Ohun gbogbo wà ní àkọsílẹ̀ | Láti ọwọ́: Ọmọtọla Dunsin Babarinde | Ọjọ́: Okudu 14, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 07

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òkúdù 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ma a fi ojoojumọ gbe aye pẹlu afiyesi pe a o ṣe idajọ ọrọ rẹ ati iṣẹ ọwọ rẹ ni ọjọ kan, ki o ba a le fi ara rẹ jin lati ma a gbe igbe aye ti o buyi kun un. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ inu bibeli ti o sọ pe:

“Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” (Málákì 3:16)

Ki ni eyi n sọ fun wa? Oun naa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ ohun gbogbo ti a n ṣe. Gbogbo ọrọ wa, iṣe wa, ẹbọ tabi ifarada wa, adura wa ati iṣẹ isin wa ni O n ri, ti ko si le e gbagbe. Ọpọ ni o lero wipe niwọn igba ti awọn eniyan ko ti ri awọn nkan ti wọn n ṣe, ohun yowu ti wọn ba ṣe ko ja mọ nkankan. Ṣugbọn bibeli kọ wa pe Ọlọrun ri ohun gbogbo ati wipe yoo mu ohun gbogbo wa si abẹ idajọ.

Oníwàásù 12:14 sọ wipe, “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.” Eyi ja si pe ati iṣẹ rere wa ati iṣẹ ti ko dara wa ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Ko si nkankan ti oju rẹ foru.

Lafikun, Mátíù 12:36 sọ wipe, “Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.” Njẹ o ri bayẹn? Gbogbo ọrọ ti a n sọ ni o wa ninu akọsilẹ. Nitorina, awọn onigbagbọ gbọdọ ṣọra ṣe pẹlu ọrọ, iwa ati ibaṣepọ wọn pẹlu awọn miran. Idi si ni pe a o mu wọn jiyin rẹ ni ọjọ kan.

Iroyin ayọ wa ni pe Ọlọrun n ṣe akọsilẹ iṣododo, adura, ififunni ati laala wa ninu ijọba rẹ naa pẹlu. Hébérù 6:10 sọ wipe, “Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀…” Nitorina, ti o ba n ti sin Ọlọrun lotitọ, ti o si dabi ẹni pe awọn eniyan ko ka ọ si, ma jẹ ki o su ọ. Ohun gbogbo ni o wa ninu akọsilẹ niwaju Ọlọrun. Yoo si pin gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ti o jẹ olododo lere ni asiko tirẹ.

Niwọn igba ti ohun gbogbo si wa ni akọsilẹ bi eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma a gbe igbe aye iwa mimọ, ki a ma a sin Ọlọrun pẹlu ọkan ti o tọ, ki a si duro ṣinṣin gẹgẹ bi olododo. Ọlọrun ti o n ṣe akọsilẹ iṣẹ gbogbo ko ni ṣalai pin gbogbo awọn olododo lere, ki o si ṣe idajọ iṣẹ kọọkan ni ibamu pẹlu idajọ-ododo rẹ ti o peye.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *