Kí ni ìdí tí a o ṣe lọ síbòmíràn | Láti ọwọ́ J.O. Lawal | Ọjọ́: Òwewè 27, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìli Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 22

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Òwewè ati Ọ̀wàrà ọdun 2026 mọ ara wọn. Adura mi ni pe ki Ọlọrun jẹ ki igbagbọ rẹ ninu rẹ wa ni iduro-ṣinṣin titi de opin, bi o ti wu ki awọn ipenija ti iwọ yoo koju ninu irin rẹ pẹlu Jesu Oluwa ri, ki o ba le gba oriyin rẹ lẹyin ohun gbogbo. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ti igbagbọ wa ninu Jesu Oluwa yoo ba jẹ eyi ti Ọlọrun yoo pin wa lere fun ninu ijọba ayeraye rẹ, o ni lati jẹ igbagbọ lati ibẹrẹ de opin. Ki eyi si to le waye, a ni lati dirọ mọ ọrọ rẹ, bi a tilẹ ri awọn ibi ti ko ti ye wa tabi ibi ti o ti mu wa binu. Idi si ni pe ọrọ rẹ ni otitọ (Jòhánù 17:17)

Wayi o, nitoripe ọrọ Oluwa jẹ otitọ, titẹwọgba ati didirọmọ nikan ni ọna ti irọ eṣu, irọ ẹran-ara ati irọ aye yi ko fi ni le pa wa run. Bẹẹni, nipa titẹwọgba ati didirọmọ ọrọ rẹ nikan naa ni ọna ti ete Ọlọrun fi le jẹ mimuṣẹ ninu aye wa lẹkunrẹrẹ. Njẹ a o wa ma a fi igba gbogbo tẹwọgba ati dirọmọ ọrọ rẹ, bi a ko tilẹ ni oye ọna ti yoo gba ṣe wa ni anfaani tabi bi o tilẹ tako nkan ti o wa ninu ọkan wa?

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ọjọ kan wa ti awọn apọsiteli ti o wa pẹlu Jesu Oluwa ni lati pinnu lori boya wọn yoo dirọmọ ọrọ rẹ, ki wọn si da ẹni ti Ọlọrun fẹ ki wọn da, tabi wọn yoo kọ ọrọ rẹ silẹ, ki wọn si pada si igba aye ti wọn ti n gbe ki wọn to wa si ọdọ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe Oluwa sọ awọn nkan kan ni ọjọ naa ti o bi ọpọ awọn ọmọ ẹyin rẹ ninu. O si wa bi wọn ninu debi wipe wọn dẹkun lati ma a tẹle. (Wo: Jòhánù 6:25-66)

Ṣe O wa sọ nkan kan lọjọ naa ti ko ki i ṣe otitọ ni? Rara o, ko kuku ṣe bẹ ẹ. Ki wa ni idi ti inu fi bi wọn debi wipe wọn pada lẹyin rẹ, ti wọn ko si tẹle mọ? Idi naa ni pe wọn ko ṣetan lati tẹwọgba otitọ ti O n sọ fun wọn, ki wọn si ma a gbe ni ibamu pẹlu rẹ. Bibeli si wa sọ fun wa pe a o ri ọpọ awọn ti wọn n pe ara wọn ni onigbagbọ ti wọn yoo ma a ṣe bakanna ni awọn ọjọ ikẹyin yi. Awọn naa yoo yipada kuro ninu otitọ lati fetisi irọ nitoripe wọn ko fẹ tẹwọgba, ki wọn si gbe aye wọn ni ibamu pẹlu rẹ. (Wo: 2 Tímótì 4:3-4)

Ni kukuru, lẹyin igba ti ọpọ awọn ọmọ ẹyin rẹ ti fi silẹ, a sọ fun wa ninu bibeli pe Oluwa kọju si awọn apọsiteli mejila rẹ lati bere lọwọ wọn boya awọn naa ko ni fi silẹ. Wo akọsilẹ Johanu lori eyi:

“Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi?  Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun.  Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.” (Jòhánù 6:67-69)

Njẹ o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwa funrarẹ lo pe awọn apọsiteli yi lati wa pẹlu rẹ, ko ṣetan lati fi ipa mu wọn lati duro ti i. Dipo eyi, nṣe ni O jẹ ki wọn pinnu funralara wọn boya wiwa pẹlu rẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun, eyi ti o ṣeeṣe ki o bi wọn ninu nigba miran, ṣe iyebiye si wọn tabi ifasiko ṣofo lasan naa.

Bawo wa ni wọn ṣe fọhun si eyi? Kama fọrọgun, Peteru lo dahun fun gbogbo wọn. O si fi ye Oluwa pe awọn ko nibomiran ti awọn n re. Ki ni idi? Gẹgẹ bi o ti sọ, Jesu nikan ni O ni ọrọ iye ainipẹkun ti wọn nilo lati ni iriri imuṣẹ ete Ọlọrun fun aye wọn lọwọ. Ki wa ni idi ti wọn yoo ṣe lọ si ibomiran?

Njẹ ki wa ni idi ti awa naa yoo ṣe lọ si ibomiran, ti a ba ni aridaju pe Jesu Oluwa wa ni ọrọ iye ainipẹkun ti yoo mu ete Ọlọrun ṣẹ ninu aye wa lọwọ? Ki ni idi ti igbagbọ wa ninu rẹ ko ṣe ni jẹ lati ibẹrẹ de opin, ti a ba gba lotitọ pe Oun ni ọna, otitọ ati iye? Lotitọ, ọrọ rẹ le nira nigba miran fun wa lati gba tabi ki o lodi si nkan ti a ti fi gbogbo igba gbagbọ tabi ki o ma wa si imuṣẹ lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn oun ni otitọ ti yoo sọ wa di ominira, ti yoo si jẹ ki aye wa jẹ nkan ti o yẹ ki wọn jẹ.

Ti a ba wa fẹ ki aye wa jẹ nkan ti o yẹ ki wọn jẹ ni otitọ, nṣe ni ki a ma a fi ojoojumọ tẹwọgba ati dirọmọ ọrọ Oluwa si wa, bi o tilẹ jẹ wipe ṣiṣe bẹ ẹ le ma larinrin fun wa. Aijẹbẹ, nṣe ni ki a rọra fi silẹ bi awọn ọmọ ẹyin asiko naa ṣe fi silẹ, ki a si lọ ṣe ohun yowu ti o ba wu wa pẹlu aye wa. Lẹyin ohun gbogbo, gbogbo wa naa ni yoo ri boya a yan-an re tabi a ko yan-an re, bi o tilẹ jẹ wipe yoo ti pẹ ju ni asiko yi lati ṣe atunṣe kankan. Adura mi ni pe a ko ni yan ohukohun ti yoo pada jẹ ki a kun fun abamọ ayeraye, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *