Ó ní láti ṣe ǹkankan tí ó yàtọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 27

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia pọ si fun ọ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu kọkanla ọdun yi, iyẹn oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri awọn igbesẹ ti o tọ fun ọ lati gbe ki o ba a le ṣe amulo wiwa rẹ ninu aye rẹ fun aluyọ rẹ ni ibi yowu ti a ti n di ọ lọwọ laye. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin iku Usa, ọkunrin naa ti Ọlọrun lupa nitori ti o fọwọkan Apoti Ẹri, Dafidi pinnu lati gbe Apoti naa lọ si ile ọkunrin kan ti a n pe ni Obedi-Edomu. Idi si ni pe ẹru nkan ti o le ṣẹlẹ si awọn ara ile rẹ, ti a ba gbe Apoti naa wa si ọdọ wọn, ba a. Nitorina, ko ki i ṣe nitori inu-ire ni a fi gbe Apoti naa wa si ile Obedi. Dipo bẹẹ, nitoripe Dafidi ati awọn eniyan rẹ ri ṣiṣe eyi gẹgẹ bi ọna lati bọ lọwọ ibinu Ọlọrun ni. (Wo: 2Sámúẹ́lì 6:1-10)

Amọ ṣa o, si iyalẹnu wọn, lẹyin igba ti Apoti naa ti wa ni ọdọ Obedi-Edomu fun oṣu mẹta, iroyin tọ Dafidi wa pe Oluwa ti bukun fun ile ọkunrin naa ati ohun gbogbo ti o ni nitori Apoti rẹ ti o wa pẹlu rẹ. Wayi o, irufẹ iroyin bayi ko ṣa le dede tan kalẹ ti ko ba jẹ wipe iṣoriire Obedi-Edomu jẹ agbaayanu. Ṣugbọn iṣoriire rẹ yi jẹ agbaayanu, nitoripe o yara, o si pọ lọpọ-lọpọ, eyi ti o gba oṣu mẹta pere fun gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ lati mọ pe o ti fi ipo eniyan lasan silẹ lati di ọlọrọ. (Wo: 2Sámúẹ́lì 6:11-15)

Nitorina, Dafidi ko fi asiko ṣofo rara lati lọ gbe Apoti naa kuro ni ile Obedi-Edomi wa si ile oun tikararẹ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a le ma le sọ wipe eyi ko dara, a ko ri akọsilẹ rẹ ninu bibeli pe oun naa ni iriri irufẹ iṣoriire ti Obedi-Edomu ni, lẹyin igba ti o gbe Apoti Oluwa wa si ile rẹ. Ki ni idi? A ko fun wa ni esi kankan si eyi ninu bibeli.

Lafikun, a ko ni akosilẹ rẹ ninu bibeli pe Abinadabu, ọkunrin ti Apoti naa wa ni ile rẹ ki a to gbe lọ si ile Obedi-Edomu, ni iriri irufẹ iṣoriire ti Obedi-Edomu ni, bi o tilẹ jẹ wipe Apoti naa wa ni ile rẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Dipo eyi, nṣe ni o tun padanu ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ, Usa, nitori Apoti naa. O ma ṣe o! (Wo: 1Sámúẹ́lì 7:1-2; 2Sámúẹ́lì 6:3)

Ki wa ni o fa ti ọrọ ti Obedi-Edomu ṣe yatọ? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, a ko fun wa ni idi kankan pato ninu bibeli. Ṣugbọn ọkunrin yi ni lati ṣe nkankan yatọ. Bẹẹni, o ni lati ṣe nkankan ti awọn yoku, pẹlupẹlu awọn alufa, ko ṣe ni mimojuto Apoti yii. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe ọmọ Isiraẹli nipa ibi, o ni irufẹ iriri iṣoriire ati ojurere lati ọdọ Ọlọrun ti awọn miran ko ni.

Njẹ ki wa ni o ṣe yatọ? A ko le mọ titi igba ti a o fi duro ni iwaju itẹ Ọlọrun. Ṣugbọn o damiloju pe ohun yowu ti o ṣe tọ ọ wa nipasẹ ifihan lati ọdọ Ọlọrun ni. Nigba ti o si ṣe, o fun ni gbogbo iyatọ aye yi.

Nibakanna, ti Ọlọrun ba le fi sinu ọkan wa awọn ifihan ohun ti a nilo lati ṣe lati ni iriri aluyọ ti o lagbara ni ibikibi ti a ti nilo rẹ ninu aye wa, nkan ti yoo tẹle yoo ya ati awa ati awọn ti o wa ni ayika wa lẹnu, ti a ba ṣiṣẹ le lori. Ki a tilẹ sọ otitọ, eyi yoo fun wa ni ẹri ti ko wọpọ jẹ. Nitorina, dipo ti a o fi ma gbiyanju lati ṣe awọn nkan ti awọn miran n ṣe, bi o ti wu ki o dara to, nṣe ni ki a kọ lati ma gbadura si Ọlọrun lati fun wa ni awọn ifihan nkan ti o yẹ ki a ṣe ni pato lati le tayọ ati lati le ṣoriire bi o ti tọ laye yi. Idi si ni pe nkan ti o ṣiṣẹ fun awọn miran le ma ṣiṣẹ fun wa. Njẹ ki a gba ojurere lati gba irufẹ awọn ifihan wọnyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ibukun.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *