Ikú tó farasin | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 03, 2022 | Vol. 11, No. 9
Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ lailodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu Agẹmọ 2022. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun, ninu aanu rẹ, ma fi gbogbo igba pa iwọ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ mọ kuro ninu gbogbo ewu pakute Eṣu ti o farasin. Amin.
Bi akọsilẹ bibeli ti ṣe lọ, igba meji ọtọọtọ ni ọba Isiraẹli, Sọọlu, ba Dafidi sọrọ lori ki o fi ọmọ rẹ ṣaya. Igba akọkọ, Merabu, ọmọbinrin rẹ agba, ni o kọkọ fi lọ ọ. Ṣugbọn ọdọmọkurin yi kọ jalẹ. O sọ fun pe awọn eniyan oun ko lowo tabi ni iyi to lati jẹ àna ọba. Nitorina, Sọọlu jami lẹnu ọrọ naa, o si fi ọmọ rẹ fun elomiran. (Wo: 1Sámúẹ́lì 18:17-19)
Lẹyin igba ti o ṣe diẹ si, ẹwẹ, awọn iranṣẹ Ṣọọlu tun sọ fun pe ọmọbirin rẹ kekere, iyẹn Mikali, ti yo ifẹ fun Dafidi. Nitorina, lẹsẹkẹsẹ ni o sọ fun wọn pe ki wọn ba Dafidi sọrọ lẹkan si pe anfaani miran tun ti ṣi ṣilẹ fun lati di àna ọba ati wipe nkan kanṣoṣo ti o nilo lati ṣe ni ki o mu ọgọ́rùn-ùn nkan ọmọkunrin awọn ara Filisitini wa – loba pari. Eyi wa tunmọ si pe Dafidi kọkọ gbọdọ pa ọgọ́rùn-ún ọmọkọrun Filisitini ki o to le ri nkan ọmọkunrin wọn. (Wo: 1Samuẹli 18:20-25)
Ki gan wa lo fa ti Sọọlu ṣe taku lori fifi ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ fun Dafidi gẹgẹ bi aya? Ṣe oun nikan ni ọkunrun ti o dangajia to lati fẹ awọn ọmọ rẹ ni? Rara! Abi ṣe inu rẹ lo dun to bẹẹ si Dafidi ti o fi fẹ ki o jẹ àna rẹ ni dandan? Rara! Bibeli jẹ ki o ye wa pe Ṣọọlu n jowu Dafidi ni akoko yi nitori aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi jagunjagun ati nitori iyi ti o ni laarin awọn eniyan. Nitorina, ko ki i ṣe nitoripe inu rẹ dun si lati ni gẹgẹ bi àna ni o ṣe fẹ ki o fẹ ọkan lara awọn ọmọbinrin rẹ; dipo eyi, nitoripe o fẹ lo ọrọ igbeyawo naa gẹgẹ bi pakute iku fun un ni. Ti ko ba wa jẹ pe Ọlọrun wa pẹlu rẹ, nṣe ni ko ba di oku nibi ti o ti n ṣe akitiyan lati di ana ọ̀ba. (Wo: 1Sámúẹ́lì 18:29-27)
Ki wa ni koko ọrọ yi? Oun naa ni pe awọn igba ma n wa ti ojurere awọn eniyan kan si wa tabi ti awọn nkan ti wọn n tọrọ lọwọ wa le jẹ oògùn iku, iparun tabi ẹsin ti a fi ewe ṣúgà pọn. Ti Ọlọrun ko ba si ṣi wa ni oju lati ri nkan ti awọn eniyan wọnyi n gbero lati ṣe si wa, ki O si fi ọna abayọ han wa, o ṣeeṣe ki a lugbadi ete ibi wọn. Nitorina, a ko gbọdọ fi igba kankan lero pe a o wa ni ipamọ nitori pe iwa wa dara si awọn ti o wa ni ayika wa, nitoripe a wa ni mimọ niwaju Ọlọrun tabi nitoripe a ma n fi gbogbo igba ṣọraṣe ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn elomiran. Dipo eyi, nṣe ni ki a ma fi gbogbo igba fa ara wa le Ọlọrun lọwọ fun ipamọ. Nitoripe ti Oun ko ba pa wa mọ, a ko le wa ni ipamọ, bi o ti wu ki a ni ifura to tabi bi awọn igbesẹ wa lati wa ni ipamọ ṣe le munadoko to (Saamu 127:1).
Ranti Ùráyà, ọkan lara awọn jagunjagun Dafidi. Ranti pe oun funrarẹ ni o mu lẹta idajọ iku rẹ lọ sọdọ awọn ti o ṣeto iku rẹ. Bẹẹ si ni ko mọ nkankan titi o fi parun. Bawo ni ko ba tilẹ ṣe mọ pe ọba ti o fi ọkan tan, ti o si ṣetan lati ku fun ni ọjọkọjọ ati ni akokokakoko le fi idajọ iku pamọ sinu lẹta ti o gbe le e lọwọ? Tabi ba wo ni o ṣe fẹ mọ pe gbogbo ojurere ati aanu ti ọba n fi han fun ni awọn wakati ikẹyin rẹ laye jẹ ete lasanlasan lati jẹ ki o gba ọmọ-àlè gẹgẹ bi ọmọ? Ko si bi o ṣe fẹ mọ awọn nkan wọnyi ti o ko ba ṣe pe a ba fun ni iṣipaya wọn. Nitorina, o ṣegbe nitoripe ko ni iṣipaya awọn nkan ti o le jẹ ki o gbaradi, ki o si bọ ninu iku ti o n bọ wa mu lọ. (Wo: 2Sámúẹ́lì 11)
Eyi jẹ ki o ye wa pe awọn eniyan daradara, awọn olootọ eniyan ati awọn olododo eniyan le lugbadi iwa ika awọn eniyan, pẹlupẹlu awọn ti wọn fi ọkan tan, ti Ọlọrun ko ba ṣaanu fun wọn, ki O si tun daabo bo wọn. Nitorina, mo n sọ fun ẹ lẹẹkan si pé kí o kọ́ lati ma fi gbogbo igba fa ara rẹ ati ohun gbogbo ti o jẹ tirẹ le Ọlọrun lọwọ fun ipamọ dipo ki o gbójúlé didara tabi jijafafa rẹ. Adura mi si ni pe ki Oun, ninu ẹkunrẹrẹ aanu rẹ, ma fi gbogbo igba fi gbogbo pakute ọta ti o farasin han ọ, ki O si tun ma ko ẹṣẹ rẹ yọ kuro ninu wọn. Amin.
Ki o ni oṣu Agẹmọ ti o ga.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Ikú tó farasin | Pst. J.O. Lawal | Agẹmọ 03, 2022 | Vol. 11, No. 9 Read More »
