Lo o fun imọriri | Lati ọwọ: Paitọ J.O. Lawal

Ọjọ: Ọpẹ 05, 2021 | Atẹlera: Latori tabili | Nọmba: Vol. 10, No. 31

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olugbala ati Oluwa wa. O fun mi ni ayọ gidigidi lati ki ọ kaabọ sinu oṣu ti o pari ọdun yi, iyẹn oṣu Ọpẹ 2021. Mo si gbadura pe ki aye ati ile rẹ kun akunwọsilẹ fun ayọ ati alaafia ninu gbogbo oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ṣe wọ inu oṣu ti o kẹyin ọdun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati lo o lati mọ riri Ọlọrun ati awọn ti O ti lo lati bukun fun ọ ni ọna kan tabi omiran ninu ọdun naa. Ki si ni idi ti o fi yẹ ki o mọ riri Ọlọrun? Akọkọ, idi ni ni pe ifẹ rẹ fun ọ ni eyi (1Tẹsalonika 5:18). Ifẹ Ọlọrun ni pe ki ẹni kọọkan ti o n gbe ninu aye ti O da, ti o si n jẹ igbadun ipese rẹ ti o wa ninu aye naa lati fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o mọ oore, bi o ti wu ki igba ri fun iru ẹni bẹ. Nitorina, bi awọn nkankan ko ba tilẹ lọ deede fun wọn ninu aye yi ni asiko yi, wọn si nilo lati kọ bi a n ṣe n fi ọpẹ fun Ọlọrun fun awọn nkan ti o n lọ deede fun wọn. Idi si ni pe nkan ko ba ti buru ju bi o ṣe wa fun wọn lọ, ti ko ba ki i ṣe ti Ọlọrun (Saamu 124).

Ekeji, o nilo lati mọ riri Ọlọrun nitoripe eyi ni yoo ṣi ilẹkun silẹ fun ọ lati ri nkan gba si lọwọ rẹ ati lati tun ni iriri aṣepe awọn nkan ti o ti ri gba lọwọ rẹ (Saamu 50:23). Wo o, nkankinkan ti a ba ni lọwọlọwọ yi, bi o ti wu ki o dara tabi buru to, ko ki i ṣe ohun ti o dara julọ fun wa lati ni ni aye yi. Ko si igba ti nkan ti o dara ju eyi ti a ni lọwọ lọ ko ki i wa ni ọwọ Ọlọrun, awọn nkan ti o kọja nkan ti oye wa le gbe tabi tọpinpin rẹ (Efesu 3:20). Ti a ko ba si kọ lati ma fi ọpẹ fun Ọlọrun fun ẹbun wiwa laaye ati fun gbogbo awọn nkan rere ti o wa ninu aye wa, a ko ni fi ara wa han gẹgẹ bi ẹni ti o yẹ lati ri nkan pupọ miran gba si lọwọ rẹ tabi lati ri aṣepe awọn nkan ti ko lọ deede ninu aye wa.

Nitorina, eyi ti iwọ yoo fi ma wo awọn nkan ti ko lọ deede ninu aye rẹ, ti o o si ma ṣe aroye lori wọn, kọkọ fi aye silẹ lati fi ara balẹ ṣe agbeyẹwo awọn nkan ti o n lọ deede ninu aye rẹ, ki o si ma fi ọpẹ fun Ọlọrun fun wọn. Si ranti pe ọwọ rẹ ni ohun rere ati ohun ti o peye gbogbo ti n wa. Nitorina, ti ohunkohun ba n lọ deede ninu aye rẹ, Oun ni o wa nidi rẹ. O ṣi yẹ ki o mọ eyi, ki o si fi ọkan otitọ dupẹ lọwọ rẹ fun un. (Wo: Saamu 103:1-5; Aisaya 26:12; Jemisi 1:17)

Siwaju si, ma ṣe gbagbe ara rẹ nitori awọn nkan daradara melokan ti Ọlọrun ti ṣe fun ọ de ibi pe o ko ni ranti lati dupẹ lọwọ rẹ. Idi si nipe nkan si tun pọ ti o le ri gba lọwọ rẹ. Ti o ko ba wa fi ẹmi imoore han fun awọn nkan ti O ti ṣe fun ọ, njẹ o ko ni ma gbe ilẹkun ohun rere miran ti o le ri gba lọwọ rẹ ti mọ ara rẹ bi? Ranti awọn adẹtẹ mẹwa ti Jesu wo san. Ọkan ṣoṣo lara wọn ni o pada wa dupẹ lọwọ rẹ. Inu awọn yoku ti dun kọja ala, de ibi pe wọn ko ranti lati pada wa dupẹ lọwọ rẹ. Ọkunrin kan ti o si wa pada wa yi nikan naa ni o ri ọrọ ibukun miran gba si lọwọ rẹ — igbagbọ rẹ mu ọ lara da. Nibakan naa, iye awọn ti o ba pada tọ Ọlọrun wa ni opin ọdun yi lati dupẹ lọwọ rẹ fun gbogbo awọn nkan ti O ti ṣe fun wọn ninu ọdun naa nikan naa ni yoo ri ọpọ nkan gba si lọwọ rẹ, ti wọn yoo si tun ri aṣepe awọn nkan ti O ti ṣe fun wọn tẹlẹ.

Bawo wa ni o ṣe le fi ẹmi imoore han si Ọlọrun fun awọn nkan ti O ti ṣe fun ọ ni ọdun yi? Akọkọ, o le fi han nipa yiyin in pẹlu ọrọ rẹ, orin rẹ ati ijo rẹ (2Samuẹli 6:14; Luuku 17:15; Iṣe Apọsiteli 3:8). Ekeji, o le fi han nipa fifi nkan fun un. Eyi tunmọ si pe ki o fi nkan silẹ fun ọrọ ijọba rẹ, fun itankalẹ ihinrere rẹ. Nitorina, ti o ko ba i ti fi igba kankan ninu ọdun yi ṣe nkankan fun ijọba Ọlọrun ni mimọ riri awọn nkan ti O ti n ṣe ninu aye rẹ, mura lati ṣe bẹ ninu oṣu yi. Ẹkẹta, o le fi han nipa fifi gbogbo igba lo awọn nkan ti O fun ọ lati polongo ododo rẹ.

Ni akotan, bi mo ti ṣe tọkasi siwaju, ko ki i ṣe Ọlọrun nikan ni o yẹ ki o mọ riri rẹ ni opin ọdun yi; o yẹ ki tun mọ riri gbogbo awọn ti O ti lo lati bukun fun ọ, daabo bo ọ tabi fa ọ soke ninu ọdun naa. Mo mọ pe ko si ẹnikankan ninu wa ti o le mọ gbogbo awọn ti Ọlọrun ti lo tabi ti o n lo lati mu ki aye wa dara si ati ki o si tun wa ni ailewu si. Ṣugbọn awọn kan wa ti o jẹ wipe a le tọka si ipa ribiribi ti wọn ti ko ninu aye wa. O si yẹ ki a ronu si ọna ti a le fi mọ riri awọn naa pẹlu. Idi si ni pe ti wọn ko ba fi ara wọn jin fun Ọlọrun lati lo fun wa, o ṣeeṣe ki awọn irufẹ igbega tabi igbala kan ti a ri gba ni ọdun yi di ọrọ ọjọ iwaju.

Wayi o, ma ṣe ṣe awawi kankan lori ọrọ yi. Ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni eniyan ma n nilo owo ti o pọ lati mọ riri awọn miran, ti a ba ni arojinlẹ. Nitorinaa, nṣe ni ki o ṣe bi Dafidi, ẹni ti o jẹ wipe, ni ọjọ ọpọ yanturu rẹ, o fi ẹbun ranṣẹ si gbogbo awọn ọrẹ rẹ ti wọn tẹwọgba, ti wọn si pese fun ni gbogbo akoko ti o n sa kaakiri nitori Sọọlu ọba (1Samuẹli 30:26-31). Ki Ọlọrun si busi fun ọ lọpọlọpọ pẹlu ohun rere gbogbo ni ọsu Ọpẹ yi, ki o ba le fi tọkantọkan fi imoore rẹ han si i ati si gbogbo awọn ti O ti lo fun ọ ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni oṣu Ọpẹ 2021 ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *