April 2022

Bì wọ́n lulẹ̀ | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 01, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 10, No. 52

Olùfẹ́: kí oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlááfìà jẹ́ tìrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu inu didun ni mo ki ọ kaabọ sinu oṣu karun ọdun yi, oṣu Èbíbí. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun jẹ ki ayọ rẹ ma fi gbogbo ọjọ inu oṣu naa kun akunwọsilẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Laipẹ yi, nṣe ni gbogbo awọn aye ti o wa lori ẹrọ ayelukara wa kun fun iroyin ọmọdebirin ọmọ ọdun mẹwa kan ti wọn sọ pe awọn ọmọ ilẹ-ẹkọ rẹ kan fi ipa ba lopọ, iyẹn nigba ti wọn wa ni Dubai fun awọn ere-idaraya agbaye kan. Lati igba na si wa ni oniruuru esi ọrọ ti n jade lori iṣẹlẹ naa. Awọn kan sọ pe awọn obi ọmọ yi lo yẹ ki a bu fun iṣẹlẹ naa. Awọn miran sọ wipe ile-iwe ọmọ naa ni o yẹ ki a bu fun aiwulo awọn adari rẹ ni mimojuto awọn ọmọ naa. Awọn miran ẹwẹ si sọ wipe awọn gbajumọ kan ati awọn aṣa aibikita ti wọn ni lati ma fi awọn fọnran igbe aye iṣekuṣe wọn sori ẹrọ ayelukara ni o yẹ ki a bu fun iṣẹlẹ naa.

Amọ ṣa o, emi ti wa bere awọn ibere wọnyi lọwọ ara mi lori ọrọ naa: Melo ninu wa gan lo san ju awọn ọmọ yi lọ lotitọ pẹlu igbe aye ti a n gbe lọwọlọwọ yi? Melo ninu wa ni o san ju wọn lọ nigba ti awa naa wa ni ọjọ ori ti wọn wa yi? Mo ṣa ranti daradara pe nigba ti emi paapaa wa ni bi ọjọ ori ọmọ yi, emi naa ni awọn erokero ti ara mi ati awọn ẹmi eṣu ti o n yọ mi lẹnu ti mo ni lati doju ija kọ. Nitorina, emi naa ko ba ti dabi ọkan ninu wọn tabi ki o tilẹ buru fun mi ju wọn lọ.

Ki wa lo fa a ti n ko ṣe dabi ọkan lara wọn? Oore-ọfẹ Ọlọrun ni ko jẹ ki n dabi ọkan lara wọn. Ọna wo si ni oore-ọfẹ rẹ gba ṣe eyi? Akọkọ, o fun mi ni awọn obi ti ko fi aye silẹ fun mi lati dabi wọn, yala nipa ọrọ wọn ni tabi nipa iwa wọn. Ekeji, o fi mi ṣinu ijọ ti mo ti n fi gbogbo igba gbọ ọrọ Ọlọrun, gba adura ati gbọ ọrọ iyanju awọn ẹni-bi-Ọlọrun. Nitorina, awọn erokero wọnyi ti ko ba ti ba aye mi jẹ ko ri aye lati gberu tabi lati fi ara han ninu iṣesi mi.

Nitorinaa, ti o ba jẹ obi, jẹ ki Ọlọrun lo ọ lati pa awọn ọmọ rẹ ati awọn ọmọ miran ni ayika rẹ mọ. Lọna wo? Mojuto irufẹ agbegbe ti o ṣeto silẹ fun awọn ọmọ wọnyi lati dagba ninu rẹ nipa iṣesi rẹ ati ọrọ ẹnu rẹ. Idi si ni pe eyi ni agbara pupọ lati sọ boya ibi yoo bori wọn tabi ko ni bori wọn. Ti o ko ba ki si ṣe obi, o nilo lati ba ara rẹ sọ otitọ ọrọ lori awọn ero buburu ati ifẹkufẹẹ ti o n lepa lati fi ara han ninu iṣesi rẹ. Aijẹbẹ, o di dandan ki wọn bori rẹ, ki wọn si pa aye rẹ run. Lotitọ, aye le ma mọ tabi gbọ nipa bi aye rẹ ṣe bajẹ, gẹgẹ bi wọn ti gbọ nipa ti ọmọdebirin yẹn ati awọn miran bi tirẹ. Ṣugbọn ko ja mọ nkankan boya wọn gbọ si tabi wọn ko gbọ si. Ti aye rẹ ba ti bajẹ, o ti bajẹ naa niyẹn.

Idi si ni yi ti o ṣe gbọdọ ba ara rẹ sọ otitọ ọrọ nipa awọn ero buburu ati ifẹkufẹẹ ti o ni. Ma ṣe dibọn, ki o ṣe bi igba ti wọn ko si nibẹ. Dipo eyi, mojuto wọn. Gbogbo wa naa ni awọn nkan wọnyi n fi ojoojumọ yọ lẹnu. Jesu ati awọn apọsiteli igbaani naa gan fi ojoojumọ ba iyọlẹnu awọn nkan wọnyi pade. Eyi lo si fa ti Peteru ṣe kọ iwe si awọn ijọ Ọlọrun, ti o sọ wipe, “Olùfẹ́, mo bẹ̀ yín bí álejó áti èrò, láti fá sẹ́yín kúrò nínú ífẹ́kúfẹẹ́ ara, tí ń bá ọkán yín jagun.” (1Pétérù 2:11) Nitorina, gbogbo igba ni erokero, ero ibajẹ ati ero iparun ma n gbogun ti ọkan wa. A si gbọdọ gba eyi gẹgẹ bi ododo. Aijẹbẹ, a ko ni le mojuto wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

Lotitọ, awọn ero buburu yi ko ki i ṣe tiwa. Satani ni o ni wọn. Fun apẹrẹ, ko ki i ṣe aba Jesu ni lati fo silẹ lati ori tente Tẹmipili, ki O si ku. Aba ti Satani ni iyẹn. Bẹẹ si ni ko ki i ṣe ero Judasi Isikariọti ni lati da Jesu. Ero Satani ni. Iyatọ ti o wa wa laarin Jesu ati Judasi ni nkan ti awọn mejeji ṣe si awọn erokero ti Satani fi si wọn lọkan. Nigba ti Jesu bi awọn ero buburu yi lulẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun, nṣe ni Judasi fi aye gba wọn lati gbakoso aye rẹ, ki wọn si pa a run. (Wo: Matiu 4:1-11; Johanu 13:2, 2Kọrinnti 10:5)

Nibakanna, ti a ko ba fẹ ki awọn eru buburu ti o n ba ọkan wa jagun fi ara han ninu aye wa, ki wọn si ba aye wa jẹ, a gbọdọ ṣe amulo ti o peye ọrọ Ọlọrun, adura gbigba ati ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun lati le da awọn ero wọnyi mọ ati lati le bi wọn lulẹ. A si gbọdọ ṣetan lati ṣe eyi lojoojumọ, nitori ojoojumọ ni Satani ṣetan lati ba aye wa jẹ, niwọn igba ti aye ba ti ṣi ṣilẹ fun un. Nitorina, ji kuro ninu oorun ti o n sun, ki o si gbaradi fun ohun yowu to ba de. Ijakadi igbagbọ wa ni eyi. Ijakadi ti o si dara ni, nitori a ti ni awọn nkan ti a nilo lati rin ninu iṣẹgun ninu ijakadi naa ni ojumọ kọọkan ti o ba mọ.

Ki o ni oṣu Èbìbí 2022 alárinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Bì wọ́n lulẹ̀ | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ́: Èbìbí 01, 2022 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 10, No. 52 Read More »

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN AYỌKA: TÍMÓTÌ 4:7-11 ỌJỌ́RÚ 27, IGBE 2022

ÀKỌ́SÓRÍ: “Má ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí ìtàn asán; ṣùgbọ́n tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.” (Tímótì 4:11)

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Bi a ti ṣe kọ ninu ẹkọ ti a kọ sẹyin lori titọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun, iwa-bi-Ọlọrun ko ki ṣa dede jẹyọ ninu aye eniyan, bi o tilẹ ti ni amuyẹ lati ọdọ Ọlọrun fun un. A gbọdọ tọ ara wa lati wa bi Ọlọrun ki iwa-bi-Ọlọrun to le bẹrẹ si ni jẹyọ laye wa lọna ti o ni apẹẹrẹ. Aijẹbẹ, bi a tilẹ pe ara wa ni ọmọ rẹ, iwa ati iṣeṣi wa le ma fi taratara jọ tirẹ ni ọna pupọ. Eyi si ni o jẹ ki ọpọ Kirisitiẹni loni ri bi wọn ti ṣe ri, ti igbe aye wọn ko si wú awọn ti o wa ni ayika wọn lori debi pe wọn yoo fẹ ba Ọlọrun ni ajọṣepọ. Ti a ba wa fẹ ki awọn ti o wa ni ayika wa tabi ni awujọ wa gba iwuri lati ba Ọlọrun ṣepọ nipasẹ igbe aye ti a ngbe, a gbọdọ tọ ara wa lati wa bi i rẹ.

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN

Bawo wa ni a ṣe le tọ ara wa si iwa-bi-Ọlọrun? A le tọ ara wa si iwa bi Ọlọrun nipa ṣiṣe amulo awọn ipese rẹ fun wa lati gbe igbe aye ti o dabi tirẹ. Ranti wipe Peteru ṣọ eyi fun wa nipa iwa-bi-Ọlọrun: “Gẹ́gẹ́ bí agbára Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí í ṣe ti ìyè àti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa ògo áti ọlá ńlá rẹ̀. Nípa èyí tí o ti fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó si ṣe iyebíye fún wa: pé nìpa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin kí ó le di alábáápín nínú ìwà bí Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ ti n bẹ ninu aye nipa ifẹkufẹẹ.” (2Pétérù 1:3-4) Njẹ o ri bayẹn? Nipa mimọ Ọlọrun, a ti di ajogun awọn ipese rẹ fun wa lati gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run.

Lafikun, Pọọlu naa sọ eyi fun wa: “Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ń mú ìgbàlà wà fùn gbogbo ènìyàn ti farahàn. Ó ń kọ wa pé, kí á ṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a si maa wà ní àìrékọjá, ní òdodo, àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsìnyí.” (Títù 2:11-12) Ṣe o tun ri bayẹn? Ẹkọ wa fun gbogbo wa lati kọ lori bi a ti ṣe n gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ninu aye ti a wa yi. A si le kọ ẹkọ yi nipasẹ oore-ọfẹ Ọlọrun, eyi ti a tun le pe ni ipese rẹ.

Ki wa ni awọn nkan ti Ọlọrun ti pese fun lati gbe igbe ayẹ bi tirẹ ninu aye yi, ti a si le ṣe amulọ wọn? Awọn naa ni iwọnyi:

–    Ẹ̀mí Ọlọ́run: Pataki ninu awọn ipese Ọlọrun fun gbogbo awọn ọmọ rẹ lati gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run ni Ẹmi Mimọ rẹ ti O fun wa lati ma ba wa gbe titi lailai. Ki si ni idi ti Ọlọrun fi fun wọn ni Ẹmi rẹ lati ma ba wọn gbe titi lailai? Idi ni ki O ba le dari wọn sinu gbogbo ọtitọ ti wọn nilo lati mọ lati gbe irufẹ aye ti O fẹ ki wọn gbe ati lati fun wọn ni okun, igboya, oriya ati itunu ti wọn nilo lati gbe aye naa. Ọlọrun ti mọ pe ko si nkankan ti a le da se lailai jẹ wipe Ẹmi rẹ ṣe wa yẹ lati ṣe (Jòhánù 15:5). Idi naa niyi ti O fi fi Ẹmi rẹ jinki wa lọfẹ. Awa ni a wa gbọdọ kọ lati ma fi gbogbo igba rin pẹlu afiyesi pe a ko le gbe igba aye ìwà-bí-Ọlọ́run laifi ti Ẹmi mimọ ṣe. Niwọn igba ti a ba si ti da ara le Ẹmi yi fun okun, igboya, ifaraji ati ohun yowu ti a tun le nilo lati gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe, ko si ni ki a ma ṣe aṣeyọri ninu gbigbe igbe aye naa. (Wo: Ìsíkíẹ̀lì 36:27; Jòhánù 14:26; Jòhánù 16:12-15; 2Kọ́rínntì 3:4-6; Gàlátíà 5:16; Fílípì 3:3)

–    Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Bi a ti ṣe sọ siwaju, a nilo lati ṣe amulo wiwa Ẹmi Ọlọrun ninu aye wa lati gbe igba aye iwa-bi-Ọlọrun. Amọ ti a ko ba mọ ọna lati ṣe eyi, wiwa rẹ ninu wa ko ni jamọ nkankan taarataara. Ọkan lara ọna ti a wa le gba ṣe amulo wiwa rẹ ninu wa ati pẹlu wa ni fifi ara wa jin fun ọrọ iwe mimọ. Nkan ti a n sọ nipe ọrọ Ọlọrun, ti a kọ silẹ fun wa ninu bibeli, jẹ ọkan lara nkan ti Ẹmi Ọlọrun ma n lo lati ṣe awọn Ọmọ Ọlọrun yẹ fun igbe aye iwa mimọ. Iwọ naa wo nkan ti Pọọlu sọ fun awọn alagba ijọ Efesu lori eyi: “Njẹ nisinsinyi, ara, mo fi yin le Ọlọrun lọwọ ati ọrọ oore-ọfẹ rẹ, ti o le gbe yin duro, ti o si le fun yin ni ini laarin gbogbo awọn ti Oluwa sọ di mimọ.” (Iṣe Apọsiteli 20:32) Nitorina, ẹnikẹni ti o ba fẹ mọ ifẹ Ọlọrun daju lori bi o ṣe yẹ ki o gbe aye rẹ lati wu u ninu ohun gbogbo, ki o si tun duro ṣinṣin ninu ifẹ rẹ naa ti o mọ gbọdọ fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun. O gbọdọ maa ka a, ki o maa tẹti gbọ ọ, ki o si ma ṣe asaro ninu rẹ lojoojumọ ki o ba le yee, ki o si le ṣe amulo rẹ (Jọ́súà 1:8; Mátíù 13:1-23). Aijẹbẹ, ko si bi yoo ṣe le gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun.

–    Ànfààní àdúrà gbígbà: Ipese Ọlọrun miran fun awọn ọmọ rẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun ni anfaani adura gbigba si i. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, gbogbo awa ti a jẹ ọmọ rẹ ninu Kirisiti Jesu ni a le tọ ọ wa pelu igboya ati laibẹru nigbakigba lati tẹwọgba awọn nkan ti O ti pese silẹ fun igbayegbadun wa ati igbayetẹlọrun wa (Éfésù 3:12; Hébérù 4:16). Nitorina, ẹnikẹni ninu wa ti o ba wa fẹ ri ifarahan iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ninu rẹ ni ọna ti o peye, ti ko si fẹ ṣe alaini ohun ti o dara kankan lati gbe aye ti o wu Ọlọrun, gbọdọ fi ara rẹ jin fun adura gbigba, ni aisimi ati ni aiṣaarẹ. Bi Jesu Oluwa wa si ti fi ye wa, lalai ṣe pe a ba n fi gbogbo igba gbadura si Ọlọrun lati fun wa ni okun nipasẹ Ẹmi rẹ, ko si ni bi a ko ṣe ni ṣubu sinu idanwo Eṣu. Bẹẹni, o ṣeeṣe ki ọkan wa fẹ ṣe ohun ti o tọ, ti o si yẹ. Ṣugbọn niwọn igba ti ko ba ti si okun fun ailera ara wa, ko si bi iwa-bi-Ọlọrun yoo ṣe ṣeeṣe fun wa. Idi niyi ti a ko fi gbọdọ fi adura gbigba ṣere rara, boya adura gbigba fun ara wa ni o tabi adura gbigba pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran, paapaa julọ awọn ti ijọ wa wa. (Wo: Lúùkù 22:31-32&39)

–    Ànfààní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn: Pataki lara awọn nkan ti ẹnikẹni ti o ba ṣẹṣẹ di atunbi ninu Jesu gbọdọ mọ ni pe nṣe ni a tun un bi sinu idile Ọlọrun, sinu agbo ile igbagbọ, sinu ara Kirisiti (1Kọ́rínntì 12:12-13; Gàlátíà 6:10; 1Tímótì 3:14-15). Nitorina, igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run ati ìgbáyégbádùn ko ki i ṣe adagbe ni fun un bikoṣe eyi ti yoo gbe pẹlu itọni, iranlọwọ ati ibawi awọn ọmọ Ọlọrun yoku. Idi si ni yi ti o fi gbọdọ pọn ni dandan fun ara rẹ lati darapọ mọ agbo awọn ọmọ Ọlọrun yowu ti o ba wa ni arọwọto rẹ, ti o si ri pe oye bi a ti ṣe n gbe aye tẹ Ọlọrun lọrun ye wọn. Awọn wọnyi ni Ọlọrun yoo ma lo lati kọ ọ, lati gba a niyanju, lati tu u ninu ati ran a lọwọ ni akoko ailera rẹ ati lati ṣe aṣọna fun ẹmi rẹ. Aijẹbẹ, ko si bi yoo ṣe le gbe igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run. Ọpọ ni aimọkan ti wa jẹ ki wọn ṣe aṣiṣe lori eyi, ti Eṣu si ti rapala wọle lati ṣi wọn lọna ati lati jẹ wọn niya, nitoripe wọn ko ṣe amulo ti o peye ibaṣepọ ti wọn ni anfaani rẹ pẹlu ijọ ọmọ Ọlọrun kankan. Wọn ro lọkan wọn pe awọn le da igbe aye Kirisitiẹni gbe ni. Amọ aṣiṣe yi gan an ni Eṣu lo lati ya wọn sọtọ lati rẹ wọn jẹ. Ti awa naa ko ba si fẹ ki Eṣu ni anfaani lati ya wa sọtọ kuro lọdọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o le ran igbagbọ wa ati ìwà-bí-Ọlọ́run wa lọwọ, a gbọdọ mu ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ ijọ wa ni ọ́kúnkúndùn. (Wo: Ìṣe Àpọ́sítélì 20:28-31; Éfésù 4:11-16; Hébérù 3:12-13; Hébérù 10:24-25; Hébérú 12:15-17)

–    Iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli Ọlọrun: Bibeli sọ eyi fun wa nipa awọn angẹli: “Ẹ̀mí tí ń jísẹ́ ha kọ́ ni gbogbo wọn í ṣe bí, tí a n rán lọ láti maa jọ́sìn nítorí àwọn tí yoo jogún ìgbàlà?” (Hébérù 1:14) Ki ni nkan ti eyi n jẹ ki o ye wa? O n jẹ ki o ye wa pe iṣẹ iranṣẹ gbogbo awọn angẹli ni lati ṣiṣẹ ran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ. Idi si ni yi ti a fi kọ wa lati ma ṣoore fun awọn eniyan, paapaa-julọ awọn alejo ati awọn ti a ko mọ ri. Nitoripe a ko le sọ igba ti a o ṣoore fun angẹli kan tabi omiran ti a ran lati yọ wa ninu ewu tabi ran wa lọwọ (Hébérù 13:2). A si ri oniruuru àpẹrẹ ninu bibeli awọn ti a ran angẹli si lati ran igbe aye iwa mimọ wọn lọwọ tabi laye yọ wọn kuro ninu ewu ti o sọrọ mọ gbigbe igbe aye yi. Lọọti, Daniẹli ati Jesu Kirisiti Oluwa wa si wa lara awọn wọnyi (Jẹnẹsisi 19; Daniẹli 6; Luke 22:39-44). Nitorina, gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a nilo lati ma fi gbogbo igba fi sọkan pe awọn angẹli Ọlọrun rọgba yi wa ka lati ran igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run wa lọwọ. Niwọn ti a ba si n rin pẹlu afiyesi yi, ẹru ko ni fi igba kankan ba wa lati duro lori ẹsẹ wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun, bi o ti wu ki inunibini awọn ti o wa ni ayika tabi awujọ wa to. Aiwa ni oye yi ni o jẹ ki ọpọ ọmọ Ọlọrun fi ibẹrubojo fi ara wọn jin fun oniruuru ẹṣẹ ati iwa aitọ lawujọ wọn.

Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ

Igbe aye ìwà-bí-Ọlọ́run jẹ eyi ti ọmọ rẹ kọọkan gbọdọ lepa lati gbe. Idi si ni pe Ọlọrun ti pese gbogbo nkan ti wọn nilo lati gbe igbe aye yi fun wọn. Awọn ti o ba wa lepa lati ṣe amulo awọn ipese yi nikan naa ni yoo ri igbe aye yi gbe pẹlu irọrun, nitoripe Ẹmi Ọlọrun yoo ṣe ni irọrun fun wọn. 

ÌBÉÈRÈ

–    Bawo ni o ṣe ṣe pataki si fun awọn ọmọ Ọlọrun lati ni oye ipese Ọlọrun fun wọn lati gbe igbe aye ti O fẹ ki wọn gbe?

