ỌJỌRU 16, OKUDU 2021
AYỌKA: 2PETERU 1:20-22
AKỌSORI: AKỌSORI: “Nitori Oluwa Ọlọrun ki o ṣe nnkan kan ṣugbọn o fi ohun ikọkọ rẹ han awọn wolii iranṣẹ rẹ.” (Emọọsi 3:7)
ỌRỌ AKỌSỌ
Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun ti ṣeto awọn kan fun wa ninu ijọ gẹgẹ bi adari, lati pese wa fun iṣẹ iranṣẹ ati lati jẹ ki a dagba soke lati dabi Jesu Kirisiti ni gbogbo ọna (Efesu 4:11-16). Lara awọn ti O ṣi seto fun eyi ni awọn ti a n pe ni wolii. Awọn wo gan wa ni a lẹtọ lati ma pe ni wolii Ọlọrun ninu ijọ loni? Ṣe gbogbo awọn ti a n pe ni wolii loni abi awọn ti o n pe ara wọn ni wolii loni naa ni wolii Ọlọrun? Ti ko ba ki i ṣe gbogbo wọn ni wolii rẹ, bawo ni a ṣe le da awọn wolii tootọ mọ? Ki ni ojuṣe wọn? Njẹ wọn tilẹ ni awọn nkan ti a le pe ni aal bi? Iha wo ni o yẹ ki a kọ si ọrọ tabi isọtẹlẹ wolii? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ bibeli yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, nipaṣẹ Ẹmi mimọ rẹ, fi imọ ati oye ti o peye fun wa lori ẹkọ yi, ki a ba le mọ riri awọn wolii otitọ ti O yan si aarin wa, ki a si tun ba le yẹra fun awọn eke wolii ti Eṣu le fẹ lo lọna kan tabi omiran lati ṣi wa lọna.
TANI WOLII?
Loju ọpọ eniyan, wolii jẹ ẹnikan ti o ma n ri iran si awọn eniyan ati ti o ma n sọ asọtẹlẹ. Ṣugbọn jijẹ wolii kọja riri iran tabi sisọ tẹlẹ si awọn eniyan. Bi a ṣe ri ninu bibeli, wolii jẹ ẹnikan ti Ọlọrun ya sọtọ lati fi ara rẹ, ifẹ rẹ ati ete rẹ han, ti O si tun n fi ọrọ rẹ si lẹnu loore-koore fun ẹkọ, ikilọ, igbaniniyanju, imuniduro, itunininu ati idajọ awọn eniyan. Iṣẹ iranṣẹ wolii wa le jẹ si awọn eniyan ijọ kan, agbegbe kan, ilu kan, orilẹ-ede kan tabi si oniruuru eniyan tabi orilẹ-ede. Ṣugbọn gbogbo rẹ ni i ṣe pẹlu ifẹ Ọlọrun ti O yan an, ti O si gbe iṣẹ le lọwọ. (Wo: Numeri 24:2-4&15-16; Jeremaya 1:4-11; Esikiẹli 2:1-3:4; 1Korinnti 14:3)
Eyi wa tunmọ si pe eniyan ko le di wolii nitori pe a kan da ororo le lori bi ami tabi nitori pe oun tẹle wolii kan tabi omiran kaakiri tabi nitori pe o jẹ ọmọ wolii. Ọlọrun funrarẹ gbọdọ yan fun iṣẹ iranṣẹ yi ni. Aijẹbẹ, a ba da garawa ororo le wa lori tabi ki a ma jẹun, ki a si tun ma sun pẹlu wolii, a ko le da wolii Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, Eliṣa ni Ọlọrun sọ fun Wolii Elija lati yan gẹgẹ bi wolii fun awọn eniyan rẹ. O si ṣe awari rẹ nitootọ lati pe si iṣẹ yi. Ṣugbọn ni ọjọ ti a fẹ gba Elija soke ọrun, o jẹ ki o ye ọkunrin yi pe ti Ọlọrun ko ba ro ni agbara lati ṣiṣẹ wolii ati lati wa ni aye olori awọn wolii yoku, ko si nkan ti oun le ṣe si. Ka wa sọ pe Ọlọrun ko ti yan Eliṣa lati ibẹrẹpẹpẹ ni, gbogbo bi o ṣe n tẹle Elija kaakiri ko ba kan ja si pabo ni. (Wo: 1Awọn Ọba 19:16; 2Awọn Ọba 2:1-16)
BAWO NI ỌLỌRUN NṢE FI ARA RẸ ATI IFẸ RẸ HAN WOLII?
Wayi o, ọna wo wa ni Ọlọrun n gba fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han wolii? Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, Ọlọrun le fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han wolii nipa bi ba a sọrọ ni ẹnu ko ẹnu (ojukoroju), ni inu iran tabi ni oju ala. Fun apẹẹrẹ, a sọ eyi fun wa ninu iwe Numeri, ori ikejila, lati ẹsẹ ikarun: “Oluwa si sọ kalẹ wa ninu ọwọn ikuukuu, o si duro ni ẹnu ọna agọ naa, o si pe Aarọni ati Miriamu: awọn mejeeji si jade wa. O si wi pe, Ẹ gbọ ọrọ mi nisinsinyi: bi wolii Oluwa ba n bẹ ninu yin, emi Oluwa yoo farahan fun un ni ojuran, emi o si ba a sọrọ ni oju ala. Mose iranṣẹ mi ko ri bẹẹ, oloootọ ni ninu gbogbo ile mi. Oun ni Emi n ba sọrọ ni ẹnu ko ẹnu ati ni gbangba, kii si i ṣe ni ọrọ ti o ṣe okunkun; apẹẹrẹ Oluwa ni oun o si ri…” (Numeri 12:5-8). Eyi fi han wa pe ko ki i ṣe ọna kan ṣoṣo ni Ọlọrun ma n gba fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han awọn wolii rẹ. Orisirisi ọna ni. Oun nikan naa si ni O le sọ iru ọna ti yoo gba tabi ti yoo ma gba ju lati ba ẹnikẹni ti O ba yan gẹgẹ bi wolii rẹ sọrọ.
Njẹ eyi wa jasi pe gbogbo ẹni ti o ba ti n riran, lala tabi gbohun naa ni wolii tabi naa ni ẹni ti Ọlọrun n ba sọrọ? Rara o. Bi a ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn n riran, lala tabi gbohun na ni wolii Ọlọrun. Peteru tilẹ sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn awọn wolii eke wa laarin awọn eniyan naa pẹlu…” (2Peteru 2:1) Ti awọn wolii eke ba wa ni aye igbaani, o yẹ ki a le mọ pe wọn si tun wa sibẹ naa loni. Amọ, a kan nilo lati mọ pe ẹni ti o ba jẹ wolii tootọ yoo ma ri iran, la ala ati gbọ ohun Oluwa loorekoore, ni ibamu pẹlu ifẹ ati ete Ọlọrun.
IYATỌ LAARIN WOLII OTITỌ ATI WOLII EKE
Bawo wa ni a ṣe le mọ boya eke wolii ni eniyan tabi wolii Ọlọrun nitootọ ni? Lakọkọ, ti ọrọ ẹni ti o pe ara rẹ ni wolii ko ba wa si imuṣẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ eke wolii. Bibeli sọ pe, “Nigba ti wolii kan ba sọrọ ni ọrukọ Oluwa, bi ohun naa ko ba ri bẹẹ, ti ko ba si ṣẹ, eyi naa ni ohun ti Oluwa ko sọ: wolii naa ni o fi sọrọ; ki iwọ ki o ma ṣe bẹru rẹ.” (Ditaronomi 18:22) Nitorina, ẹni ti o ba jẹ wolii Ọlọrun nitootọ, ọrọ ti o ba sọ ni orukọ Oluwa yoo ri bi o ṣe wi tabi ki o wa si imuṣẹ. Njẹ eyi tun wa jasi pe gbogbo wolii ti ọrọ rẹ ko ba ti wa si imuṣẹ ni eke? Rara! Fun apẹẹrẹ, wolii Oluwa tootọ ni Jona jẹ. Sibẹsibẹ, asọtẹlẹ rẹ si awọn ara Ninefe ko wa si imuṣẹ. Ki lo si fa? Ironupiwada awọn ara Ninefe ni o fa. Eyi tunmọ si pe iha ti a ba kọ si ọrọ Ọlọrun ti wolii ba sọ fun wa naa ni ipa ti o ga lati ko lori boya ọrọ naa yo wa si imusẹ tabi ko ni wa si imuṣẹ (Jeremaya 18:5-10). Amọ ṣa o, ti ohun gbogbo ba ri bi o ṣẹ yẹ ki wọn ri, ohunkohun ti wolii otitọ ba sọ ni orukọ Oluwa di dandan ki o wa si imuṣẹ.
Ekeji, a le mọ eke wolii nipa bi ọrọ rẹ ba ṣe ba ifẹ Ọlọrun ti a ti kọ sinu iwe mimọ mu si. Iwọ na wo nkan ti Ọlọrun sọ fun awọn eniyan rẹ: “Bi wolii kan ba dide laarin yin tabi alalaa kan, ti o si fi ami tabi iṣẹ iyanu kan han ọ, Ti ami naa tabi iṣẹ iyanu naa ti o sọ ba ṣẹ, wi pe, Ẹ jẹ ki a tele ọlọrun miiran lẹyin, ti iwọ ko mọ ri ki a si maa sin wọn; Iwọ ko gbọdọ feti si ọrọ wolii naa, tabi alalaa naa: nitori pe Oluwa Ọlọrun yin n dan yn wo ni, lati mọ bi ẹyin ba fi gbogbo aya yin, ati gbogbo ọkan yin fẹ Oluwa Ọlọrun yin.” (Ditaronomi 13:1-3) Nitorina, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni wolii, ti ọrọ rẹ si lodi si nkan ti a kọ wa ninu bibeli, a ko gbọdọ feti si. O ṣeeṣe ki o jẹ pe eke wolii ni. Ti ko ba si ki i ṣe eke, a jẹ wipe o ti n fi aye gba Eṣu lati ya lo niyẹn, o si nilo adura ati ironupiwada. O wa ṣeni laanu pe ọpọ ọmọ Ọlọrun, ti o yẹ ki otitọ yi ye, ni o n tẹle awọn eke wolii ti wọn n kọ wọn lati wuwa lodi si ifẹ Ọlọrun. Irufẹ awọn wọnyi yoo si da ara wọn lẹbi nikẹyin ni.
Ekẹta, a le mọ eke wolii nipa bi iwa rẹ ba ṣe wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun si. Jesu sọ wipe: “Ẹ maa kiyesi awọn eke wolii ti o n tọ yin wa ni awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikooko ni wọn ninu. Eso wọn ni ẹyin o fi mọ wọn…” (Matiu 7:15) Ọna wo ni Jesu sọ pe a o fi mọ awọn eke wolii o? Nipa eso ti aye wọn n so. Iru eso wo wa ni O n sọrọ nipa? O n sọrọ nipa eso Ẹmi mimọ, eso ododo, bi ifẹ, ayọ, igbagbọ, itẹriba, suuru, ikora-ẹni-nijaanu ati bẹẹbẹẹ lọ (Galatia 5:22-23). Ẹnikẹni ti o ba wa pe ara rẹ ni wolii, ti awọn nkan wọnyi ko si jẹyọ ninu aye rẹ ni ọna ti o ṣe fojuri, eke ni. O le ma yọ ina lẹnu, ki asọtẹlẹ rẹ si ma wa si imuṣẹ. Amọ eke ni. O tilẹ ṣeeṣe ki o jẹ pe nṣe ni o n dọgbọn si ọrọ ara rẹ ki asọtẹlẹ rẹ ba le ma wa si imuṣẹ. Idi ni pe asọtẹlẹ, iṣẹ iwosan, iṣẹ imularada ati awọn iṣẹ ami miran ṣe e dọgbọn si. Awọn eniyan le lo ẹmi oṣo tabi ti ajẹ lati ṣẹ awọn nkan wọnyi. Ṣugbọn eso Ẹmi Ọlọrun ko ṣe e dọgbọn si. Ti o ko ba ti ni Ẹmi rẹ ninu rẹ, o le so eso Ẹmi rẹ. Ko ju bayẹn lọ.
OJUṢE WOLII
Pẹlu awọn nkan ti a ti wa sọ silẹ yi, ki wa ni ojuṣe ẹnikẹni ti a ba pe ni wolii? Ti a ko ba i ti gbagbe, a ti sọ siwaju pe ti a ba n sọrọ nipa wolii, a n sọrọ nipa ẹnikan ti o n ri ifihan Ọlọrun ati ifẹ rẹ gba, ki o ba le rin ninu rẹ, ki o si ba le tọ awọn ẹlomiran lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Eyi wa jasi pe akọkọ ninu ojuṣe wolii ni lati mọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ. Ẹni ti ko ba ma mọ Ọlọrun ko le ṣe iṣẹ wolii. Ka ti lẹ sọ ododo, Ọlọrun ko le gbe iṣẹ wolii fun ẹni ti ko ba mọ ọn tabi ṣetan lati mọ ọn. Eyi ko wa jasi pe ko le gba ẹnu ẹni ti ko mọ ọn sọrọ rara. Ti O ba le gba ẹnu kẹtẹkẹtẹ Balaamu sọrọ, O le gba ẹnu ẹnikẹni, bi o tilẹ jẹ apaniyan, sọrọ tabi sọtẹlẹ (Numeri 22:21-31; Johanu 12:47-51).
Ṣugbọn ẹni yowu ti yo ba jẹ wolii ti Ọlọrun yo maa ti ẹnu rẹ sọrọ yoo jẹ ẹni ti o mọ ọn, ti o si tun mọ ifẹ rẹ. Bẹẹni, ibaṣepọ irufẹ ẹni bẹ pẹlu ti Ọlọrun gbọdọ munadoko. Eti rẹ gbodọ fi gbogbo igba wa ni yiya silẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun. Ọkan rẹ si gbọdọ fi gbogbo igba ma lepa lati ka ọrọ rẹ ati lati ṣe aṣaro ninu rẹ. Aijẹbẹ, wolii tara rẹ ni yoo jẹ; iṣẹ tara rẹ ni yoo si ma a jẹ pẹlu. Ailoye eyi ni o fa ti a fi ni ọpọ ti wọn pe ara wọn ni wolii loni ti Ọlọrun ko ye. Awọn wọnyi rope ki a kan riran, lala tabi gbohun ni o ma n sọ eniyan di wolii. Wọn ko mọ pe a gbọdọ ji pepe ninu imọ ọrọ Ọlọrun ki a ba le ma ṣe iyatọ ti o peye laarin ọrọ ti o ti ọdọ Ọlọrun wa ati eyi ti o ti ọdọ Eṣu wa. (Wo: Aisaya 50:4-5; Jeremaya 23:16-22)
Ojuse wolii keji ni lati gbe igbe aye rẹ ni ibamu pẹlu imọ Ọlọrun ati imọ ifẹ rẹ ti a ti fi han an, paapaa julọ lati inu iwe mimọ. Ẹnikẹni ti o ba wa pe ara rẹ ni wolii, ti igbesi aye rẹ si lodi si ọrọ inu iwe mimọ, n fi ara rẹ si abẹ idajọ Ọlọrun, yatọ si pe o wa ni abẹ ewu ayalo Eṣu. Irufẹ awọn wọnyi si ni Jesu n ba wi, nigba ti O sọ pe, “Ki i ṣe gbogbo ẹni ti n pe mi ni Oluwa, Oluwa, ni yoo wọle ijọba ọrun; bi ko ṣe ẹni ti n ṣe ifẹ ti Baba mi ti n bẹ ni ọrun. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo wi fun mi ni ọjọ naa pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ ni orukọ rẹ? Ati ni orukọ rẹ ki a fi le awọn ẹmi eṣu jade? Ati ni orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigba naa ni emi o si wi fun wọn pe, Emi ko mọ yin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹyin oniṣẹ ẹṣẹ.” (Matiu 7:21-23) Njẹ o ri bayi? Pe eniyan n sọtẹlẹ lorukọ Jesu ko jasi wipe ko ni pari irin ajo rẹ sinu ina ọrun apadi. Niwọn igba ti ko ba ti ma ṣe ifẹ Ọlọrun ninu ọrọ, iwa ati iṣe rẹ, eke ni Ọlọrun yoo ka si. Ọpọ si ni irufẹ awọn wọnyi ma n ṣi lọna nipaṣe awọn iwa irira wọn.
Ojuse wolii kẹta ni lati sọ ọrọ Ọlọrun ni ẹkunrẹrẹ fun awọn eniyan rẹ, lalai fi kun tabi yọ kuro nibẹ. Eyi jasi pe wolii Ọlọrun ko gbọdọ jẹ opurọ tabi ẹni ti ẹru lati sọ otitọ ma n ba. Idi si ni pe iha ti awọn eniyan yoo kọ si ọrọ rẹ duro lori imura, itara ati iduro ṣinṣin rẹ lati ba awọn eniyan sọ ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi Ọlọrun ti sọ. Boya awọn to n ba sọrọ wa gbọ tabi wọn ko gbọ o ko ki i ṣe iṣoro tirẹ. Eyi ti Ọlọrun n fẹ lati ọdọ rẹ ni lati sọ ọrọ rẹ lotitọ ati lẹkunrẹrẹ fun awọn yowu ti O ba ran an si. (Wo: Jeremaya 1:4-8; Isikiẹli 2:1-8 & 33:1-9) Ti Ọlọrun ko ba si ba sọrọ, ko yẹ ki o la ẹnu rẹ lati sọ nkankan.
Ṣe o wa ṣeeṣe ki Ọlọrun ma ni nkankan ti O fẹ ti ẹnu wolii ba eniyan sọ? O ṣeeṣe. A ri ninu iwe mimọ pe akoko kan wa ti Ọba Sọọlu n fẹ ki Ọlọrun ba oun sọrọ nipa ala, nipa Urimu tabi nipa awọn wolii. Ṣugbọn Ọlọrun ko da lohun. Ki lo fa? Idi ni pe ẹnikan ti ko naani ọrọ Ọlọrun ati alaigbọran ni. Aijẹbẹ, iba ti ma tẹlẹ ọrọ inu iwe mimọ, yala Ọlọrun ba sọrọ nipa iran, ala tabi wolii tabi ko ba sọrọ. Nitorina, awọn igba ma n wa ti Ọlọrun le pinnu lati ma ba eniyan sọrọ nipasẹ wolii, niwọn igba ti ẹni na ko ba ti ṣetan lati tẹle ọrọ iwe mimọ tabi ti ẹni naa jẹ olorikunkun. Igba miran ẹwẹ, o le ma jẹ ni kiakia ni Ọlọrun yo ba wolii rẹ sọrọ lori ọrọ ti awọn eniyan mu tọ ọ wa. Ti eyi ba si ribẹ, ẹni ti o ba jẹ wolii otitọ yoo ni suuru titi Ọlọrun yoo fi fi ifẹ rẹ lori ọrọ ti o wa nilẹ han an ni dipo ti yoo fi kan wa ikankan sọ. (Wo: 1Samuẹli 28:3-6; Isikiẹli 3:26-27; Jeremaya 42&43)
Amọ, nitori ailoye ọrọ Ọlọrun, ọpọ wolii loni lo ro wipe gbogbo igba ti awọn eniyan ba tọ wọn wa naa ni wọn gbọdọ ri nkan sọ tabi ri nkan sọ lẹsẹkẹsẹ. Eyi si lo fa ti Eṣu fi n ri wọn yaalo. O le jẹ nitori owo ti wọn fẹ gba lọwọ awọn ti o wa ni tabi nitori pe wọn ko fẹ ki wọn ma foju ẹni ti Ọlọrun ko ba sọrọ wo wọn. Eyi ti o wu ko jẹ, ijiya gidi n bẹ fun ẹnikẹni ti Ọlọrun ko ran niṣẹ bi wolii ti o si n jẹ iṣẹ tabi ẹni ti o n yi ọrọ Ọlọrun po. Bi Balaamu ṣe ni ojukokoro to gẹgẹ bi ariran, gbogbo igba ni o n jẹ ko ye awọn eniyan pe oun ko le sọ nkan ti Ọlọrun ko ba fi si oun lẹnu lati sọ. Sibẹsibẹ, Ọlọrun da ṣeria fun nitori ojukokoro rẹ. Ti iwọ naa, bi wolii, ba fi aye gba ojukokoro, ibẹru tabi ifẹ oriyin awọn eniyan lati ma a sọ ọrọ Ọlọrun bi ko ṣe tọ tabi lati jẹ iṣẹ ti ko ran ọ, o di dandan ki iwọ na jẹ iyan rẹ niṣu. (Wo: Book 23:11-12&25-26; Jeremaya 23:9-32)
AALA IṢẸ WOLII
Njẹ ṣe wolii tabi iṣẹ wolii ni aala bi? Bẹẹni. Bi wolii tilẹ jẹ ẹni ti Ọlọrun yan lati fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han, ki o ba le tọ awọn eniyan sọna, kilọ fun wọn tabi fun wọn ni idajọ Ọlọrun, eyi ko tunmọ si pe gbogbo nkan naa ni o mọ tabi ti o le mọ nipa awọn ti Ọlọrun ran an si. Pọọlu sọ eyi fun wa: “Nitori imọ wa ko to nnkan, isọtẹlẹ wa ko si to nnkan pẹlu.” (1Kọrinnti 13:9) Eyi tunmọ si pe ọwọ nkan ti Ọlọrun ba fi han wolii rẹ nikan naa ni yoo mọ, ti yo si le sọrọ tabi ṣiṣẹ le lori. Eyi ti Ọlọrun ko ba fihan an, ko si nkan ti o le ṣe le lori. Idi si niyi ti a fi gbọdọ ma fi gbogbo igba lepa lati mọ gbogbo ifẹ Ọlọrun lati inu iwe mimọ. Aijẹbẹ, a le wa labẹ ewu ṣiṣe amulo ọrọ wolii ti o kan n fi abala diẹ lara ifẹ Ọlọrun fun wa han.
Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun lo wolii Eliṣa lati sọ asọtẹlẹ fun arabinrin kan pe yoo bimọ, o si bimọ gẹgẹ bi asọtẹlẹ na. Amọ Ọlọrun ko wa fi han wolii yi pe ọmọ naa yoo ku nigba ti o ba dagba diẹ, ti o yẹ ki awọn obi rẹ bẹrẹ si ni gbadun rẹ. Nitorina, nigba ti ọmọ naa ku, wolii Eliṣa sọ wipe, “…Ọlọrun si pa a mọ fun mi, ko si sọ fun mi.” (2Awọn Ọba 4:27) Eyi n jẹ ki o ye wa pe gbogbo nkan naa kọ ni wolii ma n ri. Nitorina, a ko gbọdọ pa ọrọ iwe mimọ ti lati kan ma wa asọtẹlẹ wolii kaakiri. Aijẹbẹ, a le tipasẹ asọtẹlẹ wolii ṣina tabi kọsẹ.
IHA TI O YẸ KI A KỌ SI WOLII
Iha wo wa ni o yẹ ki a kọ si wolii ati iṣẹ iranṣẹ wọn? Akọkọ, a gbọdọ gba wọn gbọ, niwọn igba ti a ba ti mọ daju pe wolii otitọ niwọn ati wipe ọrọ wọn wa ni ibamu pẹlu ọrọ iwe mimọ. Ọba Jehoṣafati sọ eyi fun awọn eniyan rẹ ni akoko kan: “…Ẹ gba Oluwa Ọlọrun yin gbọ, bẹẹ ni a o fi ẹsẹ yin mulẹ; ẹ si gba awọn wolii rẹ gbọ, bẹẹ si ni ẹyin o ṣe rere.” (2Kironika 20:20) Yatọ si eyi, Jesu Oluwa wa naa sọ wipe, “Ẹni ti o ba gba wolii ni orukọ wolii, yoo jẹ ere wolii…” (Matiu 10:41) Nitorina, ti a ba fẹ ti ipasẹ wolii yowu ti Ọlọrun ba ran si wa lati jere ifẹ, oju-rere tabi aanu Ọlọrun, a gbọdọ gba a gbọ, ki a si tẹle ohunkokun ti o ba sọ fun wa. Eyi ti o ba jẹ mọ ki a ronupiwada, ki a ronupiwada. Eyi ti o ba si jẹ mọ ki a dupẹ lọwọ Ọlọrun, ki a si tun duro ṣiṣin ninu igbagbọ wa ati ododo rẹ, ki a ṣe bẹẹ gẹgẹ. Nipa bayi, a o le jere iṣẹ iranṣẹ wolii.
Yatọ si eyi, a nilo lati bọwọ fun awọn wolii ti Ọlọrun n lo fun wa, ki a si ma fi nkan ini wa ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ, gẹgẹ bi a ṣe kọ wa ninu bibeli. Idi si ni pe eyi ni ere lori pupọ niwaju Ọlọrun. Amọ, ti a ba n ri wọn fin tabi sọ ọrọ odi si wọn, a le wa si abẹ idajọ Ọlọrun ti o lewu. (Wo: Numeri 12; 1Awọn Ọba 17:7-24; 2Awọn Ọba 4:8-37; Emọọsi 7:10-17; Matiu 10:40-42; 1Tẹsalonika 5:12-13)
Ni afikun, a ko gbọdọ gbagbe pe ẹlẹran ara ni wolii kọọkan. Nitorina, bi a ti ṣe sọ siwaju, a ko gbọdọ tẹle wolii kankan ti isọtẹlẹ rẹ tabi igbe aye rẹ ko ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. A gbọdọ ma fi gbogbo igba ranti ọrọ Pọọlu ti o sọ wipe, “Ẹ maa ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti n ṣe afarawe Kirisiti.” (1Kọrinnti 11:1) Aijẹbẹ, ọrọ wa le dabi ti wolii ọdọ kan ti agba wolii kan ṣi lọna, ti o si jẹ ki o ṣegbe (1Awọn Ọba 13).
ỌRỌ IPARI
Ni akotan, wolii jẹ ẹnikan ti Ọlọrun yan lati fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han, ki O ba le lo o lati fi ifẹ ati ete rẹ han si awọn eniyan. Amọ, ko wa ki i ṣe gbogbo wolii naa ni Ọlọrun yan, ko si ki i ṣe gbogbo wolii ti Ọlọrun yan naa ni o ma n fi ododo jẹ iṣẹ ti o gbe fun wọn. Idi si ni yi ti ọmọ Ọlọrun kọọkan fi gbọdọ ni imọ ti o peye nipa wolii ati iṣẹ wọn, ki o ma ba bọ sọwọ awọn eke wolii ati ki o ma ba duro lori iṣọtẹlẹ ti ko fi gbogbo ifẹ Ọlọrun han, ki o si kọsẹ.
IBEERE
- Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran imọ ati oye rẹ nipa wolii ati iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ si?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (Whatsapp Number : 07085711280)
