Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ TẸSALÓNÍKÀ KÍNNÍ AYỌKA: 1TẸSALÓNÍKÀ 4:13-18 ÀKỌ́SÓRÍ: “”Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii ṣe lasan.” (1Tẹsalonika 2:1)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kọja lọ ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, a ri wipe o ṣe pataki ki ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni Kirisitiẹni fi ara rẹ jin fun gbigbe igbe aye ti o wu Ọlọrun. Idi si ni wipe nkan ti a da wa fun ni eyi. Ṣugbọn ti a ko ba mọ awọn nkan ti o sorọ mọ gbigbe igbe aye yi, bi a tilẹ ni lọkan lati gbe e, a ko ni gbe e. Eyi si wa lara idi ti Pọọlu ati awọn yoku rẹ ninu iṣẹ iranṣẹ ṣe fi ara balẹ kọ awọn ara Tẹsalonika ni awọn nkan ti wọn nilo lati mọ nipa gbigbe igbe aye ti o wu Ọlọrun. Bi a si ti ri ninu lẹta yi, igbe aye ti o wu Ọlọrun jẹ igbe eye aileri, igbe aye ifẹ ati igbe aye ẹni ti o to oju bọ. Amọ ṣa o, aye yi kọ ni ohun gbogbo pari si fun Kirisitiẹni. Ijọba ayeraye Ọlọrun si n bọ wa fi idi mulẹ ni akoko ti O ti yan. Eyi si jẹ nkan ti ẹnikọọkan wa gbọdọ mura silẹ de. Ṣugbọn, niwọn igba ti a ko mọ ọjọ tabi akoko ti eyi yoo waye, ko si ni ki awọn ara wa kan ma sun ninu Oluwa ki akoko yi to de. Ọpọlọpọ ni o si tun sun ninu rẹ tabi ku fun oniruuru idi. Bawo wa ni o ṣe yẹ ki a tẹwọgba eyi, gẹgẹ bi Kirisitiẹni? Nkan ti Pọọlu n ba awọn ara Tẹsalonika sọrọ le lori ni eyi ninu abala lẹta rẹ ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. O si ṣe pataki ki a kọbiara si, ki a si ma ṣe amulo rẹ, ki gbogbo idamu, wahala ati iku ti o sọrọ mọ gbigbe aye yi ma ba fi irẹwẹsi sọkan wa, ki wọn si jẹ ki a yẹ ẹsẹ ninu irinajo igbagbọ wa.
MÁ ṢE ṢE BÍ ÀWỌN TÍ KÒ NÍ ÌRÈTÍ
Wayi o, ninu lẹta rẹ si awọn ara Éfésù, ori ikeji, Pọọlu jẹ ki o ye wa pe ẹnikẹni ti ko ba ni Jesu, ko ni ireti ifọkanbalẹ tabi igbadun kankan kọja aye ti a wa yi (Éfésù 2:12). Aye yi ni gbogbo igbadun, ifọkanbalẹ ati aye jijẹ rẹ mọ. Lẹyin eyi, idajọ ti o tọ si awọn ti ko mọ Ọlọrun ni yoo ba pade. Eyi yoo si yọri si ipọnju ati irora ayeraye, eyi ti ko ṣe fẹnusọ fun. Amọ bawo wa ni ti Kirisitiẹni ti ṣe jẹ? Ṣe inu aye yi naa ni gbogbo igbadun tabi ifọkanbalẹ rẹ mọ bi? Rara o! Aye yi kọ ni igbadun rẹ mọ. Ṣugbọn aye yi ni gbogbo irora, aibalẹọkan, ẹkun, ijakulẹ, oṣe ati idamu yowu ti o le ba pade mọ. Idi si ni pe Ọlọrun ti pese aye silẹ fun ninu ijọba ayeraye rẹ, eyi ti o n bọ wa. A sọ eyi nipa ijọba yi ninu iwe ifihan: “Mo si gbọ ohun nla kan lati ori itẹ ni wa, n wi pe, Kiyesi i, agọ Ọlọrun wa laarin awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ eniyan rẹ, ati Ọlọrun tikararẹ yoo wa pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nu kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.” (Ìfihàn 21:4-5)
Nitori eyi, Kirisitiẹni ni gbogbo idi lati foju sọna fun ọjọ yi, ọjọ ti ilẹ yoo mọ, ti yoo si bọ sinu ile ayọ ayeraye ti Ọlọrun ti pese silẹ fun. Amọ ṣa o, niwọn igba ti o ba si wa ni aye yi, ti Jesu ko si ti de, ko si bi ko ṣe ni ba ara rẹ ni awọn asiko ti yoo sọrọ mọ pipadanu awọn ẹni ti o fẹran tabi ti o sunmọ gidigidi sọwọ iku, bi awọn wọnyi tilẹ jẹ Kirisitiẹni. O le jẹ nipasẹ aisan, ogun, ijamba, inunibini tabi ajalu. O tilẹ le jẹ wipe awọn ti a n sọ yi ti dagba, ti wọn si ti da arugbo ki wọn to kun. Ṣugbọn a ko le fẹ iru rẹ ku nitoripe aye ti a wa ninu rẹ jẹ eyi ti ko ni wa titi lailai. Bẹẹ si ni awa ti a wa ninu aye naa ko ni wa ninu rẹ titi lailai. O di dandan ki a kuro ninu rẹ lọjọ kan, boya nipasẹ iku ni o tabi nipasẹ bibọ Jesu. Ti a ba wa ri pe eniyan wa kan fi aye silẹ, ko yẹ ki a ṣe bi awọn ti ko mọ Ọlọrun ti ṣe n ṣe rara. Nṣe ni o yẹ ki a ṣe bi ẹni ti o ni imọ ati imoye nkan ti Ọlọrun ti sọ nipa ayeraye ti o n bọ, yala fun awọn ti o gba a gbọ tabi awọn ti ko gba a gbọ.
Eyi si ni Pọọlu fẹ ki o ye awọn ara Tẹsalonika ninu abala lẹta rẹ ti a n gbe yẹwo bayi. Wo nkan ti o sọ lori rẹ:
“Ṣugbọn awa ko fẹ ki ẹyin ko jẹ ope, ara, ni ti awọn ti o ti sun, pe ki ẹ ma banu jẹ gẹgẹ bi awọn yooku ti ko ni ireti. Nitori bi awa ba gbagbọ pe Jesu ti ku, o si ti ji dide, gẹgẹ bẹẹ ni Ọlọrun yoo mu awọn ti o ti sun pẹlu ninu Jesu wa pẹlu ara rẹ. Nitori eyi yii ni awa n wi fun yin nipa ọrọ Oluwa, pe awa ti o wa laye, ti a si ku lẹyin de atiwa Oluwa, bi o ti wu ki o ri, ki yoo ṣaaju awọn ti o sun lati pade rẹ. Nitori Oluwa tikararẹ yoo sọ kalẹ lati ọrun wa ti oun ti ariwo, pẹlu ipe Ọlọrun; awọn oku ninu Kirisiti ni yoo si kọ ji dide. Nigba naa ni a o si gba awa ti o wa laaye ti o si ku lẹyin soke pẹlu wọn sinu ikuukuu, lati pade Oluwa ni oju ọrun. Bẹ ni awa o si maa wa lọdọ Oluwa titi lae. Nitori naa, ẹ maa fi ọrọ wọnyi tu ara yin ninu.” (1Tẹsalóníkà 4:13-18)
Bi a ko tilẹ sọ ninu lẹta yi, o ṣeeṣe pe lara iroyin ti Timoti mu wa fun Pọọlu nipa ijọ yi ni pe wọn n ṣọfọ, wọn si n barajẹ gidigidi nitori awọn ara wọn kan ti wọn ku tabi ki a sọ wipe ti wọn sun ninu Oluwa. Ti a ko ba gbagbe, gẹgẹ bi akọsilẹ Luuku ninu Iṣe Awọn Apọsiteli, nigba ti arabinrin kan ti a n pe ni Dọkasi, ti o jẹ ọmọ ijọ Joopa, ku, awọn ọmọ ijọ rẹ, paapaa julọ awọn opo ijọ naa ti o ti ran lọwọ lọpọlọpọ, bẹrẹ si ni sukun, ti wọn si n ba ara jẹ pupọ. Ti ko ba wa ṣe pe Peteru wa si ọdọ wọn, ti Ọlọrun si lo lati ji arabinrin yi, o ṣeeṣe ki iku rẹ fi irẹwẹsi si ọkan ọpọ ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn miran ti wọn mọ gẹgẹ bi ẹni ire. (Wo: Iṣe Apọsiteli 9:36-42)
Irufẹ irẹwẹsi yi lo wa fẹ dabi ẹni pe o n ba ijọ awọn ara Tẹsalonika yi finra ni akoko yi. Nitorina, Pọọlu gba wọn niyanju lori iha ti o yẹ ki wọn kọ si iku awọn onigbagbọ. Ki si ni awọn nkan ti o sọ lori eyi? Akọkọ, o fẹ ki wọn mọ pe awọn onigbagbọ ti o ba ku ninu aye yi kan sun ni. Eyi jasi pe nipa ti ara nikan ni wọn ti ku – nipa ti ẹmi wọn wa laaye. Eyi yoo si di mimọ daju fun wa nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada wa lati ko awa ti a jẹ ayanfẹ rẹ wa sọdọ rẹ.
Pọọlu wa tẹsiwaju lati ṣe alaye bi eyi yoo ti ṣe waye. O jẹ ki o ye wa pe gbogbo wa naa ko ni yoo ku ki Jesu to de. Awa kan yoo wa laaye ni akoko bibọ rẹ. Amọ ṣa o, awa ti a wa laaye kọ ni yoo kọkọ darapọ mọ. Awọn ti o ti ku ni yoo kọkọ darapọ mọ, ti yoo si gba agọ ara tuntun ti o dabi tirẹ (1Kọrinnti 15; Filipi 3:20). Bi a tilẹ ti ṣe ri ninu bibeli, awọn ti o ku ninu Kirisiti ti wa pẹlu rẹ lọwọlọwọ yi (2Kọrinnti 5:1-8; Filipi 1:21-25). Ṣugbọn nigba ti O ba de ni a to tun ri wọn. Awa naa yoo si wa gba agọ ara tuntun nigba ti a ba darapọ pẹlu wọn ati Jesu nigba ti O ba de.
Ki wa ni koko gbogbo nkan ti Pọọlu sọ yi? Oun naa ni pe ko si idi fun wa lati banujẹ tabi ṣọfọ bi awọn alaigbagbọ lori awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ wa ninu ijọ, ti wọn jẹ ẹbi wa tabi ti wọn jẹ ọrẹ wa ti wọn ti ku tabi ti wọn ba ku. Wa kiyesi eyi: Pọọlu ko sọ wipe ki a ma banujẹ rara tabi ṣọfọ rara lori awọn eniyan wa ti wọn ba sun ninu Kirisiti. Ti a ba tilẹ ka lẹta rẹ si awọn ara Roomu, o sọ nibẹ pe ki a ma ba awọn ti o n sukun sukun, ki a si ma ba awọn ti o n yọ yọ (Roomu 12:15).
Nitorina, ko ki i ṣe wipe Pọọlu fẹ ki a ro pe ko tọ fun Kirisitiẹni lati sọkun tabi ṣọfọ lori awọn eniyan tabi ọrẹ rẹ ti o ba ku. Jesu Oluwa wa gan sọkun nigba ti O de iboji Lasaru, iyẹn ki O to ji dide (Johanu 11:35). Ko wa si nkan ti o buru nibẹ ti awọn ọmọ ẹyin rẹ naa ba sukun nitori awọn eniyan wọn ti o ku. Nkan ti Pọọlu kan fẹ ki o ye wa ni pe ko yẹ ki a ma banujẹ tabi ṣọfọ lori wọn bi awọn alaiagbagbọ ti ko ni ireti ati ba Jesu jọba titi lailai.
Awa naa mọ bi awọn alaigbagbọ ṣe ma n ṣọfọ ati barajẹ lori awọn eniyan wọn ti o ba ku. Wọn le ma po ara mọlẹ tabi ki wọn ma gbe ara wọn ṣepe. Awọn miran tilẹ le pa gbogbo ojuṣe wọn si ara wọn ati si awọn miran ti o wa ninu aye wọn ti nitori pe wọn n ṣọfọ. A si ri awọn ti wọn ti jẹ ki aye wọn bajẹ patapata nitori pe wọn padanu awọn kan ninu aye wọn. Ṣugbọn eyi ko gbọdọ ri bẹ pẹlu awa ti a jẹ Kirisitiẹni. Lotitọ, ko si ẹni ti inu rẹ yo dun ti o padanu eniyan rẹ tabi ololufẹ rẹ, bi wọn tilẹ ti di arugbo. Amọ, niwọn igba ti awọn ti o ku yi ba ti ku sinu Kirisiti, a gbọdọ mọ lọkan wa pe oju a tunrari. A o tun pade lọjọ kan lọdọ Jesu. A ko si ni ya ara wa mọ lẹyin ipade yi.
Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ mọ pe bi eniyan tilẹ fi wa silẹ, Ọlọrun ko ni fi igba kankan fi wa silẹ. Gbogbo igba ni O ṣetan lati duro ti wa ati lati ri pe ààyè ẹni ti o fi wa silẹ ko ṣofo ninu aye wa. Tiwa kan ni ki a gba a laye lati tu wa ninu, nitoripe Baba itunu gbogbo ni Oun jẹ (2Kọrinnti 1:3-4). Awọn nkan wọnyi si ni Pọọlu sọ pe ki a ma lo lati gba ara wa niyanju ati lati tu ara wa ninu ti a ba padanu ẹnikẹni ninu Kirisiti, ki a ma ba ba ara jẹ kọja ala, ki a si sọ ara wa di idakuda.
ỌRỌ IPARI
O wa ṣeeṣe ki a ri ẹni ti yoo bere pe iha wo ni o wa yẹ ki a kọ si awọn ti o ku, ti ko si ki i ṣe Kirisitiẹni. Bi o tilẹ jẹ pe awọn wọnyi ko ni ireti ijọba ayeraye, niwọn igba ti wọn ti ku, ko si nkan ti a le ṣe lori ọrọ wọn mọ. Bi o ti wu ki a barajẹ to lori ọrọ wọn, ibarajẹ wa ko le yọ wọn kuro ninu ewu ọrun apadi. O ti bọ na. Awọn ti o ku laye nikan ni a le ran lọwọ ki awọn naa ma ba pari irinajo wọn si ibikanna. Nitorina, boya ẹni ti o ku jẹ ọmọ Ọlọrun tabi ọmọ Eṣu, a ko gbọdọ barajẹ tabi banujẹ lori wọn bi awọn ti ko ni oye ọrọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, nṣe ni ki a ma fi gbogbo mura silẹ lati jẹ alabapin ireti ogo ayeraye wa ti o n bọ, iyẹn Jesu Kirisiti Oluwa wa.
IBEERE – Bawo ni ẹkọ yi ṣe ran oye rẹ lori iku ati ajinde lọwọ si?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)