Fi ojú sílẹ̀ láti ṣọ́ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 12, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 41

Olufẹ: ki oore ọfẹ ati aanu di pupọ si fun ọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èrèlé 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun tikararẹ ṣe ọ ni mimọ ati ailabuku, lọkan, lẹmi ati lara, nigba ti Jesu Oluwa ati Olugbala wa ba de. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu iwe mimọ, Jesu Kirisiti Oluwa wa n pada bọ wa fun ijọ rẹ ni akoko ti Ọlọrun Baba ti yan. Ṣugbọn ko ki i ṣe ijọ eleeri tabi ijọ ti o ti dibajẹ ni O n pada bọ wa fun. Dipo eyi, O n pada bọ wa fun ijọ ti ko ni abuku, ti ko ni abawọn ati eyi ti yo wa ni ibarẹ pẹlu rẹ nigba ti o ba de. (Wo: Efesu 5:26; 2Peteru 3:14)

Amọ ṣe a wa le wa ni ailabawọn, ailabuku ati aini ohunkohun ti le fa idojuti nigba ti O ba pada wa? Bẹẹni, a le e wa bẹ ẹ. A le e wa bẹ ẹ nitoripe Ẹmi Ọlọrun wa ninu wa, O si n fi gbogbo ara ṣiṣẹ lati ri pe eyi ri bẹ. Bẹẹni, O n ṣiṣẹ ni gbogbo igba lati ri daju pe iṣẹ rere ti O bẹrẹ ninu wa nigba ti a ṣẹṣẹ di atunbi jẹ ṣiṣe titi di ọjọ Oluwa. Nitorina, wiwa ni ailabuku wa nigba ti Jesu ba de ko da lori ifẹ wa tabi ilakaka wa ṣugbọn o da lori iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ninu wa ati lori wa. (Wo: Filipi 1:6 & 2:12-13)

Amo ṣa o, awa naa si wa tun gbọdọ ni lọkan lati wa ni ailabaku nigba ti O ba pada de. Yatọ si iyẹn, a tun gbọdọ ma ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ lati gbe igbe aye ti O fẹ ki a gbe. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki o jẹ wipe awa gan ni a o papa wa fooro iṣẹ ti O n ṣe lati jẹ ki a wa ni alailabuku.
Siwaju si, o ṣe pataki ki a ma fi oju silẹ lati ṣọ ara wa, ki Satani ma ba ṣe aṣeyọri ni titan ẹnikẹni kuro laarin wa lọ si ibi ti yoo ti pa igbagbọ ati aye wọn run. Bibeli sọ awọn nkan wọnyin fun wa lori ọrọ yi:

“Ẹ kiye sara, ara, ki ẹnikẹni ninu yin ki o ma ṣe ni ọkan buburu ati ti aigbagbọ, eyi ti yoo mu yin kuro lọdọ Ọlọrun alaiye.” (Heberu 3:12)

“Ẹ maa kiye sara ki ẹnikẹni ki o ma ṣe kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, ki gbongbo ikoro kan ki o ma baa hu soke ki o si yọ yin lẹnu, ọpọlọpọ a ti ipa rẹ di aimọ. Ki ẹnikẹni ma baa di alagbere tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Isọ, ẹni ti o ti itori okele ounjẹ kan ta ogun ibi rẹ. Nitori ẹyin mọ pe lẹyin naa, nigba ti o fẹ lati jogun ibukun naa, a kọ ọ (nitori ko ri aaye ironupiwada) bi o tilẹ jẹ wi pe o fi omije wa a gidigidi.” (Heberu 12:15-17)

Njẹ o ri bayẹn? Ti gbogbo wa ba fẹ wa ni mimọ ati ailabuku nigba ti Jesu Oluwa wa ba pada de, a gbọdọ fi oju silẹ lati ma ṣọ ara wa. Nipa ṣiṣe eyi, a o le gbe igbesẹ akin lati tọ ara wa sọna, lati ba ara wa wi ati lati daabo bo awọn ara wa, ti a ba kẹfin pe Satani n ṣiṣẹ lati fi pakute mu wọn nipasẹ owu jijẹ, ojukokoro, ẹtanu, iṣọtẹ, ainitẹlọrun, pansaga tabi iṣẹ ẹran ara miran.

Fun apẹrẹ, nigba ti awọn ara ile Kloe ti ijọ awọn ara Kọrinti ri pe ẹran ara ti gba ijọba ijọ yi, wọn ko fi akoko ṣofo rara lati fi to Apọsiteli Pọọlu, ti o jẹ adari wọn ninu ẹmi, leti. Wọn ri wipe iyapa, owu jijẹ, igberaga, iṣekuṣe, iyanjẹ ati aibikita fun igbagbọ awọn ti wọn ṣi jẹ ọmọ ọwọ ninu igbagbọ ti n fa ijọ yi ya. Nitori eyi wọn kọ lẹta si apọsiteli yi, wọn si bere fun amojuto rẹ ni kiakia. Idi niyi ti o ṣe kọ 1Kọrinti. Nitorina, lẹta yi jẹ idahun si ipohunrere ati adura awọn ọmọ ijọ kan ti wọn fẹ ri pe ijọ Ọlọrun wa ni mimọ ati ni ailabuku nigba ti Jesu ba de.

O wa ṣeni laanu pe, loni, ti awọn ara kan ba n ṣe nkan ti o jọ mọ eyi, ti wọn bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ri wipe ijọ wọn wa ni yiya si mimọ si Oluwa, nṣe ni awọn ara miran yoo ma pe wọn ni orukọ, ti wọn yoo si ma ba wọn ja. Ki ni idi? Idi ni pe ifẹ wọn si okunkun si wa digbi. Nitorina, wọn ko fẹ ki iṣẹ rẹ di fifihan tabi mimojuto. Ti a ba wa fi aye gba irufẹ awọn wọnyi lati pa otitọ lẹnu mọ tabi tẹ ori rẹ ba laarin wa, nṣe ni a o ma ran wọn lọwọ lati pa ara wọn ati awọn miran run ati lati ba orukọ Ọlọrun jẹ.

Nitorina, ti wiwa wa ni ailabuku nigba ti Jesu ba de ba ka ọ lara, fi oju rẹ silẹ, ki i si ṣe lati ṣọ ara rẹ nikan ṣugbọn lati ṣọ awọn ara rẹ yoku naa. Ti o ba si wa ri wipe wọn n kuna ni ọna kan tabi omiran, ma ṣe fa ṣẹyin rara lati koju wọn tabi awọn ti o le ran wọn lọwọ pẹlu otitọ, yala inu wọn dun si tabi ko dun si. Amọ ọjọ kan n bọ ti wọn yoo dupẹ lọwọ rẹ fun ṣiṣe oun ti o tọna lati gba wọn la tabi ti wọn yoo da ara wọn lẹbi fun kikọ ifẹ Ọlọrun fun aye wọn silẹ.

Ki o ni ọṣẹ ti o ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi ojú sílẹ̀ láti ṣọ́ wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 12, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 41 Read More »

Ọ̀nà láti jẹ́ pípamọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 40

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Èrèlé 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun pa ọ mọ kuro ninu gbogbo ibi awọn ọjọ ikẹyin yi ti o n pa igbagbọ ati aye awọn eniyan run. Amin.

Mo gba adura yi si Ọlọrun fun ọ nitoripe mo mọ pe ifẹ rẹ ni lati pa gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ mọ kuro ninu idibajẹ ati awọn ibi ti o wa ninu awọ ọjọ ikẹyin yi. Bibeli tilẹ sọ fun wa pe a le gbẹkẹle lati pa wọn mọ nitori olododo Ọlọrun ni o jẹ (1Tẹsalóníkà 5:23-24). Ṣugbọn ọtọ ni ki Ọlọrun mura giri lati pa aye ati igbagbọ wa mọ; ọtọ tun si ni ki awa naa fi ara wa si ibi ti yoo ti le ṣe bẹ ẹ. Ti o ko ba fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa aye ati igbagbọ rẹ mọ, o ko le wa ni ipamọ. Eyi ko si ki ṣe epe. Otitọ pọnbele ni.

Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti Ọlọrun ti le pa ọ mọ kuro ninu awọn idibajẹ awọn ọjọ ikẹyin yi? O le ṣe eyi nipa fifi ara rẹ jin fun ọrọ otitọ rẹ, yala o rọrun fun ọ lati tẹwọgba tabi ko rọrun fun ọ lati tẹwọgba. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si Timoti, sọ eyi:

“Nitori naa mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kirisiti Jesu, ẹni ti yoo ṣe idajọ alaaye ati oku, ati nitori ifarahan rẹ ati ijọba rẹ. Waasu ọrọ naa, ṣe aisinmi ni akoko ti o wọ, ati akoko ti ko wọ; baniwi, ṣe itọni, gbani niyanju pẹlu ipamọra ati ẹkọ gbogbo. Nitori pe igba yoo de, ti wọn ki yoo le gba ẹkọ ti o ye kooro, ṣugbọn bi wọn ti jẹ ẹni ti eti n rin, wọn o lọ ko olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Wọn o si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ, wọn o si yipada si itan asan.” (2Tìmótíù 4:1-4)

Ki ni Pọọlu sọ fun Timoti ninu akọsilẹ yi? Akọkọ, o sọ fun pe ki o ma waasu ọrọ Ọlọrun dipo ti yoo fi ma fi ero ọkan tirẹ, ero ọkan awọn eniyan ti o gbaju-gbaja lawujọ, itan adugbo tabi iṣeṣe ṣe iwaasu. Ekeji, o sọ fun pe ki o ma wa ni igbaradi lati tọ awọn ọmọ Ọlọrun sọna, lati ba wọn wi ati lati gba wọn niyanju, yala o rọrun fun tabi ko rọrun fun. Ṣugbọn ṣe ko yẹ ki Timoti ti mọ awọn nkan wọnyi tẹlẹ ni, paapaa julọ niwọn igba ti o jẹ wipe pasitọ awọn pasitọ ni o jẹ? O yẹ ki o ti mọ wọn.

Ki wa lo de ti o fi nilo ẹnikan lati ṣeṣẹ ma pasẹ fun lati fi ara rẹ jin fun ṣiṣe awọn nkan wọnyi? Bi a ti ri ninu akọsilẹ yi, idi ni pe akoko kan n bọ (akoko naa si ti de bayi) ti ọpọ awọn ti o pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ko ni fi ara mọ ẹkọ ti o ye kooro ṣugbọn ti wọn yoo wa awọn ti yoo ma sọ nkan ti eti ti o n rin wọn fẹ gbọ fun wọn. Pọọlu tilẹ tẹsiwaju lati sọ wipe awọn wọnyi yoo yi eti wọn pada kuro lọdọ otitọ ki wọn ba le ma gbọ awọn itan abalaye ati irọ. Nigbati ti eyi ba si ṣẹlẹ, o ṣeeṣe ki Timoti bẹrẹ si ni ro wipe boya oun ti fe le mọ wọn ju, ki o si wa titori eyi bẹrẹ si ni yi iwaasu rẹ pada lati tẹ ifẹ wọn lọrun. Nitorina, Pọọlu kilọ fun niwaju Ọlọrun ati niwaju Jesu Kirisiti lati ma ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, yoo pa iṣẹ iranṣẹ rẹ run, yoo si tun padanu ere rẹ.

Nibakanna, ọpọ ninu ijọ loni ni ko fẹ fi ara mọ otitọ mọ, iyẹn ti wọn ba tilẹ ti fi igban kankan tẹlẹ fi ara mọ ọn. Idi si niyi ti wọn fi n gba inu ijọ kan de inu ijọ miran, ti ko si jẹ fi idi mọlẹ si ibi kankan. Awọn adari bi Aarọni ti yoo fun wọn ni ohunkohun ti wọn ba fẹ, bi o tilẹ jẹ ere wura ni, tẹ awọn wọnyi lọrun ju awọn adari ti yoo koju wọn pẹlu otitọ nipa aye wọn ati nipa ifẹ Ọlọrun fun wọn. (Wo: Ẹ́kísódù 32)

Wayi o, otitọ ti o wa nibẹ ni pe Ọlọrun ko le pa irufẹ awọn eniyan bi eyi mọ kuro ninu idibajẹ tabi ko wọn yọ ki eṣu ma ba ṣi wọn lọna tabi pa wọn run. Ti iwọ naa ko ba si fẹ ki opin aye rẹ ri bi ti wọn, ti o ba fẹ ki Ọlọrun ko ọ yọ ni awọn ọjọ ikẹyin yi, ki O si tun jẹ ki igbagbọ rẹ duro deede, nṣe ni ki o ya fi ara rẹ jin fun ọrọ rẹ ti o ye kooro ati fun itọni ti Ẹmi, dipo eyi ti iwọ yoo fi ma wa awọn ti yoo ma fi ọwọ ra ọ lori ti o o fi ṣegbe kiri. Mo si tun fẹ ki o mọ eyi daju: awa kan si wa ti a ko ni yi iwaasu wa pada lati tẹ ọ lọrun. Bẹẹni, awa kan si wa ti a ko jẹ fun ọ ni ere wura kankan lati bọ, ohun yowu ki o sọ nipa wa tabi ki o ro nipa wa. Idi si ni pe iwọ kọ ni a o jiyin fun bikoṣe Ọlọrun ti O ran wa niṣẹ. Njẹ ki Ọlọrun fun ọ ni ọkan ti yoo ma fi igba gbogbo wa ni irẹlẹ lati tẹwọgba ọrọ otitọ rẹ lalai jiyan. Amin.

Kí o ní oṣu Èrèlé 2023 tí ó ga.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀nà láti jẹ́ pípamọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èrèlé 05, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 40 Read More »

Ẹ ṣààmì sí wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 22, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 39

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọṣẹ miran lọdun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki ọkan rẹ wa ni pipe ati ni irẹlẹ niwaju rẹ ni gbogbo igba, ki o ma ba ni iriri iṣubu kankan ṣugbọn iriri igbega lọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi bibeli ti ṣe sọ fun wa, igberaga jẹ ọkan pataki lara awọn idi ti awọn eniyan fi ma n ni iriri iṣubu tabi ti a fi ma n di wọn lọwọ lati ni iriri igbega laye yi. Ti a ba si wa n rin ninu igberaga, a je wipe o ṣeeṣe ki a bi wa lulẹ lati ipo atata yowu ti a le wa tabi ki a ma jẹ ki a gberi kọja ibi ti a wa laye. Nitorina, ṣọra fun oniruuru igberaga, ki o si ri wipe o ko fi aye gba ọkankan ninu wọn lati fi gbongbo mulẹ ninu aye rẹ. (Wo: Iwe Owe 16:18; Jemisi 4:6-7; 1Peteru 5:5-6)

Wayi o, ọkan lara oniruuru igberaga ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i tete damọ, ṣugbọn ti o si wa ninu ọpọlọpọ wa, ni o ni i ṣe pẹlu aigbọran si awọn alaṣẹ nipa ti ẹmi. Ti mo ba si n sọrọ nipa awọn alaṣẹ nipa ti ẹmi, mo n sọrọ nipa awọn ti Ọlọrun yan le ọ lori ninu ijọ rẹ. Awọn wọnyi ni O yan lati bọ ọ pẹlu ọrọ rẹ ati lati ma ṣọna lori ọkan rẹ nipa adura gbigba ati ibaṣepọ igbagbọ. Nitorina, nkan ti mo n sọ kọ nipe gbogbo pasitọ, wolii, ajinyinrere tabi apọsiteli ti o ba pade naa ni adari ẹmi fun ọ, ti o si gbọdọ gbọran si lẹnu.

Ti eniyan ko ba ki i ṣe adari ninu ijọ rẹ, ko pọn dandan fun ọ lati tẹle aṣe yowu ti o ba pa fun ọ, yala o dara tabi ko dara, ti ko ba ki i ṣe pe ẹ ti jọ ni ajọsepọ tẹlẹ, ti o si tun mọn-ọn si ẹni ti o le fọkantan. Ṣugbọn ti eniyan ba jẹ adari ijọ rẹ, o pọn dandan fun ọ lati gbọran si aṣẹ rẹ, niwọn igba ti awọn aṣẹ naa ba ti wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. O wa ṣeni laanu pe ọpọ igba ni a ma n ri awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n bu ọla ti o ga fun awọn adari ijọ ti a ko yan le wọn lori nigba ti wọn a si ma tabuku awọn ti a yan le wọn lori ninu ijọ wọn.

Ṣugbọn eyi ko tọna rara, o si tun lodi si ifẹ Ọlọrun fun aye wa. Pọọlu, nigba ti o n ba awọn ara Kọrinnti sọrọ lori nkan wọnyi, sọ wipe niwọn igba ti wọn n ran awọn adari ijọ kan ti ko si lori awọn ijọ wọn lọwọ, ti wọn si tun n bọwọ fun wọn, ṣe ko wa yẹ ki wọn ran oun tikararẹ lọwọ, ki wọn si tun bọwọ fun ju awọn wọnyi lọ, niwọn igba ti o jẹ pe oun ni baba wọn ninu igbagbọ ati pe ko fi igba kankan dẹkun lati ma sin wọn pẹlu ọrọ Ọlọrun ati adura? O yẹ bẹẹ. (Wo: 1Kọrinnti 9:11-12)

Nibakanna, ti o ba rọ iwọ naa lọrun lati ran awọn adari ijọ kan ti ko ma ṣọna le ọ lori ninu igbagbọ tabi ti o ko tilẹ ti fi igba kankan pade lọwọ ati lati bọwọ fun wọn, ṣe o wa yẹ ki o ṣoro fun ọ lati bọwọ fun awọn adari ijọ rẹ ti o n fi gbogbo igba sin ọ ati lati ran wọn lọwọ ju awọn wọnyẹ lọ? Ni kukuru, ara idi ti a fi ma n ri awọn adari ijọ wa fin lọna yi ni igberaga. Nigba ti a ba woye pe adari ijọ kan ko ni imọ to tabi dagba to tabi jafafa to tabi ka iwe to lati paṣẹ fun wa tabi dari wa, a ko ni gbọran si lẹnu tabi mu ni pataki.

Lafikun, ti a ko ba ni imọ ewu ti o sorọ mọ ki a ma gbọran si awọn adari ijọ wa lẹnu tabi ki a ma ri wọn fin, ọpọ ninu wa ninu ijọ loni si ni ko ni imọ awọn nkan wọnyi, o ṣeeṣe ki a ma ṣe aigbọran si wọn lẹnu tabi ki a ma tabuku wọn bi o ti ṣe wu wa. Ṣugbọn bi a ti ṣe ri ninu Iwe mimọ, ewu buruku lo sọrọ mọ ki a ma tabuku awọn adari wa ninu ẹmi tabi ki a ma kọ awọn eniyan lati ṣe orikunkun si wọn, bi o ti wu ki awọn adari yi kere lọjọ ori to tabi jẹ ẹni ti ko láapan to. Nitorina, ki ara rẹ nílọ̀ lórí awọn nkan yi. Aijẹbẹ, o le ma pẹ rara ti wa a fi ko ara rẹ sinu iyọnu ti Ọlọrun ko ni ko ọ yọ ninu rẹ. (Wo: Numeri 12&17)

Ni akotan, Pọọlu sọ eyi fun wa nipa bi o ti yẹ ki a ma ṣe si awọn ti ko ba mu awọn adari wa ninu ijọ ni pataki: “Bi ẹnikẹni ko ba si pa ofin wa ninu lẹta yii mọ, ẹ ṣaami si ẹni naa. Ẹ ma ṣe ba a kẹgbẹ ki oju ba a le ti i. Ṣibẹ, ẹ ma ṣe kaa si ọta, ṣugbọn ẹ maa kilọ fun-un gẹgẹ bi arakunrin yin.” (2Tẹsalóníkà 3:14-15) Njẹ o ri bayi? A sọ fun wa pe ki a ṣaami si ẹnikẹni ninu ijọ wa ti ko ba mu awọn adari wa ni pataki, ti o n sọrọ si wọn bi o ti ṣe wu tabi ti o n kọ awọn eniyan lati kọ etí ikún si aṣẹ wọn. Ki si ni idi? Akọkọ, ki a ba le kilọ fun wọn. Ekeji, ki a ba le yẹra fun wọn ti wọn ko ba gbọ ikilọ. Aijẹbẹ, awa funrawa le jẹ alabapin ninu ewu ti o sorọ mọ aigbọran wọn lẹyin-ọ-rẹyin.

Nitorina, ma fi gbogbo igba kiyesi bi awọn ti o n baa rin ninu ijọ ti ṣe n ṣe si awọn adari yin ninu ẹmi, bi o ti wu ki o fẹran wọn to. Eyi ni yoo jẹ ki o mọ boya wọn yoo busi idagbasoke rẹ ninu ijọba Ọlọrun tabi boya wọn yo lọwọ si iṣubu rẹ. Njẹ ki Ọlọrun kun ọ fun oye, okun ati igboya ti o peye lati ṣe eyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ atata.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ẹ ṣààmì sí wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 22, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 39 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:3-10 | ỌJỌ́RÚ 25, SẸRẸ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

(Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri iha ti o yẹ ki a kọ si awọn ara wa ninu Kirisiti ti o ba ṣubu sinu ẹṣẹ. Iha wo si ni o yẹ ki a kọ si wọn? Iha imupadabọsipo ni o yẹ ki a kọ si wọn. Eyi tunmọ si pe ojuṣe wa ni lati ri daju pe iru awọn Kirisitiẹni bẹ ko ku tabi sọnu patapata sinu ẹṣẹ. Ki eleyi wa to o ṣeeṣe, awa ti a fẹ mu wọn padabọsipo gbọdọ jẹ ẹni ti o n tẹle itọni Ẹmi Ọlọrun, onisuuru ati onirẹlẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ba nkan jẹ ju bi o ti ṣe wa lọ. Amọ bi a tun ti ṣe kọ ninu ẹkọ yi, ko pọn dandan ki ẹnikẹni ninu wa ṣubu sinu ẹṣẹ. Ti gbogbo wa ba tilẹ mura gidigidi lati jẹ alabaapin ninu aye awọn ọmọ ijọ wa, ọpọ igba ni Ọlọrun yoo ri wa lo lati dena ki wọn ko sinu pakute ẹṣẹ. Ṣugbọn ti a ba gbe igberaga wọ bi ẹwu, ti a ko si ṣetan lati ba awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa ṣe pọ tabi lati fi aye gba wọn lati mọ bi nkan ti ṣe n lọ ninu aye wa, ko si ni ki Satani ma ri wa ya sọtọ ni awọn abala aye wa kan lati fi iya jẹ wa tabi lati sọ igbagbọ wa di igbagbe.

ÌGBÉRAẸNI-NÍGBỌ̀NWỌ́
Ori ọrọ yi si tun ni Pọọlu wa ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Nkan ti o si fẹ ki o ye awọn ọmọ Ọlọrun yi naa ni pataki ki wọn ma gbe ara wọn ni igbọnwọ ninu irinajo wọn. Lotitọ, olukuluku ọmọ Ọlọrun ni yoo dahun funrarẹ nigba ti Ọlọrun ba n ṣe idajọ. Ko si si ẹnikankan ninu wa ti yoo ni awijare tabi ti yoo le sọ wipe oun kuna nitori aṣiṣe awọn kan tabi nitoripe oun ko ni onigbọnwọ. Nitorina, ẹnikọọkan wa gbọdọ mura lati mojuto ohun gbogbo ti o ba jẹ ojuṣe rẹ lati tẹ Ọlọrun lọrun ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ, yala o ri ẹni ti yoo ran an lọwọ tabi ko ri.

Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni ki ẹnikọọkan wa ma fi gbogbo igba duro bi oluranlọwọ fun awọn ara wa. Aijẹbẹ, a ko ni mu ofin Kirisiti ṣẹ. Eyi si le jẹ ki a jẹbi iṣubu tabi ikuna awọn ara wa kan tabi omiran. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọ wipe ki ẹnikọọkan wa gbe igberaga ju sigbo, ki a si dẹkun lati ma ri ara wa ni bàbàrà, ki Ọlọrun ba le ri wa lo lati ma gbe awọn ara wa ninu Kirisiti nigbọnwọ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:

“Nitori bi eniyan kan ba n ro ara rẹ si ẹni pataki kan, nigba ti ko jẹ nnkan, o n tan ara rẹ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ wo, nigba naa ni yoo si ni ohun isogo nipa ti ara rẹ nikan, ki yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ. Nitori olukuluku ni yoo ru ẹru ara rẹ. Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti o n kọ ọ.” (Gàlátíà 6:3-6)

Njẹ o ri bayi? Igberaga ni o ma n fa ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i fi ba ara wọn ṣepọ lọna ti o tọ ati ti o yẹ. Niwọn igba ti wọn ko ba si ni ibaṣepọ ti o munadoko laarin ara wọn, ko si bi wọn ṣe le ran ara wọn lọwọ lọna ti o peye. Ki wa lo n fa irufẹ igberaga yi? Nkan kan gbogi ti o ma n fa naa ni ki a ma fi iṣẹ́ igbagbọ wa we ti awọn ọmọ Ọlọrun miran. Eyi ni o le jẹ ki a ka ara wa si ẹni pataki niwaju ara wa, nigba ti a ko si ja mọ nkankan laisi Ọlọrun.

Ko si idi kankan lati fi iṣẹ igbagbọ wa we ti ẹnikẹni. Ti a ba n ṣe agbeyẹwo iṣẹ wa, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu ireti Ọlọrun lori rẹ. Ti a ba si n ṣe agbeyẹwo irinajo igbagbọ wa bakanna, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun n reti lati ọdọ wa. Eyi jasi pe a ko gbọdọ ma wo aago-alaago sare tabi wo iṣẹ oniṣẹ ṣiṣẹ. Eyi ni ko ni jẹ ki a ba ẹnikẹni ninu ijọ wa lo pẹlu ọkan igberaga tabi pẹlu ọkan ẹni ti ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun.

Gbogbo wa ni a ṣe pataki si Ọlọrun ati si ijọba rẹ. Idi si niyi ti o ṣe jẹ wipe gbogbo wa ni o ran ọmọ rẹ Jesu Kirisiti lati rapada. O ṣeeṣe, lotitọ, ki oye bi a ti ṣe n gbe aye tẹ ẹ lọrun tete ye awa kan ju awọn kan lọ, eyi ko tunmọ si pe a ṣe pataki ju awọn wọnyi lọ niwaju rẹ. Nitori eyi, ọna ti a o gba ma ran igbagbọ ati aye wọn lọwọ ni a gbọdọ ma fi gbogbo igba san, ko ki i ṣe bi a o ti ṣe fi ẹnu tẹnbẹlu wọn tabi ja wọn kulẹ.

Bi mo ti ṣe wa sọ siwaju, wipe a gbọdọ ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ ko tunmọ si pe ki a wa sọ ara wa di bukata fun awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ko tunmọ si pe ki a fi ojuṣe adura gbigba wa, ojuṣe mimọ ifẹ Ọlọrun wa tabi awọn ojuṣe itọju ile wa kọ awọn ọmọ Ọlọrun miran lọrun. Eyi ko bojumu rara, ko si wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki a tilẹ sọ otitọ, imọtaraẹninikan ni yoo jẹ ki a ṣe eleyi. O si lewu fun igbagbọ wa. Nitorina, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe wi, ẹnikọọkan gbọdọ mura lati gbe bukata rẹ, lalai duro de ẹnikẹni fun iranwọ.

Amọ ṣa o, Pọọlu tun wa la ọrọ rẹ, ki a ma ba ṣi i tunmọ. Lọna wo? O jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe ẹnikọọkan ninu ijọ Ọlọrun gbọdọ mura lati gbe ẹru aye rẹ, eyi ko jasi pe ki a pa awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ti ṣẹgbẹ kan, ki a si ọ pe ki awọn naa lọ ma mojuto bukata wọn funra wọn. Dipo eyi, a gbọdọ mọ pe ara ojuṣe wa ni lati ma a pin awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ninu ohun rere gbogbo ti a ba n rigba lọwọ rẹ. Ko yẹ ki a gbagbe pe awọn wọnyi ni o n kọ wa ni ọrọ Ọlọrun ti a n mulo ti aye wa fi n lọ deede. Nitorinaa, aṣẹ Ọlọrun ni pe bi aye wa ti n tipasẹ wọn lọ deede naa ni o yẹ ki a ma tọju wọn pẹlu awọn nkan ini wa. (Wo:1Kọrinnti 9:14)

Yatọ si eyi, ti enikan ba tọ wa sọna nipa ti ara, ti itọsọna rẹ si ja si igbega tabi ọrọ fun wa, ṣe ko yẹ ki a fi ẹmi imoore han siru ẹni bẹ ẹ? O yẹ! Nitorinaa, ma ṣe jẹ ki o ni ọ lara rara lati ma fifun awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ Ọlọrun, ti o si n ṣọna ninu adura lori aye rẹ, ni ibamu pẹlu bi a ti ṣe bukun fun ọ. O lere lori pupọ. (Wo: Numeri 10:29-3)

Eyi lo si fa ti Pọọlu fi tẹsiwaju lati sọ awọn ọrọ pataki yi fun wa lori fififunni:

“Ki a ma ṣe tan yin jẹ; a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, oun ni yoo ka. Nitori ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti ara rẹ, nipa ti ara ni yoo ka idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti Ẹmi, nipa ti Ẹmi ni yoo ka iye ainipẹkun. Ẹ ma si jẹ ki agara da wa ni rere e ṣe: nitori a yoo kaa nigba ti akoko ba de, bi a ko ba rẹwẹsi. Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Gàlátíà 6:7-10)

Njẹ o ri bayi? Wipe Ọlọrun fẹ ki a ma fifun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, ti o si n ṣọna lori aye wa, ati awọn miran ti O pa wa lasẹ lati ma fifun ko tunmọ si pe ki a kan ṣe bi a ba ti ṣe fẹ. Alakalẹ fififunni wa ninu iwe mimọ ti a gbọdọ tẹle. Aijẹbẹ, a kan tan ara wa jẹ ni – ififunni wa ko ni ni ere kankan lori. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi, Ọlọrun ko si lara awọn ti a le gan tabi tan jẹ. Nkan ti a ba ṣe ni a o gba ere rẹ lọwọ rẹ. Irugbin ti a ba fun ni Ọlọrun yoo fi ibukun ati ere sori rẹ. Ti a funrugbin nipa ti ara, ni ibamu pẹlu ifẹ inu wa, ninu rikiṣi, ọtẹ, itanjẹ ati ikunsinu, eso ti ara ti o jẹ idibajẹ naa ni a o ka. Ti a ba si funrugbin nipa ti Ẹmi, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun bi a ti ṣe la a kalẹ ninu iwe mimọ, eso ti Ẹmi ti a o ma gbadun titi ayeraye naa ni a o ka.

