Fi ara rẹ han be ẹni to ṣe gbẹkẹle

J.O. Lawal | Ojo: Erẹna 14, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 45

Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ẹrẹna 2021. Mo gbadura pe ki o gba okun lati ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati tayọ ninu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

learn more here

Wayi o, ọrọ iyanju mi si ọ bi a ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi ni pe ki o ma fi gbogbo igba fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun le gbọkanle lati mu iṣẹ rẹ tẹsiwaju. Jesu Oluwa wa, ni igbakan, pa owe kan fun awọn eniyan, O wi pe, “Ṣugbọn kin ni ẹyin n ro? ọkunrin kan wa ti o ni ọmọ ọkunrin meji; o tọ ekini wa, o si wi pe, ọmọ lọ ṣiṣẹ lonii ninu ọgba ajara mi. O si dahun wi pe, Emi ki yoo lọ: ṣugbọn o ronupiwada nigbẹyin, o si lọ. O si tọ ekeji wa, o si wi bẹẹ gẹgẹ. O si wi fun un pe, Ẹmi o lọ, baba: ko si lọ. Ninu awọn mejeeji, ewo ni o ṣe ifẹ baba rẹ?” (Matiu 21:28-31)

Kedere lo han pe owe yi jẹ eyi ti a sọ lati tẹ mọ wa leti bi o ṣe ṣe pataki to fun wa lati duro niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti o le fọkantan. Bi owe na ṣe lọ, ọmọkunrin akọkọ ti baba inu owe na sọ fun gbangba-gbangba pe oun ko ni lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara rẹ nigba ti o sọ pe ki o lọ. Idi wo ni o ṣe sọ eyi? A ko sọ fun wa. Ṣugbọn ko ṣetan lati jẹ bi baba rẹ ro pe oun o lọ ṣe nkan ti ko pinnu lati ṣe. Ṣe eyi wa tunmọ si pe o dara bi o ṣe kọ lati ṣe iṣẹ baba rẹ? Rara o. Amọ, bi ko tilẹ bojumu, nipa ṣiṣe oloootọ si i, o jẹ ki o le ronu ọna miran ti iṣe rẹ yoo fi jẹ ṣiṣe.

Ọna miran wo ni baba yi wa gba lati jẹ ki iṣẹ rẹ di ṣiṣe? Eyi ni i ṣe pẹlu riran ọmọkunrin rẹ keji lati ṣe iṣẹ na. Nigba ti o si ba ọmọ yi sọrọ, ni kiakia ni o dahun, ti o si sọ pe, “Bẹẹni sa, ma lọ.” Amọ ṣa o, ko lọ rara. Ki ni idi ti ko fi lọ? A ko sọ fun wa. Ṣugbọn koko ọrọ ṣa ni pe o kan fun baba rẹ ni ireti asan ni; ko ṣe ifẹ rẹ rara. Nitorina, o jẹ ẹnikan ti ko ṣe gbara le. Ni idakeji ẹwẹ, ọmọkunrin baba yi akọkọ, ti o ti sọ pe oun ko ni lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara rẹ, ronupiwada nigba ti o ya, o si lọ lati ṣe ifẹ baba rẹ. Nitorina, bi o tilẹ jẹ pe ni ibẹrẹpẹpẹ ko fi ara rẹ han bi ẹni ti baba rẹ le gbọkan le lati ṣe iṣẹ rẹ, oun lo wa fi ara rẹ han bi ẹni ti o ṣe e gbẹkẹle ni ikẹyinkẹyin.

Ni ọna kanna, Ọlọrun n wa awọn ti O le gbọkan le lati ṣe iṣẹ rẹ loni, yatọ si awọn afọnnu lasan. O n wa awọn ti ko ni pa iṣẹ rẹ lati gba awọn eniyan la, lati gbe awọn eniyan soke ati lati tun aye awọn eniyan to ti, fun idi kankan. Njẹ iru eniyan yi ni mo wa jẹ bi? Njẹ iru eniyan yi ni iwọ na jẹ bi? Abi afọnnu lasan ni wa?

Pọọlu sọ nipa ara rẹ pe, “Mo dupẹ lọwọ ẹni ti o fun mi ni agbara, ani Kirisiti Jesu Oluwa wa, nitori ti o ka mi si oloootọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ.” (1Timoti 1:12) Ṣe o ri bayi? Ọlọrun ri Pọọlu gẹgẹ bi ẹnikan ti Oun le fa ọrọ rẹ, ẹbun ẹmi rẹ ati aye awọn eniyan le lọwọ lai gba idojuti. O ri gẹgẹ bi ẹni ti Oun le gbọkanle lati wa ni ibi ti Oun ba fẹ ki o wa, ni igba ti Oun ba fẹ ki o wa nibẹ, ki o si tun ma ṣe ohunkohun ti Oun ba fẹ ki o ma ṣe nibe. Ṣe o wa ja a kulẹ tabi ko ja a kulẹ? Rara o, ko ja a kulẹ. Dipo eyi, nṣe ni o ri daju pe oun ko fi oore-ọfẹ rẹ ṣofo ati pe oun ko fi ohunkohun ti O fẹ ki oun ṣe silẹ lalai ma ṣe.

Awa na gbọdọ pinnu lọkan wa lati ma ja Ọlọrun kulẹ ṣugbọn lati fi ara wa han bi ẹni ti o le gbọkan le ninu ohun gbogbo ti O ba fun wa tabi ti O ba ni ki a ṣe. A gbọdọ pinnu lati ma ṣe pa iṣẹ rẹ ti fun idi kankan tabi lati ma ṣe ileri lati sin awọn eniyan rẹ ni ọna ti a ko ni lọkan lati sin wọn. Nipa ṣiṣe eyi, Oun yo le gbọkan le wa lati fun wa ni awọn ẹbun rẹ ati iṣẹ iranṣẹ rẹ si ati lati fun wa wi ere ti o pọ si (Luuku 16:10). Yatọ si eyi, nipa ṣiṣe bayi, a n tun fun awọn onigbagbọ ti o wa ni ayika wa ni okun ati imọkanle lati jẹ olotitọ si Ọlọrun bakanna.

Ka tilẹ sọ otitọ, ọkan pataki lara awọn idi ti ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun koṣe jẹ eni ti o ṣe darade loni ni pe wọn ko ni ọpọlọpọ apẹẹrẹ awọn ti o ṣe fọkanta ni ayika wọn. Awọn apẹẹrẹ ti wọn n ri ni ọpọ igba jẹ ti awọn fi oni ku, fi ọla dide tabi apẹẹrẹ awọn ti o n ṣi ẹbun Ọlọrun, awọn eniyan Ọlọrun ati awọn nkan ini ijọba Ọlọrun lo. Ti o ba si jẹ ọkan lara iru awọn eniyan yi, mọ pe o ko fun awọn ọmọ Ọlọrun ti iwuri tabi oriyin lati jẹ olotitọ ṣugbọn ẹni ti ko ṣe gbara le. Ko si si bi Ọlọrun yoo ṣe ri ọ bi alailẹṣẹ ninu bi o ṣe n pa awọn eniyan rẹ ati iṣẹ rẹ yowu ti o n ṣe lara. Nitorina, ji kuro ni ogbe ti o n to, ki o si bẹrẹ si ni fi ara rẹ han gẹgẹ bi olotitọ ninu iṣẹ iṣin rẹ si Ọlọrun. Njẹ ki o gba okun lati ṣe eyi titi de opin, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o jẹgbadun ọsẹ rẹ.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *