Idi ti o ṣe le padanu agbara iyanu | PaitoJ.O. Lawal
Ọjọ: Agẹmọ 25, 2021
Atẹlera: Latori tabili Paitọ
Nọmba: Vol. 10, No. 12
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Olugbala wa. Pẹlu idunnu ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o kẹyin oṣu Agẹmọ 2021. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki oju rẹ wa ni ṣiṣi lati le ma fi gbogbo igba ṣe iyatọ laarin nkan ti ẹmi ati nkan ti ara, ki o ma ba fi igba kankan mọ padanu ipese rẹ fun alaafia ati igbega rẹ. Amin.
Ọkan lara idi ti ọpọ lara awọn ọmọ Ọlọrun loni ṣe ma n ṣaba padanu ipese rẹ fun alaafia ati iṣorire wọn ni adamọdi igbagbọ pe nkan ẹmi gbọdọ wa ni ọna ti o jọniloju tabi ti o ga. Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni nkan ẹmi ma n jọniloju. Nkan ti mo n sọ ni pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni iwosan, itusilẹ, isọdọtun tabi igbega lati ọwọ Ọlọrun ma n gba ọna ti o yani lẹnu ṣẹlẹ. Ti oye eyi ko ba si ye wa, o ṣeeṣe ki a padanu nkan ti O fi ranṣẹ si wa tabi ki a kọ ọ silẹ nitoripe ko gba ọna babara yọ si wa.
Fun apẹẹrẹ, lẹyin igba ti Jakọbu fi ile baba rẹ silẹ lati lọ si Harani, o duro lati sun ni ibikan ti ko fẹ ba irọrun de fun rara. Nkan kan ṣoṣo ti o ri nibi ti a n wi yi ko ju okuta kan ti o lo dipo irọri. Sibẹsibẹ, ni ibi kannaa yi, o la ala ri Ọlọrun, awọn angẹli rẹ ati ọrun. O tilẹ ti ri ọrọ ibukun gba lati ẹnu Ọlọrun ninu ala naa. Nigba ti o si ji, ẹru ba a, o si sọ wipe, “Oluwa n bẹ nihin-in yii nitootọ; emi ko si mọ…Ihin yii ti ni ẹru to? Eyi ki i ṣe ibomiran bi ko ṣe ile Ọlọrun, eyi si ni ẹnu bode ọrun.” (Jẹnẹsisi 28:16-17)
Nitorina, Ọlọrun le wa digbi nibikan, ki a si ma mọ, niwọn igba ti a ko ba ṣi wa ni oju lati ri i. Mo si mọ pe iwọ naa mọ pe igba gbogbo ni Ọlọrun ma fi n tọkantọkan wa ni gbogbo ipejọpọ awọn eniyan rẹ, nitoripe Jesu ti sọ fun wa pe, “Nibi ti ẹni meji tabi mẹta ba gbe wa ni orukọ mi, nibẹ ni Emi yoo wa ni aarin wọn.” Ṣugbọn melo ninu wa ni o n fi gbogbo igba mu ọrọ yi ni ọkunkundun, ki a ba le ṣe amulo rẹ? Melo ninu wa ni o n fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi pe nigbakugba ti a ba pejọ papọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun, Oluwa wa nibẹ pẹlu wa, ti O n wo ohun gbogbo ti a n ṣe, ti O si ṣetan lati pin wa ni ere fun igbagbọ wa tabi lati ba wa wi fun aiṣedede wa? (Wo: Matiu 18:20; Iṣe Awọn Apositeli 5:1-11)
Ailoye awọn nkan wọnyi ni o fa ti ọpọ fi n wa si ipade ijọ lọsọọsẹ, ti wọn ko si ni iriri iṣẹ iyanu Ọlọrun ni ọna gboogi kan tabi omiran. Eyi naa lo si tun fa ti ọpọ fi n ti ori oke de ori oke ati ọdọ wolii de ọdọ wolii, ti wọn n wa iṣẹ iyanu ti ko sọnu kaakiri. Ka tilẹ sọ otitọ, iṣẹ iyanu ti ọpọ n sare wa kaakiri ni wọn le ri gba wẹrẹ ni aarin ijọ wọn, ti o ba ṣe pe wọn n ṣe amulo to peye wiwa Ọlọrun ninu gbogbo ipejọpọ wọn.
Wo o, o le wa ninu ipejọpọ ti o kun fun itusilẹ agbara Ọlọrun lọpọ yanturu, ki o si ma mọ tabi gbadun rẹ, niwọn igba ti o ba ya akuri ninu ẹmi. Pọọlu so eyi fun wa: “Ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa, nigba ti ẹyin ba pe jọ ati ẹmi mi, pẹlu agbara Jesu Kirisiti Oluwa wa.” (1Korinnti 5:4) Njẹ o ri bayi? Igbakigba ti a ba pejọpọ ni orukọ Jesu Oluwa wa, agbara rẹ ma n wa nibẹ pẹlu wa lati gbala, wosan, tu silẹ, gbega ati pẹlupẹlu ṣe idajọ ibi. Nkan ti a si nilo ni ki a fiyesi eyi, bi o tilẹ je pe a ko ri agbara naa soju tabi mọ-ọn lara, ki a si tun ṣe amulo rẹ lati yi ọrọ aye wa pada si rere.
Ṣugbọn ti a ba ya akuri nipa ti ẹmi, awọn nkan ti ko le pe wa ni a o ma foju silẹ fun ninu awọn ipejọpọ wa. A le ma foju silẹ fun orin aladun, lero pe ninu rẹ agbara Ọlọrun wa. Tabi ki a ma foju silẹ fun ẹni kan ti yoo pariwo ọrọ Ọlọrun lewa lori tabi ẹni ti yoo fi ọrọ didun sọ wa ji lati gbadura tabi ẹni ti yoo ṣe nkan kan tabi omiran lati jẹ ki ara wa mi titi tabi ki ori wa dide jan an. Ti a ko ba si ri awọn nkan yi, a le ni lọkan pe Ọlọrun ko fi taratara wa ninu awọn ipade naa, ti O ba tilẹ wa ninu wọn rara.
Wayi o, ọna kan gboogi lati padanu agbara ati ipese Ọlọrun fun wa ni yẹn. Bi o tilẹ jẹ pe ko si nkankan ti o buru pẹlu orin ti o larinrin, iwasu ti o ga tabi adura ti o mu gbigbohun soke lọwọ ninu ipade awọn onigbagbọ, ko ki i ṣe awọn nkan wọnyi ni o ma n tu agbara tabi ibukun Ọlọrun silẹ fun awọn eniyan. Dipo eyi, Ọlọrun funrarẹ ni O ma n tu silẹ. Bẹẹni, wiwa rẹ ninu aye wa tabi ninu ipejọpọ wa ni o ma n tu agbara rẹ silẹ fun igbadun wa. Nitorina, dipo ti a o fi fi igbagbọ wa sinu rẹ lati ni iriri iṣẹlẹ iyanu, ti a ba fi sinu awọn akitiyan babara awọn eniyan kan, a ko ni ni iriri agbara rẹ ti a n fẹ lati ri rara. Ko ju bẹyẹn lọ.
Idi si ni yi ti a fi gbọdọ ma fi gbogbo igba gbadura pe ki Ọlọrun ṣe ọkan wa yẹ, ki a ma ba tipaṣẹ wiwa awọn nkan babara padanu ifihan agbara Ọlọrun. Ki Ọlọrun si dahun ibeere yi lori aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Idi ti o ṣe le padanu agbara iyanu | PaitoJ.O. Lawal Read More »





