AKỌSORI: “Ma ṣe feti si ọrọ tabi itan asan; ṣugbọn tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun.” (Efesu 4:11)
ỌRỌ AKỌSỌ
Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igba ikẹyin yoo jẹ igba ewu fun ọpọlọpọ eniyan, paapaa julọ fun awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun (2Timoti 3:1-5). Ewu ti a si n sọrọ nipa yi kọja ewu ijamba ọkọ tabi ti ajakalẹarun tabi ti akitiyan awọn ika ati ọdaju eniyan; o tun ni i ṣe pẹlu ewu ọkan eniyan. Ewu ọkan eniyan yi si ni olori gbogbo ewu ti o wa laye. Ẹni ti o ba wa bori oniruuru ewu yowu ti o le wa laye ti ko si bori ewu ọkan rẹ ko bori nkankan rara. Amọ ẹni ti o ba ti bori ewu ọkan rẹ ti kogo ja. Ọna wo wa ni a le gba, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, lati bori gbogbo nkan ti o le ṣe ijamba fun ọkan wa? Ọna naa ni ki a tọ ara wa ni iwa-bi-Ọlọrun.
TỌ ARA RẸ SI IWA-BI-ỌLỌRUN
Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si Timoti sọ eyi fun un: “Ma ṣe feti si ọrọ tabi itan asan; ṣugbọn tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun. Nitori ere-idaraya ti ara ni ere diẹ, ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun ni ere fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aye isinsinyi ati ti eyi ti n bọ. Otitọ ni ọrọ naa, o si yẹ fun itẹwọgba gbogbo eniyan. Nitori fun eyi ni awa n ṣe laalaa ti a si n jijakkadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alaaye, ẹni ti i ṣe Olugbala gbogbo eniyan, paapaa julọ awọn ti o gbagbọ. Nkan wọnyi ni ki o maa palaṣẹ ki o si maa kọ awọn eniyan.” (1Timoti 4:7-11)
Ki ni koko aṣẹ ti Pọọlu pa fun Timoti ninu abala lẹta rẹ yi si? Oun naa ni pe ki o tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun. Akọkọ naa, o kọkọ sọ fun pe ki o ma ṣe fi akoko rẹ ṣofo lori awọn nkan ti ko ni ran igbe aye iwa-bi-Ọlọrun rẹ lọwọ. Awa naa si gbọdọ di eyi mu ṣinṣin. Oniruuru nkan lo wa laye yi ti ko le ran igbe aye igbagbọ wa lọwọ. Oniruuru sinima, eto, ẹkọ ati bẹẹbẹẹ lọ lo wa ti ko le ran igbagbọ wa lọwọ rara. Yoo si dara pupọ ti a ba le mọ awọn nkan wọnyi ki a si yẹra fun wọn. Aijẹbẹ, ṣa dede ni a o ri pe aiwa-bi-Ọlọrun bẹrẹ si ni jẹyọ ninu aye wa, bi o tilẹ jẹ pe ọmọ rẹ ni a jẹ. (Wo: 2Tim 2:16)
Ki wa ni idi ti Timoti fi nilo lati tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun? Pataki lara awọn idi naa ni yi:
- Ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣẹ bẹ: Idi akọkọ ti Pọọlu fi paṣẹ fun Timoti lati tọ ara rẹ bi a ti ṣe e wa bi Ọlọrun ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe bẹ. Ti ko ba ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe bẹ ẹ, a jẹ wipe ifakoko ati ifagbara ṣofo lasan ni ṣiṣe bẹẹ ko ba ja si fun. Ṣugbọn ifẹ Ọlọrun ni fun gbogbo ọmọ rẹ lati ma gbe igbe aye ẹni ti o dabi rẹ. Idi ti O filẹ fi da wa ni ki a ba le ma gbe igbe aye ẹni ti o dabi rẹ. Ilodi si igbe aye yi ni o si fa ti idajọ rẹ fi n bọ lori awọn ọmọ alaigbọran. (Wo: Efesu 5:3-7; 1Tẹsalonika 4:3-8;1Peteru 1:15-16)
- O ni amuyẹ lati tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun: Ọtọ ni ki a paṣẹ fun eniyan lati ṣe nkan tabi ki a gba a niyanju lati ṣe nkan; ọtọ si tun ni ki o ni amuyẹ lati ṣe e. Ko si bi a ti ṣe pariwo mọ eniyan to tabi gba a niyanju to lati ṣe nkan, ti ko ba ni amuyẹ lati ṣe, asan ati ofo ni gbogbo ariwo, iyanju tabi ikilọ wa si yoo ja si. Nibakanna, ti Timoti ko ba ni amuyẹ lati gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun, aṣẹ ti Pọọlu pa fun lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ko ni ni itumọ rara. Nitorina, idi ti Pọọlu fi sọ fun ọkunrin yi lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ni pe o ni amuyẹ lati ṣe bẹ. Ẹnikẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun ni amuyẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Wo nkan ti Peteru sọ fun wa lori eyi: “Gẹgẹ bi agbara Ọlọrun ti fun wa ni ohun gbogbo ti i ṣe ti iye ati iwa-bi-Ọlọrun, nipa imọ ẹni ti o pe wa nipa ogo ati ọla nla rẹ. Nipa eyi ti o ti fi awọn ileri rẹ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹyin ki o le di alabaapin ninu iwa bi Ọlọrun, nigba ti ẹyin ba ti yọ kuro ninu ibajẹ ti n bẹ ninu aye nipa ifẹkufẹẹ.” (2Peteru 1:3-4) Njẹ o ri bayi pe gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ti fun ni ohun gbogbo ti a nilo lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe inu aye ibajẹ ati irukerudo ni a n gbe. Ti a ko ba wa gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun, ko ni jẹ nitori pe a ko le ṣe bẹ ẹ; dipo eyi, yoo jẹ nitoripe a jẹ ope niti ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye yi tabi nitoripe a kọ lati ṣe amulo ipese rẹ fun wa. (Wo: Titu 2:11-12)
- Iwa bi Ọlọrun ko ki i ṣa dede waye: Otitọ ni pe gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ti ṣe yẹ ninu ọkan wa nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Amọ ṣa o, iwa-bi-Ọlọrun ko ki i kan dede waye. Eniyan gbọdọ tọ ara rẹ lati wa bi Ọlọrun ni. Idi si ni pe aye ti a wa jẹ aye ti oniruuru nkan wa ti ko ni jẹ ka fẹ gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Ifẹ owo, ifẹ ipo, ifẹ iyi, ifẹkufẹ ti ara ati bẹẹbẹẹ lọ ni o kun inu aye yi, ti ko si ni fẹ ki a gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe. Yatọ si eyi, ọpọ igba ni ẹran ara wa gan yo fẹ tako iwa-bi-Ọlọrun nitori ifẹkufẹ rẹ. Ti a ko ba wa fi eleyi sọkan, ki a si bẹrẹ si ni kọ ara wa lati yago fun ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu aiwa-bi-Ọlọrun ati lati tẹramọ awọn nkan ti yoo mu ki a gberu si ni gbigbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, ko si bi a o ṣe ma gbe igbe aye yi lojoojumọ. Idi si niyi ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe ki o tọ ara rẹ lati ma gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Ko kan ni dede waye funrarẹ o. Eyi ko ki i ṣe ọrọ pe ti Ọlọrun ba fẹ ki n gbe igbe aye to wu u, yoo mọ bi yoo ṣe mu mi lati ṣe bẹ. Ọlọrun ti ṣe ohun gbogbo ti O nilo lati ṣe ki a ba le gbe igbe aye ti o wu u. Ọwọ wa lo wa ku si lati pinnu bi Daniẹli lati gbe igbe aye naa ti O fẹ fun wa ati lati