Ọjọ: Okudu 20, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 7
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọṣẹ miran ninu oṣu Okudu 2021. Mo gbadura pe ki a mu ọkan rẹ ro lati ma fi gbogbo igba fi aye gba ọrọ yowu ti Ọlọrun yoo ma mu tọ ọ wa ni gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ ati lati ṣe rere pẹlu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Mo gba adura yi fun ọ nitori pe ọrọ Ọlọrun fi ye wa daju ṣaka pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti o n ka tabi gbọ ọrọ Ọlọrun naa ni o ma n jere rẹ nikẹyinkẹyin. Ki si ni idi? Idi ni pe ki a to le jere ọrọ Ọlọrun, a ko kan gbọdọ ka a tabi gbọ ọ lasan; a tun gbọdọ ṣe amulo rẹ. Kiki ẹni ti o ba si n ṣe amulo ọrọ rẹ ti o ka tabi gbọ ni yoo ni iriri ẹkunrẹrẹ ibukun nkan ti O n sọ. Ẹni ti o ba kan gbọ ọrọ rẹ tabi ka a lasan, ṣugbọn ti ko ṣe amulo rẹ kan n tan ara rẹ jẹ ni – ko ni ri ilapa nkan ti o yẹ ki ọrọ naa ṣe ninu aye rẹ. (Wo: Matiu 7:24-27; Jemisi 1:12-25; Ifihan 1:3)
Nitorina, afojusun wa ti a ba n ka tabi gbọ ọrọ Ọlọrun gbọdọ duro lori ṣiṣe amulo rẹ. Aijẹbẹ, yatọ si pe ọrọ naa ko ni mu ifẹ rẹ ṣe ninu aye wa, yoo tun wa duro tako wa gẹgẹ bi ẹlẹrii nigba ti Ọlọrun ba bẹrẹ idajọ rẹ (Johanu 12:48). Fun apẹẹrẹ, igba kan wa ti awọn adari awọn Juu perete ti o ku ni ilẹ Juda tọ Jeremaya wa lati sọ fun pe ki o ba wọn wa oju Ọlọrun, ki wọn ba le mọ ibi ti o yẹ ki wọn lọ tabi duro si. Wọn tilẹ tun sọ siwaju fun pe, “Ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹrii otitọ ati ododo laarin wa, bi awa ko ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọrọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ yoo ran ọ si wa. Ibaa ṣe rere, ibaa ṣe ibi, awa o gba ohun Oluwa Ọlọrun wa gbọ, sọdọ ẹni ti awa ran ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gba ohun Oluwa Ọlọrun gba gbọ.” (Jeremaya 42:5-6)
Njẹ o ṣe akiyesi pe awọn eniyan wọnyi sọ pe awọn o ṣe amulo ọrọ Ọlọrun, boya o ba wọn lara mu tabi ko ba wọn lara mu? Ṣibẹṣibẹ, nigba ti Jeremaya pada de pẹlu ọrọ Ọlọrun fun wọn, esi wọn si ni pe, “Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa ko ran ọ lati wi pe, Ẹ ma lọ si ijibiti lati ṣatipo nibẹ: Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neraya ni o fi ọrọ si ọ ni ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kalidia lọwọ, lati pa wa ati lati ko wa ni igbekun lọ si Babeli.” (Jeremaya 43:2-3) Nitorina, wọn kọ ọrọ Oluwa silẹ, wọn si ṣe gẹgẹ bi ọgbọn ati ifẹ inu wọn.
Ki wa ni idi ti awọn eniyan yi ṣe sọ fun Jeremaya ki o ba wọn wadi ero Ọlọrun fun wọn, nigba ti wọn ko ṣetan lati gba ohun yowu ti ifẹ rẹ fun wọn ba jẹ? Idi ni pe wọn ko mọ pe kiba san fun wọn lati ma mọ ifẹ Ọlọrun rara ju kan mọ ifẹ rẹ tan, ki wọn si wa kọ jalẹ lati ṣe lọ. Ko si nkan miran ti eyi yo yọri si fun wọn ju iya onibeji lọ. Wọn ko kan ni jẹ iya fun aiṣe ifẹ Ọlọrun lasan; wọn o tun jẹ iya lori pe wọn mọ ifẹ rẹ, wọn si tun wa mọ-ọn-mọ kọ ọ silẹ.
Nitorina, Jeremaya sọ eyi fun wọn: “Oluwa ti sọ ni ti yin ẹyin iyoku Juda, ẹ ma lọ si Ijibiti: ẹ mọ dajudaju pe emi ti jẹrii sii yin ni oni yii. Nitori ọkan yin ni ẹyin tan jẹ, nigba ti ẹyin ran mi si Oluwa Ọlọrun yin, wi pe, Gbadura fun wa si Oluwa, Ọlọrun wa: ati gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Oluwa Ọlọrun wa yoo wi, bẹẹ ni ki o sọ fun wa, awa o si ṣe e. Emi si ti sọ fun yin loniii, ṣugbọn ẹyin ko gbọ ohun Oluwa, Ọlọrun yin, ati gbogbo eyi ti oun ti ran mi sii yin. Njẹ nitori naa, ẹ mọ dajudaju pe, ẹyin yoo ku nipa ida, nipa iyan, ati nipa ajakalẹ arun, ni ibẹ naa nibi ti ẹyin fẹ lati lọ ṣe atipo.” (Jeremaya 42:19-22) Njẹ o ri bayi? Aṣiṣe gba a ni, itanraẹnijẹ si ni pẹlu lati ṣafẹri ifẹ Ọlọrun tan, ki a tun wa kọ jalẹ lati ṣe nkan ti O n sọ fun wa. Ewu onibeji ni eleyi yoo mu wa sori wa.
O wa ṣe ni laanu pe ọpọ wa ko ni oye pe nkan ti a n fa sori ara wa ni eyi, nigba ti a ba wa si awọn ipade wa tabi ti a wa ri awọn adari wa, ti a gbọ ọrọ Ọlọrun lori bi o ṣe yẹ ki a gbe aye wa, ti a si tun wa kuro lati lọ ṣe idajeki nkan ti a gbọ. Ki wa ni larija pe a n wa gbọ ọrọ Ọlọrun, nigba ti o jẹ pe nṣe ni yoo tun ko wa sinu iyọnu ti o pọ si? Ṣe ko ni san fun wa lati kuku yago fun ọrọ rẹ patapata ju ki a gbọ tan, ki a tun wa ma sọ fun ara wa pe, “Nkan ti o ba wu oniwaasu ni o le fi ẹnu rẹ sọ. Nkan ti emi o n ṣe n bẹ ninu mi?” Ko si ọmọ ti eleyi yoo bi fun wa bi ko ṣe ijiya ati inira ti o ga si, bi o ṣe ṣeeṣe ki o ti ma ṣẹlẹ ninu aye rẹ lọwọlọwọ bayi. Nkan ti mo n sọ na ni pe irufẹ iha yi si ọrọ Ọlọrun yoo kan jẹ ki iya rẹ pọ ju ti awọn ti ko tilẹ mọ ifẹ Ọlọrun rara lọ ni.
Nitorina, ma fi ara rẹ sinu iyọnu si mọ nipa kikọ lati ṣe amulo otitọ ọrọ Ọlọrun ti o mọ. Mo si gbadura pe ki a dari rẹ sinu ironupiwada ati imupadabọsipo ni ibi yowu ninu aye rẹ ti o ba ti n jiya nitori eyi, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọṣẹ ti o ga.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
