Ọjọ: Belu 28, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 30
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ si ọjọ Isinmi ti o kẹyin oṣu Belu 2021. Mo gbadura pe ki didara Ọlọrun ṣan ni akunwọsilẹ ninu aye ati ile rẹ ni eyi ti o ku ki osu naa ati odun yi pari, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ yi, mo fẹ gba ọ niyanju pe ki o mu iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ni ọkunkundun ati tọkantọkan. Ki ni idi? Akọkọ, idi ni ki Ọlọrun ba a le lo lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Ti a o ba sin Ọlọrun tọkantọkan ati ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, a le doju nkan ti o fẹ mu jade nipasẹ nkan ti a n ṣe ru. Eyi ko si ni dara fun wa tabi fun awọn ti a n sin nitori rẹ.
Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn Juu aye igba Jesu Oluwa wa ni awọn alufa, olukọ ofin, Farisi ati Sadusi ti wọn n ṣiṣẹ lati sin wọn, sibẹsibẹ, Oluwa sọ pe wọn da bi agbo aguntan ti ko ni oluṣọ. Eyi tunmọ si pe iṣẹ iranṣẹ awọn adari ẹsin wọn yi ko mu ete Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Ki wa ni idi? Ṣe nitoripe nkankan n ṣe awọn eniyan yi ni? Rara o! Dipo bẹẹ, idi ni pe ọpọ ninu awọ adari ẹsiin wọn yi ni o jẹ alagabagebe, awọn ti ọkan wọn ko mura tan lati sin Ọlọrun ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. (Wo: Matiu 9:35-36; Matiu 23)
Wayi o, ti a ba ni ki a fi iṣẹ iranṣẹ awọn wọnyi we ti awọn diakoni meje akọkọ ninu ijọ, a o ri pe iyatọ nla gba a ni o wa ni aarin wọn. Idi si ni pe bi o tilẹ jẹ pe a ko ya awọn diakoni yi sọtọ lati waasu bikoṣe lati ṣe amojuto ounjẹ pinpin fun awọn ọmọ Ọlọrun, iṣẹ iranṣẹ wọn yọri si titan kalẹ ọrọ Ọlọrun si ati idagbasoke ijọ rẹ. Ki lo si fa a? Nkan ti o fa a naa ni pe awọn diakoni yi ṣe iṣẹ isin wọn pẹlu ọkan ti o ṣe olotitọ si Ọlọrun. Nitorina, ti a ba jẹ olotitọ si Ọlọrun ninu iṣẹ isin wa, O le lo ohunkohun ti a ba n ṣe, bi o ti wu ki o ma ja mọ nkankan to loju awọn eniyan, lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Amọ ti a ko ba jẹ olotitọ si, bi mo ti ṣe sọ siwaju tẹlẹ, afaimọ ni ki a ma di iṣẹ rẹ lọwọ tabi ba a jẹ.
Bẹẹni, ni awọn igbakan, ni tootọ, Ọlọrun ma n mọn-ọn-mọn foju fo aiṣedeede awọn eniyan si ninu iṣẹ isin wọn, ti yoo si tun mu ki ete rẹ wa si imusẹ nipasẹ nkan ti wọn n ṣe. Fun apẹẹrẹ, igba kan wa ti Mose ati Arọni ṣe aigbọran si, ti wọn si tun ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ ti O ran wọn. Eyi tunmọ si pe, pẹlupẹlu aigbọran awọn ọkunrin yi, Ọlọrun si tun ṣe iṣẹ iyanu fun awọn eniyan rẹ nipasẹ nkan ti wọn ṣe. Amọ ṣe wọn wa ri ere gba fun aiṣododo wọn? Oti o! Dipo eyi, nṣe ni a da seria fun wọn gidigidi. (Wo: Numeri 20:1-13)
Lafikun, ti a ba wo igbe aye Samusoni, a ri pe ẹkọ kan pataki ti o kọ wa ni pe o ṣeeṣe ki a jẹ alaiṣootọ si Ọlọrun ninu aye wa tabi ninu iṣẹ isin wa, ki a si tun ma ri iṣẹ tabi ọwọ agbara rẹ ninu ohun ti a n ṣe. Amọ ṣa o, bi a tun ṣe ri nipasẹ itan aye ọkunrin yi, ti a ba tẹsiwaju pẹlu aiṣodo si Ọlọrun ninu aye wa tabi ninu iṣẹ isin wa, akoko naa di dandan ki o de ti yoo jẹ ki oju wa ri ere aiṣododo wa gbogbo, eyi ti o si le ka wa laya. (Wo: Onidajọ 13-16)
Nitorina, ti o ko ba jẹ olododo ninu iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun, mọ pe o di dandan ko lẹyin. Ọkan lara ọmọ ti eyi yoo si bi ni pe o ko ni ri ere tabi oriyin gba lọwọ rẹ fun ohunkohun ti o ba n ṣe. Awọn nkan miran ti o si tun le ti ẹyin rẹ jade wa ni emi tabi ẹnikankan ko le sọ. Ṣugbọn o le buru jọjọ. Idi si ni yi ti o fi nilo lati ṣe agbeyẹwo bi iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun ṣe dangajia to. Ranti pe a ko le tan an jẹ tabi mu un ṣere. Eyi tunmọ si pe nkan ti o ba gbin naa ni o o ka. (Wo: Saamu 18:25-26; Galatia 6:7-8)
Ti o ba gbin ẹtan, aiṣododo tabi agabagebe ninu iṣẹ isin rẹ si i, eso ti iwọ naa yoo ka di dandan ki o fi han. TI o ba si gbin isododo, ifarabalẹ ṣiṣẹ ati ifẹ ninu iṣẹ isin rẹ si, eso ti o o ka naa yoo fi han. Nitorina, ye parọ tan ara rẹ jẹ mọ nipa iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun, ki o si dojukọ otitọ nipa bi o ṣe dangajia si. Bẹẹni, ṣe agbeyẹwo didangajia iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun pẹlu imọlẹ ọrọ rẹ, ki o ba le ṣe ohun ti o tọ nipa rẹ. Aijẹbẹ, ara rẹ nikan naa ni o o da lẹbi nigba ti Oun naa ba bẹrẹ si ni pin ọ lere gẹgẹ bi iṣẹ isin rẹ ṣe gba. Mo si gbadura pe o ko ni padanu ere isẹ isin rẹ si Ọlọrun nikẹyinkẹyin tabi ki o jẹ iya lọpọlọpọ nitori pe o ko sin in bi o ṣe tọ ati bi o ṣẹ yẹ, ni orukọ Jesu. Amin
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