O wa ku sọwọ wa irufẹ irugbin ti a fẹ fun ati bi a ti ṣe fẹ fun. Amọ iyanju Pọọlu si wa ni pe ki a ma ṣe jẹ ki agara da wa ni rere ṣiṣe si gbogbo eniyan, paapaa julọ awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, ki a ma ṣe amulo gbogbo anfaani ti Ọlọrun ba fun wa lati fifunni ati lati fifunni ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ni akoko ti o tọ, Ọlọrun yoo pin wa lere. Ọlọrun nikan ni O mọ akoko ti o tọ fun ere ohun rere yowu ti a ba ṣe. Oun nikan naa si tun ni O mọ irufẹ ere ti o tọ si wa laye yi ati ninu ijọba ayeraye rẹ. Ko wa yẹ ki a ma ṣe oore ni ireti pe ọna kan pato ni Ọlọrun gbọdọ gba lati san wa lẹsan rẹ. Ifurugbin nipa ti ara ni eyi jasi. O si ṣeeṣe ki a ma ri nkankan gba lori rẹ.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọmọ Ọlọrun kọọkan gbọdọ mura lati gbe ẹru rẹ dipo eyi ti yoo fi sọ ara rẹ di bukata fun awọn ara rẹ ninu Kirisiti. Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma ran awọn ara wa lọwọ lati gbe ẹru aye wọn ati lati rin irinajo igbagbọ wọn ni pipe. Ọna ti a wa n gba ṣe eleyi ṣe pataki pupọ si Ọlọrun. A si nilo lati mọ ọn, ki a si tun tẹle. Aijẹbẹ, a ko ni ri ere kankan gba fun ohun rere yowu ti a ba ṣe.

ÌBÉÈRÈ

  • Ọna pataki wo ni Pọọlu sọ ninu ẹkọ yi pe a le gba lati dena iṣubu awọn ara wa ninu Kirisiti?
  • Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:3-10 | ỌJỌ́RÚ 25, SẸRẸ 2022 Read More »

Ìdájọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ṣẹrẹ 22, 2022 Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ Nọ́múbà: Vol. 11, No. 38

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Tayọtayọ ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Sẹrẹ 2023. Adura mi si ni pe ki ohun gbogbo ti Ọlọrun ti n sọ fun ọ ṣe aṣeyọri lati sọ ọ di irufẹ ẹni ti O fẹ ki o jẹ ninu aye yi dipo ti yoo fi ṣiṣẹ lodi si ọ ni ọjọ ikẹyin. Amin.

Lọjọkan, nigba ti O n ba awọn Juu sọrọ, Jesu sọ nkan wọnyi fun wọn: “Bi ẹnikẹni ba si gbọ ọrọ mi, ti ko si pa wọn mọ, emi ki yoo ṣe idajọ rẹ nitori ti emi ko wa lati ṣe idajọ aye, bi ko ṣe lati gba aye la. Ẹni ti o ba kọ mi, ti ko si gba ọrọ mi, o ni ẹnikan ti n ṣe idajọ rẹ; ọrọ ti mo ti sọ, oun naa ni yoo ṣe idajọ rẹ ni ọjọ ikẹyin.” (Johanu 12:47-48) Pẹlu nkan ti Oluwa sọ fun awọn eniyan wọnyi, daju ṣaka ni o ye wa pe ko ki i ṣe nkan tuntun ni ki awọn eniyan gbọ ọrọ rẹ, ki wọn si ma mu lo. Nitorina, ti o ba ti n gbọ ọrọ Ọlọrun, ti o ko si mu lo, ko yẹ ki o ya ẹnikẹni lẹnu.

Ni kukuru, Oluwa sọ wipe Oun ko ṣetan lati ṣe idajọ ẹni yowu ti o gbọ ọrọ Oun, ti o si kọ ọ silẹ. Idi si ni pe iṣẹ rẹ ni asiko yi ko da lori ki o ṣe idajọ awọn eniyan bi ko ṣe pe ki o gba wọn la. Eyi ko wa jasi pe awọn ti o kọ ọ silẹ ko ni gba idajọ rara. A o da wọn lẹjọ ni ọkọ ikẹyin. Ta si ni yoo da wọn lẹjọ? Gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, ọrọ rẹ ti wọn kọ silẹ gan an ni yoo duro tako wọn ni ọjọ naa.

Nitorina, ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ ọ wa, ti o si n kọ lati mu ni ọkunkundun ati lati ṣiṣẹ le lori, mọ wipe ọrọ kanna yi yoo jẹri lodi si ọ ni ọjọ kan. Ọ̀run nikan si kọ ni eyi yoo ti ṣẹlẹ; yoo ṣẹlẹ laye yi naa pẹlu. Fun apẹrẹ, Solomọni, nigba ti o n ba awọn ọmọkunrin rẹ sọrọ lori agbere, jẹ ki o ye wọn kedere pe ti wọn ko ba kọbiara si nkan ti o n sọ fun wọn, ọjọ kan n bọ ti wọn yoo ranti ọrọ rẹ, ti wọn yoo si da ara wọn lẹbi.

Iwọ naa wo ọrọ ti o sọ lori nkan iwọnyi: “Ni igbẹyin aye rẹ iwọ yoo kerora, nigba ti agbara rẹ ati ara rẹ ba ti joro tan. Iwọ yoo wi pe, “Mo ti koriira ẹkọ to! Ọkan mi ṣe wa koorira ibawi! N ko gbọran si awọn olukọ mi lẹnu, tabi ki n feti si awọn ti n kọ mi lẹkọọ. Mo ti bẹrẹ iparun patapata ni aarin gbogbo awujọ eniyan.” (Ìwé Òwe 5:11-14) Njẹ nkan ti o jọ mọ eyi ti ṣẹlẹ si ọ ri bi? Ṣe o ti ba ara rẹ ni ipo ri ti o ti n da ara rẹ lẹjọ fun ikuna rẹ lati ṣe amulo awọn imọran ọlọgbọn ti o ti fi igba kan gba lati ọwọ awọn obi rẹ, adari ijọ rẹ tabi awọn enyan daradara miran ti o wa ninu aye rẹ?

Ki a ma fa ọrọ gun, emi ti wa ni irufẹ ipo yi ri. Mo si fẹ ki o gba mi gbọ pe ko ki i ṣe iriri ti o sunwọ̀n rara. Mo n sọrọ nipa ipo ninu eyi ti iwọ funrarẹ ti mọ pe iwọ gan ni o ṣe ara rẹ. Idi si ni pe o le ranti daada gbogbo awọn ọrọ ikilọ ati ikiyesara ti o gbọ, ti o si kọ lati ṣe amulo rẹ. O wa bẹrẹ si ni woye pe ki o ti mọ, ki o ti mu awọn ọrọ yi lo; ki o ti mọ, ki o ti ma ya olorikunkun. Sibẹsibẹ, o tun mọ wipe ẹpa ko boro mọ ati wipe ti ko ba jẹ wipe Ọlọrun ba ṣaanu fun ọ, o di dandan ki o ma ba ọran ti o da finra titi o o fi jade laye. Ti o ba tilẹ wa pọn ara rẹ loju, ti o si da ara rẹ lẹbi niru asiko naa, ko ni yi nkankan pada.

Wayi o, bi ọrọ Ọlọrun ti ma n ṣe idajọ awọn eniyan ati bi yoo ti ṣe ṣe idajọ wọn ni ọjọ ikẹyin gan an niyẹn. Wọn yoo ranti gbogbo otitọ ti wọn ti gbọ, ti wọn si ti kọ lati ṣe amulo. Wọn a si mọ pe ko si awawi kankan fun ikuna wọn niwaju Ọlọrun. Wọn a mọ pe ko si awawi kankan fun biba aye ara wọn jẹ tabi fun yiyan ọrun apadi ni ile. Ṣugbọn yoo ti wa pẹ ju lati yi ohunkohun pada ni akoko yi. Yoo ti pẹ ju lati le yi awọn èso iṣẹ ọwọ wọn pada. Nitorina, nṣe ni wọn yoo ba awọn nkan wọnyi finra titi lailai.

Ṣugbọn niwọn igba ti a ba si wa ninu aye yi, awọn nkan ti a le yi pada wa. Niwọn igba ti èémí ìyè ba si wa ninu wa, a si le yi pada kuro ni ọna aigbọran-si-Ọlọrun, ki a si bẹrẹ si ni gbọran si lẹnu, ki a si tun ma mu ọrọ rẹ ni pataki. Nipa ṣiṣe eyi, Oun yoo le wo wa san, gba wa lọwọ idamu ti o sorọ mọ awọn aṣiṣe ti a ṣe ṣẹyin ati tun aye wa ṣe. Nitorina, a ko ni nilo lati ma fi ayeraye kabamọ lori awọn aṣiṣe wa. Adura mi si ni pe ki o fi awọn ọrọ yi si ọkan, ki o si yi pada kuro ninu ṣiṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki ọrọ Ọlọrun dide lodi si ọ ninu aye yi lọjọkan tabi ni ọjọ Oluwa. Amin.

Ki o ni ọsẹ ire.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ìdájọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ Láti ọwọ́: J.O. Lawal Ọjọ́: Ṣẹrẹ 22, 2022 Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ Nọ́múbà: Vol. 11, No. 38 Read More »

Níbo lo ti nílò láti tayọ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 15, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 37

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu ọdun tuntun yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki o tayọ ninu ohun gbogbo ti o dara, ti o si tọna niwaju rẹ ni ojumọ kọọkan ninu ọdun tuntun yi, ki aye rẹ ba le jẹ ki awọn ti o wa ni ayika rẹ fi ogo fun ọrukọ rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Kọrinnti, sọ eyi: “Ṣugbọn bi ẹyin ti n pọ si ni ohun gbogbo, ni igbagbọ, ati ọrọ ati imọ, ati ninu aapọn gbogbo, ati ni ifẹ yin si wa, ẹ kiyesi, ki ẹyin ki o maa pọ sii ninu iṣẹ ore-ọfẹ [fififunni] yii pẹlu.” (2Kọrinnti 8:7 – pẹ̀lú àfikún)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn eniyan Ọlọrun kaakiri awọn ijọ wa kaakiri agbaye loni ni o n rẹyin ninu awọn nkan wọnyi. Ẹyin patapata ni wọn wa ninu igbagbọ wọn ninu Ọlọrun, ninu imọ rẹ ti wọn ni, ninu itara wọn fun, ninu isọrọ pẹlu oore-ọfẹ ati ninu ifẹ wọn fun ara wọn. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe wọn n fi ẹnu jẹwọ pe awọn mọ Ọlọrun, o nira fun awọn eniyan lati gbagbọ pe eniyan rẹ ni wọn jẹ.

Ṣe o wa le jẹ pe bi awa naa ṣe ri niyi? A n fi ẹnu wa jẹwọ pe a mọ Ọlọrun ṣugbọn ko han gbangba-gbangba rara si awọn ti o wa ni ayika wa pe tirẹ ni a n ṣe. Idi si ni pe ko si nkankan ti o farapẹ titayọ nipa igbagbọ wa, ifẹ wa, isọrọ wa, imọ wa ati itara wa fun Ọlọrun. Eyi ko si ki i ṣe ifẹ Ọlọrun fun wa. Ifẹ rẹ fun wa ni pe ki a tayọ ninu ohun rere gbogbo. Ti a ko ba wa fẹ tẹsiwaju lati ma gbe igbe aye alaileso ati alailere, a nilo lati bẹrẹ si ni ṣe amulo oore-ọfẹ rẹ ti o n fi gbogbo wa ni arowọto wa, ti o si tun peye, lati lakaka lati tayọ ninu awọn nkan ti yoo jẹ ki awọn eniyan ma fi ogo fun nipasẹ wa.

Bi a ti ṣe ri ni ti awọn ara Kọrinnti, Pọọlu le fi igboya sọ pe wọn tayọ ninu igbagbọ, isọrọ, itara, imọ ati ifẹ. Ibi kan ṣoṣo ti wọn n rẹyin naa ni o ni i ṣe pẹlu ififunni. Nitorina, o sọ fun wọn pe, “Bi ẹyin ti ṣe tayọ ninu awọn eso Ẹmi yoku, nṣe ni ki ẹ ri daju pe ẹ tun tayọ ninu oore-ọfẹ ififunni.”

Nkan ti eyi si tunmọ si ni pe ko si abala aye wa kankan ninu eyi ti Ọlọrun ko ti fẹ ki a tayọ. Nitorina, ti a ba ri abala aye wa kan ninu eyi ti a ti n rẹyin, o di dandan ki Ọlọrun pe akiyesi wa si. O le ṣe eyi nigba ti a ba n ṣe agbeyẹwo aye wa funrawa pẹlu ọrọ rẹ. O si tun le ṣe eyi nipasẹ awọn adari ijọ wa tabi awọn kan lara wa ninu ijọ.

Bi o ti wu ki o ri, niwọn igba ti Ọlọrun ba ti n fi abala aye wa ninu eyi ti a ti nilo lati lakaka fun itayọ han wa, a ko gbọdọ ba a tabi awọn ti o ran si wa jiyan tabi ma wa awawi fun bi a ti ṣe n rẹyin. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a tẹwọgba ohunkohun ti o ba sọ fun wa, ki a si bẹrẹ si ni lakaka ni kiakia lati tayọ ni ibikibi ti a ba ti nilo lati tayọ. Eyi ni yoo fi han pe a mura lati dagba soke ati lati di ohun gbogbo ti O fẹ ki a da.

Nitorina, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi, mura lọkan rẹ lati bẹ aye rẹ wo ninu imọlẹ ọrọ Ọlọrun, ki o ba le ri awọn ibi ti o ti n rẹyin ninu titayọ. Bi o si ṣe n ṣe eyi, Ẹmi Ọlọrun yoo ṣi oju rẹ lati ri ohun gbogbo ti o nilo lati ri, yoo si tun fun ọ ni okun lati ṣe ohun ti o nilo lati ṣe lati wa ni ibi ti Ọlọrun fẹ ki o wa.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ aláririn.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Níbo lo ti nílò láti tayọ? | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 15, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 37 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:1-2 | ỌJỌ́RÚ 11, SẸRẸ 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.”

(Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu iwe Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri wipe bi o tilẹ jẹ wipe a ti di ominira ninu Kirisiti, a ko sọ wa di ominira ninu rẹ ki a ba le ma gbe igbe aye ti o wu wa. Dipo eyi, a sọ wa di ominira ninu rẹ ki a ba le ma gbe igbe aye igbagbọ ti o n ṣiṣẹ pẹlu ifẹ. Amọ ti a ko ba fi ara wa jin fun itọni ẹmi Ọlọrun, ki a si gbe ọkan wa le fun okun lati gbe igbe aye ifẹ, ko si ni ki ẹran ara ma gba iṣakoso aye wa. Ti eyi ba si wa ribẹ, dipo ti a o fi ma so eso ẹmi, nṣe ni a o ma mu ifẹkufẹ ẹran ara ṣẹ.

TÍ KÌRÌSÌTÍẸ̀NÌ BÁ ṢUBÚ SÍNÚ Ẹ̀ṢẸ̀
Bi Pọọlu ṣe wa fi ye wa, niwọn igba ti a ba n rin nipa itọni ati ipese Ẹmi Ọlọrun, a ko ni mu ifẹkufẹ ẹran ara ṣẹ. Ti a ba wa ri ẹni ti o mu ifẹ ẹran ara ṣẹ nkọ, lẹyin igba ti o ti di ọmọ Ọlọrun? Ti a ba ri ninu wa ti o bọ sinu pakute ẹṣẹ kan tabi omiran nkọ? Ki ni ki a ṣe fun iru ẹni bẹ? Ṣe ki a gba pe ẹni naa ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun rara ni tabi pe ko ki i ṣe ọmọ rẹ mọ?

Ọpọ ni o ti pada lẹyin Kirisiti nitori pe wọn ṣe awọn aṣiṣe kan ni awọn akoko kan, ti Satani si lo eyi lati jẹ ki wọn ri ara wọn bi ẹni ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun rara. A si ri awọn miran ti o jẹ wipe ijọ Ọlọrun ni o fi ẹnu ati iṣesi le wọn kuro lẹyin Jesu lẹyin igba ti a mu wọn ninu ẹṣẹ kan tabi omiran. Ara idi si niyi ti awọn miran ṣe n di atunbi loorekoore. Ẹlomiran ko tilẹ le sọ iye igba ti o ti di atunbi. Nitoripe igbakigba ti o ba ti bọ sinu pakute ẹṣẹ ni yoo tun mura lẹkansi lati di atunbi.

Ṣe awọn nkan wọnyi wa wa ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun bi? Gẹgẹ bi Pọọlu ṣe fi ye wa ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo yi, awọn nkan wọnyi ko wa ni ibamu pẹlu ọrọ rẹ rara. Lotitọ, o ṣeeṣe ki ọmọ Ọlọrun, ti o ti di ominira ninu Kirisiti , ṣubu ṣinu ẹṣẹ kan tabi omiran. Eyi ko wa jasi pe ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun mọ tabi pe ki a le kuro ninu ijọ, ki ba orukọ rẹ jẹ tabi ki a sọ di alaiwulo laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Ko si tun jasi pe o nilo lati tun di atunbi lẹkansi. Nkan ti irufẹ ẹni bẹ nilo, niwọn igba ti o ba ti mọ ẹṣẹ rẹ ni ẹṣẹ, ni imupadabọsipo.

Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ lori eyi:

“Ara, bi a tilẹ mu eniyan ninu ẹṣẹ kan, ki ẹyin ti i ṣe ti Ẹmi ki o mu iru ẹni bẹẹ bọ sipo ninu ẹmi iwa tutu; ki iwọ tikararẹ ma kiyesara, ki a ma baa dan iwọ naa wo pẹlu.” (Galatia 6:1)

Ki ni nkan akọkọ ti a kiyesi ninu ọrọ Pọọlu yi? Oun naa ni pe o ṣeeṣe ki ọmọ Ọlọrun jin sinu ọfin ẹṣẹ. Ko pọn dandan ki eyi ṣẹlẹ ṣa o. Amọ o ṣeeṣe. Ti eyi ba si ṣẹlẹ, ti a si mọ si, igbesẹ wo ni o yẹ ki a gbe? Pọọlu sọ wipe imupadabọsipo iru ẹni bẹ ni a gbọdọ ṣiṣẹ le lori. Si kiyesi, ko sọ wipe nṣe ni ki a le ẹni bẹ kuro ninu ijọ. Ko si sọ pe nṣe ni a sọ pe ki irufẹ ẹni bẹ pada di atunbi lẹkansi. Dipo eyi, o sọ wipe ki a mu ẹni yi padabọsipo. Igba ti a ba wa bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati mu ẹni naa padabọsipo, ti a si ri iha ti o kọ si nkan ti a n ṣe, ni a to le sọ pe ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun tẹlẹ.

Bi Jesu Oluwa wa ṣe fi ye wa, ti arakunrin tabi arabinrin wa ninu igbagbọ ba kuna tabi ṣubu sinu ẹṣẹ, ẹṣẹ ti ọrọ Ọlọrun fi idi rẹ mulẹ gẹgẹ bi ẹṣẹ, iṣẹ awa ti a mọ si ni lati fi aṣiṣe rẹ han an. Ti o ba si gba lati ṣe atunṣe, Jesu ni ki a jẹ ki ọrọ naa tan si ibẹ. Ti ko ba gba, O ni ki a tun wa enikan tabi ẹni meji lati mu lọ sọdọ rẹ, ki a ba le fi aṣiṣe rẹ han an. Ti o ba si gba lati ṣe atunṣe, ki a jẹ ki ọrọ naa tan si ibẹ. Amọ ti ko ba gba, Oluwa sọ wipe ki a jẹ ki ijọ Ọlọrun mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, ki awọn agbagba ninu rẹ ba le ba a sọrọ. Ti ko ba si tun wa gba lati ṣe atunṣe, nṣe ni ki a bẹrẹ si ni ri ẹni naa gẹgẹ bi ẹni ti ko mọ Ọlọrun tẹlẹ, ti o si nilo lati ṣẹṣẹ di ẹni igbala. (Wo: Matiu 18:15-17)

Ṣugbọn daju ṣaka ni pe nkan ti Ọlọrun fẹ ni pe ti ẹnikẹni ninu wa ba bọ sinu pakute ẹṣẹ, bi a o ti ṣe mu padabọsipo lo gbọdọ wa lọkan wa. Ohunkohun ti ijọkijọ ba si n ṣe, eyi ti o lodi si eyi, ko ki i ṣe ifẹ Ọlọrun. Nitorina, ko le yọri ṣi igbero ati ifidimulẹ awọn ọmọ Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu. Igbero wọn ati iduroṣinṣin wọn ni o si yẹ ki o jẹ wa logun. Idi ni yi ti Jemisi ṣe sọ fun wa ninu lẹta rẹ: “Ara, bi ẹnikẹni ninu yin ba ṣina kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si mu n bọ sipo ninu igbagbọ. Ki ẹyin ki o mọ pe, ẹni ti o ba yi ẹlẹsẹ kan pada kuro ninu iṣina rẹ, yoo gba ọkan kan la kuro lọwọ iku, yoo si mu ki a dari ọpọlọpọ ẹṣẹ ji ẹni naa.” (Jemisi 5:19-20)

Wayi o, yatọ si pe ki a mura lati ṣiṣẹ fun imupadabọsipo awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba kuna, awọn ti yoo ṣiṣẹ yi ati ọna ti wọn yoo gba ṣe naa ṣe pataki pẹlu. Gẹgẹ bi Pọọlu ti fi ye wa ninu lẹta yi, awọn ti wọn ba n rin nipa ti Ẹmi Ọlọrun nikan ni o ni anfaani lati ṣiṣẹ imupadabọsipo fun ẹnikẹni ti o ba jin ṣinu ọfin ẹṣẹ. Eyi jasi pe awa ti a ba si n gbe ninu ẹṣẹ kan tabi omiran tabi ti irin-ajo igbagbọ wa ko fi ogo fun Ọlọrun ni ọna ti o han kedere ko lẹtọ lati da si iru ọrọ yi. Nṣe ni o yẹ ki a lọ gbajumọ ọrọ aye ara wa, ki awa funrawa ba le wa ni pipe ni ìṣe niwaju Ọlọrun.

Siwaju si, Pọọlu ti jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe awọn ti o n rin nipa ti Ẹmi Ọlọrun ni o le mu awọn eniyan padabọsipo kuro ninu pakute ẹṣẹ, awọn wọnyi naa gbọdọ ṣiṣẹ yi pẹlu iwa tutu, oju-aanu ati ikiyesara. O tunmọ si wipe wọn ko gbọdọ gbogun ti ẹni ti wọn fẹ mu pada bọsipo. Wọn ko gbọdọ duro ni iduro pe awọn san ju u lọ, ki wọn si ma sọrọ si ṣakaṣaka, bi igba ti ẹni naa ko lọgbọn lori tabi ja mọ nkankan rara. Eyi ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Eyi paapaa si le ṣi ilẹkun silẹ fun idanwo Satani lati wọle tọ awọn naa wa nibi ti wọn ko ti reti rẹ, ki a si gbe wọn ṣubu.

Ranti pe bibeli sọ wipe, “Nitori ẹni ti ko ṣaanu, ni a o ṣe idajọ fun laisi aanu; ṣugbọn aanu a maa bori idajọ.” (Jemisi 2:13) Lafikun, o tun sọ wipe, “Nitori iru idajọ ti ẹyin ba ṣe, oun ni a o ṣi ṣe fun yin. Iru oṣuwọn ti ẹyin ba fi wọn, oun ni a o si fi wọn fun un yin.” (Matiu 7:3) Nitorina, a gbọdọ mọ iru iha ti a o kọ si ẹnikẹni ti o ba ṣubu ṣinu ẹṣẹ laarin wa, ki a ma ba ti ara wọn jẹbi, kọṣẹ tabi ṣi ilẹkun silẹ fun iṣubu ti awa tikara wa.

Pọọlu wa kasẹ ọrọ yi nilẹ nipa sisọ eyi: “Ẹ maa ṣe alabaapin ninu awọn iṣoro ati idaamu ọmọnikeji yin, ki ẹ si fi bẹẹ mu ofin Kirisiti ṣe.” (Galatia 6:1-2) Ki ni idi ti o fi sọ eyi? O sọ ọ lati jẹ ki a mọ pe ti a ba n mojuto ara wa, gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun, ti a n kiyesi nkan ti o n lọ ninu aye ẹnikọọkan wa, o ṣeeṣe ki a le dena iṣubu awọn arakunrin ati arabinrin wa sinu ẹṣẹ. Amọ ti a ba pa ara wa ti, ti ẹnikọọkan si n ṣe bi o ba ti ṣe wu, a ko rin ninu ofin Kirisiti, ti i ṣe ifẹ. Lafikun, ti a ba kọ lati fi aye fun awọn ara wa lati mọ bi o ti ṣe n lọ ninu aye wa, paapaa julọ niwọn igba ti a mọ daju pe wọn ko ni ibi lọkan si wa, nṣe ni a n ṣilẹkun aye wa silẹ fun eṣu lati ya wa sọtọ jẹ niya. Awọn nkan wọnyi si ni o yẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun mọ ninu gbogbo awọn ijọ wa, ki a ba le ma fi gbogbo igba ran awa wa lọwọ lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa ati lati ma fi aye gba Satani lati ri aye ṣiṣẹ ninu aye wa tabi laarin ijọ wa.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
O ṣeeṣe ki ọmọ Ọlọrun tootọ ṣubu sinu ẹṣẹ. Amọ awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ti o sunmọ wọn, ti o si n rin ninu ifẹ rẹ ko gbọdọ jẹ ki wọn di titẹmọlẹ sinu ẹṣẹ wọn. Ojuṣe wa si wọn ni lati mu wọn padabọsipo, ki eṣu ma ba ṣogo lori wọn. Eyi ko wa ni i ṣeeṣe ti a ko ba tọ wọn wa pẹlu ẹmi irẹlẹ, suuru ati ikiyesara.

ÌBÉÈRÈ

  • Ki ni awọn nkan ti o le fa Kirisitiẹni ṣubu sinu ẹṣẹ?
  • Ọna wo ni ẹkọ yi gba tun imọ rẹ ṣe lori iha ti o yẹ ki a kọ si iṣubu Kirisiẹtiẹni sinu ẹṣẹ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:1-2 | ỌJỌ́RÚ 11, SẸRẸ 2022 Read More »

Ọlọ́run gbé e ga | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 08, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 36

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ keji ninu ọdun tuntun yi, ọdun 2023. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun funrarẹ gbe o ga ninu ọdun naa ni gbogbo abala aye rẹ ti igbega ti tọ si ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ẹnikan ṣoṣo ti o ni agbara lati gbe awọn eniyan ga tabi rẹ wọn silẹ ni Ọlọrun. Fun apẹrẹ, Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Filipi, sọ eyi fun wọn nipa Jesu Oluwa wa: “Nitori naa, Ọlọrun pẹlu si ti gbe e ga gidigidi, o si ti fun un ni orukọ kan ti o tobi ju gbogbo orukọ lọ…” (Fílípì 2:9) Tani O gbe Jesu lọ si ipele ti o ga julọ ni gbogbo iṣẹda? Ọlọrun ni! Ta tun ni O fun Jesu ni orukọ ologo, orukọ mimọ ati orukọ ti o lagbara? Ọlọrun ni!

Nitori naa, Jesu Oluwa wa ko di Oluwa gbogbo ẹda Ọlọrun, pẹlu awọn angẹli ati awọn ẹmi eṣu, funrarẹ. Ọlọrun ni o gbe ga si ipo ti O ti ni aṣẹ ati agbara lori gbogbo ẹda ati lori ohun gbogbo. Lafikun, Oun kọ ni O sọ orukọ ara rẹ di ologo, alagbara ati eyi ti o ni iyi. Ọlọrun ni O fun ni orukọ yi i, ti O si tun ro pẹlu gbogbo aṣẹ rẹ. Idi si ni yi ti orukọ rẹ ṣe jẹ eyi ti a n bọwọ fun ni ibi gbogbo ti ẹda Ọlọrun wa, lorilẹ aye yi, ni ọrun ati ni isalẹ aye yi; idi ni yi ti gbogbo eékún fi gbọdọ wole ti a ba ti darukọ rẹ ati ti gbogbo ahọn fi gbọdọ jẹwọ pe Oun ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.

Wayi o, niwọn igba ti Jesu Oluwa wa ko le gbe ara rẹ ga, ti o si jẹ wipe Ọlọrun funrarẹ ni O gbe e ga, ta wa ni ẹni naa laye yi ti o le gbe ara rẹ ga? Ko si! Siwaju si, niwọn igba ti Jesu Oluwa wa ko le sọ orukọ ara rẹ di nla ati alagbara ṣugbọn ti O nilo Ọlọrun lati sọ ọ di orukọ nla, orukọ ti o lagbara ati orukọ ti o dun leti lati gbọ, ta wa ni ẹni naa laye yi ti o le sọ orukọ ara rẹ di nla, alagbara ati eyi ti o dun un gbọ leti? Ko si!

Lotitọ, awọn eniyan le gbiyanju lati gbe ara wọn ga nipasẹ iṣẹ aṣekara, ijafafa, ibaṣepọ pẹlu awọn ti o ti di ẹni nla, arekereke, iwa ipa tabi iṣẹ oṣo. Ṣugbọn ti Ọlọrun ko ba fẹ wọn ni ibi giga laye yi, ko si nkan ti wọn le ṣe ti wọn yoo fi de ibẹ. Nibakan naa, awọn eniyan le ṣe oniruuru nkan lati ni orukọ ti o ga ati ti o dara, orukọ ti awọn eniyan yoo ma wari fun ti a ba ti mẹnuba a. Ṣugbọn ti Ọlọrun ko ba fun wa ni orukọ ti o ga, ti o si niyi gẹgẹ bi ẹbun, gbogbo akitiyan wa lati sọ orukọ wa di nla ko ni ja mọ nkankan.

Lafikun, lati fi han wa pe Ọlọrun nikan ni O le gbe awọn eniyan ga, ki O si tun bukun fun wọn pẹlu orukọ ti o ga, ti o si tun lagbara, awọn igba ma n wa ti yoo rẹ awọn ti a ti gbe ga ati ti a ti sọ di nla tẹlẹ silẹ nitoripe wọn ko ri i gẹgẹ bi orisun igbega wọn. Fun apẹrẹ, ninu iwe Daniẹli, ori ikẹrin, Ọba Nebukadinesari sọ iriri rẹ pẹlu Ọlọrun lori ọrọ yi fun wa. O sọ bi oun ti ṣe fi igbakanri ro wipe oun ni oun sọ ara oun di ẹni nla ati alagbara ati bi Ọlọrun ṣe rẹ oun silẹ, ki oun ba le kẹkọ lori igbega ti oun ni. Ki a si to wa tun ọkunrin yi gbe ga lẹkansi, o ti kokọ lo igba melokan lati gbe ile aye bi ẹranko, bi asínwín.

Nitorina, ti a ba fẹ ki a gbe wa ga laye yi, o si yẹ ki a fẹ bẹ, ti a ba fẹ di ẹni nla laye, o si yẹ ki a fẹ bẹ, ẹnikan ṣoṣo ti a gbọdọ ma wo fun eyi ni Ọlọrun. A ko gbọdọ fi igbẹkẹle wa sinu agbara wa, ẹkọ wa, ọgbọ́n wa, ọrọ̀ wa tabi ibaṣepọ wa pẹlu awọn eniyan nla kan. Ko si ikankan ninu awọn nkan wọnyi ti yoo ṣiṣẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, igberaga ni yoo jẹ ki a fi igbẹkẹle wa sinu agbara wa tabi awọn ibaṣepọ wa fun igbega wa tabi iṣọdi ẹni nla wa. Bi bibeli si ṣe sọ fun wọn, nkan ẹyọkan ṣoṣo ni awọn agberaga le reti lati ọwọ Ọlọrun – idojuti. (Wo: Jemisi 4:6; 1Peteru 5:6)

Nitorina, ti a ba fẹ lati ni iriri igbega ninu aye wa lọdun yi, ẹ jẹ ki a rẹ ara wa silẹ niwaju Ọlọrun ati niwaju ọrọ oore-ọfẹ rẹ. Yoo si ri daju pe a ko fo wa ru nigba ti akoko igbega wa ba to. Ọna ti a gba gbe Jesu Oluwa wa ga leyi o. Bibeli sọ wipe bi o tilẹ jẹ wipe ọkan ni Oun ati Ọlọrun Baba, O sọ ara rẹ di aláìjámọ́nkànkan, O rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun, O si gbọran si i lẹnu, titi de oju iku ori igi agbelebu (Filipi 2:5-8). Nitori naa, Ọlọrun gbe e ga si ipele ti o ga ju ninu gbogbo iṣẹda rẹ. Ti awa naa ba si ṣe awokọṣe irẹlẹ rẹ, bi a ti ṣe paṣẹ fun wa ninu Iwe Mimọ, ti a n gbọran si Ọlọrun lẹnu ninu ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe, bi a tilẹ dojukọ iku, Oun yoo gbe awa naa ga pẹlu. Ko si si ẹni naa ti yoo le sọ ibi ti yoo gbe wa ga de. Nitorina, rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun lọdun tuntun yi, yoo si gbe ọ lọ lati inu igbega si igbega.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọlọ́run gbé e ga | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 08, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 36 Read More »

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 5:13-26 | ỌJỌ́RÚ 04, SẸRẸ 2022

download your pdf version here

ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu iwe Galatia, a ri awọn ewu ti o sorọ mọ ki a pa Jesu Kirisiti ti gẹgẹ bi ọna lati di ẹni idalare niwaju Ọlọrun, ki a si wa ma tẹle ofin Mose. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ẹnikẹni ti o ba ṣe eyi ko le ri ere kankan jẹ lara Kirisiti. Yatọ si eyi, irufẹ ẹni bẹ gbọdọ mura lati ṣe ohun gbogbo ti ofin Mose pa laṣẹ fun awọn ti a fun. Aijẹbẹ, nṣe ni yoo fi ara rẹ si abẹ egun ofin naa. Siwaju si, Pọọlu jẹ ki o ye wa pe ẹnikẹni ti o ba si tun dirọ mọ ofin Mose gẹgẹ bi ọna lati di ẹni idalare niwaju Ọlọrun, lẹyin igba ti o ti gba Jesu gbọ gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala rẹ, ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ Jesu Kirisiti. Nitorina, a gbọdọ ṣọ ara wa gidigidi gẹgẹ bi Kirisitẹni, ki a si ma fi aye gba ẹnikẹni, bi o ti wu ki ẹni naa lọla tabi gbajumọ ninu ijọ to, lati ge wa kuro ni ara Kirisiti nipa fifi wa si abẹ igbekun ofin Mose.

MÁ ṢI ÒMÌNIRA RẸ NÍNÚ KÍRÍSÌTÌ LÒ
Wayi o, pe a ti wa di ominira ninu Kirisiti, ti a ko si si labẹ ofin Mose, ko jasi pe a kan le ma gbe igbe aye ti o wu wa. O si wa ṣeni laanu pe ọpọ ni o n ṣiwawu nitori pe wọn n ṣi ọrọ iwe mimọ nipa ominira wa ati oore-ọfẹ wa ninu Kirisiti tunmọ. Awọn wọnyi ro wipe niwọn igba ti a ko ti si ni abẹ ofin Mose ṣugbọn ti a wa ni abẹ oorẹ-ọfẹ Kirisiti, a le ma gbe igbe aye ti o ba wu wa, ki a ma tinu ẹṣẹ bọ ṣinu ẹṣẹ – oore-ọfẹ Jesu gbe e. Idi si niyi ti o fi dabi ẹni pe awọn ti wọn dirọ ofin Mose ma n ri ọrọ sọ, ti wọn si ma n fẹ ki o ye awọn eniyan pe awọn gan ni awọn mọ nkan ti awọn n sọ ati ti awọn n ṣe.

Eyi ko si jẹ tuntun rara. O wọpọ nigba aye awọn Pọọlu naa. Nitorina, ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi, o ba wa sọrọ lori rẹ. O si jẹ ki o ye wa pe wipe a ko si ni abẹ ofini Mose ko tunmọ si pe ẹru ẹṣẹ ni wa tabi pe ki a ma ṣi ominira wa ninu Kirisiti lo. Iwọ naa wo diẹ lara nkan ti o sọ:

“Nitori a ti pe yin si ominira, ara kiki pe ki ẹ ma ṣe lo ominira yin bi anfaani sipa ti ara, ṣugbọn ẹ maa fi ifẹ sin ọmọnikeji yin. Nitori pe a ko gbogbo ofin ja ninu eyi pe, “Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ gẹgẹ bi ara rẹ.” Ṣugbọn bi ẹyin ba n bu ara yin san, ti ẹ si n jẹ ara yin run, ẹ kiyesara ki ẹ ma ṣe pa ara yin run.” (Gàlátíà 5:13-15)

Njẹ o ri bayi? Aṣilo ominira ninu Kirisiti wa. Eyi ti o jasi pe a le bẹrẹ si ni ṣiwawu, ki a ma ṣe ifẹ inu ara wa nitoripe a ri ara wa gẹgẹ bi ẹni ti ko si ni abẹ ofin Mose. A ko si si ni abẹ ofin Mose lotitọ. Amọ ṣa o, gẹgẹ bi Pọọlu ti fi ye wa, a ko sọ wa di ominira ninu Kirisiti ki a ba le ma gbe igbe aye ti o wu wa. Dipo eyi, a sọ wa di ominira ninu rẹ ki a ba le ma gbe igbe aye ti o wu Ọlọrun. Igbe aye wo ni o si wu Ọlọrun? Igbe aye ifẹ ni i.

Ti a ko ba gbagbe, Pọọlu ti jẹ ki o ye wa siwaju ninu lẹta yi pe nkan ẹyọkan ṣoṣo ti o ṣe pataki si Ọlọrun ni igbagbọ ti o n ṣiṣẹ nipa ifẹ (Gàlàtìá 5:6). Nitorina, igbe aye ti o tọ niwaju Ọlọrun, igbe aye ti yoo ri oriyin gba lọwọ rẹ ni eyi ti o n fi ifẹ sin awọn ti o wa ni ayika rẹ. Ti a ba si wo daradara, nkan ti gbogbo ofin Mose da le lori ni eyi. O da lori ki a ma rin ninu ifẹ si Ọlọrun ati si ọmọnikeji wa. Nitorina, ẹnikẹni ti o ba n rin ninu ifẹ ti ko gbogbo ofin ja.

Ki wa ni koko nkan ti a n sọ? Koko nkan ti a n sọ ni pe bi o tilẹ jẹ wipe Kirisitiẹni ko si ni abẹ ofin Mose, ti ko si nilo lati mura lati gbe igbe aye rẹ ni ibamu pẹlu ofin yin, afojusun rẹ ni gbogbo igba gbọdọ wa lori gbigbe igbe aye ifẹ. A si ti ṣe wa yẹ lati ṣe eyi. A ti tun wa bi lati ṣe eyi. Amọ ṣe a o wa ma gbe igbe aye ifẹ bi? Ṣe a o ma gbe igba aye ti o ko gbogbo ofin ja bi?

Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, wipe a di ọmọ Ọlọrun ati ominira ninu Kirisiti Jesu ko tunmọ si pe a o ma gbe igbe aye ifẹ. Idi si ni pe ọpọ igba ni ijakadi n waye laarin ẹmi Ọlọrun ti o n gbe inu wa, ti ẹmi wa si ti di ọkan pẹlu rẹ, ati ẹran ara wa. Wo nkan ti apọsiteli yi sọ lori eyi:

“Njẹ mo ni, ẹ maa rin nipa ti Ẹmi, ẹyin ki yoo si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ. Nitori ti ara n ṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmi, ati Ẹmi lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ ma baa le ṣe ohun ti ẹyin n fẹ. Ṣugbọn bi a ba n ti ọwọ Ẹmi ṣamọna yin, ẹyin ko si labẹ ofin.” (Galatia 5:16-18)

Ṣe o ri bayẹn? Bi o tilẹ jẹ wipe a ti di ọmọ Ọlọrun nipasẹ Kirisiti Jesu, bi o tilẹ jẹ wipe a ti di ẹni idalare niwaju Ọlọrun ninu Kirisiti, ti Ẹmi Ọlọrun si n gbe inu wa, ọpọ igba ni ẹran ara wa ma n fẹ ṣe awọn nkan ti o lodi si ifẹ Ọlọrun fun wa. Ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun ko ni fi aye gba a. Ọpọ igba naa si ni Ẹmi Ọlọrun a ma dari wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ti ẹran ara wa yoo si ta ko o. Idi si ni yi ti a fi ma n ri awọn miran ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun ti iwa wọn ko si jọ ti ọmọ rẹ. Lotitọ wọn le ti di ọmọ rẹ. Amọ ẹran ara ni o n ṣe akosọ aye wọn. Ifẹkufẹ rẹ ni wọn si n tẹle. Idi si ni pe wọn ko rin nipa ti Ẹmi – wọn ko fi ara wọn si abẹ iṣakoso Ẹmi Ọlọrun lati dari wọn ati lati ma fun wọn ni okun lati gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun.

Nkan ti Pọọlu sọ nibi yi wa n ran wa leti ọrọ Jesu ti o sọ wipe, “Ẹmi fẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara.” (Wo: Mátíù 26:41) Ti eyi ba si ribẹ, a gbọdọ fi okun fun ẹran ara lati tẹriba fun Ẹmi Ọlọrun ati lati ma ṣe ifẹ rẹ. Idi ni yi ti Jesu fi kọ wa pe ki a ma gbadura lai ṣinmi ati lai ṣaarẹ fun okun lati ṣe ifẹ Ọlọrun dipo ifẹ ẹran ara. Idi naa si tun ni yi ti a fi kọ wa ninu ọrọ Ọlọrun lati fi ara wa jin fun ọrọ rẹ, ki o ba le wẹ wa mọ, ki a si tun fun wa ni okun lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun.

O wa ṣeeṣe ki a ri awọn ti yoo fẹ sọ wipe awọn ko mọ ọna ti ẹran ara n gba lodi si Ẹmi Ọlọrun tabi ti wọn yoo sọ pe awọn ko mọ iṣẹ ara yatọ si ti Ẹmi. Nitori awọn wọnyi ni Pọọlu ṣe tẹsiwaju lati sọ eyi:

“Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahan, tii ṣe iwọnyi; pansaga, agbere, iwa eeri, wọbia, ibọriṣa, oṣo, ikorira, ija, ilara, ibinu, imọtara-ẹni nikan, iyapa, ẹkọ-odi. Arankan, ipaniyan, imutipara, irede-oru, ati iru iwọnyi; awọn ohun ti mo n wi fun yin tẹlẹ, ri pe, awọn ti n ṣe nnkan bawọnyi ki yoo jogun ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn eeso ti Ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa-tutu, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan ko lodi si iru wọnyi, Awọn ti i ṣe ti Kirisiti Jesu ti kan ara wọn mọ agbelebuu pẹlu ifẹ ati ifẹkufẹẹ rẹ. Bi awa ba wa laaye sipa ti Ẹmi, ẹ jẹ ki a si maa riin nipa ti Ẹmi. Ẹ ma ṣe jẹ ki a maa ṣogo-asan, ki a ma mu ọmọnikeji wa binu, ki a ma ṣe ilara ọmọnikeji wa.” (Galatia 5:19-26)

Ṣe o ti ri bayẹn? Iṣẹ ẹran ara yatọ gedegbe si eso Ẹmi Ọlọrun, bi okunkun ṣe yatọ gedegbe si imọlẹ. Nitorina, ko si ẹni ti o le ri awijare ṣe lori fifi ara rẹ jin fun iṣẹ ẹran ara. Ẹnikẹni ti o ba si fi ara rẹ jin fun wọn, bi o tilẹ sọ wipe oun ti di ominira ninu Kirisiti, kan n tan ara rẹ jẹ ni. O ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹ ma jẹ ti Kirisiti rara. Idi si ni pe awọn ti wọn n ṣe awọn nkan wọnyi ko le jogun ijọba Ọlọrun. Ko wa yẹ ki a ma ṣogo asan ninu Kirisiti Jesu. Ko yẹ ki a ma polongo ara wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu, ki aye wa si ma so eeso Ẹmi rẹ. Itanraẹnijẹ gba ni eyi. Ko si le ṣe wa ni anfaani kankan. Idi si niyi ti Pọọlu ṣe sọ pe ti a ba gba wipe abẹ iṣakoso Ẹmi Ọlọrun ni aye wa wa nitootọ, nṣe ni o yẹ ki a ma rin ni ibamu pẹlu itọni rẹ.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Pe a di ominira ninu Kirisiti ko tunmọ si pe ki a ma gbe igbe aye arufin. Amọ ti a ko ba fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati tọ wa ati lati ma fun wa ni okun ti o peye, ko si ni ki ẹran ara ma ti wa lati ma gbe igbe aye arufin. Eyi ni a wa gbọdọ fi sọkan gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ki a ma ba ṣi ipo ominira wa ninu Kirisiti lo, ki a si fi ara wa han bi eke Kirisitiẹni lẹyinọrẹyin.

ÌBÉÈRÈ

  • Awọn ọna wo ni ẹkọ yi ṣe gba wulo fun ọ gẹgẹ bi Kirisitiẹni?
    Láti ọwọ́ Johnson O. Lawal

Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ | ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 5:13-26 | ỌJỌ́RÚ 04, SẸRẸ 2022 Read More »

Fi síwájú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 01, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 35

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọ-tayọ ki ọ kaabọ sinu ọjọ akọkọ ninu ọdun tuntun yi, ọdun 2023. Adura mi si ni pe gbogbo ìṣíṣẹ̀ rẹ ninu ọdun naa ni Ọlọrun yoo tọ ni ipa ọna isinmi, ilera ati itayọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ni pataki julọ, o yẹ ki a fi iyin fun Ọlọrun fun ẹbun ọdun tuntun yi. Bi iwọ gan yo ṣe gba pẹlu mi, ọpọ ni o fojusọna lati darapọ mọ ọdun tuntun yi ṣugbọn ti wọn ti ku ba yi, fun idi kan tabi omiran. O wa yẹ ki o ye awa ti a wa laaye lati ri ọdun naa ati lati kopa ninu rẹ pe ko ki i ṣe ifẹ wa, agbara wa tabi ọgbọn wa ni o jẹ ki didarapọ wa pẹlu ọdun yi ṣeeṣe. Dipo eyi, aanu Ọlọrun ni o jẹ ki o ṣeeṣe.

Bibeli sọ wipe, “Njẹ bẹẹ ni ki i ṣe ti ẹni ti o fẹ, ki i ṣi i ṣe ti ẹni ti n sare, bi ko ṣe ti Ọlọrun ti n ṣaanu.” (Roomu 9:16) Niwọn igba ti o wa jẹ pe aanu Ọlọrun ni o fun wa ni ọdun tuntun yi gẹgẹ bi ẹbun, o yẹ ki a dupẹ lọwọ rẹ fun un. Yatọ si iyẹn, o yẹ ki a pinnu lọkan wa lati lo ẹbun ọdun naa lati yẹ ẹ si. Lotitọ, o tọna fun wa lati ni ala ati afojusun fun ọdun naa. Ṣugbọn o ṣeeṣe ki awọn ala wa ati afojusun wa ma ja mọ nkankan, ti a ko ba ka ẹni ti o fun wa ni anfaani lati le lala ati lati le ni afojusun si tabi ti a ba kọ lati fi si aye ti o tọ si i ninu aye wa.

Nigbakanri ti O n kọ awọn ọmọlẹyin rẹ lori bi wọn ṣe le ba aini wọn pade ati mu awọn ala wọn ati afojusun wọn wa si imuṣẹ, Jesu Oluwa wa sọ eyi fun wọn: “Ṣugbọn, ẹ kọkọ wa ijọba rẹ na ati ododo rẹ, yoo si fi gbogbo awọn nnkan wọnyi kun un fun yin pẹlu.” (Matiu 6:33) Bi awọn ọrọ wọnyi ṣi ṣe jẹ otitọ pọnbele ni igba ti wọn kọkọ jabọ ni ẹnu Oluwa wa naa ni wọn si tun ṣe jẹ otitọ loni. Ọna kan ṣoṣo ti a fi le ba gbogbo awọn ainu wa pade, ki a si tun ri imuṣẹ awọn ala wọn ni ki a fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu aye wa.

Lotitọ, ti a ko ba fi ṣe akọkọ ninu aye wa, a si le ri awọn nkankan tabi pupọ gan lara awọn aini wa, ala wa ati ilakaka wa laye yi yanju. Ṣugbọn, lẹyin-ọ-rẹyin, ti a ko ba fi Ọlọrun ṣiwaju ninu aye wa, awọn aini wa ti o ṣe pataki julọ ko ni jẹ yiyanju – ko tilẹ le jẹ yiyanju. Fun apẹrẹ, ọkan kọọkan ni o ma n pongbẹ lati gbe titi lailai. Bẹẹni, ninu ọkan ẹnikọọkan ni ipongbẹ lati gbe igbe aye ti o loorin ju eyi ti a n gbe lorilẹ aye yi wa. A mọ ninu wa pe irufẹ aye yi wa nibikan niwaju wa. A si mọ pe a nilo rẹ. Ṣibẹ bi a ṣe le ri aye yi gbamu tabi de ibẹ kọja nkan ti oye wa le gbe. (Wo: Oniwaasu 3:11)

Ṣugbọn Ọlọrun, eni ti o ni aye, mọ ọna lati tan ẹdun ọkan ayeraye wa yi. Lafikun, O ni agbara lati tan an. Yatọ si iyẹn, ọ̀rọ̀ wa mumu lọkan rẹ, O si n fẹ lati tan ẹdun ọkan wa yi ati awọn aini yowu ti a tun le e ni. Abalajọ ti bibeli ṣe sọ wipe ọrọ wa jẹ ẹ logun ati wipe O n fi ojoojumọ gbe bukata wa. Ohun ti a kan nilo lati ṣe ki O ba le mojuto gbogbo aini wa, ilakaka wa ati ala wa ni ki a fi siwaju ninu aye wa. (Sáàmù 68:19; 1Pétérù 5:7)

Njẹ a o wa fi siwaju ninu aye wa lọdun yi bi? Njẹ iwọ yoo fi Oun ati ohun gbogbo ti o ṣe pataki si siwaju ninu aye rẹ? Ti o ba ṣe eyi, gẹgẹ bi Jesu Oluwa wa ti fi ye wa, ko si aini rẹ kan, yala nipa ti ara ni, nipa ti ẹmi ni tabi nipa ti ero ọkan ni, ti ko ni mojuto. Ki a tilẹ sọ otitọ, yoo mojuto awọn aini rẹ ti o ko mọ nkankan nipa wọn gan, yoo si tun ri daju pe a ti tẹ ọ lọrun lẹkunrẹrẹ nigba ti ọdun yi i ba wa si opin. Adura mi si pe ki ọkan rẹ gba okun lati ma fi gbogbo igba fi siwaju ni gbogbo ọna rẹ ninu gbogbo ọdun yi, ki ohunkohun ti o nilo ninu ọdun naa ma ba ṣe alaiwaniarọwọto fun ọ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọdún ayọ̀ o.

Copyright © 2023, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Fi síwájú | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ṣẹrẹ 01, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 11, No. 35 Read More »