latori tabili paito

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu yi, iyẹn oṣu Ebibi 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ ninu ọsẹ naa ni aṣepe, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi a ti ṣe mọ, a n ṣe ayẹyẹ ọdun kẹrinla ti a ti n pade ninu ilu yi gẹgẹ bi ijọ loni. Ni akọkọ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ohun gbogbo ti O ti jẹ si wa, ti O ti ṣe fun wa, ti O ti ṣe ni aarin wa ati ti O ti ṣe nipasẹ wa ninu awọn ọdun wọnyi. Ki iyin jẹ ti orukọ rẹ ti o logo titi lailai.

Lafikun, mo tun fẹ dupẹ lọwọ gbogbo awa ti a ri ara wa gẹgẹ bi ojulowo ọmọ ijọ yi fun fifi aye gba Ọlọrun lati fi ọwọ tọ ọkan wa lati darapọ mọ ara wa ninu ibadapọ pẹlu rẹ, Mo si tun dupẹ lọwọ wa fun fifi aaye gba a lati tọ wa lati kọpa lọna ti o peye ninu ohun gbogbo ti o n mu ijọ naa tẹsiwaju. Adura ni pe ki Oluwa dardara tẹsiwaju lati ma a ṣiṣẹ ninu wa titi gbogbo ero rẹ si wa ni rere yoo fi wa si imuṣẹ ninu aye wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọdun ibadapọ miran, mo fẹ gba wa niyanju lati fi ara wa jin siwaju si fun ọrọ rẹ, fun adura gbigba, fun ibadapọ pẹlu ara wa ati fun jijẹ ẹri didara Ọlọrun si wa fun awọn ti o wa ni ayika wa. Ki ni idi? Idi ni pe awọn nkan wọnyi ni awọn eniyan mimọ igbaani fi ara wọn jin fun. Nipa bi wọn si ṣe fi ara wọn jin fun awọn nkan wọnyi, Ọlọrun ri aaye lati gbe gbogbo wọn ro lati jẹ irinṣẹ ti o ga ni ọwọ rẹ ni yiyi aye ọpọ kaakiri agbaye pada. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 2:42-42 & 8;41)

Nitorina, niwọn igba ti awa naa fẹ ki Ọlọrun gbe ẹnikọọkan wa ro lati wulo gidigidi fun un ni fifi ọwọ kan aye ọpọ ni ayika wa, a wa gbọdọ fi ara wa jin fun ọrọ rẹ, adura gbigba, ibadapọ pẹlu ara wa ati ẹri jijẹ fun awọn ti o wa ni ayika wa ju tatẹyin wa lọ. Eyi, lotitọ, le ma rọrun, nitoripe ṣiṣe awọn nkan ti o n gbe eniyan ro ko ki i fi igba gbogbo wa pẹlu irọrun. Ṣugbọn ṣiṣe eyi yoo lere lori lọna ti o ga fun wa ati fun awọn ti o wa ni ayika wa.

Mo ki ọ kaabọ lẹkaansi sinu ọdun ibadapọ miran ninu oore-ọfẹ Ọlọrun. Mo si fẹ ki o foju sọna fun iriri didara Ọlọrun ti o ga ju tatẹyinwa lọ ninu aye rẹ ati ninu ijọ wa, bi gbogbo wa ṣe n fi ara wa jin siwaju si fun idari Ẹmi rẹ.

Kí Ọlọ́run kí ó bùkún fún ọ.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ọdún ìbádàpọ̀ míràn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 17, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 03 Read More »

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun pa ọ mọ ninu ọsẹ yi ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan nibikibi ti o ba ya si, ni orukọ Jesu. Amin.

Pọọlu, ninu lẹta rẹ keji si awọn ara Tẹsalonika, sọ eyi:

“Ati ki a le gbà wa kuro lọwọ awọn eniyan buburu ati awọn ika eniyan: nitori pe kii ṣe gbogbo eniyan ni o gbagbọ́.” (2 Tẹsalóníkà 3:2)

Ki ni nkan ti a ni ki a gbadura fun? A ni ki a gbadura pe ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan. Eniyan ja si pe a ni ninu aye yi awọn ika ati ọdaju eniyan. Irufẹ awọn wọnyi a ma a ṣetan lati gbe igbesẹ-ki-gbesẹ lati han ẹnikẹni ti o ba ṣẹ wọn leemọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹṣẹ kankan ninu ọrọ yowu ti o wa nilẹ. Lafikun, irufẹ awọn wọnyi ko ki i ṣaba gbẹbẹ. Ti wọn ba ti pinnu lati ṣe ẹnikan ni ewu, o di dandan ki wọn ṣe bẹẹ gẹgẹ, bi eyi yoo tilẹ gba gbogbo asiko aye wọn tabi gbogbo owo wọn. Nitorina, ayafi ti Ọlọrun ba pa wa mọ kuro lọwọ wọn, a ko le bọ lọwọ iwa buburu wọn.

Fun apẹrẹ, ọkunrin kan ti a n pe ni Hamani ṣetan lati pa Mọdẹkai ati gbogbo awọn Juu ti o wa labẹ ijọba Ọba Ahasiwerusi nitoripe Mọdẹkai ri fin. Ṣugbọn ẹnikan ṣoṣo ni Mọdẹkai. Ki wa lo de ti Hamani fi fẹ pa gbogbo awọn Juu nitori tirẹ? Idi ni pe ika ati ọdaju eniyan ni. Ti Mọdẹkai ati awọn eniyan rẹ ko ba si lọ gbadura si Ọlọrun pe ki O da si ọrọ naa ni, ọpọlọpọ wọn ni ko ba padanu ẹmi wọn nitori iwa buburu Hamani. (Wo: Ésítà 3-9)

Ti Ọba Hẹrọdu nkọ? Ọkunrin yi ran awọn jagun-jagun rẹ lati lọ pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ọdun meji ati awọn ti ko to bẹẹ ti o wa ni Betilẹhẹmu nitoripe o ṣa fẹ pa Jesu nigba ti o wa ni ọmọ irinsẹ. Ki ni idi? Ko fẹ ki o dagba di ọba awọn Juu. Niwọn igba ti ko si wa mọ ọmọde naa ti a n pe ni Jesu, o ba kuku pinnu lati pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ti o wa ni Bẹtilẹhẹmu, nibi ti a ti bi Jesu, ti wa ni iwọn ọjọ ori rẹ. Ti Ọlọrun ko ba wa da si ọrọ naa ni, a ko ba ti pa Jesu ki o to di pe yoo tilẹ ni anfaani lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun ran wa si aye lati ṣe. (Wo: Mátíù 2:1-18)

Ki ni koko ọrọ mi? Ohun naa ni pe awọn ika ati ọdaju eniyan bi Hamani ati Hẹrọdu si wa digbi ninu aye yi ati ni ayika wa. Satani si le lo wọn nigbakugba ati fun idi-ki-di lati kọlu wa. Ṣugbọn Ọlọrun le pa wa mọ kuro lọwọ wọn. Awa na, ẹwẹ, ko gbọdọ duro de igba ti eyi yowu ninu wọn yoo ma halẹ mọ wa ki a to kọ lati ma gbadura fun aabo Ọlọrun kuro lọwọ wọ. Aijẹbẹ, wọn le ti jẹ wa niya tan ki o to di pe a o ri aaye lati gbadura.

Nitorina, kọ bi a ṣe n gbadura lojoojumọ pe ki Ọlọrun ma pa ati iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ ni gbogbo igba kuro lọwọ awọn ika ati ọdaju eniyan ti o wa layika rẹ. Yoo si ri bẹ ẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìkà àti ọ̀dájú ènìyàn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 10, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 02 Read More »

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu kaarun ọdun yi, iyẹn oṣu Èbìbí 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ma a fi igba gbogbo pa ọ mọ, ki o ma ba a ṣe ohunkohun ti yoo ba a ninujẹ, ti yoo si jẹ ki O yi ọkan rẹ pada lori mumi awọn eto rẹ fun aye rẹ ṣẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe o ṣeeṣe ki a mu inu Ọlọrun bajẹ. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki a ba a ninujẹ nipa bi a ṣe n gbe aye wa ati nipa iha ti a n kọ si ọrọ rẹ. Idi si ni pe O fẹran wa. Kiki awọn ti a ba fẹran, ti a si n kẹ, ni wọn le ba wa ninujẹ tabi mu ọkan wa poruru. Awọn ti a ko ba fẹran ko le ba wa ninujẹ, bi o ti wu ki iwuwasi wọn si wa buru to. Ki a tilẹ sọ otitọ, ọpọ ninu wa ni ko tilẹ ni fẹ fi aye gba ẹnikẹni ti a ko fẹran lati ṣe ohunkohun ti yoo mu wa karisọ.

Ṣugbọn ti ẹnikan ti a fẹran, ti o si tobi lọwọ wa, ba bẹrẹ si ni wu iwa aikanisi si wa, inu wa ko ni dun rara. Ti irufẹ ẹni bẹ ẹ ba si tun wa tẹsiwaju lati ma mu inu wa bajẹ lọna yi, a le yi ọkan wa pada lori rẹ, ki a si mu ifẹ ti a ni si wọn kuro lọkan wa. Lẹyin eyi, wọn ko tun ni le jẹ igbadun ibaṣepọ wọn pẹlu wa bi wọn ti ṣe ma n jẹ tẹlẹ mọ.

Nibakanna, nitoripe Ọlọrun fẹran wa, a le mu inu rẹ bajẹ. Ti a ba si wa fi mimu inu rẹ bajẹ ṣe aṣa, asiko naa le de ninu eyi ti yoo yi ọkan rẹ pada lori wa ati lori eto rẹ fun wa. Bawo wa ni a ko ṣe ni fi aye wa ṣofo tabi pa aye wa run, ti eyi ba lọ waye?

Fun apẹrẹ, a sọ eyi nipa idi ti Ọlọrun fi yọ Ọba Sọọlu kuro ni ipo rẹ gẹgẹ bi ọba lori orilẹ-ede Isiraẹli:

“Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe, Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.” (1 Sámúẹ́lì 15:10-11)

Njẹ o ri bayẹn? Inu Ọlọrun bajẹ nitoripe O fi Sọọlu ṣe ọba lori Isiraẹli. Ki si ni idi? Idi ni pe ọkunrin naa sọ di aṣa lati ma tapa si aṣẹ rẹ. Nkan ti o tun wa buru ju iyẹn lọ ni pe ko tilẹ ni ẹmi ironupiwada rara. O ni i lara lati fi tọkan-tọkan roninupiwada ti a ba ba a wi tabi sọ pe ki o tun iwa rẹ ṣe. Nitorina, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, O si fi ẹlomiran rọpo rẹ.

Njẹ Sọọlu wa kaanu lori ọrọ yi bi, nigba ti Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori ọrọ rẹ, ki O si wa oju rẹ fun aanu? Rara o, ko ṣe bẹ ẹ. Nṣe ni o kan n ba iṣe rẹ lọ gẹgẹ bi ọba, bi igba ti ko si nkankan ti o ṣẹlẹ. Nitorina, o pada pa aye ara rẹ fun, o si sọ ohun rere yowu ti o ṣe fun orilẹ-ede Isiraẹli gẹgẹ bi ọba di asan.

Amọ ṣa o, bi a ti ṣe ri ninu akọsilẹ naa, Samuẹli ti ko ki i ṣe oun ni a rọ loye ko dẹkun lati ma kẹdun niwaju Ọlọrun fun ọkunrin yi. Lotitọ, nigba ti o tilẹ de ikorita kan, Ọlọrun ni lati sọ fun pe ki o ye kẹdun lori ọrọ Sọọlu mọ, ki o si lọ ta ororo si elomiran lori rọpo rẹ (1 Sámúẹ́lì 16:1). Ki wa lo fa ti o fi n kẹdun fun Sọọlu bi iyẹn? Idi ni pe o mọ babara ki a mu inu Ọlọrun bajẹ ati pataki ki a ronupiwada lotitọ ti a ba ti ṣe bẹ ẹ. Aijẹbẹ, a le pada fi aye wa ati oore-ọfẹ yowu ti a le ti ri gba lọwọ Ọlọrun ṣofo.

Eyi si wa ni idi ti a fi kilọ fun awa naa ninu Iwe Mimọ ni ọna yi:

“Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande.” (Éfésù 4:30)

Njẹ o ri bayẹn? A gbọdọ ṣo ara wa ki a ma ba a fi ara wa jin fun ṣiṣe ohunkohun ti o le ba Ẹmi Ọlọrun ti O n gbe inu wa ninujẹ. Ti a ba si ti n ba ninu jẹ ni ọna kankan, nṣe ni ki a ronupiwada, ki a si wa oju rẹ fun aforiji ni kiakia. Aijẹbẹ, gẹgẹ bi Ọba Sọọlu, awa naa le pada fi gbogbo ifẹ ati oore-ọfẹ ti O ti tu si ori wa lẹkunrẹrẹ ṣofo. Njẹ ki eyi ma jẹ ipin wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní oṣù Èbìbí 2026 alárinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má mú Ọlọ̀run banújẹ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbì 03, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 15, No. 01 Read More »

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Igbe ati Èbìbí 2026 papọ. Adura mi ni pe ki Ọlọrun, ni kiakia, ya aye rẹ ya ohun gbogbo ti o n mu akude ba didara rẹ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Mo gba adura yi fun ọ nitoripe a ma n ri awọn igba ti o jẹ wipe idi ti awọn nkan rere ti Ọlọrun n ṣe ninu aye awọn eniyan rẹ ko ki i fi ja mọ nkankan ni pe awọn nkan kan ninu aye wọn n mu akude ba wọn. Ti a ko ba si mojuto awọn nkan wọnyi, ko si nkan rere kankan ti O le ṣe fun wọn ti yoo fun wọn ni itẹlọrun ati isinmi ni aye.

Fun apẹrẹ, a ko eyi sinu bibeli nipa ọkunrin kan ti a n pe ni Naamani:

“NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.” (2 Àwọn Ọba 5:1)

Ta ni o mu Naamani di ẹni nla, bi a ti ṣe ri ninu ẹsẹ bibeli yi? Ọlọrun ni. Oun ni O sọ di ẹni ti gbogbo eniyan ni orilẹ-ede rẹ, pẹlupẹlu ọba rẹ, ka si ẹni pataki ati ẹni-ọwọ. Ṣugbọn pẹlu gbogbo awọn nkan ti Ọlọrun ṣe fun-un wọnyi, ko ki ṣe ẹnikan ti inu rẹ dun, ti o si tun ni balẹ ọkan tan yanyan. Ki ni idi? Adẹtẹ ni. Eyi jasi pe, o jẹ ẹnikan ti wọn yo pada ya sọtọ kuro lọdọ gbogbo awọn ti o fẹran rẹ, ti yoo si wa ma a da gbe. Aijẹbẹ, wọn le ko ẹtẹ rẹ.

Ki wa ni titobi rẹ yoo ja mọ? Ki ni ọrọ rẹ yoo ja mọ? Ki si ni gbogbo awọn iṣẹ akikanju ti Ọlọrun ti tipasẹ rẹ ṣe yoo ja mọ? Gbogbo awọn nkan wọnyi ni ẹtẹ rẹ yoo pada sọ di asan. Ẹtẹ rẹ ko ni jẹ ki o jẹ igbadun wọn lẹkunrẹrẹ tabi fun igba pipẹ. Ero lori eyi nikan gan an ro lati sọ di onibinujẹ ẹniyan.

Awa dupẹ pe Ọlọrun lo ọdọmọbirin ẹru kan ti a mu wa si ile rẹ lati ilẹ Isiraẹli lati ran an lọwọ lati ri iwosan rẹ gba. Ọdọmọbinrin yi sọ fun un nipa Wolii Eliṣa ati bi Ọlọrun ṣe le lo o lati wo ẹtẹ rẹ san. Nigba ti o si lọ si ọdọ eniyan Ọlọrun yi, a wo ẹtẹ rẹ san nitootọ. Nitorina, lati ọjọ naa lọ, o bẹrẹ si ni sin Ọlọrun, o si tun bẹrẹ si ni jẹ igbadun ohun rere gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun pẹlu itẹlọrun ati laisi ibẹru.

Wayi o, Ọlọrun kanna ti O mojuto ẹtẹ Naamani le mojuto ohunkohun ti o n di ọ lọwọ lati jẹ igbadun didara rẹ ninu aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Nkan ti o kan nilo lati ṣe ni ki o ke pe e fun iranlọwọ. Bi o si ti n ṣe eyi, gbogbo ‘Ṣugbọn’ ti o n sọ didara rẹ di alainitunmọ ninu aye rẹ ni a o mojuto. Iwọ yoo si wa bẹrẹ si ni jẹ igbadun awọn ibukun rẹ pẹlu itẹlọrun.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ṣùgbọ́n adẹ́tẹ̀ ni | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 26, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 52 Read More »

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2026. Mo gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki o lugbadi idajọ rẹ lori ọkankan ninu awọn ti o wa ninu aye rẹ tabi ni ayika rẹ. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitoripe ko ki i ṣe gbogbo igba ti awọn eniyan ba ni iriri idajọ Ọlọrun naa ni o jẹ nitoripe awọn funrawọn buru ni. Igba miran wa ti awọn eniyan a ma a ni iriri idajọ Ọlọrun nitoripe wọn kuna lati lo aṣẹ wọn lati ṣe idajọ awọn ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn. Fun apẹrẹ, Ọlọrun sọ eyi fun Samuẹli nipa alufa Eli:

“Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.” (1 Sámúẹ́lì 3:13)

Ki ni idi ti Ọlọrun ṣẹ fẹ ṣe idajọ idile Eli? Ṣe nitoripe ọkunrin naa buru ni? O ti o! Abi ṣe nitoripe awọn ọmọ rẹ kan buru ni? O ti o! Idi ti Ọlọrun fi fẹ ṣe idajọ idile rẹ ni pe o kuna lati mu awọn ọmọ rẹ so, bi o tilẹ jẹ wipe o mọ nipa ẹṣẹ wọn daadaa.

Ti Eli ko ba mọ nipa ẹṣẹ awọn ọmọ rẹ ni, Ọlọrun ko ma ba ti da lẹbi nitori wọn. Lafikun, ti Eli ko ba wa ni ipo ẹni ti o le da awọn ọmọ rẹ lẹkun ni, ki wọn ma ba a le ma ṣẹ si Ọlọrun bi o ti ṣe wu wọn, ko ba ma ti da a lẹbi nitori wọn. Ṣugbọn yatọ si pe o mọ nipa ẹsẹ wọn, o tun wa ni ipo lati da wọn lẹjọ ati lẹkun. Sibẹsibẹ, o kuna lati ṣe eyi. Nitorina, Ọlọrun sọ fun pe Oun yoo ṣe idajọ idile rẹ fun ẹṣẹ awọn ọmọkunrin naa.

Njẹ ki wa ni idi ti Ọlọrun fi kọkọ sọ fun un nipa idajọ rẹ ti o n bọ ṣaju asiko idajọ naa? Idi ni ki o ba a le ṣe ohun ti o tọ pẹlu ikanju. Ṣe o wa ṣe ohun ti o tọ? Rara o, ko ṣe e. Dipo eyi, esi ti o fọ ni pe aaye pọ fun Ọlọrun lati ṣe ohun yowu ti o ba tọ loju rẹ lori ọrọ naa. Eyi jasi pe, ni titiẹ, ko ṣetan lati tun yọ ara rẹ lẹnu lori nkan ti awọn ọmọkunrin rẹ n ṣe mọ. (Wo: 1Sámúẹ́lì 3:18)

Ki wa ni eyi n kọ wa, ki a ma fọrọgun? Oun naa ni pe ti Ọlọrun ba fi awọn eniyan si abẹ iṣakoso wa, ko reti pe ki a fi aye gba wọn lati ma a ṣe bi o ba ṣe wu wọn. Dipo eyi, nkan ti O n reti ni pe ki a ma a lo aṣẹ wa lati fi wọn si aaye wọn, ti wọn ba n ṣe radarada. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma da ẹṣẹ Eli. Ti eyi ba si ri bẹ, igbakugba ti Ọlọrun ba da si ọrọ naa lati ṣe idajọ iwa ika ti a kọ lati ṣe idajọ rẹ, o di dandan ki awa naa kopa ninu idajọ naa, ayafi ti a ba ṣaanu fun wa. Ta wa ni o mọ ọna ti Ọlọrun yoo gba ṣe idajọ?

Nitorina, ma ṣe da bi Eli ti o kọ lati ṣiṣẹ lori ikilọ Ọlọrun lati ṣe idajọ awọn ọmọ rẹ nitoripe radarada wọn su u. Dipo eyi, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni lo aṣẹ rẹ lati fi gbogbo nkan si aaye wọn nibikibi ti o ba ti ni aṣẹ lati ṣe bẹ ẹ. Nipa bayi, iwọ yoo le pa ara rẹ mọ lati ma kopa ninu idajọ awọn alaigbọran.

Siwaju si, ma ṣe jẹ ki inu bi ọ nigba ti awọn ti o ni aṣẹ lori rẹ ko ba fi aaye gba ọ lati ma ṣe radarada labẹ isakoso wọn. Idi si ni pe ifẹ Ọlọrun ni wọn nṣe. Yatọ si iyẹn, nipa bi wọn ko ṣe fi aaye gba ọ lati ma ṣiwawu labẹ isakoso wọn, nṣe ni wọn n pa ọ mọ kuro labẹ idajọ Ọlọrun. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki o ma dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe jẹ adari ti o mọ ojuṣe wọn. Aijẹbẹ, o le ṣe ara rẹ leṣe nipasẹ idajọ Ọlọrun, ti o ba kọ lati gba ibawi. Mo gbadura pe iru eyi ko ni jẹ ipin rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ẹ̀ṣẹ̀ ÉlìLáti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 19, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 51 Read More »

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodwiọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Adura mi ni pe ki Ọlọrun lo gbogbo ipokipo ti o le ba aye rẹ, bi o ti wu ki o buro loju to, lati mu ete rere rẹ ṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ki ni idi ti mo fi gba adura yi fun ọ? Idi ni pe mo mọ pe aye ko dọgba. Wo, fun apẹrẹ, nkan ti Solomọni sọ nipa eyi:

“Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11)

Njẹ o ri bayẹn? Aye ko kan ni funralara rẹ ṣiṣẹ fun ire ẹnikẹni, bi o ti wu ki awọn amuyẹ ẹni naa ga to. Idi ni yi ti a fi ni ọpọ eniyan ti wọn ni awọn amuyẹ ti o ga, ti wọn si tun n gbe igbe aye ailojutu. Awọn amuyẹ wcn ti o yẹ ki o gbe wọn leke laye ko wulo fun wọn lọna ti o nitunmọ kankan. Awọn amuyẹ wọnyi tilẹ tun le ma a ṣiṣẹ lodi si wọn.

Ki ni idi? Idi ni pe aye ko dọgba. Aye ko kan ni fun ọ ni aṣeyọri tabi ibalẹ-ọkan nitori awọn amuyẹ, ibaṣepọ tabi iṣẹ karakara rẹ. Nṣe ni o ni lati wa ni ibi ti o tọ, ni asiko ti ọ tọ, ki o si ma ṣe ohun ti tọ. Aijẹbẹ, gbogbo amuyẹ, ọgbọn, ẹkọ ati anfaani ti o ni le pada ja si pabo.

Bawo wa ni o ṣe le fi ara rẹ si ibi ti o tọ, ni asiko ti o tọ, ki o si tun ma ṣe ohun ti o tọ pẹlu nibẹ? Nipa fifa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ ni. Ti o ba fa ara rẹ le ẹni ti o ni aye lọwọ, O le kọ ni ohun ti o dara julọ fun ọ, ki O si tun dari rẹ ni ọna ti o yẹ ki o tọ. (Wo: Àìsáyà 48:17)

Amọ ṣe iwọ yoo ṣe eyi bi? Ṣe iwọ yoo fa aye rẹ le Ọlọrun, ẹni ti o ni aye, lọwọ, ki O ba a le dari rẹ si ọna ti o yẹ ki o tọ laye, ki O si fi idi rẹ mulẹ ninu ododo, alaafia ati iṣerere? Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe ọ daada, ko ni le da ọ duro lati jẹ ẹni ti o yẹ ki o jẹ lorilẹ aye.

Ranti pe bi o tilẹ jẹ wipe aye ko ṣe daada si Josefu, o si papa jẹ ẹni to yẹ ki o jẹ laye. Idi si ni pe o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, ma ṣaroye mọ pe aye ko ṣe ọ daada. Nṣe ni ko mura lati dojukọ aye lọna yowu ti o ba gba yọ si ọ, irufẹ ọda ti o le fi kun ara rẹ. Bẹẹni, o nilo lati ṣẹgun ninu aye, bi o ti wu ki nkan ma ṣe deede si ọ to. Ọna kan ṣoṣo lati ṣe eyi, bi mo ti ṣe sọ tẹlẹ, ni ki o fa ara rẹ le Ọlọrun lọwọ. Nitorina, fa ara rẹ lọwọ. Iwọ yoo si pada duro gẹgẹ bi aṣẹgun lẹyin-ọ-rẹyin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ayé ò dọ́gba | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 12, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 50 Read More »

Àjọyọ̀ Àjíìnde | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 05, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 49

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kiristi Oluwa wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Igbe 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun ṣe ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu rẹ ni aṣepe ninu oṣu naa, ki O si tun fun ọ ni isinmi ni gbogbo ọna. Amin.

Gẹgẹ bi a ti ṣe mọ, eni jẹ ọjọ ti pupọ-julọ ninu awọn Kirisitiẹni kaakiri agbaye n ṣe ajọyọ ajiinde Jesu Kirisiti Oluwa wa. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a ri awọn Kirisitiẹni ti ko ri idi fun irufẹ ajọyọ yi, paapaa julọ niwọn igba ti Jesu Oluwa wa ko pa a laṣẹ fun wa lati ṣe bẹẹ, a ko le sọ wipe nkan ti ko dara ni. Nkan ti mo n sọ ni pe ko si nkan ti o buru ninu ki a ya ọjọ kan sọtọ lati ṣe ajọyọ ajiinde, ki a si sọ fun gbogbo agbaye nkan ti Jesu ṣe fun igbala ọmọniyan.

Amọ ṣa o, ni ṣiṣe ajọyọ ajiinde, a ko tun wa gbọdọ fi ara wa fun ṣiṣe awọn nkan ti Oluwa wa wa lati gba wọn lọwọ wa. Eyi jasi pe, ajọyọ ajiinde wa ko gbọdọ yọri si imuti-para, apejẹ iṣọnu tabi iṣekuṣe. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki o kọkọ jẹ ajọyọ fifi ọpẹ fun Ọlọrun fun bi O ti ṣaanu fun wa, ti O si ran Jesu lati ra wa pada.

Ekeji, ajọyọ wa gbọdọ jẹ eyi ti yoo tọ wa lati ran ara wa leti nkan ti ajiinde Jesu Kiristi yanju fun wa. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe duro siwaju Ọlọrun lọwọlọwọ yi gẹgẹ bi ẹni idalare. Lafikun, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe jẹ ẹda tuntun ati olododo eniyan niwaju rẹ lọwọlọwọ yi. Yatọ si iyẹn, nitori ajiinde rẹ ni a ṣe ni agbara lori Satani, ẹṣẹ ati aye yi lọwọlọwọ yi. (Wo: Róòmù 5:25; 2Kọ́ríntì 5:17-21)

Nitorina, nkan ti yoo jẹ ki ajọyọ ajiinde wa ni itunmọ ni ki a ma rin pẹlu afiyesi awọn nkan wọnyi. Ti a ko ba ma a rin pẹlu aifyesi wọn, ajọyọ ajiinde wa ko ni itunmọ. Nṣe ni a o kan ma fi han pe asan ni ohun ti O ṣe fun wa.

Wayi o, adura mi ni pe ohun ti Jesu ṣe fun iwọ ati emi nipasẹ iku, isinku ati ajiinde rẹ ko ni lailai ja si asan. Ṣugbọn awa naa gbọdọ ma a fi igba gbogbo ṣe asaro lori nkan ti O ṣe fun wa, ki a ba a le ma a fi ojoojumọ ṣe amulo rẹ lati jẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ. Mo ki ọ kaabọ lẹẹkansi sinu oṣu tuntun yi. Mo si tun gbadura pe ki o jẹ igbadun ere ajiinde Jesu Oluwa wa lẹkunrẹrẹ ninu aye rẹ ninu oṣu naa. Amin.

A ku Ajiinde.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Àjọyọ̀ Àjíìnde | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Igbe 05, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 49 Read More »

Ìdí tí wọ́n ṣe parun | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 29, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o so oṣu Ẹrẹ́nà ati Igbe 2026 papọ. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun maa fi ojoojumọ ṣaanu fun ọ, ki O si ma jẹ ki eti rẹ di si ibawi yowu ti Ẹmi rẹ le mu tọ ọ wa, ki o ma ba ṣi aye rẹ silẹ fun iparun ojiji.

Ki ni idi ti awọn ọmọ Eli ṣe parun lalai si atunṣe? Idi ni pe eti wọn di si ibawi Ẹmi Ọlọrun. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọkunrin yi jẹ alufa ninu ile Ọlọrun, ọmọ Beliali, ọmọ Eṣu ni wọn. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ko ka Ọlọrun si rara. (Wo: 1Sámúẹ́lì 2: 12-17)

Bawo gan an ni wọn ṣe wa di alufa inu ile Ọlọrun, niwọn igba ti o jẹ wipe wo ki ka a si? Ojuṣaaju! Nkan ti mo n sọ ni pe idi kan ṣoṣo ti wọn ṣe jẹ alufaa ninu ile Ọlọrun ni pe baba wọn jẹ olori alufa fun Isiraẹli ni asiko naa. Ti ko ba ki i ṣe olori alufa ni, a ko le fi wọn ṣe alufa ni ilẹ naa, bi o tilẹ jẹ wipe idile awọn alufa ni wọn ti wa.

Loni ẹwẹ, a tun ri ninu ọpọ ijọ awọn ti ko ni ibẹru Ọlọrun rara ti wọn si n ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari. Ki ni idi? Ojuṣaaju! Eyi jasi pe idi ti awọn wọnyi ṣe jẹ adari ni pe wọn ni ibaṣepọ pẹlu awọn adari ijọ kan, ko ki i ṣe nitoripe Ọlọrun yan wọn gẹgẹ bi adari awọn eniyan rẹ. Nitorina, awọn naa ko le ṣe alaijọ awọn ọmọkunrin Eli, awọn ọmọ Beliali, ninu iwuwasi wọn.

Ni kukuru, nigba ti Eli bẹrẹ si ni gba oniruuru iroyin ti ko dara nipa awọn ọmọkunrin rẹ yi, o pe wọn, o si ba wọn wi. Ṣe wọn wa gbọrọ si lẹnu? Rara, wọn ko gbọrọ si lẹnu. Ki ni idi? Wo nkan ti bibeli sọ nipa eyi:

“Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn.” (1 Sámúẹ́lì 2:24-25)

Ki ni idi ti awọn ọmọkurin Eli ko ṣe gbọrọ si baba wọn lẹnu? Id ni pe Ọlọrun ti pinnu lati pa wọn run. Ki ni idi ti Ọlọrun fi pinnu lati pa wọn run? O pinnu lati pa wọn run nitoripe wọn ti sọ ki wọn ma kọ ọrọ ibawi rẹ silẹ di aṣa.

Wayi o, eyi n kọ wa pe ki a ma ṣe lailai kọ ibawi Ẹmi Ọlọrun silẹ. Idi si ni pe ṣiṣe bẹ ẹ le pada di aṣa fun wa laipẹ. Ti o ba si ti di aṣa fun wa lati ma a kọ ibawi rẹ silẹ, o di dandan ki a ṣi aye wa silẹ fun idajọ Ọlọrun, ti a ko ba ṣaanu fun wa. Adura mi wa ni pe ki o ma fi ori kunkun ṣi abala aye rẹ kankan silẹ fun idajọ rẹ. Amọ o gbọdọ ṣọ ara rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ìdí tí wọ́n ṣe parun | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 29, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 48 Read More »

Jẹ́ olóòótọ́ ní ohun kí Kínní | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 22, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 47

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu ọsu Ẹrẹ́nà 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun fun ọ ni okun lati jẹ olotitọ si i ni ojoojumọ, ki O ba a le gbe ọ ga lati jẹ ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ laye. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ọkan lara awọn nkan ti Ọlọrun ma n wo lati gbe awọn eniyan gẹ ni iha ti wọn kọ si awọn nkan kekeke ti O fa le wọn lọwọ. Wo bi Jesu Oluwa wa ti ṣe gbe eyi kalẹ fun wa:

“Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu. Njẹ bi ẹnyin kò ba ti jẹ olõtọ ni mammoni aiṣõtọ, tani yio fi ọrọ̀ tõtọ ṣú nyin? Bi ẹnyin ko ba si ti jẹ olõtọ li ohun ti iṣe ti ẹlomiran, tani yio fun nyin li ohun ti iṣe ti ẹnyin tikara nyin? “ (Lúùkù 16:10-12)

Pẹlu nkan ti a ri nibiyi, Ọlọrun a ma a kọbiara si iha ti a ba kọ si amojuto awọn nkan kinkinkin. Ki ni idi? O jẹ ọkan lara awọn nkan ti yoo fi han boya a o jẹ olotitọ ati ẹni ti o wulo ni ṣiṣe amujuto nkan ti o pọ tabi bẹẹkọ. Nitorina, ti Ọlọrun ko ba ma a gbe ọ ga tabi busi fun ọ pẹlu awọn nkan rere, o le jẹ wipe o ko ki i ṣe olotitọ ninu awọn nkan kinkinkin.

Lafikun, a tun ri ninu ẹsẹ bibeli yi pe Ọlọrun a ma a kọbiara si iha ti a ba kọ si amojuto awọn nkan ti aye yi. Ki ni idi? Eyi jẹ ọkan lara awọn ọna ti O fi le e sọ boya a le ṣe amojuto nkan ti ẹmi daradara tabi bẹẹkọ. Idi si ni yi ti ko ki i fi fa awọn otitọ ati iṣẹ ẹmi le awọn ti o ti fi ara wọn han gẹgẹ bi ọlẹ tabi alaiṣododo ni ṣiṣe amojuto nkan ti aye yi. Wọn yoo jẹ ki akude tabi idibajẹ ba iṣẹ rẹ.

Ni ipari, lati inu awọn ẹsẹ bibeli naa, a ri wipe Ọlọrun ma n kọbiara si bi a ti ṣe n ṣe amojuto awọn dukia tabi iṣẹ awọn miran. Ti a ba mojuto nkan ti awọn miran daradara, a n fi ara wa han gẹgẹ bi ẹni ti o ṣetan lati gba awọn nkan rere ti O ni ni ipamọ fun wa. Ṣugbọn ti a ko ba mojuto nkan ti awọn miran dadarada, nṣe ni a o ma fi ara wa han bi ẹni ti ko ṣetan lati tẹwọgba awọn nkan rere ti O ni ni ipamọ fun wa. Eyi wa jasi pe ọkan lara awọn ọna ti Ọlọrun ma n gba dan wa wo lati mọ boya a ṣetan lati ri nkan gba si lọwọ rẹ tabi lati ri igbega gba lọwọ rẹ ni nipa wiwo bi a ti ṣe n ṣe amojuto nkan awọn miran. Ti iwo ko ba wa ma mojuto iṣẹ tabi nkan ti awọn miran ti n fi fun ọ daradara, nṣe ni ki o mọ wipe o ti n di igbega ati iṣoriire ara rẹ lọwọ.

Ni kukuru, koko ọrọ mi ninu gbogbo eyi ni pe Ọlọrun ma n ka bi a ti ṣe jẹ olododo si ni ṣiṣe amojuto awọn nkan kekeke ati awọn nkan ti aye yi si ni pataki gidigidi. Ti o ba wa fẹ ki O gbe ọ ga, ki O si tun busi fun ọ gidigidi, nṣe ni ki o bẹrẹ si ni fi otitọ ati ifarabalẹ han lori bi o ti ṣe n mojuto ohunkohun ti a ba ko le ọ lọwọ. Ranti Josefu. Ranti pe Ọlọrun ko ṣa dede gbe e ga lati di alamojuto ilẹ Ijibiti lalai kọkọ dan isododo rẹ wo gẹgẹ bi ọmọ ninu ile baba rẹ, gẹgẹ bi ẹru ni ile Potifari ati gẹgẹ bi ẹlẹwọn ni ilẹ Ijibiti.

Nitorina, bi o ti wu ki ipo ti o wa kere tabi buru to, fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti awọn eniyan ati Ọlọrun le fọkantan. Ti o ba si ni suuru, ko ni pẹ ti iwọ yoo fi ri ogo Ọlọrun fun igbega ati iṣoriire rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Jẹ́ olóòótọ́ ní ohun kí Kínní | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 22, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 47 Read More »

Má fi irẹwẹsi sọkan wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 08, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 45

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹ́nà 2026. Adura mi ni pe ki Ọlọrun mu ki ọsẹ naa dara jọjọ fun iwọ ati idile rẹ. Amin.

Bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati jẹ ẹnikan ti yoo ma fun awọn eniyan Ọlọrun ti o wa ni ayika rẹ ni iwuri lati ṣe ifẹ rẹ nipa ọrọ ati iṣe rẹ. Wo o, nkan ti awọn eniyan kan nilo lati fi ara wọn jin lẹkunrẹrẹ fun ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ko ju ọrọ iwuri lati ẹnu ẹnikan lọ. Bẹẹ si ni, nkan ti awọn elomiran nilo lati wa awawi lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun ko ju ẹnikan ti yoo ko irẹwẹsi ba wọn, yala nipa ọrọ tabi iṣe rẹ. Ti o ba wa fi aaye gba eṣu lati lo ọ lati ko irẹwẹsi si ba ẹnikẹni lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun, mo daju pe Ọlọrun yoo ba ọ wi ni ibamu pẹlu nkan ti o ṣe.

Fun apẹrẹ, nigba ti o ku diẹ ki awọn ọmọ Isiraẹli wọ Ilẹ Ileri, lẹyin igba ti wọn ti ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun, awọn ara Rubẹni ati awọn ara Gaadi wa sọdọ Mose pẹlu ẹbẹ kan. Oun naa si ni pe ki o gba wọn laaye lati ma sọda odo Jọdani si ilẹ awọn ara Kenani. Ki ni idi? Idi ni pe ibi ti o wa ṣaaju Jọdani dara pupọ fun awọn nkan ọsin. Awọn si wa ni agbo aguntan ati maalu ti o pọ. (Wo: Númérì 32:1-5)

Iha wo wa ni Mose kọ si ẹbẹ wọn? Wo nkan ti a kọ lori eyi ninu bibeli:

“Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi? Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn? Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na.” (Númérì 32:6-8)

Njẹ o ri bayẹn? Mose sọ fun awọn eniyan wọnyi pe nkan ti wọn ṣe jẹ nkan ti yoo ko irẹwẹsi si ba ọkan awọn ọmọ Isiraẹli yoku lati ma ṣe ifẹ Ọlọrun nipa sisọda Jọdani lati gba Ilẹ Ileri. O tilẹ fi asiko yi ran wọn leti pe idi ti gbogbo wọn ṣe ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun ni pe awọn obi wọn ko irẹwẹsi ba ara wọn lati ma gba Ilẹ Ileri naa. Awọn ara Rubẹni ati awọn ara Gaadi yi wa nilo lati fi da Mose loju pe awọn yoo kọkọ sọda Jọdani lati ran awọn ọmọ Isiraẹli yoku lọwọ lati gba Ilẹ Ileri ki awọn to pada wa do si ilẹ ti ara wọn ki o to di pe o tẹwọgba ẹbẹ wọn.

Ki ni eyi n kọ wa? Oun naa ni pe Ọlọrun ko ki i fi oju rere wo ẹnikẹni ti o ba n fi irẹwẹsi si ọkan awọn miran lati ma ṣe ifẹ rẹ. Dipo bẹẹ, nṣe ni O ma n ṣe idajọ wọn. Niwọn igba ti a ko wa le sọ ọna ti yoo gba ṣe idajọ wa ti a ba lọ ko irẹwẹsi ba ẹnikẹni lati ma ṣe ifẹ rẹ, a ni lati kiyesara lati ma jẹ idi ti ẹnikẹni ko fi ni ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ tabi jẹ igbadun ipese rẹ fun aye wọn nipa ohun ti a n sọ tabi ṣe. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun ma a fi igba gbogbo ran wa lọwọ lati wuwa ni ibamu plẹu awọn nkan wọnyi. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2026, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má fi irẹwẹsi sọkan wọn | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Ẹrẹ́nà 08, 2026 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 45 Read More »