Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọjọ ti o pari oṣu kọkanla ọdun yi. Adura mi si ni pe ki oṣu tuntun ti a fẹ wọ inu rẹ ninu ọsẹ naa dun fun wa ni gbogbo ọna, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati ma a fi igba gbogbo ṣọ́ bi o ti ṣe n ṣe si ẹnikẹni ti o ba ti fi ara rẹ jin fun iṣẹ iranṣẹ ninu ijọba Ọlọrun, ki o ma ba mu wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Ṣe a le mu ki awọn eniyan pa iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun wọn ti lotitọ? Bẹẹni, a le e ṣe bẹẹ. Ko si ki i wa ṣe awọn ti o jẹ ọmọ ijọ nikan ni o le mu ki awọn iranṣẹ Ọlọrun pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti; awọn adari ijọ bi ti wọn naa le mu ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti.
Fun apẹrẹ, nigba ti a gbe pasitọ tuntun wa si inu ijọ ti mo n lọ ni igba kan, nkan akọkọ ti o ṣe ni pe o din owo ti a n san fun awọn ti o n ṣiṣẹ inu ile-iṣẹ inu ijọ yi ku. Ki ni idi? Idi ti o sọ wipe oun ṣe ṣe bẹ ni pe wọn ko ṣe iṣẹ to lati gba irufẹ owo ti pasitọ ti tẹlẹ n ṣan fun wọn. Ṣugbọn owo ti pasitọ ti tẹlẹ n ṣan fun wọn gan ko to iye ti a n san fun awọn akẹgbẹ wọn nita. Idi ti o si ṣe n san iye ti o n san fun wọn ni pe ko fẹ ki wọn fi igba kankan bẹrẹ si ni ro wipe idi ti awọn ko fi le tọju ara wọn ati awọn ẹbi wọn lọna ti o peye ni pe awọn n ṣiṣẹ fun Ọlọrun.
Amọ nṣe ni pasitọ tuntun yi kan ba gbogbo nkan jẹ. Nitorina, ko pẹ rara ti ọpọ ninu awọn oṣiṣẹ inu ile-iṣẹ ijọ yi bẹrẹ si ni kuro. Ṣe wọn wa n kuro nitoripe wọn ko fẹ Ọlọrun ni tabi nitoripe wọn ko fẹ sin in? Rara O! Idi ti wọn ṣe wa ṣiṣẹ ninu ile-iṣẹ ijọ yi ti wọn ko lọ bẹrẹ okowo ti ara wọn tabi ki wọn lọ sisẹ ni awọn ile-iṣẹ miran ni pe wọn fẹran Ọlọrun, wọn si fẹ sin in. Ṣugbọn nigba ti wọn ri wipe pasitọ wọn ko bikita rara nipa igbaye-gbadun wọn, wọn bẹrẹ si ni kuro. O si wa san bi wọn ti ṣe kuro yi ju ki wọn duro, ki wọn si ma kun sinu lọ.
Ki a ma fọrọgun, nitoripe wọn kuro ni ọna yi, ipalara bẹrẹ si ni ba awọn iṣẹ ti wọn n ṣe. Yatọ si eyi, ko si iwuri fun awọn miran ti wọn ri bi a ti ṣe ṣe si wọn lati wa ṣiṣẹ ni ile-iṣẹ ijọ yi. Idi si ni pe awọn naa ko fẹ ni irufẹ iriri kan naa. Ṣugbọn tani o jẹ ki awọn eniyan wọnyi pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti? Adari ijọ wọn ni! Ọlọrun nikan ni o wa mọ iye awọn ti awọn adari ijọ wọn ti jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti lọna kanna.
Nitorina, ko ki i ṣe kiki awọn ọmọ ijọ nikan ni o le mu ki awọn iranṣẹ Ọlọrun pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti; awọn adari ijọ naa le mu ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Ibi ti eyi ba si ti waye, o di dandan ki ipalara ba awọn nkan kan ti Ọlọrun fẹ ṣe ninu aye awọn eniyan fun saa kan. Bẹẹni, ipalara yoo ba awọn nkan wọnyi titi yoo fi ri awọn iransẹ tuntun miran ti yoo fun ni iwuri lati bẹrẹ si ni ṣe wọn.
Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni asiko Nehemaya, iparala bẹrẹ si ni ba iṣẹ Ọlọrun lasiko kan nitoripe awọn Juu ati awọn adari wọn jẹ ki awọn ọmọ Lefi ti o n ṣiṣẹ ninu tẹmpili pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Lọna wo? Iwọ naa wo nkan ti Nehemaya sọ lori eyi ninu bibeli:
“Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn. Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.” (Nehemáyà 13:10-12)
Ṣe o ri bayẹn? Nitoripe awọn eniyan wọnyi kọ lati mojuto awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin ti wọn n ṣiṣẹ ninu tẹmpili Ọlọrun, wọn fi iṣẹ Ọlọrun silẹ, wọn si pada lọ si oko wọn ati si idi okowo wọn. Ta wa ni o lero pe eyi ni lati pa lara ju? Awọn eniyan naa ni! Awọn ni ko ni ni iriri Ibukun ti o sorọ mọ iṣẹ iranṣẹ awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin yẹn bi o ti ṣe yẹ. Ti Nehemaya ko ba wa tete da si ọrọ naa ni, Ọlọrun nikan ni O mọ bi nkan ti wọn n ṣe yi ko ba ṣe pa iṣoriire, alaafia ati ilera orilẹ-ede wọn lapapọ lara si.
Wayi o, ko ki i wa ṣe kiki ki a ma fi owo wa ran awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o wa ni aarin wa lọwọ to nikan ni o le jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. A tun le jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti nipa sisọ awọn ọrọ kobakungbe si wọn, nipa pipa irọ mọ wọn tabi nipa didi ọtẹ mọ wọn. Nigba ti a ba si ṣe eyi, a le mọ daju pe yoo pa iṣẹ ti Ọlọrun fẹ tipasẹ wọn ṣe ninu aye wa ati ninu aye awọn miran lara. Ṣe Ọlọrun yoo wa gboriyin fun wa fun eyi bi? Rara o! Dipo eyi, nṣe ni yoo fẹrẹ fi iya jẹ wa. Eyi ko si ni suwọn rara.
Nitorina, ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo finni-finni, ki a si ri daju pe a ko ma ṣe ohunkohun lati mu ki iranṣẹ Ọlọrun kankan pa iṣẹ iranṣẹ rẹ ti. Njẹ ki Ọlọrun fun wa ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi ki o to pẹ ju. Amin.
Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinin.
Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)