Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọ-tayọ ki ọ kaabọ sinu ọjọ akọkọ ninu ọdun tuntun yi, ọdun 2023. Adura mi si ni pe gbogbo ìṣíṣẹ̀ rẹ ninu ọdun naa ni Ọlọrun yoo tọ ni ipa ọna isinmi, ilera ati itayọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ni pataki julọ, o yẹ ki a fi iyin fun Ọlọrun fun ẹbun ọdun tuntun yi. Bi iwọ gan yo ṣe gba pẹlu mi, ọpọ ni o fojusọna lati darapọ mọ ọdun tuntun yi ṣugbọn ti wọn ti ku ba yi, fun idi kan tabi omiran. O wa yẹ ki o ye awa ti a wa laaye lati ri ọdun naa ati lati kopa ninu rẹ pe ko ki i ṣe ifẹ wa, agbara wa tabi ọgbọn wa ni o jẹ ki didarapọ wa pẹlu ọdun yi ṣeeṣe. Dipo eyi, aanu Ọlọrun ni o jẹ ki o ṣeeṣe.
Bibeli sọ wipe, “Njẹ bẹẹ ni ki i ṣe ti ẹni ti o fẹ, ki i ṣi i ṣe ti ẹni ti n sare, bi ko ṣe ti Ọlọrun ti n ṣaanu.” (Roomu 9:16) Niwọn igba ti o wa jẹ pe aanu Ọlọrun ni o fun wa ni ọdun tuntun yi gẹgẹ bi ẹbun, o yẹ ki a dupẹ lọwọ rẹ fun un. Yatọ si iyẹn, o yẹ ki a pinnu lọkan wa lati lo ẹbun ọdun naa lati yẹ ẹ si. Lotitọ, o tọna fun wa lati ni ala ati afojusun fun ọdun naa. Ṣugbọn o ṣeeṣe ki awọn ala wa ati afojusun wa ma ja mọ nkankan, ti a ko ba ka ẹni ti o fun wa ni anfaani lati le lala ati lati le ni afojusun si tabi ti a ba kọ lati fi si aye ti o tọ si i ninu aye wa.
Nigbakanri ti O n kọ awọn ọmọlẹyin rẹ lori bi wọn ṣe le ba aini wọn pade ati mu awọn ala wọn ati afojusun wọn wa si imuṣẹ, Jesu Oluwa wa sọ eyi fun wọn: “Ṣugbọn, ẹ kọkọ wa ijọba rẹ na ati ododo rẹ, yoo si fi gbogbo awọn nnkan wọnyi kun un fun yin pẹlu.” (Matiu 6:33) Bi awọn ọrọ wọnyi ṣi ṣe jẹ otitọ pọnbele ni igba ti wọn kọkọ jabọ ni ẹnu Oluwa wa naa ni wọn si tun ṣe jẹ otitọ loni. Ọna kan ṣoṣo ti a fi le ba gbogbo awọn ainu wa pade, ki a si tun ri imuṣẹ awọn ala wọn ni ki a fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu aye wa.
Lotitọ, ti a ko ba fi ṣe akọkọ ninu aye wa, a si le ri awọn nkankan tabi pupọ gan lara awọn aini wa, ala wa ati ilakaka wa laye yi yanju. Ṣugbọn, lẹyin-ọ-rẹyin, ti a ko ba fi Ọlọrun ṣiwaju ninu aye wa, awọn aini wa ti o ṣe pataki julọ ko ni jẹ yiyanju – ko tilẹ le jẹ yiyanju. Fun apẹrẹ, ọkan kọọkan ni o ma n pongbẹ lati gbe titi lailai. Bẹẹni, ninu ọkan ẹnikọọkan ni ipongbẹ lati gbe igbe aye ti o loorin ju eyi ti a n gbe lorilẹ aye yi wa. A mọ ninu wa pe irufẹ aye yi wa nibikan niwaju wa. A si mọ pe a nilo rẹ. Ṣibẹ bi a ṣe le ri aye yi gbamu tabi de ibẹ kọja nkan ti oye wa le gbe. (Wo: Oniwaasu 3:11)
Ṣugbọn Ọlọrun, eni ti o ni aye, mọ ọna lati tan ẹdun ọkan ayeraye wa yi. Lafikun, O ni agbara lati tan an. Yatọ si iyẹn, ọ̀rọ̀ wa mumu lọkan rẹ, O si n fẹ lati tan ẹdun ọkan wa yi ati awọn aini yowu ti a tun le e ni. Abalajọ ti bibeli ṣe sọ wipe ọrọ wa jẹ ẹ logun ati wipe O n fi ojoojumọ gbe bukata wa. Ohun ti a kan nilo lati ṣe ki O ba le mojuto gbogbo aini wa, ilakaka wa ati ala wa ni ki a fi siwaju ninu aye wa. (Sáàmù 68:19; 1Pétérù 5:7)
Njẹ a o wa fi siwaju ninu aye wa lọdun yi bi? Njẹ iwọ yoo fi Oun ati ohun gbogbo ti o ṣe pataki si siwaju ninu aye rẹ? Ti o ba ṣe eyi, gẹgẹ bi Jesu Oluwa wa ti fi ye wa, ko si aini rẹ kan, yala nipa ti ara ni, nipa ti ẹmi ni tabi nipa ti ero ọkan ni, ti ko ni mojuto. Ki a tilẹ sọ otitọ, yoo mojuto awọn aini rẹ ti o ko mọ nkankan nipa wọn gan, yoo si tun ri daju pe a ti tẹ ọ lọrun lẹkunrẹrẹ nigba ti ọdun yi i ba wa si opin. Adura mi si pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba fi siwaju ni gbogbo ọna rẹ ninu gbogbo ọdun yi, ki ohunkohun ti o nilo ninu ọdun naa ma ba ṣe alaiwaniarọwọto fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọdún ayọ̀ o.
Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
