Ọjọ: Sẹrẹ 02, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 35
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ akọkọ ninu ọdun yi, ọdun 2022. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o ni iriri iṣorire ni gbogbo ọna rẹ ninu gbogbo ọdun naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, ẹnikan le bere pe, “Njẹ o tilẹ ṣeeṣe fun eniyan lati ni iriri iṣorire ni gbogbo ọna rẹ ninu aye yi ti o kun fun oniruuru iyalẹnu ati idojukọ?” Bẹẹni, o ṣeeṣe, ti eniyan ba mọ ọna ti o yẹ ki o tọ. Fun apẹẹrẹ, ti a ba wo akọsilẹ inu iwe Joṣua, a o ri wipe ọkunrin yi ṣe idari awọn ọmọ Isiraẹli ti Moṣe ko jade lati Ijibiti wa lati inu iṣẹgun de inu iṣẹgun titi o fi mu wọn wọ ile Kenani, eyi ti Ọlọrun ti ṣeleri lati fi fun wọn. O ṣe aṣeyọri lati ibẹrẹ de opin. Nitorina, o ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ ni aṣepe, eyi ti o ni i ṣe pẹlu pe ki o fun ẹnikọọkan awọn eniyan naa ni ogun tirẹ ni ilẹ naa ti o n ṣan fun wara ati fun oyin.
Ki wa lo jẹ ki Joṣua, ti ko ki i ṣe alufa tabi wolii ṣugbọn jagunjagun, ṣe aṣeyọri ni ọna yi? Ki lo fa ti o fi ṣe aṣeyọri ni gbogbo ọna rẹ? Ifarajin rẹ fun ọrọ Ọlọrun lo fa. Ọlọrun ti kọkọ sọ eyi fun nigba ti o fẹ gba iṣẹ kiko awọn ọmọ Isiraẹli wọ ile ileri: “Iwe ofin yii ko gbọdọ kuro ni ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o maa ṣe aṣaro ninu rẹ ni ọsan ati ni oru, ki o le kiye si i lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ sinu rẹ: nitori nigba naa ni iwọ o ṣe ọna rẹ ni rere, nigba naa ni yoo si dara fun ọ.” (Joṣua 1:8)
Ki ni Joṣua nilo lati ṣe lati ṣorire ati lati ṣe aṣeyọri, gẹgẹ bi ẹṣẹ bibeli yẹn ṣe sọ? O nilo lati mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun. Akọkọ, o gbọdọ ma ka a, ma gbe yẹwo ati maa polongo rẹ si ara rẹ ati si awọn ti o n dari. Ekeji, o gbọdọ ma fi gbogbo igba ṣe aṣaro ninu nkan ti ọrọ yi sọ, lọsan ati lorun. Ki si ni idi? Idi ni pe eyi ni yoo jẹ ki o le farabalẹ gbe aye rẹ ni ibamu pẹlu nkan ti ọrọ naa sọ. O wa tunmọ si pe ti a o ba ma ṣe amulo ọrọ Ọlọrun, a gbọdọ fi ara wa jin fun ṣiṣe aṣaro ninu rẹ ni gbogbo igba. A gbọdọ ma fi gbogbo igba ronu le lori titi yoo fi di ọkan pẹlu wa, ti a ko si ni le ṣe nkankan ti o lodi si.
Ka ma fa ọrọ gun, Aṣẹ ti Joṣua gba ni pe ki oun funraraẹ mu ọrọ Ọlọrun ni pataki. Ṣe o wa ṣe bẹ ẹ tabi ko ṣe bẹ ẹ? O ṣe bẹ ẹ! Idi ti o fi ṣe aṣeyori, ti o si tun yege ni kiko awọn eniyan ti o n dari wọn ile ini wọn, gẹgẹ bi aṣe Ọlọrun, ni pe o ṣe bẹ ẹ. Nigba ti ọjọ aye rẹ si fẹ wa si opin, o fun awọn eniyan naa ni irufẹ aṣẹ ti Ọlọrun fun un, wipe, “Nitori naa ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin Mose, ki eyin ki o ma ṣe yipada kuro ninu rẹ si ọtun tabi si osi.” (Joṣua 26:6)
Nitorina, iru ẹni yowu ti o jẹ, ibi yowu ti o n gbe ati iru iṣẹ ti o tọna wo lowu ki o ma a ṣe, ti iwọ naa ba mu ọrọ Ọlọrun ni pataki ninu ọdun yi, ti o ba si fi ara rẹ jin lati kọ nkan ti o n sọ nipa bi o ṣe yẹ ki o gbe aye rẹ, lati ṣaṣaro ninu rẹ ati lati ṣe amulo rẹ, iwọ naa yoo lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun ni gbogbo nkan ti o ba dawọ le ninu ọdun naa. Lotitọ, awọn idojukọ yoo wa ninu ọdun naa, gẹgẹ bi awọn anfaani lati gbe nkan nla ṣe yoo ṣe wa ninu rẹ pẹlu. Ṣugbọn kiki awọn ti o ba mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun nikan naa ni aṣeyọri wọn ni gbogbo ọna daju, gẹgẹ bi o ti ṣe ri fun Joṣua.
Njẹ iwọ yoo wa pinu lọkan rẹ lati mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun ninu ọdun yi bi, ki o ba le ṣe aṣeyọri, ki o si yege ni gbogbo ọna rẹ? Ni ti emi o, mo ti pinu ninu ọkan mi lati mu ọrọ rẹ ni pataki ninu ọdun yi nitori pe mo fẹ yege ni gbogbo ọna ninu rẹ. Mo si mọ pe yoo jẹ ki o ṣeeṣe fun mi nipasẹ Ẹmi rẹ, nitori pe O ti sọ pe ti awa ba fẹ, ti a si gbọran, Oun yoo ri pe a jẹ igbadun awọn nkan ti o daraju ni ilẹ ti a ba wa (Aisaya 1:19). Ti iwọ naa ba si fẹ lati ṣe gẹgẹ bi O ti ṣe paṣẹ fun wa, yoo ri daju pe o ni ohun gbogbo ti o nilo lati tẹ ẹ lọrun ati lati ni iṣegun ni gbogbo igba. Njẹ ki o ma fi gbogbo igba gba okun lati ṣe bẹ ẹ gẹgẹ ni orukọ Jesu. Amin.
A kun ọdun o!
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
