Bì wọ́n lulẹ̀ | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 01, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 10, No. 52
Olùfẹ́: kí oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlááfìà jẹ́ tìrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu karun ọdun yi, oṣu Èbíbí. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki ayọ rẹ ma fi gbogbo ọjọ inu oṣu naa kun akunwọsilẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Laipẹ yi, nṣe ni gbogbo awọn aye ti o wa lori ẹrọ ayelukara wa kun fun iroyin ọmọdebirin ọmọ ọdun mẹwa kan ti wọn sọ pe awọn ọmọ ilẹ-ẹkọ rẹ kan fi ipa ba lopọ, iyẹn nigba ti wọn wa ni Dubai fun awọn ere-idaraya agbaye kan. Lati igba na si wa ni oniruuru esi ọrọ ti n jade lori iṣẹlẹ naa. Awọn kan sọ pe awọn obi ọmọ yi lo yẹ ki a bu fun iṣẹlẹ naa. Awọn miran sọ wipe ile-iwe ọmọ naa ni o yẹ ki a bu fun aiwulo awọn adari rẹ ni mimojuto awọn ọmọ naa. Awọn miran ẹwẹ si sọ wipe awọn gbajumọ kan ati awọn aṣa aibikita ti wọn ni lati ma fi awọn fọnran igbe aye iṣekuṣe wọn sori ẹrọ ayelukara ni o yẹ ki a bu fun iṣẹlẹ naa.
Amọ ṣa o, emi ti wa bere awọn ibere wọnyi lọwọ ara mi lori ọrọ naa: Melo ninu wa gan lo san ju awọn ọmọ yi lọ lotitọ pẹlu igbe aye ti a n gbe lọwọlọwọ yi? Melo ninu wa ni o san ju wọn lọ nigba ti awa naa wa ni ọjọ ori ti wọn wa yi? Mo ṣa ranti daradara pe nigba ti emi paapaa wa ni bi ọjọ ori ọmọ yi, emi naa ni awọn erokero ti ara mi ati awọn ẹmi eṣu ti o n yọ mi lẹnu ti mo ni lati doju ija kọ. Nitorina, emi naa ko ba ti dabi ọkan ninu wọn tabi ki o tilẹ buru fun mi ju wọn lọ.
Ki wa lo fa a ti n ko ṣe dabi ọkan lara wọn? Oore-ọfẹ Ọlọrun ni ko jẹ ki n dabi ọkan lara wọn. Ọna wo si ni oore-ọfẹ rẹ gba ṣe eyi? Akọkọ, o fun mi ni awọn obi ti ko fi aye silẹ fun mi lati dabi wọn, yala nipa ọrọ wọn ni tabi nipa iwa wọn. Ekeji, o fi mi ṣinu ijọ ti mo ti n fi gbogbo igba gbọ ọrọ Ọlọrun, gba adura ati gbọ ọrọ iyanju awọn ẹni-bi-Ọlọrun. Nitorina, awọn erokero wọnyi ti ko ba ti ba aye mi jẹ ko ri aye lati gberu tabi lati fi ara han ninu iṣesi mi.
Nitorinaa, ti o ba jẹ obi, jẹ ki Ọlọrun lo ọ lati pa awọn ọmọ rẹ ati awọn ọmọ miran ni ayika rẹ mọ. Lọna wo? Mojuto irufẹ agbegbe ti o ṣeto silẹ fun awọn ọmọ wọnyi lati dagba ninu rẹ nipa iṣesi rẹ ati ọrọ ẹnu rẹ. Idi si ni pe eyi ni agbara pupọ lati sọ boya ibi yoo bori wọn tabi ko ni bori wọn. Ti o ko ba ki si ṣe obi, o nilo lati ba ara rẹ sọ otitọ ọrọ lori awọn ero buburu ati ifẹkufẹẹ ti o n lepa lati fi ara han ninu iṣesi rẹ. Aijẹbẹ, o di dandan ki wọn bori rẹ, ki wọn si pa aye rẹ run. Lotitọ, aye le ma mọ tabi gbọ nipa bi aye rẹ ṣe bajẹ, gẹgẹ bi wọn ti gbọ nipa ti ọmọdebirin yẹn ati awọn miran bi tirẹ. Ṣugbọn ko ja mọ nkankan boya wọn gbọ si tabi wọn ko gbọ si. Ti aye rẹ ba ti bajẹ, o ti bajẹ naa niyẹn.
Idi si ni yi ti o ṣe gbọdọ ba ara rẹ sọ otitọ ọrọ nipa awọn ero buburu ati ifẹkufẹẹ ti o ni. Ma ṣe dibọn, ki o ṣe bi igba ti wọn ko si nibẹ. Dipo eyi, mojuto wọn. Gbogbo wa naa ni awọn nkan wọnyi n fi ojoojumọ yọ lẹnu. Jesu ati awọn apọsiteli igbaani naa gan fi ojoojumọ ba iyọlẹnu awọn nkan wọnyi pade. Eyi lo si fa ti Peteru ṣe kọ iwe si awọn ijọ Ọlọrun, ti o sọ wipe, “Olùfẹ́, mo bẹ̀ yín bí álejó áti èrò, láti fá sẹ́yín kúrò nínú ífẹ́kúfẹẹ́ ara, tí ń bá ọkán yín jagun.” (1Pétérù 2:11) Nitorina, gbogbo igba ni erokero, ero ibajẹ ati ero iparun ma n gbogun ti ọkan wa. A si gbọdọ gba eyi gẹgẹ bi ododo. Aijẹbẹ, a ko ni le mojuto wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.
Lotitọ, awọn ero buburu yi ko ki i ṣe tiwa. Satani ni o ni wọn. Fun apẹrẹ, ko ki i ṣe aba Jesu ni lati fo silẹ lati ori tente Tẹmipili, ki O si ku. Aba ti Satani ni iyẹn. Bẹẹ si ni ko ki i ṣe ero Judasi Isikariọti ni lati da Jesu. Ero Satani ni. Iyatọ ti o wa wa laarin Jesu ati Judasi ni nkan ti awọn mejeji ṣe si awọn erokero ti Satani fi si wọn lọkan. Nigba ti Jesu bi awọn ero buburu yi lulẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun, nṣe ni Judasi fi aye gba wọn lati gbakoso aye rẹ, ki wọn si pa a run. (Wo: Matiu 4:1-11; Johanu 13:2, 2Kọrinnti 10:5)
Nibakanna, ti a ko ba fẹ ki awọn eru buburu ti o n ba ọkan wa jagun fi ara han ninu aye wa, ki wọn si ba aye wa jẹ, a gbọdọ ṣe amulo ti o peye ọrọ Ọlọrun, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun lati le da awọn ero wọnyi mọ ati lati le bi wọn lulẹ. A si gbọdọ ṣetan lati ṣe eyi lojoojumọ, nitori ojoojumọ ni Satani ṣetan lati ba aye wa jẹ, niwọn igba ti aye ba ti ṣi ṣilẹ fun un. Nitorina, ji kuro ninu oorun ti o n sun, ki o si gbaradi fun ohun yowu to ba de. Ijakadi igbagbọ wa ni eyi. Ijakadi ti o si dara ni, nitori a ti ni awọn nkan ti a nilo lati rin ninu iṣẹgun ninu ijakadi naa ni ojumọ kọọkan ti o ba mọ.
Ki o ni oṣu Èbìbí 2022 alárinrin.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)


