Wu wọn lori lati jẹ ki Ibukun rẹ ṣiṣẹ | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022 | Vol. 10, No. 48
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Igbe. Adura mi si ni pe ki o ri ifarahan ẹkunrerẹ Ibukun Ọlọrun ninu aye rẹ ni gbogbo oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Gẹgẹ bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, ti o si jẹ okodoro ọrọ, Ọlọrun ti bukun fun wa pẹlu gbogbo ibukun ẹmi ti o wa ninu awọn ọrun (Efesu 1:3). Nitorina, ko si ẹnikankan ti o tun le fun ọ ni ibukun miran tabi ibukun ara ọtọ kan tabi ibukun ti o ga ju eyi ti Ọlọrun ti fun ọ lọ. O ti ni gbogbo Ibukun ti o nilo ninu aye yi lati jẹ ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ ati lati gbadun ara rẹ ni ọna ti o peye.
Amọ ṣa o, niwọn igba ti o jẹ wipe nkan ẹmi pọnbele ni Ibukun jẹ, a gbọdọ mọ bi a ti ṣe le jẹ ki o ṣiṣẹ, ki iriri rẹ ti a o ni ma ba jẹ ninu ẹmi nikan. Eyi jasi pe, a nilo lati ri ifarahan awọn Ibukun ti a ti rigba lati ọwọ Ọlọrun ninu ẹmi nipa ti ara pẹlu. Aijẹbẹ, awọn ti aye yi ko ni ri wa bi alabukunfun rara ati pe awọn naa gan paapaa ko ni jẹ igbadun aye wa bi o ti ṣe tọ gẹgẹ bi ẹni ti a bukun fun.
Bawo wa ni a ṣe le jẹ ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ? Akọkọ, a le jẹ ki wọn ṣiṣẹ nipa sisọ nkankanna pẹlu Ọlọrun nipa aye wa ati nipa ṣiṣiṣẹ tọ ọrọ wa lẹyin. Nkan ti eyi tunmọ si ni pe nigbakugba ti a ba n sọ nkankanna pẹlu Ọlọrun lori ododo wa, alaafia wa, ilera wa, iṣoriire wa, aabo wa ati awọn nkan daradara ti aye yi miran, ti a si tun n gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu nkan ti a n sọ, nṣe ni a n mu ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ. Bopẹ bosiya, a o bẹrẹ si ni ri ifarahan nipa ti ara awọn nkan ti o jẹ otitọ nipa aye wa ninu ẹmi.
Ekeji, a le mu ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ nipasẹ adura gbigba. Jesu sọ wipe, “Ẹ beere, ẹ o si ri gba, ayọ yin yoo si kun.” Eyi tunmọ si pe nipasẹ adura a le ri ifarahan awọn nkan ti Ọlọrun ti wulẹ fun wa ninu ẹmi lojutaye. Eyi, bi Jesu Oluwa wa si ṣe sọ, jẹ ọna kan ti a fi le jẹ ki ayọ wa kun lori awọn oniruuru nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa. (Wo: Johanu 16:24)
Ọna miran lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa ni ki awọn miran, paapaa julọ awọn ti o ni aṣẹ kan tabi omiran lori aye wa, pe Ibukun rẹ sori wa. Ma ṣe gbagbe pe mo ti sọ siwaju pe ko si ẹni naa ti o le fun wa ni Ibukun ti o ga, dara tabi pọ ju eyi ti Ọlọrun ti fun wa lọ. Ṣugbọn, awọn kan wa, nitoripe Ọlọrun ti fun wọn ni aṣẹ kan tabi omiran lori wa, le mu ki awọn ibukun rẹ kan ti o ti jẹ tiwa tẹlẹ ṣiṣẹ nipasẹ ọrọ adura wọn. Eyi yoo si jẹ ki a bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa ninu aye wa.
Nkan ti mo n sọ ni pe awọn ti o ni aṣẹ nitootọ lori aye wa lọna kan tabi omiran, gẹgẹ bi awọn obi wa, adari ijọ wa, ọkọ wa, olugbawaṣiṣẹ, ọga wa lẹnu iṣẹ ati awọn adari ilu tabi ti ijọba wa, le mu awọn ibukun Ọlọrun kan tabi omiran ṣiṣẹ ninu aye wa nipaṣẹ ire ti wọn ti ọkan ṣu fun wa. Idi si niyi ti a fi gbọdọ kọ lati ma mu inu wọn dun, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ki ori wọn ba le ma ya loorekoore lati pe ire Ọlọrun sori wa.
Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ibukun ti a fun Aburahamu ti fikalẹ sori ẹbi rẹ, a nilo lati mu ṣiṣẹ ninu aye ọkọọkan ninu awọn arọmọdọmọ rẹ ki wọn to le ni iriri tabi ifarahan rẹ. Fun apẹẹrẹ, ti a ba wo aye Isaki, a ri wipe igbọran rẹ si Ọlọrun ni akoko iyan buruku kan ni o kẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ fun iṣoriire rẹ laye (Jẹnẹsisi 26). Lafikun, adura rẹ fun aya rẹ tun jẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ lodi si iyagan wọn, ti awọn naa si di ọlọmọ laye (Jẹnẹsisi 25:21). Ṣugbọn ni ti Isọ, a ri wipe ire Isaki ni o yẹ ki o mu Ibukun yi ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Nitorina, Isaki paṣẹ fun lati pese ounjẹ adidun ti yoo mu ki inu oun dun to bẹẹ gẹẹ ti oun yoo gbadura pataki ti yoo mu ki Ibukun baba oun ṣiṣẹ ninu aye rẹ fun. Bi o wa tilẹ jẹ wipe Isọ kọ ni o pada gba Ibukun yi, Jakọbu, ẹni ti o gba a, ko kuna rara lati mu inu baba wọn, Isaki, dun pẹlu ounjẹ ara ọtọ ti o gbe wa fun. Nitorina, Ibukun naa di titu silẹ lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ nipa ire Isaki, aye rẹ ko si ri bakanna mọ lati igba naa lọ.
Nibakanna, ti awa naa ba kọ lati ma mu ki inu awọn ti o ni aṣẹ lori wa dun nipasẹ awọn nkan ti a n ṣe fun wọn ati ṣi wọn, ọpọ igba ni a o ri pe ori wọn yoo wu lati sọ awọn ọrọ ti yoo jẹ ki awọn Ibukun Ọlọrun kan ṣiṣẹ ninu aye wa, ti a o si bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa lojutaye. Ṣugbọn ti a ba ro pe ọrọ ire wọn ko ja mọ nkankan si wa, boya nitori imọ ti a ni pe a kuku ti gba gbogbo Ibukun ọrun lati ọwọ Ọlọrun, a jẹ wipe awọn ifarahan awọn Ibukun Ọlọrun kan wa ti a le ma ni titi ọjọ aye wa yoo fi tan lorilẹ niyẹn. Nitorina, ẹ jẹ ka kẹkọ lati ara Jakọbu, ki a si ma wo, loorekoore, awọn ọna ti a le gba wu awọn ti o ni aṣẹ lori wa lori lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa. Ki Ọlọrun si rẹ ọkan wa silẹ lati mu ọrọ yi lọkunkundun, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọsẹ ire o.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)





