Ǹjẹ́ o wà ní àrọ́wọ́tó rẹ̀? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 21, 2024 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 12, No. 38
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọdun yi, ọdun 2024. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti ko jẹ ki o wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati bukun fun awọn miran, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo igba ni Ọlọrun ma n wa awọn irinṣẹ ti O le lo lati fi idi ete rere rẹ mulẹ ninu aye awọn eniyan. O le jẹ ete rere rẹ lati wo wọn san, lati gba wọn la tabi lati jẹ ki wọn ṣoriire ni O fẹ mu ṣe. O ṣa ma n fi igba gbogbo nilo ọkunrin tabi obinrin kan tabi ọdọmọdekurin tabi odemọdebinrin kan ti o wa ni arọwọto rẹ lati lo nigbakigba ti O ba fẹ.
Fun apẹrẹ, O sọ eyi fun Isikiẹli nipa awọn eniyan Isiraẹli: “Emi si wa ẹnikan laarin wọn, ti iba tun odi naa mọ, ti iba duro ni ibi ti o ya naa niwaju mi fun ilẹ naa, ki emi ma baa parun: ṣugbọn emi ko ri ẹnikan.” (Ísíkíẹ̀lì 22:30) Iwọ naa wo bayẹn. Bi o tilẹ jẹ pe o tọ ki Ọlọrun ṣe idajọ awọn eniyan wọnyi nitori ọpọlọpọ ẹṣẹ wọn, ko si papa kanju lati ṣe idajọ wọn. Dipo bẹẹ, nṣe ni O n fi suuru wa gbogbo ilẹ naa boya Oun yoo tilẹ ri ẹnikan ti o n gbadura si Oun fun wọn, ki O ba le ṣaanu fun wọn. O wa ṣeni laanu pe ko ri ẹnikankan. Nitorina, ko si nkan miran ti O le ṣe ju ki O ṣe idajọ wọn lọ.
Nibakanna, ọpọ ni a ti fi silẹ lati jiya tabi lati ku nitoripe Ọlọrun ko ri ẹnikẹni lati lo lati mojuto wọn. Iwọ naa wo bi awa kan ṣe n gbadura ni gbogbo igba pe ki Ọlọrun da si ọrọ iṣedari orilẹ-ede yi. Ṣe o ro pe Ọlọrun ko ki i tẹti si wa ni? Tabi ṣe o ro wipe ko tilẹ wu u lati dahun adura wa ni? O kuku n tẹti siwa, O si tun n fi idahun si adura wa. Iṣoro ti o wa nibẹ ni pe O le ma ti ri ọkan kankan ni arọwoto rẹ fun lilo lati mu irufẹ itura ati ibalẹ ọkan ti a fẹ tọ wa wa. Nitorina, a tun nilo lati ma gbadura pe ki awọn ọkan ti O le lo lati gba orilẹ-ede wa la wa ni arọwọto rẹ.
Ṣugbọn awa gan an tilẹ wa ni arọwọto rẹ lati lo lati gba irufẹ awọn adura wọnyi? Ṣe a wa ni arọwọto rẹ fun lilo lati ṣe ohunkohun rara? Eleyi kọja ki a ma wa si awọn ipade ijọ wa. A le ma wa si awọn ipade ijọ wa, ki a si ma wa ni arọwọto Ọlọrun fun lilo lati bukun fun ẹnikẹni. Bi o ti ṣeeṣe ki o mọ, o ṣeeṣe ki agọ ara wa wa ninu ipade ijọ kan ṣugbọn ki a wa ni ibomiran ninu ọkan wa. Nitorina, nigba ti wọn ba ṣe awọn nkan ti o le bukun fun awọn miran, bi gbigbadura fun wọn, ninu ipade naa, ọkan wa ko kopa ninu rẹ. Bawo gan wa ni Ọlọrun ṣe fẹ ri wa lo lati bukun fun ẹnikẹni?
Ninu iwe isọtẹlẹ rẹ, Aisaya sọ ọrọ asiko kan ti o ba ara rẹ niwaju Ọlọrun ninu iran kan fun wa. Gẹgẹ bi o ti fi han wa, bi o tilẹ wa jẹ wipe o wa niwaju rẹ, Ọlọrun si tun n bere pe, “Tani n o ran? Tani yoo si lọ fun wa?” Kini idi ti Ọlọrun ko kan ṣe sọ pe, “Aisaya, mo fẹ ran ọ si awọn eniyan mi ki o ba le kọ wọn ni ọna mi?” Idi ni pe Ọlọrun ko ṣetan lati tan ara rẹ pe Aisaya wa ni arọwọto Oun fun lilo nitoripe o kan duro siwaju rẹ. Nitorina, Aisaya nilo lati fihan pe oun wa ni arọwọto rẹ fun lilo ki O to le ran lọ si ibikibi. (Wo: Àìsáyà 6:1-10)
Lọna kanna, pe a n wa si ipade ijọ ko to fun Ọlọrun lati lero wipe a wa ni arọwọtọ rẹ̀ fun lilo, iyẹn ti awa gan an ko ba fihan pe a wa ni arọwọto rẹ ati wipe O le lo wa. Wo ọpọ ijọ wa loni. Njẹ o mọ wipe awọn adari awọn ijọ yi ko kan le gba wipe a wa ni arọwọto wọn lati fun ni iṣẹkiṣẹ, biko ba ṣe pe a fihan pe a wa ni arọwọto wọn?
Fun apẹrẹ, ti o ba ma n fi igba gbogbo parẹ ni kete ti ipade ijọ kan ba ti pari, njẹ a le sọ wipe oun fi ara rẹ han bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati ṣiṣe fun Ọlọrun ninu ijọ rẹ bi? Rara! Tabi ti iṣẹ kan ba wa ti ijọ fẹ ṣe, ti o ko si fi ara rẹ han lati kopa ninu rẹ, lalai ṣe pe o gba aye, ṣe awọn adari rẹ yoo ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti o wa ni arọwọto lati darapọ mọ wọn ni ṣi ṣe iṣẹ fun Ọlọrun bi? Rara! Wo o, ẹni ti adari ijọ rẹ ba n ri ṣaaṣa ni sakani rẹ tabi ẹni ti o n fi gbogbo igba kan si i ni yoo ri bi ẹni ti o wa ni arọwọto oun lati jọ ṣiṣẹ Oluwa. Ko le ri ẹni ti o n fi gbogbo igba tabi ọpọ igba farapamọ fun un bi ẹni ti o fẹ nkan ṣe.
Nitorina, ti a ko ba wa ni arọwọto lati ṣiṣẹ pẹlu awọn adari tabi awọn ọmọ ijọ wa ninu awọn ipade wa, ki lo fẹ fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun gan yoo ri wa bi ẹni ti o wa ni arọwọto rẹ fun lilo ni ibi iṣẹ wa, ile-iwe wa tabi adugbo wa? Ko si. Lotitọ, pe eniyan wa ni arọwọto Ọlọrun ko tunmọ si pe ẹni naa koju-oṣuwọn fun un lati lo. Amọ bi o tilẹ jẹ wipe awa ni a koju-oṣuwọn julọ fun iṣẹ ti O fẹ ṣe, niwọn igba ti a ko ba ti si ni arọwọto rẹ, ko si ni ki a ma jẹ alaiwulo fun un. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹ ẹ, O ṣeeṣe ki Ọlọrun gba aṣálẹ̀ kan lọ lati lọ wa Mose kan lati lo tabi gba inu tubu lọ lati lọ mu Josẹfun miran jade wa tabi lọ si Babiloni lati lọ wa Nehemaya miran lati lo.
Adura mi ni pe ọrọ ko ni su Ọlọrun debi wipe yoo wa ẹni ti yoo fi rọpo wa lọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin. Ọna kan ti a si fi le ma jẹ ki eyi waye ni pe ki a bẹrẹ lati ma fi ara wa si arọwọto rẹ fun lilo.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ tí ó ga.
Copyright © 2024, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)