–    Mẹnuba diẹ lara awọn nkan ti o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022,  Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ọ̀NÀ LÁTI TỌ́ ARA RẸ SÍ ÌWÀ-BÍ-ỌLỌ́RUN AYỌKA: TÍMÓTÌ 4:7-11 ỌJỌ́RÚ 27, IGBE 2022 Read More »

Akori: Iyi dipo itiju | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Igbe 24, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ Nọmba: Vol. 10, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu yi. Adura mi si pe ki o ni iriri igbega iyanu ni gbogbo ibi ti a ti pa ọ ti, yan ọ jẹ, pọn ọ loju tabi ja o lole, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, mo gba adura yi fun ọ nitori pe o wa ni ibamu pẹlu nkan ti Ọlọrun ti sọ siwaju lati ẹnu ọkan lara awọn wolii rẹ igbaani nipa awọn eniyan rẹ. Ki si ni o sọ? O sọ wipe, “Kiyesi i, nigba naa ni emi o jẹ awọn ti n pọn ọ loju niya: emi a gba atiro la, emi o si ṣa ẹni ti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyin ati olokiki ni gbogbo ilẹ ti a ti gan wọn.” (Sẹfanaya 3:19)

Njẹ o ri bayi? Akọkọ, Ọlọrun ṣe ileri lati ba awọn ti o n pọn awọn eniyan rẹ loju wi. Nitorina, ti a ba ri awọn ti o n pọn iwọ naa loju lọwọlọwọ yi, mo fẹ ki o mọ pe opin ti de ba iṣẹ ọwọ wọn. Idi si ni pe dandan ni ki Ọlọrun na ọwọ gan wọn, ki O si da ṣeriya fun wọn gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn ti ri. Ko wa ki i ṣe iṣẹ tirẹ ni lati mọ nkan ti yoo ṣe fun wọn bi ko ṣe iṣẹ tirẹ. Ṣugbọn o le mọ daju pe nigbati ti o ba ṣetan pẹlu wọn, wọn ko tun ni lailai ronu lati pọn ẹlomiran loju mọ, niwọn igba ti wọn ba ṣi n mi. Ti o ba bere lọwọ rẹ, Ọba Abimeleki igba aye Aburahamu yoo sọ fun bi o ti ma n ri ti Ọlọrun ba n da ṣeriya fun awọn apọniloju, bi o tilẹ jẹ pe aimọkanmọkan ni o sun wọn de bẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 20)

Siwajusi, Ọlọrun sọ pe Oun yoo bu okiki ati iyi kun awọn eniyan rẹ ni gbogbo ibi ti wọn ti ba itiju pade sẹyin. Eyi ni yoo si jẹ iriri ti iwọ naa, ti o ba gba ọrọ rẹ pẹlu igbagbọ. Yoo jẹ ki awọn eniyan yọ mọ ọ ni gbogbo ibi ti wọn ti gan ọ tabi doju ti ọ tẹlẹ.

Ranti pe O ṣe ohun ti o jọ eyi fun Josefu. Ni ibi kanna ti o ti sinru gẹgẹ bi ẹru ati ẹlẹwọn ni o tun ti pada wa ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ijọba. Wa wo bi awọn eniyan bi Pọtifa ati aya rẹ yoo ṣe ma ṣe si i lẹyin-ọ-rẹyin. Iyẹn jẹ ọkan lara apẹẹrẹ bi Ọlọrun ti ṣe le gbe eniyan soke, ki O si tun bu iyi kun wọn ni ibi ti a ti gan wọn tẹlẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 39-41)

Nitorina, ma ṣe ba ọkan jẹ, ipo yowu ti o le wa laye lọwọlọwọ yi. Dipo bẹẹ, tẹwọgba ọrọ Ọlọrun si ọ lori igbega ati iyi rẹ. Bẹẹni, tẹwọgba ọrọ rẹ nipa sisọ nkankanna pẹlu rẹ, bi o ti wu ki nkan ri fun ọ ni akoko yi. Ti o ko ba si rẹwẹsi, o di dandan ki o ni iriri imuṣẹ ọrọ rere rẹ nipa rẹ ni akoko ti o tọ.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Akori: Iyi dipo itiju | Lati ọwọ: J.O. Lawal | Ọjọ: Igbe 24, 2022 | Atẹlera: Latori tabili Paitọ Nọmba: Vol. 10, No. 51 Read More »

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE | ỌJỌRU 13, IGBE 2022 | AKỌRI: TỌ ARA RẸ SI IWA-BI-ỌLỌRUN AYỌKA: TIMOTI 4:7-11 | J.O. LAWAL

AKỌSORI: “Ma ṣe feti si ọrọ tabi itan asan; ṣugbọn tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun.” (Efesu 4:11)

ỌRỌ AKỌSỌ
Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, igba ikẹyin yoo jẹ igba ewu fun ọpọlọpọ eniyan, paapaa julọ fun awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun (2Timoti 3:1-5). Ewu ti a si n sọrọ nipa yi kọja ewu ijamba ọkọ tabi ti ajakalẹarun tabi ti akitiyan awọn ika ati ọdaju eniyan; o tun ni i ṣe pẹlu ewu ọkan eniyan. Ewu ọkan eniyan yi si ni olori gbogbo ewu ti o wa laye. Ẹni ti o ba wa bori oniruuru ewu yowu ti o le wa laye ti ko si bori ewu ọkan rẹ ko bori nkankan rara. Amọ ẹni ti o ba ti bori ewu ọkan rẹ ti kogo ja. Ọna wo wa ni a le gba, gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, lati bori gbogbo nkan ti o le ṣe ijamba fun ọkan wa? Ọna naa ni ki a tọ ara wa ni iwa-bi-Ọlọrun.

TỌ ARA RẸ SI IWA-BI-ỌLỌRUN
Pọọlu, ninu lẹta rẹ kan si Timoti sọ eyi fun un: “Ma ṣe feti si ọrọ tabi itan asan; ṣugbọn tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun. Nitori ere-idaraya ti ara ni ere diẹ, ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun ni ere fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aye isinsinyi ati ti eyi ti n bọ. Otitọ ni ọrọ naa, o si yẹ fun itẹwọgba gbogbo eniyan. Nitori fun eyi ni awa n ṣe laalaa ti a si n jijakkadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alaaye, ẹni ti i ṣe Olugbala gbogbo eniyan, paapaa julọ awọn ti o gbagbọ. Nkan wọnyi ni ki o maa palaṣẹ ki o si maa kọ awọn eniyan.” (1Timoti 4:7-11)

Ki ni koko aṣẹ ti Pọọlu pa fun Timoti ninu abala lẹta rẹ yi si? Oun naa ni pe ki o tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun. Akọkọ naa, o kọkọ sọ fun pe ki o ma ṣe fi akoko rẹ ṣofo lori awọn nkan ti ko ni ran igbe aye iwa-bi-Ọlọrun rẹ lọwọ. Awa naa si gbọdọ di eyi mu ṣinṣin. Oniruuru nkan lo wa laye yi ti ko le ran igbe aye igbagbọ wa lọwọ. Oniruuru sinima, eto, ẹkọ ati bẹẹbẹẹ lọ lo wa ti ko le ran igbagbọ wa lọwọ rara. Yoo si dara pupọ ti a ba le mọ awọn nkan wọnyi ki a si yẹra fun wọn. Aijẹbẹ, ṣa dede ni a o ri pe aiwa-bi-Ọlọrun bẹrẹ si ni jẹyọ ninu aye wa, bi o tilẹ jẹ pe ọmọ rẹ ni a jẹ. (Wo: 2Tim 2:16)

Ki wa ni idi ti Timoti fi nilo lati tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun? Pataki lara awọn idi naa ni yi:

  • Ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣẹ bẹ: Idi akọkọ ti Pọọlu fi paṣẹ fun Timoti lati tọ ara rẹ bi a ti ṣe e wa bi Ọlọrun ni pe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe bẹ. Ti ko ba ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ni fun un lati ṣe bẹ ẹ, a jẹ wipe ifakoko ati ifagbara ṣofo lasan ni ṣiṣe bẹẹ ko ba ja si fun. Ṣugbọn ifẹ Ọlọrun ni fun gbogbo ọmọ rẹ lati ma gbe igbe aye ẹni ti o dabi rẹ. Idi ti O filẹ fi da wa ni ki a ba le ma gbe igbe aye ẹni ti o dabi rẹ. Ilodi si igbe aye yi ni o si fa ti idajọ rẹ fi n bọ lori awọn ọmọ alaigbọran. (Wo: Efesu 5:3-7; 1Tẹsalonika 4:3-8;1Peteru 1:15-16)
  • O ni amuyẹ lati tọ ara rẹ si iwa-bi-Ọlọrun: Ọtọ ni ki a paṣẹ fun eniyan lati ṣe nkan tabi ki a gba a niyanju lati ṣe nkan; ọtọ si tun ni ki o ni amuyẹ lati ṣe e. Ko si bi a ti ṣe pariwo mọ eniyan to tabi gba a niyanju to lati ṣe nkan, ti ko ba ni amuyẹ lati ṣe, asan ati ofo ni gbogbo ariwo, iyanju tabi ikilọ wa si yoo ja si. Nibakanna, ti Timoti ko ba ni amuyẹ lati gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun, aṣẹ ti Pọọlu pa fun lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ko ni ni itumọ rara. Nitorina, idi ti Pọọlu fi sọ fun ọkunrin yi lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ni pe o ni amuyẹ lati ṣe bẹ. Ẹnikẹni ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun ni amuyẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Wo nkan ti Peteru sọ fun wa lori eyi: “Gẹgẹ bi agbara Ọlọrun ti fun wa ni ohun gbogbo ti i ṣe ti iye ati iwa-bi-Ọlọrun, nipa imọ ẹni ti o pe wa nipa ogo ati ọla nla rẹ. Nipa eyi ti o ti fi awọn ileri rẹ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹyin ki o le di alabaapin ninu iwa bi Ọlọrun, nigba ti ẹyin ba ti yọ kuro ninu ibajẹ ti n bẹ ninu aye nipa ifẹkufẹẹ.” (2Peteru 1:3-4) Njẹ o ri bayi pe gbogbo awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ti fun ni ohun gbogbo ti a nilo lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe inu aye ibajẹ ati irukerudo ni a n gbe. Ti a ko ba wa gbe igbe aye ẹni ti o wa bi Ọlọrun, ko ni jẹ nitori pe a ko le ṣe bẹ ẹ; dipo eyi, yoo jẹ nitoripe a jẹ ope niti ipese Ọlọrun fun wa lati gbe igbe aye yi tabi nitoripe a kọ lati ṣe amulo ipese rẹ fun wa. (Wo: Titu 2:11-12)
  • Iwa bi Ọlọrun ko ki i ṣa dede waye: Otitọ ni pe gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni a ti ṣe yẹ ninu ọkan wa nipasẹ Ẹmi mimọ rẹ lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Amọ ṣa o, iwa-bi-Ọlọrun ko ki i kan dede waye. Eniyan gbọdọ tọ ara rẹ lati wa bi Ọlọrun ni. Idi si ni pe aye ti a wa jẹ aye ti oniruuru nkan wa ti ko ni jẹ ka fẹ gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Ifẹ owo, ifẹ ipo, ifẹ iyi, ifẹkufẹ ti ara ati bẹẹbẹẹ lọ ni o kun inu aye yi, ti ko si ni fẹ ki a gbe igbe aye ti Ọlọrun fẹ ki a gbe. Yatọ si eyi, ọpọ igba ni ẹran ara wa gan yo fẹ tako iwa-bi-Ọlọrun nitori ifẹkufẹ rẹ. Ti a ko ba wa fi eleyi sọkan, ki a si bẹrẹ si ni kọ ara wa lati yago fun ohunkohun ti o ni i ṣe pẹlu aiwa-bi-Ọlọrun ati lati tẹramọ awọn nkan ti yoo mu ki a gberu si ni gbigbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, ko si bi a o ṣe ma gbe igbe aye yi lojoojumọ. Idi si niyi ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe ki o tọ ara rẹ lati ma gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun. Ko kan ni dede waye funrarẹ o. Eyi ko ki i ṣe ọrọ pe ti Ọlọrun ba fẹ ki n gbe igbe aye to wu u, yoo mọ bi yoo ṣe mu mi lati ṣe bẹ. Ọlọrun ti ṣe ohun gbogbo ti O nilo lati ṣe ki a ba le gbe igbe aye ti o wu u. Ọwọ wa lo wa ku si lati pinnu bi Daniẹli lati gbe igbe aye naa ti O fẹ fun wa ati lati tọ ara wa lati ma gbe awọn igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu aye naa. Ranti pe, ko si bi eniyan, fun apẹẹrẹ, ti ṣe ni ọpọlọ lati mọ iṣiro to, ti ko ba fi ara rẹ jin lati kọ ati lati ṣe aṣaro ninu awọn ofin ti o sorọ mọ iṣiro, ko ni mọ nkankan nipa iṣiro – yoo kan ṣa ma gbodo ni kilasi ni. Bẹẹ gẹgẹ naa ni o ti ṣe ri pẹlu Kirisitẹni ti ko ni ṣe amulo oore-ọfẹ Ọlọrun lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun. Yoo kan ṣa ma kọsẹ ninu idibajẹ ni. (Wo: Galatia 5:16-17; 1Johanu 2:15-17)
  • Iwa bi Ọlọrun ni ere fun ohun gbogbo: Idi miran gbogi ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti lati tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun ni pe o ni ere lori fun ohun gbogbo ninu aye yi ati ninu ijọba Ọlọrun ayeraye ti o n bọ. Eyi tunmọ si pe fun anfaani Timoti ni Pọọlu ṣe sọ nkan yi fun un. Fun anfaani ọmọ Ọlọrun kọọkan naa si ni awa naa ṣe gba aṣẹ kanna lati ọwọ rẹ pe ki a tọ ara wa ni iwa-bi-Ọlọrun. Ti a ba wa ni ki a bẹrẹ si ni sọrọ lori ere iwa-bi-Ọlọrun, o di dandan ki ilẹ kun. Ṣugbọn, ti awa naa ba wo ayika wa, awọn wo ni o ni ibalẹ-ọkan ju ninu aye yi? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni! Awọn wo ni ile wọn n roju, ti ọna wọn n roju julọ? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni! Awọn wo ni ko nilo lati bẹru awọn aisan ti o n ti ara iṣekuṣe wa tabi bẹru pe ki awọn agbofinro ma wa ka awọn mọle nitori ipasipayọ owo ilu tabi idigunjale? Awọn ni ko nilo lati yọnu lori boya awọn eniyan yoo gbẹri wọn jẹ tabi wọn ko ni gbẹri wọn jẹ? Awọn ti o wa bi Ọlọrun ni, nitori pe igbe aye wọn kun fun ẹri rere. Awọn si tun ni ko nilo lati bẹru nkan ti yoo kẹyin aye wọn, nitori ti wọn mọ pe dundun ni ọsan yoo so fun wọn ni ikẹyin aye wọn. Nitorina, ti o ba tọ ara rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun, fun anfaani ara rẹ ni. Ti o ba tọ awọn ọmọ rẹ tabi awọn oṣiṣẹ rẹ ni iwa-bi-Ọlọrun, fun anfaani ara rẹ ati anfaani ara wọn ni. Ṣugbọn ti o ba ro pe aṣẹ Ọlọrun yi si wa ko ni itunmọ, o di dandan ki o kabamọ rẹ lọjọ kan.

ỌRỌ IPARI
Akoko ti a wa yi jẹ akoko igbẹyin aye. Akoko igbẹyin aye si jẹ eyi ti o ku fun oniruuru idibajẹ ati iwa ika ti o le ṣe ijamba fun ọkan eniyan. Awọn ti o ba wa wa bi Ọlọrun nikan naa ni yoo yege ni akoko yi, ti idibajẹ aye yi ko si ni sọ aye wọn di radarada, ki o si tari wọn lọ sinu ọrun apadi. O wa yẹ ki gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun kun fun ọpẹ pe a ti fun wọn ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati gbe igbe aye iwa-bi-Ọlọrun, lọkan, lero, niwa ati ni iṣe. Amọ ṣa o, ti wọn ko ba kọ lati ṣe amulo awọn nkan ti Ọlọrun ti pese fun wa lati gbe igbe aye ti o wu u, asan ati ofo ni gbogbo ilakaka rẹ lori wọn yoo jasi. Eyi jasi pe idibajẹ aye yi yoo ṣe wọn leṣe, yoo si sọ wọn di alailere ọmọ. Adura mi wa ni pe iwọ ko ni di alailere ọmọ Ọlọrun, ni orukọ Jesu. Amin. Amọ iwọ naa gbọdọ pinnu lati tọ ara rẹ lati wa bi Ọlọrun. Alaafia ni fun ọ.

IBERE
Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE | ỌJỌRU 13, IGBE 2022 | AKỌRI: TỌ ARA RẸ SI IWA-BI-ỌLỌRUN AYỌKA: TIMOTI 4:7-11 | J.O. LAWAL Read More »

Njẹ o tilẹ n gbe aye nitootọ? | Pst. J.O. Lawal. | Igbe 17, 2022. | Vol. 10, No. 50

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe. Adura mi si ni pe ki gbogbo nkan ti o sorọ mọ wiwa Jesu Kirisiti saye nitori ọmọ eniyan jẹ mimuṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Bi o ti ṣeeṣe ki o mọ, ni ọjọ Aiku toni, ọpọ onigbagbọ kaakiri aye ni o n yayọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa lati inu ipo oku wa. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a ko fun wa ni aṣẹ kankan taarataara ninu bibeli pe ki a ya ọjọ kan sọtọ lọdun ninu eyi ti a o ti bọ si gbangba tabi parapọ ṣe ajọyọ ajinde Jesu, ko ki i ṣe nkan ti o buru ni fun awọn onigbagbọ lati ṣe bẹẹ. Nkan ti ko wa ni dara rara ni ki a jẹ ki ajọyọ wa lori ajinde rẹ pari lọjọ naa.

Lafikun, ko tun ni dara rara ki a ma yọ ni gbangba lori ajinde Jesu nigba ti a ko so eso ajinde naa. Eyi gan si isoro ni ọpọ igba pẹlu ọpọ ti o pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Wọn ko sọ eso ajinde Kirisiti rara. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko mọ pe o yẹ ki awọn ma gbe aye awọn lati mu idi ti Jesu ṣe ku fun wọn, ti a si tun ji dide ṣẹ tabi wọn ko ka tilẹ kọbiara rara.

Ni kukuru, ti a ko ba ma so eso ajinde Jesu, ko tọ fun wa lati ma ṣe ajọyọ rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, o yẹ ki aye fura si igbagbọ yowu ti a ba sọ pe a ni ninu rẹ, ti a ko ba so eso ajinde rẹ. Idi si ni pe bibeli sọ eyi si gbogbo awa ti a gbagbọ ninu rẹ, ti a si ti darapọ mọ ninu iku, isinku ati ajinde rẹ: “N jẹ awa o ha ti wi? Awa o ha tẹsiwaju lati maa dẹsẹ bi, ki oore-ọfẹ ki o le maa pọ si i? Ki a ma ri. Awa ẹni ti o ti ku si igbe-aye-ẹṣẹ, awa o ha ṣe tun wa laaye ninu rẹ? Ẹyin ko ha mọ wi pe gbogbo awa ti a ti batisi sinu idapọ pẹlu Kirisiti Jesu, a ti batisi wa sinu iku rẹ pẹlu? Pẹlupẹlu, awa ku, a si ti sin wa pọ pẹlu rẹ nipa ibatisi: ki awa ki o le maa gbe igbe-aye ọtun, gẹgẹ bi a ti ji Kirisiti dide kuro ninu oku nipa ogo Baba.” (Roomu 6:1-4)

Yatọ si iyẹn, o tun sọ eyi si wa: “Nitori ifẹ Kirisiti n dari wa; nitori awa ro bayii pe, bi ẹnikan ba ti ku fun gbogbo eniyan, njẹ gbogbo wọn ni o ti ku: O si ti ku fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wa laaye ki o ma si ṣe wa laaye fun ara wọn mọ, bi ko ṣe fun ẹni ti o ku nitori wọn, ti o si ti jinde.” (2Kọrinnti 5:14-15) Njẹ o ri bayi? A ji Jesu Kirisiti dide kuro ninu ipo oku ki o ba le ṣeeṣe fun wa lati gbe igbe aye ọtun ni. O ku, a si tun ji dide fun wa ki a ma ba gbe aye wa fun ara wa mọ bi ko ṣe fun ẹni ti o ku fun wa, ti a si tun ji dide.

Nitorina, ti nkan ti O ṣe fun wa ba ja mọ nkankan loju wa lotitọ, o di dandan ki a dẹkun lati ma gbe aye lati tẹ ara wa lọrun tabi lati tẹ ẹlomiran lọrun. Dipo bẹẹ, nṣe ni a o bẹrẹ si ni gbe aye wa lati tẹ ẹ lọrun. Ṣe nkan ti a si n ṣe ni eyi? Ṣe nkan ti mo n ṣe ni eyi? Njẹ mo n gbe aye mi lati tẹ ẹni ti o jẹ ki atunbi mi sinu ẹbi Ọlọrun ṣeeṣe? Abi nṣe ni mo n gbe aye mi fun ara mi, fun awọn ọrẹ mi, fun idile mi, fun adugbo mi tabi fun ile-iṣẹ kan ti mo yan laayo?

Ka ma fa ọrọ gun, a nilo lati mọ pe ti a ba n gbe aye wa fun ara wa tabi fun ẹnikẹni tabi ohunkohun yatọ si Jesu Kirisiti Oluwa wa, a ko ri aye gbe rara. Bẹẹni, nṣe ni a n gbe aye wa lodi si idi ti o fi yẹ ki a gbe aye. Lotitọ, gbigbe aye wa fun ara wa tabi fun elomiran tabi ohun miran yatọ si fun Jesu le mu inu wa dun, jẹ ki a ro pe a ti di ẹni nla tabi jẹ ki a ro pe a ti ṣe oriire. Amọ, bi mo ti ṣe sọ fun wa tẹlẹ, bi igba ti a ko ba ri aye gbe rara ni. Ti eniyan ko ba si ri aye gbe, a jẹ wipe o ti fi anfaani lati gbe aye rẹ ṣofo niyẹn; o ti fi aye rẹ ṣofo paapaa, ko si tọ lati ri oriyin kankan gba lati ọdọ Ọlọrun.

Nitorina, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi ati bi o ti ṣeeṣe ki o darapọ mọ awọn miran lati yọ ayọ ajinde Jesu, ri daju pe o n gbe aye rẹ lati mu ete rẹ ṣe fun ọ ni. Aijẹbẹ, gbogbo nkan ti o n ṣe yo kan ja si pabo ni. Adura mi si ni pe ki aye rẹ ati gbogbo iṣẹ rẹ ninu aye yi ma ṣe ja si pabo, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Njẹ o tilẹ n gbe aye nitootọ? | Pst. J.O. Lawal. | Igbe 17, 2022. | Vol. 10, No. 50 Read More »

Ko ni i ṣe pẹlu jijẹ gaba lori wọn | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022. | Vol. 10, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa at Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo fi tayọtayọ ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe 2022. Mo si gbadura pe ki a ma fi gbogbo igba kọ ọ lati sin Ọlọrun tọkantọkan, ki o ba le ri ohun rere gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ṣiṣe bẹ gba, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, ti ẹnikẹni ninu wa ba fẹ sin Ọlọrun pẹlu tọkantọkan nitootọ, o gbọdọ fi ọrọ wọnyi ti Jesu Oluwa wa sọ sọkan: “Ẹyin mọ pe, awọn ti a n ka si olori awọn Keferi, a maa lo ipa lori wọn: ati awọn ẹni nla wọn a maa fi ọla tẹri wọn ba. Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ laarin yin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ jẹ olori laarin yin, oun ni yoo ṣe iranṣẹ yin: Ati ẹnikẹni ninu  yin ti o ba fẹ ṣe olori oun ni yoo ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo yin. Nitori ọmọ eniyan tikalararẹ ko wa ki a ba maa ṣe iranṣẹ fun un, bi ko ṣe lati maa ṣe iranṣẹ funnni, ati lati fi ẹmi rẹ ṣe irapada fun ọpọlọpọ eniyan.” (Maaku 10:42-45)

Njẹ o ri bayi pe Oluwa ko lodi si ki a di giga? O fẹ ki a jẹ ẹni giga, paapaa julọ ninu ijọba rẹ. Amọ ṣa o, O tun wa fẹ ki a mọ pe ọna kan ṣoṣo ti Ọlọrun fi le ri wa bi ẹni giga ninu ijọba rẹ ni ki a fi ara wa jin lati ma sin awọn miran. Eyi ko wa tunmọ si pe ki a sọ ara wa di ẹru gbogbo eniyan, ki a si jẹ ki wọn ma ṣe wa tabi sọrọ si wa bi o ti ṣe wu wọn. Dipo eyi, o tunmọ si pe, pẹlu ọkan irẹlẹ, ki a fi ara wa si ipo ti O ti le lo wa lati mu ifẹ rẹ ṣe ninu aye awọn eniyan.

Bi Oluwa ti ṣe fi ye wa ninu ẹsẹ bibeli yẹn, Oun funrarẹ wa si aye lati sin awọn eniyan ni, ko ki i ṣe lati jẹ ki wọn sin in. Ọna wo ni o si gba sin wọn? O sin wọn nipa ṣiṣe awọn nkan ti yoo jẹ ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. Fun apẹẹrẹ, O kọ wọn ni ọrọ Ọlọrun, O wo awọn alailera wọn san, O ji awọn oku wọn dide, O si tun ku nikẹyinkẹyin fun ẹṣẹ wọn. Ki si ni idi? Idi ni ki wọn ba le jẹ iru ẹni ti Ọlọrun fẹ ki wọn jẹ, ni ẹmi, ni ọkan ati ni ara.

Ni ọna kanna, o yẹ ki awa naa ma sin awọn eniyan bi O ti ṣe ṣe. Bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹni ti o ran wa lati ku fun ẹṣẹ ẹnikẹni, ọpọ nkan miran ni a le ṣe lati sin awọn eniyan, ki a si mu ki ifẹ Ọlọrun wa si imuṣẹ ninu aye wọn. A le ma gbadura fun wa, kọ wọn ni ọrọ Ọlọrun, pin nkan ini wa fun wọn, tọ wọn sọna ti wọn ba n kuna, mojuto ọrọ aye wọn, jẹ ki ile ipade wa rọrun fun wọn lati jọsin, ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ni kukuru, ti a ba n sọrọ nipa iṣẹ isin ninu ijọba Ọlọrun, o ni i ṣe pẹlu nkan ti a le fun awọn eniyan dipo nkan ti a le rigba lọwọ wọn. O wa ṣeni laanu pe ọpọ ni eyi ko ye. Nitorina, ọpọ igba ni wọn ma n ro pe iṣẹ isin ninu ijọba Ọlọrun ni i ṣe pẹlu ki a ni agbara lati ṣakoṣo awọn ọmọ Ọlọrun bi a ti ṣe fẹ ati lati gba ohunkohun ti o ba wu wa ni ọwọ wọn. Awọn kan tilẹ ṣetan lati ṣe nkan yowu ti o ba gba lati ni agbara lori awọn ọmọ Ọlọrun. Idi niyi ti a fi ni awọn adari ijọ loni ti o n lo ẹmi oṣo, ẹmi ajẹ, afọṣẹ, itanjẹ ati bẹẹbẹẹ lọ lati ṣiṣẹ.

Iru awọn wọnyi ko yatọ si Simoni oṣo ti igba aye bibeli, ti o fẹ ra ẹbun Ọlọrun pẹlu owo. Ki si ni idi? O fẹ fi dandanla wa ni ipo apaṣẹ lori awọn ara ilu rẹ bi o ti ṣe tẹlẹtẹlẹ. Iru wọn ko si tun yatọ si Diotirifisi igba aye bibeli ti o ṣetan lati ba awọn apọsiteli Oluwa wọ iya ija nitoripe o ṣa a fẹ ni aṣẹ lori awọn ọmọ Ọlọrun. Otitọ ọrọ wa ni pe irufẹ awọn wọnyi ko le rin jinna ninu ilepa wọn lati jẹ gaba lori awọn eniyan Ọlọrun. Idi si nipe, bopẹ-boya, Ọlọrun, ti O ni gbogbo ẹmi, yoo da ṣeriya fun wọn ni ibamu pẹlu iṣẹ ọwọ wọn. (Wo: Iṣe Apọsiteli 8:14-24; 3Johannu 9-10)

Nitorina, ma ṣe ṣe awokọṣe wọn tabi rin ni ipasẹ wọn. Dipo eyi, ṣe awọkọse Jesu Oluwa wa, ti O fi ara rẹ jin lati sin wa, ki aye wa ba le jẹ amuṣẹ ifẹ Ọlọrun. Ọlọrun yi, ti ko si ki i rẹ ẹnikẹni jẹ, yoo pin ọ lere bi o ti ṣe tọ ati yẹ fun ohun gbogbo ti o n ṣe fun awọn eniyan rẹ, ti o ko ba rẹwẹsi.

Ki o ni ọsẹ ti o ga.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Ko ni i ṣe pẹlu jijẹ gaba lori wọn | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022. | Vol. 10, No. 48 Read More »

Wu wọn lori lati jẹ ki Ibukun rẹ ṣiṣẹ | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022 | Vol. 10, No. 48

Olufẹ: ki oore-ọfẹ ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun miran ninu ọdun yi, iyẹn oṣu Igbe. Adura mi si ni pe ki o ri ifarahan ẹkunrerẹ Ibukun Ọlọrun ninu aye rẹ ni gbogbo oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.