tọ ara wa lati ma gbe awọn igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu aye naa. Ranti pe, ko si bi eniyan, fun apẹẹrẹ, ti ṣe ni ọpọlọ lati mọ iṣiro to, ti ko ba fi ara rẹ jin lati kọ ati lati ṣe aṣaro ninu awọn ofin ti o sorọ mọ iṣiro, ko ni mọ nkankan nipa iṣiro – yoo kan ṣa ma gbodo ni kilasi ni. Bẹẹ gẹgẹ naa ni o ti ṣe ri pẹlu Kirisitẹni ti ko ni ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun. Yoo kan ṣa ma kọsẹ ninu idibajẹ ni. (Wo: Galatia 5:16-17; 1Johanu 2:15-17)
- Iwa bi Ọlọrun ni ere fun ohun gbogbo: Idi miran gbogi ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ni pe o ni ere lori fun ohun gbogbo ninu aye yi ati ninu ijọba Ọlọrun ayeraye ti o n bọ. Eyi tunmọ si pe fun anfaani Timoti ni Pọọlu ṣe sọ nkan yi fun un. Fun anfaani ọmọ Ọlọrun kọọkan naa si ni awa naa ṣe gba aṣẹ kanna lati ọwọ rẹ pe ki a tọ ara wa ni iwa-bi-Ọlọrun. Ti a ba wa ni ki a bẹrẹ si ni sọrọ lori ere iwa-bi-Ọlọrun, o di dandan ki ilẹ kun. Ṣugbọn, ti awa naa ba wo ayika wa, awọn wo ni o ni ibalẹ-ọkan ju ninu aye yi? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni! Awọn wo ni ile wọn n roju, ti ọna wọn n roju julọ? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni! Awọn wo ni ko nilo lati bẹru awọn aisan ti o n ti ara iṣekuṣe wa tabi bẹru pe ki awọn agbofinro ma wa ka awọn mọle nitori ipasipayọ owo ilu tabi idigunjale? Awọn ni ko nilo lati yọnu lori boya awọn eniyan yoo gbẹri wọn jẹ tabi wọn ko ni gbẹri wọn jẹ? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni, nitori pe igbe aye wọn kun fun ẹri rere. Awọn si tun ni ko nilo lati bẹru nkan ti yoo kẹyin aye wọn, nitori ti wọn mọ pe dundun ni ọsan yoo so fun wọn ni ikẹyin aye wọn. Nitorina, ti o ba tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun, fun anfaani ara rẹ ni. Ti o ba tọ awọn ọmọ rẹ tabi awọn oṣiṣẹ rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun, fun anfaani ara rẹ ati anfaani ara wọn ni. Ṣugbọn ti o ba ro pe aṣẹ Ọlọrun yi si wa ko ni itunmọ, o di dandan ki o kabamọ rẹ lọjọ kan.
ỌRỌ IPARI
Akoko ti a wa yi jẹ akoko igbẹyin aye. Akoko igbẹyin aye si jẹ eyi ti o ku fun oniruuru idibajẹ ati iwa ika ti o le ṣe ijamba fun ọkan eniyan. Awọn ti o ba wa wa bi Ọlọrun nikan naa ni yoo yege ni akoko yi, ti idibajẹ aye yi ko si ni sọ aye wọn di radarada, ki o si tari wọn lọ sinu ọrun apadi. O wa yẹ ki gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun kun fun ọpẹ pe a ti fun wọn ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, lọkan, lero, niwa ati ni iṣe. Amọ ṣa o, ti wọn ko ba kọ lati ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun ti pese fun wa lati gbe igbe aye ti o wu u, asan ati ofo ni gbogbo ilakaka rẹ lori wọn yoo jasi. Eyi jasi pe idibajẹ aye yi yoo ṣe wọn leṣe, yoo si sọ wọn di alailere ọmọ. Adura mi wa ni pe iwọ ko ni di alailere ọmọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin. Amọ iwọ naa gbọdọ pinnu lati tọ ara rẹ lati wa bi Ọlọrun. Alaafia ni fun ọ.
IBERE
Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)