Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati aanu jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olurapada wa. Mo ki ọ pẹlu ayọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, iyẹn oṣu Agẹmọ 2025. Adura mi ni pe ki ibukun kọọkan ti o ti gba lọfẹ lati ọwọ Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye rẹ ninu ọsẹ naa lati jẹ ki o tayọ ninu ohun gbogbo ti o ba n ṣe. Amin.
Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu awọn ọrọ inu Iwe mimọ yi:
“Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà.” (Ìsíkíẹ̀lì 34:26)
Gbogbo ọmọ Ọlọrun ni o nifẹ lati ma a ni iriri awọn ibukun rẹ ninu aye wọn. Amọ ṣa o, ileri Ọlọrun kọja ki O kan fun wa ni ibukun diẹ ranpẹ; o ni i ṣe pẹlu ki O rọ ojo ibukun sori wa – ibukun yanturu, ibukun ti o n ṣan bi odo ati ibukun ti o bọ si asiko. Gẹgẹ bi ojo ti ma n sọ ilẹ-gbigbẹ di ọtun, ti yoo si mu eso wa, bẹẹ gẹgẹ ni ibukun Ọlọrun a ma a mu isọdọtun, imupadabọsipo ati ibisi ba gbogbo abala aye awọn ẹniyan.
Ki wa ni a n pe ni ojo ibukun? Akọkọ, a ni ibukun nipa ti ẹmi. Awọn ibukun wọnyi a ma a tọ wa gẹgẹ bi igbala ati idarij-ẹṣẹ, ẹbun Ẹmi Mimọ ati eso Ẹmi, ti yoo si yọri si idagbasoke nipa ti ẹmi. Ranti pe Jesu Oluwa wa, ninu Jòhánù 7:38-39, ṣeleri awọn odo omi iye fun gbogbo awọn ti o ba gbagbọ ninu rẹ. Awọn wọnyi ni odo Ẹmi Mimọ. Awa ti a si ni Ẹmi yi ninu aye wa ti ni awọn odo ibukun rẹ ninu aye wa lati ma ṣan ninu wa ati nipasẹ wa.
Siwaju si, a tun ni awọn ibukun nkan ti a le fojuri. Ọlọrun a ma a pese fun awọn aini awọn ọmọ rẹ, nipa ṣiṣi oniruuru ilẹkun fun igbega, ilọsiwaju ati igbaye-gbadun wọn. Idi ni yi ti Pọọlu fi sọ ninu iwe Fílípì 4:19 pe, “Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.”
Ni afikun, a tun ni awọn ibukun imupadabọsipo. Ọlọrun a ma da nkan ti o sọnu pada. O ma n yi ibanujẹ pada si ayọ. Jóẹ́lì 2:25 sọ wipe, “Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ…” Nitorina, bi awọn ibukun Ọlọrun ba ti n ṣiṣẹ ninu aye wa, a le reti pe ki O mu awọn nkan ti a ti sọnu padabọsipo fun wa.
Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ibukun Ọlọrun wa nilẹ ni kiakia ati lọfẹ fun gbogbo eniyan, awọn nkankan wa ti awọn eniyan naa gbọdọ ṣe lati ri wọn gba ati lati jẹ igbadun wọn. Ki ni awọn nkan wọnyi? Akọkọ, awọn eniyan gbọdọ ronupiwada, ki wọn si yipada si Ọlọrun. Ẹṣẹ a ma di riri awọn ibukun Ọlọrun gba ati ifarahan wọn lọwọ. (Wo: Àìsáyà 59:1-2)
Ekeji, a gbọdọ gbọran si ọrọ Ọlọrun. Igbọran si Ọlọrun a ma n mu ojurere rẹ wọ tọ eniyan (Ditarónómì 28:1-2). Ẹkẹta, a gbọdọ jẹ olotitọ ni sinsin Ọlọrun. Ọlọrun a ma a san awọn ti o n farabalẹ wa ati sin-in lẹsan (Hébérù 11:6). Ẹkẹrin, a gbọdọ ma a gbe igba aye igbagbọ. Gba ileri Ọlọrun gbọ, ki O si tun dirọ mọ wọn, bi o ko tilẹ ti ri wọn soju (Hébérù 6:12).
Ni akotan, bi o ti wu ki o dabi ẹni pe ọrọ aye rẹ gbẹ to lọwọlọwọ yi, Ọlọrun lagbara lati jẹ ki o ni iriri awọn ojo ibukun rẹ ni ojoojumọ. Nitorina, gbẹkẹle, duro ṣinṣin ninu otitọ, si tẹsiwaju lati ma a rin ninu igbọran. Ọlọrun kanna ti o ṣeleri ojo ibukun jẹ olotitọ lati mu ọrọ rẹ ṣẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki gbogbo abala aye rẹ ti o gbe ni iriri ojo ibukun rẹ ti o ga, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)