ỌJỌRU 14, AGẸMỌ 2021
AKỌSORI: AKỌSORI: “Awọn eniyan pupọ si wa sọdọ rẹ, wọn si wi pe, Johanu ko ṣe iṣẹ, ami kan: ṣugbọn otitọ ni ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yii.” (Johanu 10:41)
ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ ti a n kọ lori wolii ati iṣẹ iranṣẹ rẹ, a ri daju lati inu bibeli pe wolii jẹ ẹnikan ti Ọlọrun n fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han ki O ba a le lo o lati fi ifẹ rẹ tabi ara rẹ han awọn eniyan. Eyi si kọja ki a sọ asọtẹlẹ; dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu fifi ifẹ, ete, ero tabi eto Ọlọrun han si awọn eniyan. A si tun ri pe Ọlọrun le fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han wolii nipasẹ ala tabi iran tabi nipasẹ biba sọrọ ni ẹnukoẹnu. Amọ ṣa o, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni wolii, ti ko wa fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun ko ni le ṣe iyatọ ti o peye laarin ala, iran tabi ohun ti o wa lati ọdọ Ọlọrun ati eyi ti o wa lati ọdọ Eṣu. Yatọ si eyi, ko tun ni mọ igba ti o yẹ ki o gbe ẹnu dakẹ ati igba ti o yẹ ki o sọrọ. Eyi ni o si fa a ti a fi ni ọpọlọpọ wolii eke kaakiri agbaye loni.
WOLII ATI IṢẸ IYANU
Wayi o, ara nkan ti a tun nilo mọ nipa wolii ni pe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko ki i fi gbogbo igba ni i ṣe pẹlu ki a ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu. Lotitọ, bi a ṣe ri ninu bibeli, awọn wolii kan wa ti o jẹ pe Ọlọrun lo wọn fun oniruuru iṣẹ ami ati iyanu. O ṣi ṣe eyi ni ọpọ igba lati jẹ ki awọn eniyan gba a gbọ. Jesu tilẹ fi igba kan sọ eyi fun awọn ara Juu: “Bi ko ṣe pe ẹyin ba ri ami ati iṣẹ iyanu, ẹyin ki yoo gbagbọ lae.” (Johanu 4:48) Nitorina, awọn kan wa ti o jẹ pe ti ko ba ṣe pe wọn ba ri ami tabi iyanu Ọlọrun, wo ko ni gba a gbọ. O le jẹ nitori ipọnju ti o pọ fun wọn tabi nitori itanjẹ orisirisi awọn eke ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn ti ba pade tabi nitori ibaṣepọ wọn pẹlu agbara okunkun ni wọn ko ṣe fẹ ni nkankan ṣe pẹlu Jesu tabi Ọlọrun. Ṣugbọn ti awọn wọnyi ba ri iṣẹ ami ati iyanu otitọ, wọn le tipasẹ rẹ gbagbọ, ki wọn si kọ ẹṣẹ, ibọriṣa ati awọn iwa eeri wọn silẹ.
Fun apẹẹrẹ, a ri wipe nigba ti Ọlọrun ran Mose pada lọ si Ijibiti lati mu awọn eniyan rẹ jade, O fun ni aṣẹ lati ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu. Ki si ni idi? Ni akọkọ, O ṣe eyi ki awọn ọmọ Isiraẹli, ti iya ti jẹ fun ọpọlọpọ ọdun, ti wọn si ti bẹrẹ si ni ro wipe Ọlọrun awọn baba wọn ti kọ wọn silẹ tabi pe ko ni agbara lati gba wọn, ba le gbagbọ ninu rẹ ati ninu ẹni ti o ran an niṣẹ. Nitorina, bibeli sọ eyi fun wa: “Mose ati Aarọni lọ, wọn ko gbogbo agba awọn ọmọ Isiraẹli jọ: Aaroni sọ gbogbo ọrọ ti Oluwa ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ ami naa ni oju awọn eniyan naa. Awọn eniyan naa si gbagbọ: nigba ti wọn gbọ pe, Oluwa ti bẹ awọn ọmọ Isiraẹli wo, ati pe o ti ri ipọnju wọn, nigba naa ni wọn tẹ ori wọn ba, wọn si sin in.” (Ẹkisodu 4:29-31)
Idi keji ti Ọlọrun fi fun Mose ni aṣẹ ati agbara lati ṣe iṣẹ ami ati iyanu ni lati le fi dandan mu Farao lati tu awọn eniyan rẹ silẹ. Iwọ na wo nkan ti Ọlọrun sọ fun Mose lori eyi: “Emi si mọ pe ọba Ijibiti ki yoo jẹ ki ẹyin ki o lọ, bi ko ṣe nipa ọwọ agbara. Emi o si na ọwọ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlu Ijibiti ti emi o ṣe laarin rẹ: lẹyin eyi ni oun o too jẹ ki ẹ lọ.” (Ẹkisodu 3:19-20) A si ri pe bẹẹ gẹgẹ ni Ọlọrun ṣe si ọba Ijibiti ati awọn eniyan rẹ, ki o to di pe wọn gbagbọ pe Ọlọrun ni agbara lori wọn, ti wọn si tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ.
