Iṣedajọ iwa ika | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹna 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 44

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Ẹrẹ́nà 2023. Adura mi ni pe ki Ọlọrun gbe ọ ro lati jẹ ẹni naa ti yoo le ma fi gbogbo igba gbẹkẹle lati di dẹkun iwa ibi tabi lati ṣe idajọ rẹ nibikibi ti o ba wa, ki ododo rẹ ba le jọba nibẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ṣiṣe idajọ ibi tabi idajọ iwa aidara awọn eniyan ko ki fi gbogbo igba jẹ nkan ti o rọrun lati ṣe, pẹlupẹlu ninu ijọ Ọlọrun. Idi si ni pe ọpọ igba ni awọn eniyan ma n koro oju si tabi gbogun ti. Sibẹsibẹ, nkan ti o gbọdọ ma waye loorekoore ni, ti a ba fẹ ki awujọ wa wa ni ilera, ki o si tun wa ni ailewu fun wa lati gbe. Kiki awọn ti o ba si ṣetan lati ṣe idajọ iwa bi ati iwa aidara ni awọn ọna ti o tọna nikan naa ni o le jẹ adari otitọ fun Ọlọrun, yala nipa nkan ti aye yi ni tabi nipa nkan ti ẹmi.

Solomọni, ninu iwe rẹ, Oniwaasu, sọ eyi fun wa: “Nigba ti a ko ba tete ṣe idajọ fun ẹlẹṣẹ kiakia, ọkan awọn eniyan a maa kun fun ọpọlọpọ imọ lati ṣe ibi.” (Ìwé Oníwàásù 8:11) Ṣe o ri bayi? Ti awọn eniyan ba n ṣiwawu, ti ko si si ẹni ti yoo da wọn lẹjọ fun iwa aidara wọn, nṣe ni awọn ati awọn miran ti wọn ri bi wọn ti ṣe n ṣe ika ti wọn si n mu u jẹ yoo gba okun si lati tun ṣiwawu ṣiwaju si i. Ti eyi ba si tẹsiwaju, ti akoko kan ba to, Ọlọrun yoo nilo lati gbe igbesẹ lati ṣe idajọ awọn ika funrarẹ.

Fun apẹẹrẹ, asiko kan wa ti awọn ọkunrin Isiraẹli ti Mose ko jade lati Ijibiti wa bẹrẹ si ni ti ọwọ bọ ẹṣẹ agbere pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu. Awọn ọmọbinrin yi si lo eyi lati tan wọn wọ inu ibọriṣa lọ. Nitorina, Ọlọrun ran ajakalẹ-arun si arin wa lati pa wọn run. Ki ni idi? Idi ni pe ko si ẹnikankan ti o mojuto tabi ṣe idajọ ọrọ naa nigba ti o bẹrẹ. Ki a ni pe ẹnikan ti mojuto ọrọ naa, ti o si tun ṣe idajọ rẹ nigba ti o ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ọpọ ninu awọn ọkunrin naa ko ba ma ti kopa ninu radarada naa ati pe Ọlọrun ko ba ma ti gbe igbesẹ lori rẹ.

Ni kukuru, igba ti Mose yoo fi ṣọji lati ṣe idajọ ọrọ naa, ọpọ eniyan ni o ti sọ ẹmi wọn nu. Nigba ti o tilẹ tun wa bẹrẹ si ni ba awọn onidajọ aarin awọn eniyan naa sọrọ lati ṣe iwadi ọrọ na ati lati ṣe idajọ awọn ti o kopa ninu rẹ, nṣe ni ọmọkurin ọkan lara awọn adari wọn tun mọ ọmọbirin Moabu kan wọ inu agọ rẹ lọ niwaju gbogbo wọn lati ṣe iṣekuṣe pẹlu rẹ. Eyi, bi mo to ṣe sọ ṣẹyin, ni o ma n ṣaba ṣẹlẹ nigba ti awọn eniyan ba n ṣiwawu, ti ko si si ẹni ti yoo da wọn lẹkun. Nṣe ni aya wọn yoo ki si lati ṣe nkan ti o buru ju eyi ti wọn ti ṣe ṣẹyin lọ. (Wo: Nọmba 25)

Ki a wa fọpẹ fun Ọlọrun pe ọdọmọkurin alufa kan kọ lati fi aye gba radarada yi lati tẹsiwaju ni ilẹ naa. Ẹni na ni Finehasi, ọmọ-ọmọ Aarọni. Ọkunrin yi mu ọ̀kọ̀ rẹ, o tẹle alagidi ọmọ Isiraẹli yi, o si pa oun ati ẹnikeji rẹ nibi ti wọn ti n wuwa ibi wọn. Nigba ti o si ṣe eyi tan, bi akọsilẹ iṣẹlẹ naa tun ṣe fi ye wa, lẹsẹkẹsẹ ni ajakalẹ-arun naa ṣiwọ. Ọlọrun wa sọ awọn ọrọ iwuri yi nipa rẹ fun Mose:

“Finehasi, ọmọ Eliasa, ọmọ Aarọni alufaa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Isiraẹli, nipa itara rẹ nitori mi laarin wọn, ki emi ki o ma baa ṣe run awọn ọmọ Isiraẹli ninu ọwọ mi. Nitori naa wi pe, kiyesi i, emi fi majẹmu alaafia mi fun un. Yoo jẹ tirẹ ati ti iru ọmọ rẹ lẹyin rẹ, ani majemu iṣẹ alufaa titi aye; nitori ti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ, o si ṣe etutu fun awọn ọmọ Isiraẹli” (Nọ́mbà 25:11-13)

Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun sọ wipe idi ti Oun ko ṣe pa awọn ọmọ Isiraẹli run fun ẹṣẹ wọn ni asiko ti a n sọ yi ni Finehasi. Lọna wo? Gẹgẹ bi Ọlọrun ti sọ, Finehasi ṣe etutu fun ẹṣẹ awọn eniyan naa nipa ṣiṣe idajọ ọkunrin yẹn ati enikeji rẹ ninu ẹṣẹ wọn. Nitorina, igbakigba ti awa naa ba n ṣe idajọ iwa aidara tabi iwa-ika-ki-iwa-ika ni ọna ti o tọ, bi igba ti a n ṣe etutu fun ẹṣe awọn eniyan wa ni. Bi Ọlọrun si ṣe gboriyin fun Finehasi ni igba yẹn naa ni yoo ṣe gbe oriyin fun awọn naa.

Nitorina, ibibiki ti o ba ti wa ni ipo lati ṣe idajọ iwa ibi tabi lati ṣe idajọ iwa aidara awọn eniyan, ma ṣe lọra rara lati ṣe e. Bẹẹni, awọn ti ọrọ naa kan, pẹlupẹlu ninu ijọ, le da ọ lẹbi tabi sọ ọ ni orukọ-ko-rukọ fun ṣiṣe bẹ ẹ. Ṣugbọn o nilo lati ṣe ohun ti o nilo lati ṣe. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi Eli ti o kuna lati ṣe idajọ iwa ibi awọn ọmọkunrin rẹ, nṣe ni iwọ naa yoo ma ranṣẹ pe Ọlọrun wa lati ṣe idajọ ọrọ naa funrarẹ. Ta wa ni o mọ ọna ti yoo gba dajọ?

Ki o ni ọsẹ ologo.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *