Nigba ti o nilo lati tẹ siwaju | Paito J.O. Lawal

Ọjọ: Ọpẹ 26, 2021 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ | Nọmba: Vol. 10, No. 34

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ ti o pari ọdun yi. Mo si gbadura pe ki a ṣe ọkan rẹ yẹ, ki a si tun fun ni okun nipasẹ Ẹmi Ọlọrun lati gbera lati ibi ti o wa lọ si ibi ti Ọlọrun fẹ ki o wa ninu ọdun ti a n lọ sinu rẹ yi. Amin.

Nigba ti awọn ọmọ Isiraẹli sunmọ tosi ilẹ Kenani, eyi ti Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn baba-nla wọn, O sọ eyi fun wọn nipasẹ Mose: “Ẹyin ti gbe ori oke yii pẹ to: Ẹ yi pada, ki ẹyin si mu ọna yin pọn, ki ẹ si lọ si oke awọn ọmọ Amọ, ati si gbogbo agbegbe rẹ, ni pẹtẹlẹ, ni ori oke, ati ni afonifoji, ati ni iha guusu, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lẹbanoni, de odo nla ni, odo Yufurete. Wo o, mo ti fi ilẹ naa siwaju yin: ẹ wọ ọ lọ, ki ẹ si gba ilẹ naa, ti Oluwa ti bura fun awọn baba yin, fun Aburahamu, Isaaki, ati Jakọbu, lati fi fun wọn ati iru ọmọ wọn lẹyin wọn.” (Ditaronomi 1:6-8)

Kini nkan akọkọ ti Ọlọrun kọkọ pe akiyesi awọn ọmọ Isiraẹli yi si? Oun naa ni pe wọn ti duro nibi ti wọn wa pẹ to, wọn si nilo lati tẹsiwaju. Eyi tunmọ si pe itẹsiwaju wa jẹ Ọlọrun logun. Aṣeyọri wa laye yi si jẹ logun pẹlu. Ko fẹ ki a wa ni ojukan tabi ki a jẹ ki nkan ti ko to nkan tẹ wa lọrun, nigba ti o jẹ wipe a le ri ọpọlọpọ gba lọwọ rẹ. Nitorina, ti aye wa ba wa lojukannaa, ti ko si ni iriri itẹsiwaju tabi ilọsiwaju lọdun yi tabi lati ọdun melokan sẹyin, a nilo lati kan si, ki O ba le da si ọrọ wa, ki O si fi nkan ti o dojuru nibẹ han wa. Amọ ti a ba kan lero tabi gba pe ifẹ rẹ ni fun wa lati wa ni ojukannaa ninu aye yi, a jẹ wipe a ti kuna niyẹn.

Bi a ti ṣe ri niti ọrọ awọn ọmọ Isiraẹli ti O mu jade lati Ijibiti wa, akoko kan wa ti O sọ fun wọn kedere pe wọn nilo lati tẹsiwaju. Ibo wa ni ki wọn tẹsiwaju si? O rọrun lati pinnu lati tẹsiwaju laye yi. Ṣugbọn ko ki I ṣe gbogbo igba ti awọn eniyan ba gbera lati tẹsiwaju naa lo jẹ pe o ma n yọri si ilọsiwaju tabi itura. Awọn ti o ba tẹsiwaju ni ibamu pẹlu ete Ọlọrun fun aye wọn nikan naa ni yoo ri ere lori titẹsiwaju wọn.

Nitorinaa, ti o ba woye pe o ti pẹ ju ni ibi ti o wa, ti o si nilo lati tẹsiwaju, ma kan gbera lati tẹsiwaju sibi ti o ba wu ọ. Dipo eyi, ri wipe titẹsiwaju rẹ wa ni ibamu pẹlu ete Ọlọrun fun aye rẹ. Ti Ọlọrun ba si ti fi ete rẹ han ọ lori bi o ṣe yẹ ki o tẹsiwaju ati ibi ti o yẹ ki o tẹsiwaju si, ma ṣe fi akoko ṣofo rara lati ṣe bẹ.

Lẹkan si, bi a ti ṣe ri ni ti ọrọ awọn ara Isiraẹli yẹn, Ọlọrun ni O sọ fun wọn pe akoko ti to fun wọn lati tẹsiwaju. Lafikun, Oun naa ni o tun sọ fun wọn ibi ti wọn yoo tẹsiwaju lọ. Ibo si ni o yẹ ki wọn tẹsiwaju lọ? Ilẹ ti O ti ṣeleri fun awọn baba-nla wọn, ilẹ ti o n ṣan fun wara ati fun oyin, ni o yẹ ki wọn tẹsiwaju lọ. O wa ṣeni laanu pe, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun ti sọ pe akoko ti to fun wọn lati gba ilẹ yi gẹgẹ bi ini wọn ati wipe Oun ti fun wọn ni ilẹ naa, wọn kọ jalẹ lati wọ ibẹ lọ ni akoko yi lati gba a. Nitorinaa, nṣe ni wọn fi ogoji ọdun ti o tẹle akoko yi ranmu kaakiri inu aginju, lalai gba tabi gbadun nkan ti a ti fi fun wọn. (Wo: Numeri 13-14; Ditaronomi 1)

Wayi o, mo mọ pe o ko ni fẹ fi gbogbo ọdun ti a fẹ wọ inu rẹ yi ranmu kaakiri aye lalai ri nkan ti Ọlọrun ti pese silẹ fun ọ gba tabi gbadun. Nitorinaa, o nilo lati ṣetan lati tẹsiwaju lati gba gẹgẹ bi ini rẹ ohun gbogbo ti Ọlọrun ba ti sọ pe tirẹ ni. Lotitọ, awọn omiran le wa ni ilẹ naa. Ṣugbọn niwọn igba ti Ọlọrun ba ti sọ fun ọ pe tirẹ ni i ṣe, nṣe ni ki o tẹsiwaju, ki o si gba a, nitoripe Oun yoo ri daju pe O mojuto awọn omiran ti o wa nibẹ fun ọ. Yatọ si eyi, ma kan ṣe tẹsiwaju lati gba ohunkohun nitoripe o ro wipe o le e gba a. Dipo bẹẹ, nipasẹ adura, ṣiṣaṣaro ninu ọrọ Ọlọrun ati wiwa itọni ẹmi, ri daju pe ohunkohun ti o ba fẹ nawọ gan jẹ ohun ti Ọlọrun ti yan fun ọ. Si wa wo o, yatọ si pe eyi ko ni fi aye gba ọ lati fi laala tabi ifarajin rẹ sọfo lori nkan ti ko ni lere, yoo tun jẹ ki o ṣeeṣe fun ọ lati jẹgbadun ohunkohun ti o ba gba gẹgẹ bi nkan ini rẹ. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun dari rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.

A ku imura ọdun.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *