Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Òwewè 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ jẹ olotitọ si titi lailai, ki o ba a le tẹsiwaju lati ma jẹ igbadun didara rẹ ni orilẹ alaye. Amin.
Bi a ti ṣe fi han wa ninu bibeli, ọkan lari idi ti Ọlọrun fi kọ Sọọlu ni ọba lori Isiraẹli ni pe o lagidi, o si tun gberaga. Lotitọ, o ṣe awọn aṣiṣe kan. Ṣugbọn ko si ẹni ti ko le ṣe aṣiṣe. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe gbogbo wa ni a ma n kọsẹ ni ọna pupọ. (Wo: Jákọ́bù 3:2)
Nitorina, Ọlọrun ko kọ Sọọlu ni ọba nitoripe o kan ṣe awọn aṣiṣe melokan nikan. Dipo eyi, O kọ ọ nitoripe o lagidi, o si tun gberaga. Ti ko ba lagidi, ti ko si tun gberaga ni, nṣe ni ko ba wa oju Ọlọrun fun idariji awọn aṣiṣe ti o ṣe. Niwọn igba ti Ọlọrun si jẹ Ọlọrun alaanu, nṣe ni ko ba forijin, ki a sọ wipe o wa oju rẹ fun idariji awọn ẹṣẹ rẹ.
Ṣugbọn Sọọlu jẹ alagidi ati onigbera eniyan. Nitorina, ko ṣetan lati wa oju Ọlọrun fun idariji awọn ẹṣẹ rẹ. Dipo eyi, nṣe ni o n ṣe bi igba ti o jẹ wipe aigbọran rẹ si Ọlọrun ko ja mọ nkankan. Nitorina, Samuẹli, eniyan Ọlọrun ti o yan-an gẹgẹ bi ọba lori Isiraẹli, yago fun patapata. Iwọ naa wo nkan ti a sọ ninu bibeli lori eyi:
“Samueli si lọ si Rama; Saulu si goke lọ si ile rẹ̀ ni Gibea ti Saulu. Samueli kò si tun pada wá mọ lati wo Saulu titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀: ṣugbọn Samueli kãnu fun Saulu: o si dùn Oluwa nitori on fi Saulu jẹ ọba lori Israeli.” (1 Sámúẹ́lì 15:34-35)
Njẹ o ri bayẹn? Lẹyin igba ti Samuẹli ti ba Sọọlu wi tan lori aigbọran rẹ si Ọlọrun lẹẹkeji, ko wa lati bẹ ẹ wo mọ. O si wa ṣeni laanu pe Sọọlu naa ko gbe igbesẹ lati wa Samuẹli lọ mọ titi ọjọ ti o fi ẹ mu Dafidi ni ọdọ Samuẹli. Ki ni idi? O woye pe oun ko nilo eniyan Ọlọrun naa mọ. O woye pe oun le da ṣe iṣakoso ijọba naa ṣe funra oun, lalai nilo itọni Ẹmi ti Samuẹli mọ. (Wo: 1 Sámúẹ́lì 19:18-24)
Njẹ ki ni ka pe iyẹn? Igberaga ati agidi ni. Nitori igberaga ati agidi Sọọlu yi, o pada wa iṣẹ-oṣo lọ fun itọna ni igba ti opin ijọba rẹ sumọn etile. Eyi naa si ni ọna ti o gba pa ara rẹ run patapata lalai si atunṣe. (Wo: 1 Sámúẹ́lì 28)
Nibakana, a ri ọpọ ninu ijọ loni ti wọn kun fun igberaga ati agidi bi Ọba Sọọlu. Awọn naa ko ni gba ibawi tabi itọni kankan ti o wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun. Ti wọn ba si ri wipe o ko ni fi aaye gba wọn lati ṣe bi o ti ṣe wu wọn, wọn yoo ba kuku jina rere si ọ patapata. Nitorina, ọ tẹ wọn lọrun ki wọn ma lọ si oniruuru ijọ awọn Kirisitiẹni ju ki wọn duro sinu ijọ kan nibi ti a o ti le ṣamojuto wọn ati dari wọn ninu ifẹ Ọlọrun.
Ibanujẹ ni o wa jẹ pe nkan ti irufẹ awọn eniyan wọnyi ko loye rẹ ni pe ko si ni ki igbẹyin ti wọn naa ba fẹrẹ dabi ti Sọọlu. Awọn naa, niwọn igba ti wọn ko ni tẹwọgba itọni Ẹmi, yoo fẹrẹ pari irinajo wọn sinu ibọriṣa. Idi si ni pe nigba ti wọn ba nilo iranwọ Ọlọrun pẹlu ikanju, ko ni da wọn lohun. Ko si ni da wọn lohun nitoripe, bi Ọba Sọọlu, wọn ko ni wa a pẹlu ọkan otitọ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn nilo iranwọ rẹ pẹlu ikanju.
Nitorina, ti o ba n wuwa agidi ati igberaga si awọn ti Ọlọrun yan lati dari rẹ nipasẹ ti Ẹmi, nṣe ni ko yara tete tun ọna rẹ ṣe ki o to pẹ ju. Aijẹbẹ, agidi ati igberaga rẹ ko ni gba kiki ipese Ọlọrun kuro lọwọ rẹ, o tun le jẹ ki o padanu ọkan rẹ. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.
Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)