Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Igbe. Adura mi si ni pe ki gbogbo nkan ti o sorọ mọ wiwa Jesu Kirisiti saye nitori ọmọ eniyan jẹ mimuṣẹ ninu aye rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi o ti ṣeeṣe ki o mọ, ni ọjọ Aiku toni, ọpọ onigbagbọ kaakiri aye ni o n yayọ ajinde Jesu Kirisiti Oluwa wa lati inu ipo oku wa. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a ko fun wa ni aṣẹ kankan taarataara ninu bibeli pe ki a ya ọjọ kan sọtọ lọdun ninu eyi ti a o ti bọ si gbangba tabi parapọ ṣe ajọyọ ajinde Jesu, ko ki i ṣe nkan ti o buru ni fun awọn onigbagbọ lati ṣe bẹẹ. Nkan ti ko wa ni dara rara ni ki a jẹ ki ajọyọ wa lori ajinde rẹ pari lọjọ naa.
Lafikun, ko tun ni dara rara ki a ma yọ ni gbangba lori ajinde Jesu nigba ti a ko so eso ajinde naa. Eyi gan si isoro ni ọpọ igba pẹlu ọpọ ti o pe ara wọn ni onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu. Wọn ko sọ eso ajinde Kirisiti rara. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko mọ pe o yẹ ki awọn ma gbe aye awọn lati mu idi ti Jesu ṣe ku fun wọn, ti a si tun ji dide ṣẹ tabi wọn ko ka tilẹ kọbiara rara.
Ni kukuru, ti a ko ba ma so eso ajinde Jesu, ko tọ fun wa lati ma ṣe ajọyọ rẹ. Ki a tilẹ sọ otitọ, o yẹ ki aye fura si igbagbọ yowu ti a ba sọ pe a ni ninu rẹ, ti a ko ba so eso ajinde rẹ. Idi si ni pe bibeli sọ eyi si gbogbo awa ti a gbagbọ ninu rẹ, ti a si ti darapọ mọ ninu iku, isinku ati ajinde rẹ: “N jẹ awa o ha ti wi? Awa o ha tẹsiwaju lati maa dẹsẹ bi, ki oore-ọfẹ ki o le maa pọ si i? Ki a ma ri. Awa ẹni ti o ti ku si igbe-aye-ẹṣẹ, awa o ha ṣe tun wa laaye ninu rẹ? Ẹyin ko ha mọ wi pe gbogbo awa ti a ti batisi sinu idapọ pẹlu Kirisiti Jesu, a ti batisi wa sinu iku rẹ pẹlu? Pẹlupẹlu, awa ku, a si ti sin wa pọ pẹlu rẹ nipa ibatisi: ki awa ki o le maa gbe igbe-aye ọtun, gẹgẹ bi a ti ji Kirisiti dide kuro ninu oku nipa ogo Baba.” (Roomu 6:1-4)
Yatọ si iyẹn, o tun sọ eyi si wa: “Nitori ifẹ Kirisiti n dari wa; nitori awa ro bayii pe, bi ẹnikan ba ti ku fun gbogbo eniyan, njẹ gbogbo wọn ni o ti ku: O si ti ku fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wa laaye ki o ma si ṣe wa laaye fun ara wọn mọ, bi ko ṣe fun ẹni ti o ku nitori wọn, ti o si ti jinde.” (2Kọrinnti 5:14-15) Njẹ o ri bayi? A ji Jesu Kirisiti dide kuro ninu ipo oku ki o ba le ṣeeṣe fun wa lati gbe igbe aye ọtun ni. O ku, a si tun ji dide fun wa ki a ma ba gbe aye wa fun ara wa mọ bi ko ṣe fun ẹni ti o ku fun wa, ti a si tun ji dide.
Nitorina, ti nkan ti O ṣe fun wa ba ja mọ nkankan loju wa lotitọ, o di dandan ki a dẹkun lati ma gbe aye lati tẹ ara wa lọrun tabi lati tẹ ẹlomiran lọrun. Dipo bẹẹ, nṣe ni a o bẹrẹ si ni gbe aye wa lati tẹ ẹ lọrun. Ṣe nkan ti a si n ṣe ni eyi? Ṣe nkan ti mo n ṣe ni eyi? Njẹ mo n gbe aye mi lati tẹ ẹni ti o jẹ ki atunbi mi sinu ẹbi Ọlọrun ṣeeṣe? Abi nṣe ni mo n gbe aye mi fun ara mi, fun awọn ọrẹ mi, fun idile mi, fun adugbo mi tabi fun ile-iṣẹ kan ti mo yan laayo?
Ka ma fa ọrọ gun, a nilo lati mọ pe ti a ba n gbe aye wa fun ara wa tabi fun ẹnikẹni tabi ohunkohun yatọ si Jesu Kirisiti Oluwa wa, a ko ri aye gbe rara. Bẹẹni, nṣe ni a n gbe aye wa lodi si idi ti o fi yẹ ki a gbe aye. Lotitọ, gbigbe aye wa fun ara wa tabi fun elomiran tabi ohun miran yatọ si fun Jesu le mu inu wa dun, jẹ ki a ro pe a ti di ẹni nla tabi jẹ ki a ro pe a ti ṣe oriire. Amọ, bi mo ti ṣe sọ fun wa tẹlẹ, bi igba ti a ko ba ri aye gbe rara ni. Ti eniyan ko ba si ri aye gbe, a jẹ wipe o ti fi anfaani lati gbe aye rẹ ṣofo niyẹn; o ti fi aye rẹ ṣofo paapaa, ko si tọ lati ri oriyin kankan gba lati ọdọ Ọlọrun.
Nitorina, bi o ti ṣe n lọ lọsẹ yi ati bi o ti ṣeeṣe ki o darapọ mọ awọn miran lati yọ ayọ ajinde Jesu, ri daju pe o n gbe aye rẹ lati mu ete rẹ ṣe fun ọ ni. Aijẹbẹ, gbogbo nkan ti o n ṣe yo kan ja si pabo ni. Adura mi si ni pe ki aye rẹ ati gbogbo iṣẹ rẹ ninu aye yi ma ṣe ja si pabo, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.
Copyright © 2022, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

May God’s word continually be fruitful in our hearts. Amen