Ṣe o wulo abi o ko wulo?

J.O. Lawal | Ojo: Erẹna 21, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 46

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ si ọsẹ tuntun miran ninu oṣu Ẹrẹna 2021. Adura mi si ni pe ki a ṣe ọ yẹ pẹlu ohun rere gbogbo ti o nilo lati pọ si ni iwulo ni ọwọ Ọlọrun ati nibikibi ti o ba wa, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọkan lara ẹkọ ti itan Josefu kọ wa ni pe wiwa Ọlọrun ninu aye wa le jẹ ki a ma fi gbogbo igba pọ si ni iwulo, ti a ba le kọ lati ṣe amulo rẹ. Fun apẹẹrẹ, ni igba ti o wa ni ile Potifa gẹgẹ bi ẹru, Ọlọrun jẹ ki olowo rẹ fẹran rẹ, ki o si tun ṣi oju aanu wo. Ọna wo si ni Ọlọrun gba lati ṣe eyi? O ṣe eyi nipa mimu un pọ si ni iwulo. Ma ṣe gbagbe pe ẹru lasanlasan ni ninu ile ọkunrin na. Ọga yi ko si ra a nitoripe ko ni anito awọn ẹru ti o fẹ fi ifẹ han. Dipo eyi, o o ra ki o ba le bukun iyi ile rẹ ni. (Wo: Jẹnẹsisi 39:1-2)

Ti o ba wa jẹ pe Josefu ko ma ṣe awọn nkan ti yo mu ete ti olowo rẹ fi ra wa si imuṣẹ, ṣe ọkunrin na yoo fẹran rẹ bi o ṣe fẹran rẹ? Mi o ro bẹ. Nkan ti o ṣeeṣe ki o wa ye ni ki olowo rẹ bẹrẹ si ni ronu bi yo ṣe gba yọ kuro ni ile rẹ, ki o ba ye fi awọn nkan ini rẹ ṣofo. Ṣugbọn nitoripe o n bukun iyi ile Potifa, o n ṣe amojuto awọn nkan ini rẹ ati ohun gbogbo ti o n lọ ni ile rẹ daradara, o si tun n jẹ ki o ṣe orire si lojoojumọ, Potifa ko le ṣe alai ma fẹran rẹ ati alai ma jẹ ki o wa ni akata rẹ nigbogbo igba. Ni kukuru, o fa ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu idile rẹ le e lọwọ, ki oun naa ba le ri aye gbajumọ iṣẹ isin rẹ si Farao. (Wo: Jẹnẹsisi 39:3-7)

Ni bakanna, awọn adari ijọ, ile-iṣẹ nla, ile-iwe, ile-okowo ati idile paapa naa ma n fi gbogbo igba nilo awọn eniyan bi Josefu. Nkan ti mo n sọ ni pe gbogbo awọn wọnyi ni o nilo awọn eniyan ti wọn le fa awọn abala iṣẹ wọn kan le lọwọ, ki wọn ba le fi ẹdọ le ori oronro sun, pẹlu ifọkanbalẹ pe irufẹ awọn wọnyi yoo ṣe ju nkan wọn ti n reti lọ. Ibanujẹ ni o wa jẹ pe iru awọn wọnyi ṣọwọn gidigidi loni. Mo n sọ pe awọn eniyan ti o ma n lepa lati pọ si ni iwulo, ti wọn si tun ṣe fi ọkan tan nibikibi ti wọn ba wa ṣoro lati ba pade.

Ki wa gan ni o fa eyi? Akọkọ, idi kan gboogi ti o fa ni pe ọpọ ọmọ Ọlọrun ni ko ki i rin pẹlu afiyesi pe Ọlọrun n fi gbogbo igba wa pẹlu wọn. Ṣe o ri, ọmọ Ọlọrun kọọkan ni o ni amuyẹ lati jẹ eni ti o wulo lọpọlọpọ, ti o si tun ṣe gbe ara le nibikibi ti o ba ti ba ara rẹ. Ṣugbọn ti ko ba ma rin pẹlu afiyesi pe Ọlọrun wa pẹlu oun lati jẹ ki oun ri ojurere gba ati lati jẹ ki oun ṣe aṣeyọri ninu ohun gbogbo ti oun ba dawọle, o le ma fi ara rẹ jin lati ṣe awọn nkan ti yoo fi han gẹgẹ bi ẹni ti awọn eniyan le fa awọn akanṣe iṣẹ le lọwọ.

Idi keji ni pe ọpọ ọmọ Ọlọrun, bi mo ti sọ siwaju, ti o jẹ pe o yẹ ki wọn jẹ ẹni ti o wulo lọpọlọpọ, ti o si tun ṣe fi ọkan tan nibi ti wọn wa, ni ko fi aye gba ọrọ Ọlọrun lati fọ awọn iwa ati aṣa radarada ti o n di wọn lọwọ mọ kuro ninu aye wọn. Fun apẹẹrẹ, ninu lẹta Pọọlu si Titu, o sọ fun pe o nilo lati ba ọpọ ninu awọn ọmọ ijọ ti o n dari ni Kirete wi gidigidi nitori awọn asakasa kan ti wọn ni, awọn aṣa ti o n din iwulo ati pataki wọn ninu eto Ọlọrun fun wọn ku. Ki si ni awọn aṣa yi? Ara wọn ni orikunkun, irọ pipa, iwa ipanle, ọlẹ ṣiṣe ati iwa wọbia tabi ajẹranju. (Wo: Titu 1:10-13)

O wa ṣe ni laanu pe awọn nkan ti o farapẹ eyi ati awọn nkan ti o tilẹ tun buru ju eyi lọ lo tun n fa ifasẹyin fun ọpọ awa naa loni. A ri wipe iwa ọlẹ, agidi, aiṣootọ, igberaga, wọbia, aijafafa, afarawe awọn ti ko nikan ṣe ati bẹẹbẹẹ lọ n ṣọ wa di alaiwulo ni ọpọ ọna ni ibi ti a n gbe, ti a ti n ṣiṣẹ tabi ti a ti n kẹkọ ati papa ni ọpọlọpọ ijọ wa. Ni kukuru, awọn nkan wọnyi ni ọpọ igba lo n jẹ ki awọn ti Ọlọrun fẹ ẹ lo lati fa wa soke ri wa bi ẹni ti ko yẹ fun igbega tabi bi ẹni ti a ko le fun ni ojuṣe tabi ohun elo ti yoo jẹ ki ogo rẹ tan. Ti a ko ba si rẹ ara wa silẹ, ki a si bẹrẹ si ni mu ọrọ ibawi tabi atunṣe ti Ọlọrun n ran si wa lori awọn nkan wọnyi ni pataki, a le ma ri igbega kuro ninu ipo lasan ti a wa ni aye yi.

navigate to this website

Nitorina, bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, bẹrẹ si ni mojuto gbogbo awọn iwa ati aṣa aye rẹ ti ko bu iyi kun iṣẹ rẹ tabi aye awọn ti o wa ni ayika rẹ, dipo ti o o fi ma wa awawi fun wọn. Ki Ọlọrun si fi okun kun ọkan rẹ lati mu ọrọ yi ni ọkunkundun, ki o ba le ni iriri igbega rẹ ni aye rẹ. Amin.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *