Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:3-10 | ỌJỌ́RÚ 25, SẸRẸ 2022
ÀKỌ́SÓRÍ: “Emi ko sọ oore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitori pe, bi a ba ti ipasẹ ofin sọ eniyan di olododo, njẹ iku Kirisiti jẹ asan.” (Galatia 2:21)
(Galatia 2:21)
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu lẹta Pọọlu si awọn ara Galatia, a ri iha ti o yẹ ki a kọ si awọn ara wa ninu Kirisiti ti o ba ṣubu sinu ẹṣẹ. Iha wo si ni o yẹ ki a kọ si wọn? Iha imupadabọsipo ni o yẹ ki a kọ si wọn. Eyi tunmọ si pe ojuṣe wa ni lati ri daju pe iru awọn Kirisitiẹni bẹ ko ku tabi sọnu patapata sinu ẹṣẹ. Ki eleyi wa to o ṣeeṣe, awa ti a fẹ mu wọn padabọsipo gbọdọ jẹ ẹni ti o n tẹle itọni Ẹmi Ọlọrun, onisuuru ati onirẹlẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ba nkan jẹ ju bi o ti ṣe wa lọ. Amọ bi a tun ti ṣe kọ ninu ẹkọ yi, ko pọn dandan ki ẹnikẹni ninu wa ṣubu sinu ẹṣẹ. Ti gbogbo wa ba tilẹ mura gidigidi lati jẹ alabaapin ninu aye awọn ọmọ ijọ wa, ọpọ igba ni Ọlọrun yoo ri wa lo lati dena ki wọn ko sinu pakute ẹṣẹ. Ṣugbọn ti a ba gbe igberaga wọ bi ẹwu, ti a ko si ṣetan lati ba awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ninu aye wa ṣe pọ tabi lati fi aye gba wọn lati mọ bi nkan ti ṣe n lọ ninu aye wa, ko si ni ki Satani ma ri wa ya sọtọ ni awọn abala aye wa kan lati fi iya jẹ wa tabi lati sọ igbagbọ wa di igbagbe.
ÌGBÉRAẸNI-NÍGBỌ̀NWỌ́
Ori ọrọ yi si tun ni Pọọlu wa ninu abala lẹta rẹ si awọn ara Galatia ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi. Nkan ti o si fẹ ki o ye awọn ọmọ Ọlọrun yi naa ni pataki ki wọn ma gbe ara wọn ni igbọnwọ ninu irinajo wọn. Lotitọ, olukuluku ọmọ Ọlọrun ni yoo dahun funrarẹ nigba ti Ọlọrun ba n ṣe idajọ. Ko si si ẹnikankan ninu wa ti yoo ni awijare tabi ti yoo le sọ wipe oun kuna nitori aṣiṣe awọn kan tabi nitoripe oun ko ni onigbọnwọ. Nitorina, ẹnikọọkan wa gbọdọ mura lati mojuto ohun gbogbo ti o ba jẹ ojuṣe rẹ lati tẹ Ọlọrun lọrun ninu gbogbo ibaṣepọ rẹ, yala o ri ẹni ti yoo ran an lọwọ tabi ko ri.
Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni ki ẹnikọọkan wa ma fi gbogbo igba duro bi oluranlọwọ fun awọn ara wa. Aijẹbẹ, a ko ni mu ofin Kirisiti ṣẹ. Eyi si le jẹ ki a jẹbi iṣubu tabi ikuna awọn ara wa kan tabi omiran. Idi niyi ti Pọọlu ṣe sọ wipe ki ẹnikọọkan wa gbe igberaga ju sigbo, ki a si dẹkun lati ma ri ara wa ni bàbàrà, ki Ọlọrun ba le ri wa lo lati ma gbe awọn ara wa ninu Kirisiti nigbọnwọ. Iwọ naa wo nkan ti o sọ:
“Nitori bi eniyan kan ba n ro ara rẹ si ẹni pataki kan, nigba ti ko jẹ nnkan, o n tan ara rẹ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ wo, nigba naa ni yoo si ni ohun isogo nipa ti ara rẹ nikan, ki yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ. Nitori olukuluku ni yoo ru ẹru ara rẹ. Ṣugbọn ki ẹni ti a n kọ ninu ọrọ naa maa ṣe alabaapin ohun rere gbogbo ti o ni fun ẹni ti o n kọ ọ.” (Gàlátíà 6:3-6)
Njẹ o ri bayi? Igberaga ni o ma n fa ti awọn ọmọ Ọlọrun ko ki i fi ba ara wọn ṣepọ lọna ti o tọ ati ti o yẹ. Niwọn igba ti wọn ko ba si ni ibaṣepọ ti o munadoko laarin ara wọn, ko si bi wọn ṣe le ran ara wọn lọwọ lọna ti o peye. Ki wa lo n fa irufẹ igberaga yi? Nkan kan gbogi ti o ma n fa naa ni ki a ma fi iṣẹ́ igbagbọ wa we ti awọn ọmọ Ọlọrun miran. Eyi ni o le jẹ ki a ka ara wa si ẹni pataki niwaju ara wa, nigba ti a ko si ja mọ nkankan laisi Ọlọrun.
Ko si idi kankan lati fi iṣẹ igbagbọ wa we ti ẹnikẹni. Ti a ba n ṣe agbeyẹwo iṣẹ wa, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu ireti Ọlọrun lori rẹ. Ti a ba si n ṣe agbeyẹwo irinajo igbagbọ wa bakanna, nṣe ni o yẹ ki a ma ṣe ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun n reti lati ọdọ wa. Eyi jasi pe a ko gbọdọ ma wo aago-alaago sare tabi wo iṣẹ oniṣẹ ṣiṣẹ. Eyi ni ko ni jẹ ki a ba ẹnikẹni ninu ijọ wa lo pẹlu ọkan igberaga tabi pẹlu ọkan ẹni ti ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun.
Gbogbo wa ni a ṣe pataki si Ọlọrun ati si ijọba rẹ. Idi si niyi ti o ṣe jẹ wipe gbogbo wa ni o ran ọmọ rẹ Jesu Kirisiti lati rapada. O ṣeeṣe, lotitọ, ki oye bi a ti ṣe n gbe aye tẹ ẹ lọrun tete ye awa kan ju awọn kan lọ, eyi ko tunmọ si pe a ṣe pataki ju awọn wọnyi lọ niwaju rẹ. Nitori eyi, ọna ti a o gba ma ran igbagbọ ati aye wọn lọwọ ni a gbọdọ ma fi gbogbo igba san, ko ki i ṣe bi a o ti ṣe fi ẹnu tẹnbẹlu wọn tabi ja wọn kulẹ.
Bi mo ti ṣe wa sọ siwaju, wipe a gbọdọ ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ ko tunmọ si pe ki a wa sọ ara wa di bukata fun awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ko tunmọ si pe ki a fi ojuṣe adura gbigba wa, ojuṣe mimọ ifẹ Ọlọrun wa tabi awọn ojuṣe itọju ile wa kọ awọn ọmọ Ọlọrun miran lọrun. Eyi ko bojumu rara, ko si wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun fun wa. Ki a tilẹ sọ otitọ, imọtaraẹninikan ni yoo jẹ ki a ṣe eleyi. O si lewu fun igbagbọ wa. Nitorina, gẹgẹ bi Pọọlu ṣe wi, ẹnikọọkan gbọdọ mura lati gbe bukata rẹ, lalai duro de ẹnikẹni fun iranwọ.
Amọ ṣa o, Pọọlu tun wa la ọrọ rẹ, ki a ma ba ṣi i tunmọ. Lọna wo? O jẹ ki o ye wa pe bi o tilẹ jẹ wipe ẹnikọọkan ninu ijọ Ọlọrun gbọdọ mura lati gbe ẹru aye rẹ, eyi ko jasi pe ki a pa awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ti ṣẹgbẹ kan, ki a si ọ pe ki awọn naa lọ ma mojuto bukata wọn funra wọn. Dipo eyi, a gbọdọ mọ pe ara ojuṣe wa ni lati ma a pin awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa ninu ohun rere gbogbo ti a ba n rigba lọwọ rẹ. Ko yẹ ki a gbagbe pe awọn wọnyi ni o n kọ wa ni ọrọ Ọlọrun ti a n mulo ti aye wa fi n lọ deede. Nitorinaa, aṣẹ Ọlọrun ni pe bi aye wa ti n tipasẹ wọn lọ deede naa ni o yẹ ki a ma tọju wọn pẹlu awọn nkan ini wa. (Wo:1Kọrinnti 9:14)
Yatọ si eyi, ti enikan ba tọ wa sọna nipa ti ara, ti itọsọna rẹ si ja si igbega tabi ọrọ fun wa, ṣe ko yẹ ki a fi ẹmi imoore han siru ẹni bẹ ẹ? O yẹ! Nitorinaa, ma ṣe jẹ ki o ni ọ lara rara lati ma fifun awọn ti o n bọ ọ pẹlu ọrọ Ọlọrun, ti o si n ṣọna ninu adura lori aye rẹ, ni ibamu pẹlu bi a ti ṣe bukun fun ọ. O lere lori pupọ. (Wo: Numeri 10:29-3)
Eyi lo si fa ti Pọọlu fi tẹsiwaju lati sọ awọn ọrọ pataki yi fun wa lori fififunni:
“Ki a ma ṣe tan yin jẹ; a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, oun ni yoo ka. Nitori ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti ara rẹ, nipa ti ara ni yoo ka idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o ba n funrugbin sipa ti Ẹmi, nipa ti Ẹmi ni yoo ka iye ainipẹkun. Ẹ ma si jẹ ki agara da wa ni rere e ṣe: nitori a yoo kaa nigba ti akoko ba de, bi a ko ba rẹwẹsi. Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Gàlátíà 6:7-10)
Njẹ o ri bayi? Wipe Ọlọrun fẹ ki a ma fifun awọn ti o n bọ wa pẹlu ọrọ rẹ, ti o si n ṣọna lori aye wa, ati awọn miran ti O pa wa lasẹ lati ma fifun ko tunmọ si pe ki a kan ṣe bi a ba ti ṣe fẹ. Alakalẹ fififunni wa ninu iwe mimọ ti a gbọdọ tẹle. Aijẹbẹ, a kan tan ara wa jẹ ni – ififunni wa ko ni ni ere kankan lori. Bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa ninu awọn ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yi, Ọlọrun ko si lara awọn ti a le gan tabi tan jẹ. Nkan ti a ba ṣe ni a o gba ere rẹ lọwọ rẹ. Irugbin ti a ba fun ni Ọlọrun yoo fi ibukun ati ere sori rẹ. Ti a funrugbin nipa ti ara, ni ibamu pẹlu ifẹ inu wa, ninu rikiṣi, ọtẹ, itanjẹ ati ikunsinu, eso ti ara ti o jẹ idibajẹ naa ni a o ka. Ti a ba si funrugbin nipa ti Ẹmi, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun bi a ti ṣe la a kalẹ ninu iwe mimọ, eso ti Ẹmi ti a o ma gbadun titi ayeraye naa ni a o ka.
O wa ku sọwọ wa irufẹ irugbin ti a fẹ fun ati bi a ti ṣe fẹ fun. Amọ iyanju Pọọlu si wa ni pe ki a ma ṣe jẹ ki agara da wa ni rere ṣiṣe si gbogbo eniyan, paapaa julọ awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun. Dipo bẹẹ, ki a ma ṣe amulo gbogbo anfaani ti Ọlọrun ba fun wa lati fifunni ati lati fifunni ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe ni akoko ti o tọ, Ọlọrun yoo pin wa lere. Ọlọrun nikan ni O mọ akoko ti o tọ fun ere ohun rere yowu ti a ba ṣe. Oun nikan naa si tun ni O mọ irufẹ ere ti o tọ si wa laye yi ati ninu ijọba ayeraye rẹ. Ko wa yẹ ki a ma ṣe oore ni ireti pe ọna kan pato ni Ọlọrun gbọdọ gba lati san wa lẹsan rẹ. Ifurugbin nipa ti ara ni eyi jasi. O si ṣeeṣe ki a ma ri nkankan gba lori rẹ.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
Ọmọ Ọlọrun kọọkan gbọdọ mura lati gbe ẹru rẹ dipo eyi ti yoo fi sọ ara rẹ di bukata fun awọn ara rẹ ninu Kirisiti. Sibẹsibẹ, ifẹ Ọlọrun ni fun wa lati ma ran awọn ara wa lọwọ lati gbe ẹru aye wọn ati lati rin irinajo igbagbọ wọn ni pipe. Ọna ti a wa n gba ṣe eleyi ṣe pataki pupọ si Ọlọrun. A si nilo lati mọ ọn, ki a si tun tẹle. Aijẹbẹ, a ko ni ri ere kankan gba fun ohun rere yowu ti a ba ṣe.
ÌBÉÈRÈ
- Ọna pataki wo ni Pọọlu sọ ninu ẹkọ yi pe a le gba lati dena iṣubu awọn ara wa ninu Kirisiti?
- Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2023 Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07025105978)
Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ GÀLÁTÍÀ ÀYỌKÀ: GÀLÁTÍÀ 6:3-10 | ỌJỌ́RÚ 25, SẸRẸ 2022 Read More »




