Ọjọ: Okudu 13, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 6
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Okudu 2021. Adura mi si ni pe ki a pa iwọ ati idile rẹ mọ lati ri ire ti Ọlọrun yoo mu wa fun orilẹ-ede yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Dafidi, ninu ọkan ninu awọn orin rẹ, sọ pe, “Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye. Duro de Oluwa; ki o si tuju ka, yoo si mu ọ ni aya le: mo ni duro de Oluwa.” (Saamu 27:13-14) Ki ni igbagbọ ọkunriin yi? Igbagbọ rẹ ni pe yoo ri ire Oluwa ni ilẹ alaaye. Ki si ni idi ti o fi igbagbọ lọna yi? Idi ni pe o n duro de Oluwa ti ko ki i jani kulẹ.
Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, gẹgẹ bi ọdọmọkurin, Dafidi dojukọ inunibini ti o le koko lati ọdọ Sọọlu, ti o jẹ ọba lori Isiraẹli ni akoko ti a n wi yi. Nitorina, oun, awọn jagunjagun rẹ ati awọn ẹbi wọn ni lati ma fi gbogbo igba sa lati ibikan si ibomiran; wọn ko si le gbe aye bi awọn eniyan gidi ṣe n gbe aye. Igba kan tilẹ wa, ẹwẹ, ti a sọ ina si agọ wọn ti wọn n lo fi igba diẹ, ti awọn ara Amaleki si ko gbogbo awọn iyawo ati ọmọ wọn lọ. Eyi si ni awọn jagunjagun lara tobẹẹ gẹẹ ti wọn fi bẹrẹ si ni sọrọ nipa lilẹ ni okuta, nitori wọn woye pe ibaṣepọ wọn pẹlu rẹ ko mu ikankan wa fun wọn ju idamu lọ.
Sibẹsibẹ bibeli sọ pe Dafidi ko ba ọkan jẹ nitori awọn nkan wọnyi. Dipo eyi, o fun ara rẹ ni okun ninu Oluwa, niwọn igba ti O mọ pe o di dandan ki O fun oun ni iṣẹgun ni gbogbo ọna, ki O si tun fi opin si gbogbo awọn ọjọ irinkinri rẹ ni ọjọ kan (1Samuẹli 30:6). Idi ni yi ti o ṣe sọ pe oun ni igbagbọ pe oun yoo ri didara Oluwa ni ilẹ alaye. Ṣe o wa ri tabi ko ri? O ri. O ri didara Ọlọrun ni oju ẹmi rẹ, ko si ki i ṣe lẹyin iku rẹ. Ko kan di ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli nikan, o tun ni oore-ọfẹ ti ko wọpọ lati fi ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ jọba lori ilẹ na ki o to ku.
Ṣugbọn ki lo fa ti Dafidi fi ri didara Oluwa nikẹyinkẹyin ni oju ẹmi rẹ, pẹlu gbogbo iriri buruku ti o ni gẹgẹ bi ọdọmọkunrin? Bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yi, nitoripe o duro de Oluwa dipo ki o sọ ireti nu ni. Oluwa ti yan gẹgẹ bi ọba dipo Sọọlu; O si tun fun ni ọpọlọpọ ileri ti o ga, ti o si tun dara. Ṣugbọn ki o to le ri imuṣẹ awọn nkan wọnyi, o nilo lati fi igbagbọ ati suuru rẹ ninu Oluwa han. Lotitọ, o nilo lati ṣe eyi fun ọdun melokan. Amọ, igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun ati suuru rẹ ko ja si pabo. Nitorina, o wa le sọ fun awọn miran ninu orin rẹ ti o wa loke pe ki awọn naa ṣe bi oun ṣe ṣe, ti wọn ba fẹ ri didara Oluwa ni ilẹ alaye.
Njẹ wọ na fẹ lati ri didara Oluwa ni oju aye rẹ bi? Njẹ iwọ na fẹ wa laye ati lalaafia nigbati Ọlọrun ba dana ṣun aṣọ ẹgan orilẹ-ede yi, ti O si tun wọ ni aṣọ ogo ati iyin? Ẹmi fẹ wa laye ati ni alaafia nigba ti eyi ba ṣẹle. Mo si tun fẹ ki idile mi wa laye ati lalaafia pẹlu nigba ti o ba ṣẹlẹ. Mo si wa ni igbagbọ bi ti Dafidi pe Oluwa ti o dara, ẹni ti o gba wa la kuro lọwọ ẹṣẹ wa, ti O si mu wa wa sinu ijọba ologo rẹ, yoo jẹ ki eyi ri bẹ. Nitorina, irufẹ nkan yowu ti mo le ri tabi gbọ, mi o ni ba ọkan jẹ tabi igbe igbagbọ mi ninu rẹ sọnu. Dipo bẹ, nṣe ni ma mu ọkan le, ti ma si tun duro de e. Bẹẹni, emi o duro de e nitoripe o n ṣe itọju me, O si tun ṣe gbọkanle. Njẹ iwọ naa yoo ha ṣe bakanna bi?
Ki o ni ọṣẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