Siwaju si, ni igba aye ọba Ahabu, a ri wipe ibọriṣa ati iṣẹ oṣo gbilẹ to bẹẹ gẹẹ ti awọn eniyan Isiraẹli fi gbagbe Ọlọrun patapata, ti wọn ko si mọ bi o ṣe yẹ ki wọn sin in mọ. Nitorina, nigba ti Ọlọrun ṣetan lati mu wọn padabọsipo, O kọkọ fi iyan ọdun mẹta ati abọ bẹ wọn wo nipasẹ ọrọ ẹnu wolii rẹ, Elija. Lẹyin eyi, O tun wa lo wolii yi lati mu ki ina sọkalẹ lati ọrun sori ẹbọ sisun rẹ, ki o ba le fi awọn oriṣa ti wọn n bọ ati awọn wolii awọn oriṣa yi han gẹgẹ bi eke. (Wo: 1Awọn Ọba 17&18)
Nitorina, ọkan pataki lara idi ti Ọlọrun fi ma n tipasẹ awọn wolii rẹ ṣe iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu ni lati jẹ ki awọn eniyan le gba a gbọ ki wọn si ronupiwada, kọ ibọriṣa silẹ tabi ri gẹgẹ bi alagbara lori ohun gbogbo. A si tun fi idi eyi mulẹ nipasẹ iṣẹ iranṣẹ awọn apositeli, ẹfanjẹlisiti ati wolii Jesu ti wọn lọ kaakiri agbaye lati polongo ọrọ rẹ fun araye. A ri wipe pupọ ninu ibi ti wọn lọ ni wọn ti ṣe ọpọlọpọ isẹ ara ati iṣẹ iyanu ti o pe akiyesi awọn eniyan si ihinrere Jesu, ti o si tun jẹ ki wọn gbagbọ. (Wo: Iṣe Awọn Apositeli 5:12, 8:4-8 & 14:3)
Amọ ṣa o, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni Ọlọrun ma n lo awọn wolii tabi awọn iranṣẹ rẹ miran fun iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu. Ailoye eyi si n jẹ ki ọpọ padanu awọn ibukun tabi aabo ti wọn ko ba ma ri gba lati ara awọn wolii Ọlọrun ti O n ran si wọn. Nkan ti mo n sọ ni wipe ọpọ ni o ro pe ẹni ti ko ba ti ma ṣe iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu ko ki i ṣe wolii otitọ. Ṣugbọn pataki julọ ninu iṣẹ iranṣẹ wolii ni lati fi ifẹ, ete ati ero Ọlọrun han awọn eniyan, ki i ṣe lati ṣe iṣẹ iyanu. Iṣẹ iyanu melo ni awọn wolii bi Aisaya, Jeremaya, Emọọsi, Miika, Daniẹli ati bẹẹbẹẹ lọ ṣe? A ko ni akọsilẹ wọn. Ṣugbọn wọn fi tọkantọkan fi ifẹ ati eto Ọlọrun han gbogbo awọn ti O ran wọn si.
Bi a tilẹ tun ṣe ri ninu akọsori wa, Johanu onitẹbọmi ti o fi Jesu han fun awọn Juu gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun gan ko ṣe iṣẹ iyanu kankan (Johanu 10:41). Sibẹsibẹ, Jesu sọ wipe ko si wolii naa tabi eniyan naa ti a bi ninu obinrin ti o ga ju Johanu yi lọ niwaju Ọlọrun, ayafi awọn ọmọ ijọba ọrun (Matiu 11:11). Eyi si n jẹ ki o ye wa wipe Ọlọrun ko ki i gbe odiwọn pataki iṣẹ wolii kan tabi omiran le ori iye iṣẹ iyanu ti wọn ṣe ṣugbọn lori bi wọn ṣe fi tọkantọkan jẹ iṣẹ yowu ti o ba gbe le wọn lọwọ si.
Ti a o ba i ti gbagbe, a ti ri idi ti Ọlọrun fi ma n lo awọn wolii rẹ lati ṣe iṣẹ iyanu. Amọ ko ki i ṣe gbogbo igba ni O ma n ṣe eyi tabi ni o nilo lati ṣe eyi. Ibikibi ti Ọlọrun ba ti mọ pe awọn eniyan ri iṣẹ iyanu rẹ to lati gbagbọ, O le ma ṣe iṣẹ iyanu miran fun wọn nibẹ mọ. Fun apẹẹrẹ, ninu iwe Matiu ti a n gbe yẹwo fun ẹkọ yi, a ri eyi ka:
“Awọn Farisi pẹlu awọn Sadusi si wa, wọn n dan an wo, wọ si n fẹ ki o fi ami han fun wọn lati ọrun wa. Ṣugbọn o dahun o si wi fun wọn pe, Nigba ti o ba di aṣalẹ, ẹyin a wi pe, ọjọ yoo dara: nitori ti oju ọrun pọn. Ati ni owurọ ẹyin a wi pe, ọjọ ki yoo dara lonii, nitori ti oju ọrun pọn, o si ṣu dẹdẹ. A! Ẹyin agabagebe, ẹyin lee mọ ami oju ọrun; ṣugbọn ẹyin ko le mọ ami akoko wọnyi? Iran buburu ati pansaga n fẹ ami: a ki yoo si fi ami fun un, bi ko ṣe ami ti Jona wolii. O si fi wọn silẹ, oo kuro nibẹ.” (Matiu 16:1-4)
Njẹ o ri bayi? Jesu kọ jalẹ lati ṣe iṣẹ ami kan tabi omiran fun awọn Farisi ati Sadusi ti o tọ ọ wa. Ki si ni idi? Idi ni wipe wọn ti ni aafani lati ri ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami ti Ọlọrun jẹ ki O ṣe. Sibẹsibẹ, wọn ko gbagbọ. Akoko kan wa ti O tilẹ sọ wipe egbe ni fun awọn ilu bi Korasini, Kapanaumu ati Bẹtisaida nitoripe bi o tilẹ jẹ pe O ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ninu wọn, wọn ko ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn (Matiu 11:20-24). Nitorina, fun ẹni ti ko ba ni i gbagbọ rara, bi o tilẹ ri ẹgbẹgbẹrun iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu wolii, bi Farao na ni ọkan rẹ yoo ṣe yigbe, ti ko si ni ronupiwada. Ti Ọlọrun ba wa kọ lati fi iṣẹ ami han iru ẹni bẹ, njẹ o buru bi? Ko buru rara.
Yatọ si eyi, ara awọn idanwo ti Eṣu fun Jesu, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli, ni pe ki o sọ okuta di akara (Matiu 4:1-4; Luuku 4:1-4). O si fẹ ki o ṣe eyi ki o ba le fi ara rẹ han gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Njẹ Jesu wa ṣe gẹgẹ bi o ti wi bi? Rara o! Ki si ni idi ti ko fi ṣe bẹ? Idi ni wipe Jesu ko kan le dede ṣe iṣẹ iyanu ti ko ba ṣe wipe Ọlọrun lo ni ko ṣe e (Johanu 5:19 & 14:10). Eyi tunmọ si pe ifẹ Ọlọrun ni O n fi gbogbo igba tẹle; ko ki i ṣe ifẹ ti ara rẹ (John 8:29). Nitorina, niwọn igba ti o jẹ pe ifẹ Eṣu ni pe ki O sọ okuta di akara, ko le da lohun rara. A si gbọdọ jẹ ki eyi yewa yekeyeke, ki a ma ba titori pe a fẹ jẹ ki o ye awọn eniyan pe ti Ọlọrun ni a nṣe nitootọ jẹ iṣẹ ti ko ran wa.
Ni afikun, ko ki i ṣe gbogbo iṣẹ iyanu naa ni o ma n ti ọwọ Ọlọrun wa. Adamọdi iṣẹ iyanu wa. Awọn wolii eke naa a ma ṣe iyanu nipaṣẹ agbara awọn ẹmi Eṣu. Idi niyi ti Jesu Oluwa wa fi sọ eyi fun wa: “Nitori awọn eke Kirisiti, ati eke wolii yoo dide, wọn o si fi ami ati ohun iyanu nla han: tobẹẹ bi o le ṣe e ṣe, wọn o tan awọn ayanfẹ paapaa. Wo o, mo wi fun yin tẹlẹ.” (Matiu 24:24-25) Njẹ o ri bayi? Ti a ko ba ṣọra, a le tipaṣẹ iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu kọsẹ tabi ṣọnu.
Ni kukuru, a ko le sọ pe eniyan ko ki i ṣe wolii Ọlọrun tabi wolii otitọ nitoripe ko ṣe iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu ni ibamu pẹlu erongba wa. A ko si le gbe odiwọn pataki iṣẹ wolii kankan le bi o ṣe ṣe iṣẹ iyanu to. Ọlọrun ti O n gbe iṣẹ le awọn wolii rẹ lọwọ naa ni o le sọ bi iṣẹ wolii kan ṣe ṣe pataki si ati irufẹ iṣẹ iyanu tabi iṣẹ ara ti yoo ṣe tabi ti ko ni i ṣe.
ỌRỌ IPARI
A gbọdọ yago fun fifi iṣẹ iyanu ṣe ami tabi odiwọn boya enikan jẹ wolii Ọlọrun tootọ tabi wolii eke. Boya wolii kan yoo ṣe iṣẹ iyanu tabi ko ni i ṣe ku si ọwọ Ọlọrun; ko si ni i ṣe pẹlu eniyan rara. Nitorina, pataki iṣẹ wolii ni ki o fi ifẹ Ọlọrun ati ete rẹ han si awọn eniyan bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, ki oun na si gbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu otitọ Ọlọrun ti o mọ. Ti o ba ti ṣe eyi, iṣẹ iranṣẹ rẹ yoo jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun, bi ko tilẹ wa pẹlu iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu.
IBEERE
– Ọna wo ni ẹkọ yi gba ran imọ ati oye rẹ lọwọ lori iṣẹ iranṣẹ wolii?
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