Gẹgẹ bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, ti o si jẹ okodoro ọrọ, Ọlọrun ti bukun fun wa pẹlu gbogbo ibukun ẹmi ti o wa ninu awọn ọrun (Efesu 1:3). Nitorina, ko si ẹnikankan ti o tun le fun ọ ni ibukun miran tabi ibukun ara ọtọ kan tabi ibukun ti o ga ju eyi ti Ọlọrun ti fun ọ lọ. O ti ni gbogbo Ibukun ti o nilo ninu aye yi lati jẹ ohun gbogbo ti o yẹ ki o jẹ ati lati gbadun ara rẹ ni ọna ti o peye.

Amọ ṣa o, niwọn igba ti o jẹ wipe nkan ẹmi pọnbele ni Ibukun jẹ, a gbọdọ mọ bi a ti ṣe le jẹ ki o ṣiṣẹ, ki iriri rẹ ti a o ni ma ba jẹ ninu ẹmi nikan. Eyi jasi pe, a nilo lati ri ifarahan awọn Ibukun ti a ti rigba lati ọwọ Ọlọrun ninu ẹmi nipa ti ara pẹlu. Aijẹbẹ, awọn ti aye yi ko ni ri wa bi alabukunfun rara ati pe awọn naa gan paapaa ko ni jẹ igbadun aye wa bi o ti ṣe tọ gẹgẹ bi ẹni ti a bukun fun.

Bawo wa ni a ṣe le jẹ ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ? Akọkọ, a le jẹ ki wọn ṣiṣẹ nipa sisọ nkankanna pẹlu Ọlọrun nipa aye wa ati nipa ṣiṣiṣẹ tọ ọrọ wa lẹyin. Nkan ti eyi tunmọ si ni pe nigbakugba ti a ba n sọ nkankanna pẹlu Ọlọrun lori ododo wa, alaafia wa, ilera wa, iṣoriire wa, aabo wa ati awọn nkan daradara ti aye yi miran, ti a si tun n gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu nkan ti a n sọ, nṣe ni a n mu ki Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ. Bopẹ bosiya, a o bẹrẹ si ni ri ifarahan nipa ti ara awọn nkan ti o jẹ otitọ nipa aye wa ninu ẹmi.

Ekeji, a le mu ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ nipasẹ adura gbigba. Jesu sọ wipe, “Ẹ beere, ẹ o si ri gba, ayọ yin yoo si kun.” Eyi tunmọ si pe nipasẹ adura a le ri ifarahan awọn nkan ti Ọlọrun ti wulẹ fun wa ninu ẹmi lojutaye. Eyi, bi Jesu Oluwa wa si ṣe sọ, jẹ ọna kan ti a fi le jẹ ki ayọ wa kun lori awọn oniruuru nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa. (Wo: Johanu 16:24)

Ọna miran lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa ni ki awọn miran, paapaa julọ awọn ti o ni aṣẹ kan tabi omiran lori aye wa, pe Ibukun rẹ sori wa. Ma ṣe gbagbe pe mo ti sọ siwaju pe ko si ẹni naa ti o le fun wa ni Ibukun ti o ga, dara tabi pọ ju eyi ti Ọlọrun ti fun wa lọ. Ṣugbọn, awọn kan wa, nitoripe Ọlọrun ti fun wọn ni aṣẹ kan tabi omiran lori wa, le mu ki awọn ibukun rẹ kan ti o ti jẹ tiwa tẹlẹ ṣiṣẹ nipasẹ ọrọ adura wọn. Eyi yoo si jẹ ki a bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa ninu aye wa.

Nkan ti mo n sọ ni pe awọn ti o ni aṣẹ nitootọ lori aye wa lọna kan tabi omiran, gẹgẹ bi awọn obi wa, adari ijọ wa, ọkọ wa, olugbawaṣiṣẹ, ọga wa lẹnu iṣẹ ati awọn adari ilu tabi ti ijọba wa, le mu awọn ibukun Ọlọrun kan tabi omiran ṣiṣẹ ninu aye wa nipaṣẹ ire ti wọn ti ọkan ṣu fun wa. Idi si niyi ti a fi gbọdọ kọ lati ma mu inu wọn dun, ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ki ori wọn ba le ma ya loorekoore lati pe ire Ọlọrun sori wa.

Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ibukun ti a fun Aburahamu ti fikalẹ sori ẹbi rẹ, a nilo lati mu ṣiṣẹ ninu aye ọkọọkan ninu awọn arọmọdọmọ rẹ ki wọn to le ni iriri tabi ifarahan rẹ. Fun apẹẹrẹ, ti a ba wo aye Isaki, a ri wipe igbọran rẹ si Ọlọrun ni akoko iyan buruku kan ni o kẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ fun iṣoriire rẹ laye (Jẹnẹsisi 26). Lafikun, adura rẹ fun aya rẹ tun jẹ ki Ibukun yi ṣiṣẹ lodi si iyagan wọn, ti awọn naa si di ọlọmọ laye (Jẹnẹsisi 25:21). Ṣugbọn ni ti Isọ, a ri wipe ire Isaki ni o yẹ ki o mu Ibukun yi ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Nitorina, Isaki paṣẹ fun lati pese ounjẹ adidun ti yoo mu ki inu oun dun to bẹẹ gẹẹ ti oun yoo gbadura pataki ti yoo mu ki Ibukun baba oun ṣiṣẹ ninu aye rẹ fun. Bi o wa  tilẹ jẹ wipe Isọ kọ ni o pada gba Ibukun yi, Jakọbu, ẹni ti o gba a, ko kuna rara lati mu inu baba wọn, Isaki, dun pẹlu ounjẹ ara ọtọ ti o gbe wa fun. Nitorina, Ibukun naa di titu silẹ lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ nipa ire Isaki, aye rẹ ko si ri bakanna mọ lati igba naa lọ.

Nibakanna, ti awa naa ba kọ lati ma mu ki inu awọn ti o ni aṣẹ lori wa dun nipasẹ awọn nkan ti a n ṣe fun wọn ati ṣi wọn, ọpọ igba ni a o ri pe ori wọn yoo wu lati sọ awọn ọrọ ti yoo jẹ ki awọn Ibukun Ọlọrun kan ṣiṣẹ ninu aye wa, ti a o si bẹrẹ si ni ri ifarahan awọn Ibukun naa lojutaye. Ṣugbọn ti a ba ro pe ọrọ ire wọn ko ja mọ nkankan si wa, boya nitori imọ ti a ni pe a kuku ti gba gbogbo Ibukun ọrun lati ọwọ Ọlọrun, a jẹ wipe awọn ifarahan awọn Ibukun Ọlọrun kan wa ti a le ma ni titi ọjọ aye wa yoo fi tan lorilẹ niyẹn. Nitorina, ẹ jẹ ka kẹkọ lati ara Jakọbu, ki a si ma wo, loorekoore, awọn ọna ti a le gba wu awọn ti o ni aṣẹ lori wa lori  lati mu Ibukun Ọlọrun ṣiṣẹ ninu aye wa. Ki Ọlọrun si rẹ ọkan wa silẹ lati mu ọrọ yi lọkunkundun, ni orukọ Jesu. Amin.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Wu wọn lori lati jẹ ki Ibukun rẹ ṣiṣẹ | Pst. J.O. Lawal | Igbe 03, 2022 | Vol. 10, No. 48 Read More »