Ọjọ: Agẹmọ 11, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 10
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Agẹmọ. Adura mi fun ọ si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki o ni iriri awọn nkan ti yoo jẹ ki o gbagbe awọn ọdun iyọnu rẹ ati awọn nkan buburu ti awọn eniyan ti ṣe si o, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe Josẹfu pada wa di ẹni nla, gẹgẹ bi ete Ọlọrun fun un, ọna ti o gba goke agba jẹ eyi ti ko rọrun rara. Lakọkọ, awọn ẹbi rẹ gan an, iyẹn awọn arakunrin rẹ ti wọn jọjọ jẹ ẹjẹ kanna, ni wọn gbimọ papọ lodi si, ti wọn si ta a si oko ẹru. Ki wa ni idi? Idi ni wipe wọn n jowu rẹ, ọkan wọn si tun koro si i. Ko dun mọ wọn ninu rara pe baba wọn fẹran rẹ ju gbogbo wọn lọ ati pe ko si tun fi pamọ. Lafikun, wọn ko fẹran bi o ṣe jẹ pe gbogbo igba naa ni o ma n fi ẹjọ awọn iwa aida wọn sun – ko kan dun mọ wọn ninu rara pe aye tirẹ tọọ, ko si lọjupọ bi ti wọn. Siwaju si, wọn ko fẹran bi o ṣe jẹ pe oun nikan naa ni o ma n fi gbogbo igba lala pe oun yoo di ẹni giga ju gbogbo wọn lọ. Nitorina, wọn ṣe ohun gbogbo ti wọn le ṣe lati yanju rẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 37)
Ṣugbọn nitori pe Ọlọrun nifẹ rẹ, ko si tun pa a ti, o ba ara rẹ gẹgẹ bi ẹru nile ọkunrin kan ti o mọ riri aye rẹ ti o tọ ati ijafafa rẹ lẹnu iṣẹ, ti o si tun fi aye gba a lati gberu si. Nitorina, lẹyin igba diẹ, o di ẹni ti o ṣe pataki julọ ninu ilẹ olowọ rẹ. O di alamojuto ọrọ ọkunrin yi, awọn ẹru rẹ ati ohun gbogbo ti o n lọ ninu ile rẹ. O wa ṣeni laanu pe, nigba ti o wa dabi ẹnipe aye rẹ fẹ bẹrẹ si ni lojutu pada ni awọn ika ẹmi ti wọn ti pinnu lati ba aye rẹ jẹ ti iyawo olowo rẹ lati gbe awọn igbese omugo ati iṣekuṣe kan ti o jẹ ki o ba ara rẹ ninu ẹwọn. (Wo: Jẹnẹsisi 39)
Sibẹsibẹ, Ọlọrun ko pa ọdọmọkunrin yi ti, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹwọn ni o wa. Dipo eyi, O jẹ ki o ba ojurere pade lẹẹkan si, ki o si tun pade ọlọla eniyan kan ti o papa wa ṣi ilẹkun igbega ati ibalẹ ọkan fun (Jẹnẹsisi 40). Eyi si ni nkan ti bibeli sọ nipa rẹ nigbati o bi akọbi ọmọ rẹ lẹyin ọdun diẹ si: “Josẹfu si sọ orukọ akọbi ni Manase: wi pe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ mi, ati gbogbo ile baba mi.” (Jẹnẹsisi 41:52)
Iwọ na ro wo. Ọlọrun jẹ ki Josẹfu gbagba gbogbo iyọnu ati gbogbo ikoro ti o jẹ lati ọwọ awọn arakunrin rẹ. Eyi tunmọ si pe, Ọlọrun jẹ ki awọn iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ ti o mu gbogbo inira, ibanujẹ, abamọ ati ibinu rẹ, paapaa si awọn ti o ṣẹ kuro. Nitorina, o wa le gbe iyoku ọjọ aye rẹ ninu ọrọ, ayọ ati ibalẹ-ọkan. Nkan ara ma leyi o!
Lọna kanna, Ọlọrun yi i kanna ti O jẹ ki Josẹfu gbagbe gbogbo iyọnu ati ikoro ọkan rẹ le jẹ ki iwọ naa gbagbe gbogbo iyọnu, ibanujẹ, inira ati ibinu rẹ, paapaa si awọn ti Eṣu ti lo tabi ti o n lo lati ṣe ọ nika tabi ni ọ lara. Bẹẹni, O le mu awọn iṣẹlẹ waye ti yoo jẹ ki o gbagbe patapata bi o ṣe n ri ti eniyan ba n jiya tabi ti o ba wa ninu inira. Nkan ti o si nilo lati ṣe ko ju ki o fi gbogbo ọkan rẹ gbẹkẹ le e, ki o si tun ni ikọbiarasi ti o tọ bi ti Josẹfu. Oun yoo si mu ọ wa si ipo naa laye yi ti ọkan rẹ yoo ti kun fun ayọ to bẹẹ gẹẹ ti o ko fi ni ri aye lati sọkun, kabamọ tabi ronu lati gbẹsan lara ẹnikẹni fun ohun yowu ti o ṣẹ si ọ.
Wo o, awọn ti o ri aye lati bu awọn miran, korira wọn tabi wa bi wọn yoo ṣe gbẹsan lara wọn ri bayi nitori pe wọn ko i ti ni iriri odiwọn ayọ Oluwa to koju osuwọn ni. Ti a ba sọ iru awọn ẹni bẹẹ sinu odo ayọ rẹ, ti o si bo wọn mọlẹ, gbogbo ibinu, aroye ati ikorira wọn ni yoo poora, ti gbogbo afojusun wọn ko si ni kọja bi wọn yoo ṣe ma jẹgbadun ẹkunrẹrẹ ibukun ti Ọlọrun ti tu si wọn lori. Ki wa gan ni o fẹ? Ṣe o fẹ ma fi gbogbo iyoku ọjọ aye rẹ ṣe aroye, korira tabi bu awọn elomiran fun ipa ti wọn ko ninu laasigbo ati ajalu rẹ ni? Abi ṣe ni o fẹ lati gbe iyoku aye rẹ ninu ẹkunrẹrẹ ayọ Oluwa, nibi ti o ko ti ni ri aye lati ranti ikuna tabi irora atẹyinwa tabi ranti iwa ika awọn ti wọn ṣe aidara si ọ?
Niti temi o, ma a gbe iyoku aye mi pẹlu ọkan ti ko si ikorira, ibanujẹ, ikoro tabi ẹsan kankan ninu rẹ ṣugbọn ti o kun fun kiki ayọ ati ọpẹ si Ọlọrun. Idi si ni pe o dami loju pe O n ṣiṣẹ lati jẹ ki ohun gbogbo, pẹlu iwa ika awọn eniyan si mi, ṣiṣẹ pọ fun rere ati itẹsiwaju mi ati fun iyin orukọ ologo rẹ (Roomu 8:28). Mo si gbadura pe ki iwọ naa ri okun gba ninu rẹ lati ni irufẹ ọkan kanna, ni orukọ iyebiye ti Jesu. Amin
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
