Sọ iriri rẹ pẹlu rẹ fun wọn | Paito J.O. Lawal

Ojo: Igbe 11, 2021 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu igbe 2021. Ki o si ni iriri isinmi Ọlọrun ati ibalẹ ọkan lẹkunrẹrẹ ni gbogbo ọsẹ na, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ọkan lara awọn nkan ti o le jẹ ki iriri isinmi lati ọdọ Ọlọrun ati ibalẹ ọkan ma fi gbogbo igba pọ si fun wa ni ki ọpọlọpọ eniyan ninu aye yi di ẹni igbala ati ẹni isọdọtun nipasẹ igbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Awọn ẹni ti a ba ti gbala, ti a si tun ti sọ aye wọn di ọtun nipasẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa ki i da wahala silẹ ni awujọ. Wọn ki i jale, digunjale, fipabanilopọ, lu owo ara ilu ni ponpo, ṣẹ oṣo owo, lo ogun oloro tabi ni awọn aladugbo wọn lara. Nitorina, bi iru awọn wọnyi ba ṣe pọ si ni awujọ wa naa ni a o ṣe gbadun alaafia ati ibalẹ ọkan to. Idi gan si ni yi ti a fi gba wa ni iyanju ninu iwe mimọ lati ma ma gbadura fun ara wa nikan ṣugbọn fun gbogbo eniyan pẹlu, nitoripe Ọlọrun le ti ipasẹ adura wa dari wọn lati ni igbala. (Wo: 1Timoti 2:1-4)

Ṣugbọn adura gbigba pe ki Ọlọrun dari awọn eniyan lati ni igbala nikan ko to lati jẹ ki wọn ri igbala. A tun gbọdọ ma a ba wọn sọrọ nipa igbala naa ninu Kirisiti Jesu ti Ọlọrun n fi i lọ wọn lọfẹ. Ko si di igba ti a ba di ajinhinrere ki a to le ṣe eyi; a kan nilo lati ni iriri igbala yi funrawa ni. Ṣe a ti gba wa la kuro ninu ẹṣẹ wa? Ṣe a ti ni iriri itusilẹ kuro lọwọ agbara Ẹsu lotitọ? Ṣe aye wa n fi ojoojumọ gbadun ifẹ ati didara Ọlọrun ni ọna ti o kọja afẹnusọ? Ti gbogbo awọn nkan wọnyi ba jẹ otitọ niha tiwa, a jẹ wipe a ti ni anito nkan ti a nilo lati pe awọn ti o wa ni ayika wa lati wa kopa ninu iriri ti a n ni pẹlu Ọlọrun nipasẹ Kirisiti Jesu niyẹn.

Fun apẹẹrẹ, ni igba kan ri, Jesu Oluwa wa ba obinrin ara Samaria kan ni gbolohun fun iṣẹju bi melokan lẹba kanga omi kan ni ilu kan ti a n pe ni Sikari. Wayi o, obinrin yi ni lati jẹ oniwahala eniyan kan, ẹni ti ọpọ eniyan ko ni fẹ ba da nkankan pọ. Idi si ni pe, bi akọsilẹ iṣẹlẹ yi ti fi han wa, o ti ṣe igbeyawo ni igba marun ati wipe ọkunrin ti o wa pẹlu rẹ ni akoko yi gan ko ki i ṣe ọkọ rẹ rara – wọn kan jọ n ṣe ajumọgbepọ ni. Nitorina, ko fẹrẹ jọ wipe obinrin rere ni. Sibẹsibẹ, nigba ti Jesu ṣetan pẹlu nkan ti O n ba a sọ, ti O si fi ọna lati tan ohungbẹ rẹ fun ifẹ ati ibalẹ ọkan han an, ko fi akoko ṣofo rara lati lọ ko gbogbo awọn ti o ni anfaani lati ko lati inu ilu rẹ wa lati pade Jesu. (Wo: Johanu 4:4-45)

Njẹ ẹsẹ ọrọ Ọlọrun meloo ni obinrin yi mọ lati le ṣe nkan ti o ṣe yi? Perete! Ka tilẹ sọ otitọ, ko nilo lati mọ ẹsẹ ọrọ Ọlọrun pupọ lati le ko awọn eniyan wa pade Jesu. O kan nilo lati le fi itara sọ fun wọn iriri ohun tikararẹ pẹlu Jesu ni ati bi iriri yi ṣe fun ni odiwọn igbagbọ ti o nilo lati le ni igbe aye ọtun ati igbe aye ti o nitunmọ.

Ni ọna kanna, nkan ti a nilo lati le pe awọn eniyan lati wa sọdọ Jesu ko ki i ṣe imọ bibeli ti o ga. Dipo eyi, nkan ti a nilo ni itara ti o ga lati le ba wọn sọrọ lori awọn nkan daradara ti aye wa ti ni iriri rẹ nipasẹ ibadapọ wa pẹlu rẹ, ki awọn naa ba le e tọ ọ wa lati ni awọn iriri ti o tun dara ju awọn eyi ti a ti ni lọ. Bi wọn ba si ṣe n tọ ọ wa, ti aye wọn si n yipada, awujọ wa naa yoo bẹrẹ si ni ni iriri alaafia ati iṣinmi ti o ga ju tatẹyinwa lọ.

Nitorina, bi o ṣe n lọ ni ọse yi, pinnu lọkan rẹ pe eniyan pupọ si yoo tipasẹ rẹ gbọ ihinrere awọn nkan ti Jesu Oluwa ti ṣe fun ọ, ti O n ṣe fun ọ ati ti O si n ṣe pẹlu rẹ. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun, nipasẹ Ẹmi rẹ, kun ọ pẹlu itara ti o ga lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣẹ atata.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *