tun dakun irora rẹ. Bi Ọlọrun ṣe wa sọ fun wọn, wọn nilo lati lọ bẹ ẹ fun iforiji ati adura. Aijẹbẹ, ibinu rẹ yoo wa sori wọn. (Wo: Jóòbù 42:7-9)
Nibakanna, ibinu Ọlọrun le sọkalẹ si ori ẹnikẹni ninu wa fun fifi ẹnu tẹnbẹlu awọn miran. Wo o, Ọlọrun n wo gbogbo awọn ibaṣepọ wa lati ri bi a ti ṣe n ṣe ninu wọn. Ibi ti O ba si ti ri pe a n fi ailakasi wu aye tabi igbagbọ awọn miran lewu pẹlu ọrọ wa, ko ni fi oju fo. Lotitọ, ninu aanu rẹ, O le pe akiyesi wa si aṣiṣe wa, bi O ti ṣe ṣe fun awọn ọrẹ Joobu, ki a ba a le ronupiwada, ki a si ṣe ohun ti o tọ. Ṣugbọn O tun le pinnu lati ṣe idajọ wa lalai kilọ fun wa rara, bi O ti ṣe ṣe idajọ Miriamu ati Aarọni fun bi wọn ti ṣe fẹnu tẹnbẹlu Mose nigba kan. (Wo: Númérì 12)
Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ko si nkan ti o buru ninu ki a fi aṣiṣe awọn eniyan han wọn ti wọn ba ṣe aṣiṣe, a nilo lati ri daju pe a ko ṣe eyi lori awọn nkan ti a ko i ti ṣe iwadi wọn daju. Yatọ si iyẹn, a tun nilo lati kọ bi a ti ṣe n fẹsọ ba awọn eniyan wi, ti a ba tilẹ mọ daju pe wọn ti ṣe aṣiṣe. Aijẹbẹ, nkan ti o yẹ ki o jẹ ọrọ ibawi le di ọrọ ifẹnu-tẹnbẹlu ẹni. Eyi si le ma mu ete ti o wa ni ọkan wa ṣẹ. Dipo bẹ ẹ, o tilẹ tun le fi wa si abẹ idajọ Ọlọrun. Njẹ ki Ọlọrun ma jẹ ki a fi iwa omugọ fi ara wa si abẹ idajọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)