Fífi ìgbàgbọ́ rẹ hàn bí ojúlówó | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Agẹmọ 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 13

Olufẹ: Ki oore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o gbẹyin ninu oṣu Agẹmọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ri daju pe igbagbọ rẹ ko yẹ bi o ti wu ki awọn nkan ti Satani n ju si ọ ti to, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara nkan ti a ri ninu Iwe mimọ ni pe Ọlọrun, lati igba de igba, ma n fi aaye gba Satani lati dan awọn ọmọ rẹ wo. Eyi ko si ni i ṣe pẹlu ki wọn ba a le kuna. Dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu fifi igbagbọ wọn han ninu rẹ gẹgẹ bi ojulowo, ki a ba a le fi ogo fun nipasẹ iduro ṣinṣin wọn. (Wo: 1Pétérù 1:6-7)

Fun apẹrẹ, ọkan lara awọn idi ti Ọlọrun fi fi aaye gba Satani lati dan Joobu wo ni ki o le han kedere si Satani pe ojulowo ni igbagbọ Joobu ninu rẹ, ko ki i ṣe ofege. Ṣaaju idanwo yi, Satani ti sọ fun Ọlọrun pe idi ti Joobu fi jẹ olododo si ni pe o n jẹ igbadun ibukun ati aabo rẹ. Eyi jasi pe, ti Ọlọrun ba mu aabo Joobu kuro, ti O si fi aaye gba Satani lati pọn-ọn loju, ko ni sin Ọlọrun mọ – nṣe ni yoo bẹrẹ si ni gbe ṣepe. (Wo: Jóòbù 1&2)

Bawo wa ni Ọlọrun ṣe fẹ fi han Satani pe nkan ti o ro nipa Joobu ko ri bẹ ẹ? Nipa fifi aaye gba a lati dan-an wo ni. Ṣe Joobu wa kuna bi? Rara o, ko kuna. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun pa a mọ. Ọlọrun ko jẹ ki Satani dan-an wo kọja nkan ti o le farada. Lafikun, Ọlọrun fun ni okun lati farada idanwo naa.

Nibakanna, Ọlọrun le pa awa naa mọ nigba ti eṣu ba n dan wa wo. Lọna wo? Lakọkọ, gẹgẹ bi O ti ṣe fun Joobu, ko ni gba ki a dan wa wo kọja agbara wa. Ekeji, yoo ṣe wa yẹ pẹlu ohun gbogbo ti a nilo lati rin ni iṣẹgun lori awọn idanwo Satani. (Wo: 1 Kọ́ríntì 10:13)

Sugbọn awa naa gbọdọ kọ iha ti o tọ si awọn idanwo tabi idojukọ ti o n tọ wa wa. Lọna wo? Akọkọ, a ko gbọdọ lero wipe a le bori wọn nipa ọgbọn tabi ilakaka wa. Aijẹbẹ, a o jọ ara wa loju gẹgẹ bi Peteru ti ṣe jọ ara rẹ loju nigba ti o ṣẹ Jesu. Ekeji, a gbọdọ gbẹkẹle Ọlọrun patapata fun gbogbo nkan ti a nilo, pẹlupẹlu suuru, lati bori gbogbo idanwo wa. Ẹkẹta, a gbọdọ ma a fi igba gbogbo ran ara wa leti wipe olododo ni Ọlọrun, Ẹni ti ko ni jẹ ki a dan wa wo kọja nkan ti agbara wa le gbe ṣugbọn ti yoo gbe wa ro ni gbogbo asiko idanwo naa.

Wayi o, ibi ti awọn eniyan ko ba ti ni oye yi lati le ṣe amulo rẹ, nigba ti eṣu ba n dan wọn wo, o ṣeeṣe ki wọn bẹrẹ si ni kun si Ọlọrun tabi ki wọn bẹrẹ si ni gboju le ẹran ara fun nkan ti o jẹ wipe Ẹmi Ọlọrun nikan ni O le ṣe. Eyi yoo si ja si iṣubu fun wọn, ti a ko ba ṣaanu fun wọn. Nitorina, bi o ti wu ki awọn nkan ti Satani n gbe ko ọ loju ri, yala wọn tobi ni tabi wọn kere, fi awọn nkan wọnyi si ọkan lati ṣiṣẹ tọ wọn. Dipo ki oju ki o si ti ọ, nṣe ni a o jẹ ki o ni iriri awọn asiko itura ati imupadabọsipo ti o ga lati ọdọ Oluwa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *