Ọjọ: Agẹmọ 04, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 9
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu oṣu Agẹmọ 2021. Mo si gbadura pe ki a ṣọ ọ lati ma ṣe ṣe ohunkohun ninu oṣu naa ti yoo di ipese Ọlọrun lọwọ lati ṣan wọ inu aye at ile rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o le di ṣisan ipese Ọlọrun sinu aye wa lọwọ tabi ti o le di wa lọwọ lati ri ipese rẹ gba ni ki a ni ahun, ahun si Ọlọrun ati ahun si awọn ti O fẹ ki a lawọ si. Fun apẹẹrẹ, nigba ti O n ba awọn eniyan rẹ sọrọ nipasẹ wolii Hagai, Ọlọrun sọ eyi:
“Ẹ kiyesi ọna yin. Ẹ gun ori oke nla lọ, ẹ si mu igi wa, ki ẹ si kọ ile naa; inu mi yoo si dun si i, a o si yin mi logo ni Oluwa wi. Ẹyin ti n reti ọpọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni ẹ ri: nigba ti ẹyin si mu un wa ile, mo si fẹ ẹ danu. Nitori kin ni? ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku yin si n sare fun ile ara rẹ. Nitori naa ni a ṣe da iri ọrun duro lori yin, a si da eso ilẹ duro. Mo si ti pe ọda sori ilẹ, ati sori oke nla, ati sori ọka, ati sori waini titun, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori eniyan, ati sori maluu, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ yin.” (Hagai 1:7-11)
Njẹ o ri bayi? Ọlọrun, ninu ẹṣẹ bibeli yi, sọ wipe Oun ni o wa nidi ijakulẹ ati oṣi ti awọn eniyan rẹ n ba finra. Eyi tunmọ si wipe Oun ni O n di wọn lọwọ lati jẹgbadun ibukun rẹ ninu aye wọn ati lori ọrọ aye wọn. Ki si ni idi? Bi O ṣe fihan, idi ni wipe wọn ko lawọ si i. Gbogbo wọn gbajumọ kikọ ile ti ara wọn ati mimojuto awọn okowo wọn. Ṣugbọn wọn ko ṣe eyi fun ile rẹ ti o wa ni aarin wọn. Wọn kan ṣa kọ lati fi akoko wọn tabi awọn nkan ni wọn jin lati kọ ile yi. Nitornia, wọn bẹrẹ si ni iriri aṣedanu. Bi Ọlọrun si ṣe tẹsiwaju lati sọ fun wọn, laijẹ pe wọn ba ronipiwada, ti wọn si bẹrẹ si ni fi akoko wọn ati awọn nkan ini wọn jin fun kikọ tẹmpili rẹ, nkan ko ni rọgbọ fun wọn rara.
Nibakanna, ti awa naa ba kọ iṣẹ ijọba Ọlọrun silẹ, ti a ko si fi akoko wa tabi nkan ini wa jin lati ṣe e, nṣe ni a o ma di ṣisan ibukun rẹ ninu aye wa lọwọ. Lotitọ, O ti bukun fun wa pẹlu gbogbo ibukun ẹmi inu awọn ọrun ninu Kirisiti Jesu (Efesu 1:3). Amọ sa o, a le di isẹ awọn ibukun yi lọwọ nipa anikanjọpọn ati iwa ahun. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe a ti bukun fun wa ni aini odiwọn, a tun le ba iforo ailodiwọn naa pade ninu aye wa nitori iwa ahun wa.
Lafikun, nigba ti O n sọrọ nipasẹ Malaki, Ọlọrun fi ẹsun kan awọn eniyan rẹ pe wọn n ja Oun lole nipa ṣiṣe alailotọ ni mimu idamẹwa ati ọrẹ wọn wa lati tọju awọn alufa rẹ, awọn alaini ni ilẹ naa ati awọn ajoji aarin wọn. Eyi tunmọ si pe ni igbakugba ti a ba tọju fun ara wa nkan ti Ọlọrun fẹ ki a fun awọn elomiran, a n ja lole niyẹn. Bawo wa ni a ṣe fẹ ja Ọlọrun lole, ki a si tun ma reti ki ibukun rẹ ṣan lalai ni idiwọ ninu aye wa? Ko le ṣeeṣe. (Wo: Malaki 3:8-12)
Siwaju si, Ọlọrun sọ wipe nigba ti awọn eniyan yi gan ba tun wa mu ọrẹ wa fun, ọrẹ ti o fọ loju, ti o yarọ tabi ti o n ṣaisan ni wọn ma n mu tọ ọ wa. Iwọ naa ro wo. Awọn eniyan yi ko lojuti to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi n mu wa fun Ọlọrun awọn nkan ti wọn ko le fun awọn ọga wọn nibi iṣẹ, awọn gomina wọn tabi awọn ana wọn. Eyi si bi Ọlọrun ninu to bẹẹ gẹẹ ti O fi sọ fun wọn pe ki wọn kuku gbe ilẹkun tẹmpili wọn ti, ki wọn si ye mu ẹbọ ati ọrẹ ti ko nitunmọ wa fun un mọ. Ti O ba wa ri awọn nkan ti wọn n mu wa fun un bi nkan ti ko wulo, njẹ yoo ha pin wọn ni ere fun un bi? Rara! (Wo: Malaki 1:6-14)
Ni ọna kanna, ti awa naa ba n ja Ọlọrun lole nipa ṣiṣe ahun si awọn ti O ti pa aṣẹ fun wa lati lawọ si, nṣe ni a o ma ti ferese ipese rẹ mọ ara wa, bi awọn eniyan igba aye Malaki ti ṣe ṣe. Ti a ba si wa n mu awọn afọju, abirun ati alaisan ọrẹ (awọn nkan ti o kere si wa jọjọ ati ti o kere si oore-ọfẹ rẹ lori aye wa) wa fun iṣẹ rẹ tabi fun awọn ti O fẹ ki a fun ni nkan, a ko ni ri ere kankan gba lọwọ rẹ fun fifi funni wa, boya laye yi tabi ninu ijọba ayeraye rẹ. Bawo ni yo sẹ wa banininujẹ to, ti mo ba wa rigbọ lọjọ kan pe gbogbo fifi funni mi ni mo ṣe lasan? Yio dunni jọjọ.
Ẹwẹ, ẹnikan wa le sọ pe, “Ṣebi bibeli sọ wipe fifi funni wa gbọdọ jẹ niwọn nkan ti a ba ni dipo eyi ti a ko ni. Nkan ti mo si n ṣe n eyi. Ki wa lo tun fa a ti Ọlọrun tabi ẹnikan yoo tun ṣe wa ma a sọ wipe mi o ṣe to?” Ootọ ọrọ ni! Amọ ki ẹni naa tun jẹ ki o ye oun pe Ọlọrun mọ ohun gbogbo ti a ni. Nitorina, O mọ igba ti nkan ti a n fi funni lati ara nkan ini wa kere jọjọ si oore-ọfẹ rẹ to wa lori aye wa. Nigbakugba ti eyi ba si ri bẹ, nṣe ni a n yan an jẹ, ti a ko si ni ri nkankan gba lọwọ rẹ fun fifi funni wa. Nitori eyi, fi ara rẹ balẹ lati mojuto ifarajin rẹ si lilawọ nitori pe Ọlọrun naa n fi ara balẹ mojuto. Mo si gbadura pe ki O ma fi gbogbo ri ọ gẹgẹ bi olotitọ ninu awọn nkan wọnyi, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ arinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
