Ó ṣí wọn ní ìyè | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 13, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 20

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2026. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun, nipasẹ Ẹmi rẹ ti O n gbe inu wa, ma a fi ojoojumọ kun ọkan rẹ pẹlu oye ete, eto ati ipese rẹ fun ọ lọna ti o peye, ki o ba a le da ohun gbogbo ti O fẹ ki o da laye yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Lẹyin ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa, O bẹrẹ si ni fi ara rẹ han ọmọ ẹyin rẹ ni oniruuru ibi ati ni oniruuru akoko. Lara awọn akoko naa ni O ti sọ awọn nkan melokan fun diẹ lara awọn ọmọ ẹyin wọnyi nipa ara rẹ, gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu Iwe mimọ. Ṣugbọn fun wọn lati ni oye nkan ti O n fi han wọn lati inu Iwe mimọ, wọn nilo ki a ṣi wọn ni iye. Nkan ti Luuku sọ lori eyi niyi:

“O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi. Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn,” (Lúùkú 24:44-45)

Njẹ o ri bayẹn? Jesu Oluwa wa ṣi awọn ọmọ ẹyin rẹ ni iye ki wọn ki o ba a le ni oye nkan ti O n fi han wọn ninu Iwe mimọ. Eyi jasi pe a ko le lailai ni oye Iwe mimọ ti Ọlọrun funrarẹ ko ba i ti ṣi iye wa lati ni oye rẹ. Ti a ko ba si ni oye rẹ, a ko ni le gbe aye wa ni ibamu pẹlu ete, eto ati ipese Ọlọrun fun wa lọna ti o peye.

Jesu le e gbe aye rẹ lọna ti o peye ni ibamu pẹlu ete, eto ati ipese Ọlọrun fun un nitoripe O ni oye Iwe mimọ ati nkan ti o ṣọ nipa rẹ. Bi Luuku si tun ṣe sọ fun wa, nigba ti O n ba meji lara awọn ọmọ ẹyin rẹ sọrọ lẹyin ajinde rẹ, Jesu sọ fun wọn nipa ete, eto ati ipese Ọlọrun lori rẹ fun wọn lati inu Iwe mimọ, bẹrẹ lati ori Mose ati gbogbo awọn wolii. Bi O si ṣe n sọ awọn nkan wọnyi fun wọn, nṣe ni ọkan wọn n gbina ninu wọn. (Wo: Lúùkù 24:13-32)

Ki wa lo fa ti o ṣe ṣeeṣe fun Jesu lati ba awọn ọmọ ẹyin wọnyi sọrọ nipa ara rẹ lati ipasẹ Iwe mimọ? Idi ni pe O ni oye Iwe mimọ lọna ti o peye. Bawo ni O si ṣe ni oye rẹ lọna ti o peye? Nipasẹ Ẹmi Mimọ ni!

Nibakana, awa naa le ni oye ete, eto ati ipese Ọlọrun fun wa lati ipasẹ Iwe mimọ. Ṣugbọn Ẹmi Mimọ yoo nilo lati ṣi wa ni iye ki eyi to le ṣelẹ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe ṣi awọn ọmọ ẹyin rẹ ni iye ki wọn ki o le ni oye Iwe mimọ. Aijẹbẹ, a le ma ṣi nkan gbe si ara wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a n kẹkọ ninu Iwe mimọ pẹlu ifarajin ti o ga, ki a si tun bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti o lodi si ete, eto ati ipese rẹ fun wa. Eyi ko si ni suwọn fun wa rara.

Ranti wipe awọn ti o n fi ojoojumọ kẹkọ ninu Iwe imọ lati wadi ẹni ti yoo jẹ Mesaya wọn ati asiko ti yoo tọ wọn wa ni o kan Jesu mọ agbelebu. Ki wa ni ko jẹ ki wọn da Jesu mọ gẹgẹ bi Mesaya wọn? Idi ni pe a ko ṣi wọn ni iye lati ni oye Iwe mimọ ti wọn n kẹkọ ninu rẹ. (Wo: Ìṣe Àpósítélì 13:27)

Nitorina, ko to lati ma a kẹkọ ninu Iwe mimọ; o tun ṣe pataki ki Ọlọrun ṣi wa ni iye lati ni oye nkan ti o n sọ. Aijẹbẹ, nkan ti a n kẹkọ le lori ninu rẹ ko ni ṣe wa ni anfaani. Adura mi wa ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ ṣi ọ ni iye lati ni oye ọrọ rẹ ni igbakigba ti o ba n gbọ, ka a, kẹkọ ninu rẹ tabi ṣaṣaro ninu rẹ, ki gbogbo ete ati eto rẹ fun aye rẹ le jẹ mimuṣẹ. Amin.

Kí o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *