November 2025

Má jẹ́ kán pa iṣẹ́ ìrańṣẹ́ wọn tì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 30, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 31

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọjọ ti o pari oṣu kọkanla ọdun yi. Adura mi si ni pe ki oṣu tuntun ti a fẹ wọ inu rẹ ninu ọsẹ naa dun fun wa ni gbogbo ọna, ni orukọ Jesu. Amin.

Wayi o, bi a ti ṣe n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju lati ma a fi igba gbogbo ṣọ́ bi o ti ṣe n ṣe si ẹnikẹni ti o ba ti fi ara rẹ jin fun iṣẹ iranṣẹ ninu ijọba Ọlọrun, ki o ma ba mu wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Ṣe a le mu ki awọn eniyan pa iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun wọn ti lotitọ? Bẹẹni, a le e ṣe bẹẹ. Ko si ki i wa ṣe awọn ti o jẹ ọmọ ijọ nikan ni o le mu ki awọn iranṣẹ Ọlọrun pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti; awọn adari ijọ bi ti wọn naa le mu ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti.

Fun apẹrẹ, nigba ti a gbe pasitọ tuntun wa si inu ijọ ti mo n lọ ni igba kan, nkan akọkọ ti o ṣe ni pe o din owo ti a n san fun awọn ti o n ṣiṣẹ inu ile-iṣẹ inu ijọ yi ku. Ki ni idi? Idi ti o sọ wipe oun ṣe ṣe bẹ ni pe wọn ko ṣe iṣẹ to lati gba irufẹ owo ti pasitọ ti tẹlẹ n ṣan fun wọn. Ṣugbọn owo ti pasitọ ti tẹlẹ n ṣan fun wọn gan ko to iye ti a n san fun awọn akẹgbẹ wọn nita. Idi ti o si ṣe n san iye ti o n san fun wọn ni pe ko fẹ ki wọn fi igba kankan bẹrẹ si ni ro wipe idi ti awọn ko fi le tọju ara wọn ati awọn ẹbi wọn lọna ti o peye ni pe awọn n ṣiṣẹ fun Ọlọrun.

Amọ nṣe ni pasitọ tuntun yi kan ba gbogbo nkan jẹ. Nitorina, ko pẹ rara ti ọpọ ninu awọn oṣiṣẹ inu ile-iṣẹ ijọ yi bẹrẹ si ni kuro. Ṣe wọn wa n kuro nitoripe wọn ko fẹ Ọlọrun ni tabi nitoripe wọn ko fẹ sin in? Rara O! Idi ti wọn ṣe wa ṣiṣẹ ninu ile-iṣẹ ijọ yi ti wọn ko lọ bẹrẹ okowo ti ara wọn tabi ki wọn lọ sisẹ ni awọn ile-iṣẹ miran ni pe wọn fẹran Ọlọrun, wọn si fẹ sin in. Ṣugbọn nigba ti wọn ri wipe pasitọ wọn ko bikita rara nipa igbaye-gbadun wọn, wọn bẹrẹ si ni kuro. O si wa san bi wọn ti ṣe kuro yi ju ki wọn duro, ki wọn si ma kun sinu lọ.

Ki a ma fọrọgun, nitoripe wọn kuro ni ọna yi, ipalara bẹrẹ si ni ba awọn iṣẹ ti wọn n ṣe. Yatọ si eyi, ko si iwuri fun awọn miran ti wọn ri bi a ti ṣe ṣe si wọn lati wa ṣiṣẹ ni ile-iṣẹ ijọ yi. Idi si ni pe awọn naa ko fẹ ni irufẹ iriri kan naa. Ṣugbọn tani o jẹ ki awọn eniyan wọnyi pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti? Adari ijọ wọn ni! Ọlọrun nikan ni o wa mọ iye awọn ti awọn adari ijọ wọn ti jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti lọna kanna.

Nitorina, ko ki i ṣe kiki awọn ọmọ ijọ nikan ni o le mu ki awọn iranṣẹ Ọlọrun pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti; awọn adari ijọ naa le mu ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Ibi ti eyi ba si ti waye, o di dandan ki ipalara ba awọn nkan kan ti Ọlọrun fẹ ṣe ninu aye awọn eniyan fun saa kan. Bẹẹni, ipalara yoo ba awọn nkan wọnyi titi yoo fi ri awọn iransẹ tuntun miran ti yoo fun ni iwuri lati bẹrẹ si ni ṣe wọn.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni asiko Nehemaya, iparala bẹrẹ si ni ba iṣẹ Ọlọrun lasiko kan nitoripe awọn Juu ati awọn adari wọn jẹ ki awọn ọmọ Lefi ti o n ṣiṣẹ ninu tẹmpili pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. Lọna wo? Iwọ naa wo nkan ti Nehemaya sọ lori eyi ninu bibeli:

“Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn. Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.” (Nehemáyà 13:10-12)

Ṣe o ri bayẹn? Nitoripe awọn eniyan wọnyi kọ lati mojuto awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin ti wọn n ṣiṣẹ ninu tẹmpili Ọlọrun, wọn fi iṣẹ Ọlọrun silẹ, wọn si pada lọ si oko wọn ati si idi okowo wọn. Ta wa ni o lero pe eyi ni lati pa lara ju? Awọn eniyan naa ni! Awọn ni ko ni ni iriri Ibukun ti o sorọ mọ iṣẹ iranṣẹ awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin yẹn bi o ti ṣe yẹ. Ti Nehemaya ko ba wa tete da si ọrọ naa ni, Ọlọrun nikan ni O mọ bi nkan ti wọn n ṣe yi ko ba ṣe pa iṣoriire, alaafia ati ilera orilẹ-ede wọn lapapọ lara si.

Wayi o, ko ki i wa ṣe kiki ki a ma fi owo wa ran awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o wa ni aarin wa lọwọ to nikan ni o le jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti. A tun le jẹ ki wọn pa iṣẹ iranṣẹ wọn ti nipa sisọ awọn ọrọ kobakungbe si wọn, nipa pipa irọ mọ wọn tabi nipa didi ọtẹ mọ wọn. Nigba ti a ba si ṣe eyi, a le mọ daju pe yoo pa iṣẹ ti Ọlọrun fẹ tipasẹ wọn ṣe ninu aye wa ati ninu aye awọn miran lara. Ṣe Ọlọrun yoo wa gboriyin fun wa fun eyi bi? Rara o! Dipo eyi, nṣe ni yoo fẹrẹ fi iya jẹ wa. Eyi ko si ni suwọn rara.

Nitorina, ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo finni-finni, ki a si ri daju pe a ko ma ṣe ohunkohun lati mu ki iranṣẹ Ọlọrun kankan pa iṣẹ iranṣẹ rẹ ti. Njẹ ki Ọlọrun fun wa ni okun lati ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi ki o to pẹ ju. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má jẹ́ kán pa iṣẹ́ ìrańṣẹ́ wọn tì | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 30, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 31 Read More »

Fi ṣe àkọ́kọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 30

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pẹlu ayọ ti o ga ni mo fi ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ya aye rẹ ya ohunkohun ti o ti fi gbedeke sori ilọsiwaju rẹ, ki gbogbo iriri ainilosiwaju le wa si opin ninu aye rẹ. Amin.

Ọkan lara awọn nkan ti o ma n ṣaba di ilọsiwaju awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ ni aifi tọkan-tọkan fi ara wọn jin fun Ọlọrun. Ki si ni idi ti a ki i fi fi gbogbo igba fi tọkan-tọkan fi ara wa jin fun un? Idi kan pataki ni pe ifẹ wa lati ni awọn nkan daradara aye yi ati lati da bi awọn ti o wa ni ayika wa ko ki n ṣaba jẹ ki a roju-raye.

Ṣe ko dara ki a ni awọn nkan ti o dara ti aye yi ni tabi ki a wa ni ipo pataki laye? O dara. Ki a tilẹ sọ otitọ, Ọlọrun ko lodi si ki a ni awọn nkan daradara ti aye yi tabi ki a wa ni ipo ti o ga laye. Dipo eyi, bi a ti sọ fun wa ninu bibeli, Oun funrarẹ ni O ma n fi ohun gbogbo fun wa fun igbadun wa (1Tímótì 6:17).

Amọ ṣa o, awa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun ni lati mọ wipe a ko le ni awọn nkan ti aye yi to dara nipa sisare tẹle wọn lasan tabi nipa ṣiṣe aniyan lati ni wọn lasan. Bi a ba tilẹ ni ohunkohun ni ọna yi, ko si aridaju pe nkan naa yoo jẹ nkan ti a nilo tabi nkan ti a le jẹgbadun. Ọna kan ṣoṣo ti a fi wa le ni awọn nkan daradara aye yi ti a nilo, ki a si tun jẹgbadun wọn, ni ki Ọlọrun, Baba wa, ki o mu wọn wa fun wa tabi ki o dari wa si ibi ti a o ti ri wọn.

Idi si ni yi ti Jesu Oluwa wa fi sọ eyi fun wa:

“Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa? Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.” (Mátíù 6:31-33)

Njẹ o ri bayẹn? Ọlọrun ko fẹ ki a ma ṣe aniyan lori ohunkohun ti a nilo laye. Lafikun, ko fẹ ki a sọ ohun gbogbo nipa aye wa di ifagagbaga pẹlu awọn miran. Dipo eyi, O fẹ ki a ma fi igba gbogbo fi ṣe akọkọ ninu ohun gbogbo ti a ba n ṣe. Nipa bayi, yoo le fun wa ni ohun gbogbo ti a nilo laye ati agbara lati jẹgbadun wọn.

O wa ṣeni laanu pe ọpọ wa ni ko ma a rin ninu imọlẹ otitọ yi. Nitorina, nṣe ni a n fi igba gbogbo ṣe ara wa leṣe nipa fifi agagbaga pẹlu awọn ti aye yi lati ni awọn nkan daradara aye. Ti a ko ba si ronupiwada, ki a bẹrẹ si ni fi Ọlọrun ṣe akọkọ, ki a si tun gbe e leke ohun gbogbo ti a nilo tabi ti a fẹ laye, a ko ni ye ṣi ilẹkun aye wa silẹ fun ewu lai nidi.

Ranti wipe Ọlọrun mọ ohun gbogbo ti a nilo. Ko si tun wa mọ ohun gbogbo ti a nilo nkan, O tun n fẹ lati fun wa ni ohun gbogbo ti a nilo. Amọ ti a ko ba fun ni aaye ti o tọ si ninu aye wa, a ko ni dẹkun lati ma ṣiṣẹ lodi si awọn nkan ti O n ṣe lati mu inu wa dun laye. Ibi ti eyi ba si ti ri bẹẹ, ko si ẹnikẹni ti a o le dalẹbi bi ko ṣe ara wa.
Nitorina, bi o ti ṣe n lọ ni ọsẹ yi, pinnu ninu ọkan rẹ lati ma fi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye rẹ. Njẹ ki Ẹmi Ọlọrun fun ọ ni okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Fi ṣe àkọ́kọ́ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 23, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 30 Read More »

O kàn ń tan ara rẹ jẹ ní | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 29

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lọpọlọpọ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ kẹta ninu oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ fun ọ ni okun lati mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun, ki o ba a le so eso ti o yẹ ki o so ninu aye rẹ. Amin.

Jakọbu, ninu lẹta rẹ, sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ.” (Jákọ́bù 1:22) Ṣe ko ki i ṣe nkan ti o dara ni lati gbọ ọrọ Ọlọrun ni? Nkan ti o dara ni lati ṣe bẹ ẹ. Johanu tilẹ sọ fun wa ninu iwe Ifihan pe awọn odiwọn ibukun kan wa ti o ma n tẹle kika ọrọ Ọlọrun tabi gbigbọ ọ (Ìfihàn 1:3).

Amọ ṣa o, gbigbọ ọrọ Ọlọrun tabi kika a ko ma to. A tun nilo lati ṣe nkan ti ọrọ naa n sọ. Aijẹbẹ, ifẹ Ọlọrun ko ni wa si imuṣẹ ninu aye wa tabi lorilẹ aye. Niwọn igba ti ifẹ rẹ ko ba si ma wa si imuṣẹ ninu aye wa tabi ninu aye ti a wa, a ko le ni iriri alaafia ati ayọ ti a n fẹ ni.

Jesu Oluwa wa na sọ itan kan fun wa ni ibamu pẹlu ọrọ yi. O da lori baba kan ti o ni ọmọkunrin meji, ti o si sọ fun ọmọkunrin rẹ akọkọ, “Lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara loni.” Nṣe wa ni ọdọmọkunrin naa sọ wipe oun kọ ni lọ. Nitorina, baba yi lọ si ọdọ ọmọkunrin rẹ keji, o si sọ fun pe, “Lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara loni.” Ọdọmọkunrin naa si sọ wipe oun o lọ. Ṣugbọn ko lọ rara. Ọmọkunrin baba yi akọkọ, ẹwẹ, wa pada ni iyipada ọkan, o si lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara baba rẹ. (Wo: Mátíù 21:28-31)

Ibere wa ni pe, “Tani o ṣe ifẹ baba rẹ ninu awọn ọdọmọkurin mejeeji yi?” Ọmọkunrin baba yi akọkọ ni o ṣe ifẹ rẹ. Ọmọkunrin rẹ keji ti o ṣe bi ẹni pe oun jẹ onigbọran ọmọ ko ṣe ifẹ baba rẹ rara. Nitorina, ti baba yi ba fẹ pin ẹnikẹni lere fun ṣiṣe ifẹ rẹ lọjọ naa, ọmọkunrin rẹ akọkọ ni yoo pin lere, ko ki i ṣe ọmọkunrin rẹ keji.

O wa ṣeni laanu pe, pupọ ninu wa ni o dabi ọmọkunrin baba yi keji. Nigba ti ọrọ Ọlọrun ba n tọ wa wa, nṣe ni a o ma mi ori wa ni ibamu pẹlu ọrọ naa, ti a o si tun ma pariwo fun ayọ nigba miran nitori nkan ti Ọlọrun n sọ fun wa. Ṣugbọn ti o ba di ki a ṣiṣẹ tọ nkan ti a n gbọ, ọtọ ni nkan ti a o ma ṣe. Wa gbiyanju a ti wo bi eyi yoo ṣe ma dun Ọlọrun lọkan to.

Ki a ma fọrọgun, Jakọbu sọ fun wa pe awọn ti o ba n ṣe ba yi kan n tan ara wọn jẹ ni. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti wọn ko ṣiṣẹ le lori ko le ṣe aye wọn tabi aye ti wọn wa ninu rẹ ni anfaani. Ko ni yi aye wọn tabi ọrọ aye wọn pada. Nitorina, nṣe ni wọn kan n fi akoko, okun ati owo ti wọn n ko sori gbigbọ tabi kika ọrọ naa ṣofo.

O wa ṣeeṣe ki o jẹ wipe bi iwọ naa ṣe ri ni eyi. O ma n ṣaba ṣe bi ẹni pe o n fọwọsowọpọ pẹlu Ọlọrun ti ọrọ rẹ ba n tọ ọ wa. Ṣugbọn nkan ti o wa ni ọkan rẹ ni iwọ yoo papa ṣe, ko ki i ṣe nkan ti O fẹ ki o ṣe. Nṣe ni o kan n tan ara rẹ jẹ. Nitorina, gbogbo asiko, okun ati owo ti o n na lori gbigbọ ati kika ọrọ rẹ di dandan ki o ṣofo. Idi si ni pe ọrọ Ọlọrun ti o ko ni ṣiṣẹ le lori ko le yi aye rẹ tabi igba pada fun ọ.

Wayi o, emi ko fẹ fi akoko, okun ati owo ti mo n na lori gbigbọ tabi kika ọrọ Ọlọrun ṣofo mọ. Dipo eyi, mo fẹ ki ọrọ rẹ ṣiṣẹ ninu aye mi, ki o si ṣe aye mi ni ohun gbogbo ti O fẹ ki o jẹ. Idi si niyi ti ma a fi ma fi ojoojumọ bere fun okun lati ma kan jẹ olugbọ ọrọ rẹ lasan ṣugbọn oluṣe ọrọ rẹ pẹlu. Njẹ iwọ naa yoo ṣe bẹẹ gẹgẹ bi? Ti iwọ naa yoo ba ṣe bẹẹ gẹgẹ, njẹ ọrọ rẹ ti o n gbọ ko tun ni ṣofo ninu aye rẹ mọ ṣugbọn yoo ma a so eso ti Ọlọrun fẹ ri ninu rẹ.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

O kàn ń tan ara rẹ jẹ ní | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 16, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 29 Read More »

Má fi àyè gba àrífín | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 28

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lalai lodiwọn lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Pẹlu idunnu ti o ga ni mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ma a fi ojoojumọ ṣe ọ yẹ pẹlu ohun gbogbo ti o nilo lati ṣe amulo ti o peye awọn ẹbun rẹ ninu aye awọn iranṣẹ rẹ ti o wa ninu aye rẹ, ki o ba a le jere awọn nkan ti O ran wọn lati ṣe ninu aye rẹ lẹkunrẹrẹ. Amin.

Jesu Oluwa wa fi igba kan sọ nkan yi fun awọn eniyan ilu-abinibi rẹ:

“Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria.” (Lúùkù 4:27)

Ki ni idi ti O ṣe sọ eyi? O sọ ọ lati fi han wa pe ko ki i ṣe nkan tuntun ni fun awọn ti o sunmọ awọn ẹni-ami-ororo Ọlọrun lati má jere pupọ tabi rara lati ara oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa lori aye wọn. Ki ni idi? Idi ni pe wọn ma n ṣaba fi aye gba àrífín lati di wọn lọwọ lati ba awọn eniyan wọnyi lo lọna ti o yẹ.

Bi a ti ṣe ri ni ti ọrọ Eliṣa, eyi ti Jesu mẹnuba ninu ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yẹn, bi o tilẹ jẹ wipe ọpọlọpọ adẹtẹ ni o wa ni Isiraẹli ni asiko rẹ, ko wo ọkankan ninu wọn san. Ṣe nitoripe ko ni agbara Ọlọrun to ni ko ṣe wa wo wọn san ni? Rara o! Idi ni pe wọn ko ka agbara Ọlọrun ti o wa ninu rẹ si to lati wa sọdọ rẹ fun iwosan. Ṣugbọn nigbati Namani, ẹni ti o jẹ ajeji patapata, wa sọdọ rẹ lati gba iwoṣan fun ẹtẹ rẹ, ọjọ kanna gan-an ni a wosan. Eyi tunmọ si pe ti awọn adẹtẹ ti o wa ni Isiraẹli naa ba wa sọdọ rẹ fun iwosan ni, a ko ba wo awọn naa san kuro ninu ẹtẹ wọn. (Wo: 2Àwọn Ọba 5)

Nibakanna, nigba ti Jesu lọ si ilu-abinibi rẹ, ko le ṣe iṣẹ iyanu ti o ga pupọ nibẹ. O si wa ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ti o ga ni ọpọlọpọ ibimomiran ki O to wa sibẹ. Ki wa ni idi ti ko ṣe le ṣe ọpọ iṣẹ iyanu ni aarin wọn? Idi naa ni pe wọn ko ka oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa ninu aye rẹ si. Nitorina, wọn ko le tẹwọgba ati jẹgbadun ibukun Ọlọrun ti O mu wa fun wọn. (Wo: Máàkù 6:1-6)

O wa ṣeni laanu pe ọpọ awọn onigbagbọ loni naa ni o n padanu didara Ọlọrun ti o le e jẹ ti wọn nitoripe wọn ko ka oore-ọfẹ rẹ ti o wa ninu aye awọn iranṣẹ rẹ ti o n jiṣẹ fun wọn si to tabi rara. Awọn miran ti ko sunmọ awọn iranṣẹ Ọlọrun wọnyi le ma a jẹgbadun oore-ọfẹ Ọlọrun ninu aye wọn ni awọn ọna ti o ga, ki wọn si tun ma jẹ awọn ẹri iyanu. Ṣugbọn awọn ti wọn n ri wọn lore-koore le ma ma jẹgbadun pupọ didara Ọlọrun nipasẹ wọn. Idi si ni pe wọn ti fi aye gba arifin lati di wọn lọwọ lati ba wọn ṣe pọ ni awọn ọna ti yoo jẹ ki Ọlọrun le tipasẹ wọn bukun fun wọn lọna ti o ga.

Ti o ba wa jẹ wipe iwọ naa ko jẹgbadun didara Ọlọrun lọna ti o ga nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ ti o wa ninu aye rẹ, o le fẹ yẹ ara rẹ wo. O ṣeeṣe ki o jẹ wipe o ti fi aye gba arifin lati di ọ lọwọ lati ba wọn ṣe pọ ni awọn ọna ti yoo jẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa ninu aye wọn bukun fun ọ lalai ni idena. O wa ni lati ronupiwada lẹsẹkẹsẹ, ki o si bẹrẹ si ni ba wọn ṣe pọ pẹlu ìfẹ́, ìgbàgbọ́ ati ọ̀wọ̀. Nipa ṣiṣe eyi, awọn ilẹkun oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa ninu aye wọn yoo le jẹ ṣiṣi silẹ fun igbadun rẹ lailai si idiwọ.

Kí o ní ọ̀sẹ̀ alárinrin.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Má fi àyè gba àrífín | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 28 Read More »

Ó ní láti ṣe ǹkankan tí ó yàtọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 27

Olufẹ: Ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia pọ si fun ọ ni ilọpo-ilọpo lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu kọkanla ọdun yi, iyẹn oṣu Belu 2025. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati ri awọn igbesẹ ti o tọ fun ọ lati gbe ki o ba a le ṣe amulo wiwa rẹ ninu aye rẹ fun aluyọ rẹ ni ibi yowu ti a ti n di ọ lọwọ laye. Amin.

Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, lẹyin iku Usa, ọkunrin naa ti Ọlọrun lupa nitori ti o fọwọkan Apoti Ẹri, Dafidi pinnu lati gbe Apoti naa lọ si ile ọkunrin kan ti a n pe ni Obedi-Edomu. Idi si ni pe ẹru nkan ti o le ṣẹlẹ si awọn ara ile rẹ, ti a ba gbe Apoti naa wa si ọdọ wọn, ba a. Nitorina, ko ki i ṣe nitori inu-ire ni a fi gbe Apoti naa wa si ile Obedi. Dipo bẹẹ, nitoripe Dafidi ati awọn eniyan rẹ ri ṣiṣe eyi gẹgẹ bi ọna lati bọ lọwọ ibinu Ọlọrun ni. (Wo: 2Sámúẹ́lì 6:1-10)

Amọ ṣa o, si iyalẹnu wọn, lẹyin igba ti Apoti naa ti wa ni ọdọ Obedi-Edomu fun oṣu mẹta, iroyin tọ Dafidi wa pe Oluwa ti bukun fun ile ọkunrin naa ati ohun gbogbo ti o ni nitori Apoti rẹ ti o wa pẹlu rẹ. Wayi o, irufẹ iroyin bayi ko ṣa le dede tan kalẹ ti ko ba jẹ wipe iṣoriire Obedi-Edomu jẹ agbaayanu. Ṣugbọn iṣoriire rẹ yi jẹ agbaayanu, nitoripe o yara, o si pọ lọpọ-lọpọ, eyi ti o gba oṣu mẹta pere fun gbogbo awọn ti o wa ni ayika rẹ lati mọ pe o ti fi ipo eniyan lasan silẹ lati di ọlọrọ. (Wo: 2Sámúẹ́lì 6:11-15)

Nitorina, Dafidi ko fi asiko ṣofo rara lati lọ gbe Apoti naa kuro ni ile Obedi-Edomi wa si ile oun tikararẹ. Bi o tilẹ wa jẹ wipe a le ma le sọ wipe eyi ko dara, a ko ri akọsilẹ rẹ ninu bibeli pe oun naa ni iriri irufẹ iṣoriire ti Obedi-Edomu ni, lẹyin igba ti o gbe Apoti Oluwa wa si ile rẹ. Ki ni idi? A ko fun wa ni esi kankan si eyi ninu bibeli.

Lafikun, a ko ni akosilẹ rẹ ninu bibeli pe Abinadabu, ọkunrin ti Apoti naa wa ni ile rẹ ki a to gbe lọ si ile Obedi-Edomu, ni iriri irufẹ iṣoriire ti Obedi-Edomu ni, bi o tilẹ jẹ wipe Apoti naa wa ni ile rẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Dipo eyi, nṣe ni o tun padanu ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ, Usa, nitori Apoti naa. O ma ṣe o! (Wo: 1Sámúẹ́lì 7:1-2; 2Sámúẹ́lì 6:3)

Ki wa ni o fa ti ọrọ ti Obedi-Edomu ṣe yatọ? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, a ko fun wa ni idi kankan pato ninu bibeli. Ṣugbọn ọkunrin yi ni lati ṣe nkankan yatọ. Bẹẹni, o ni lati ṣe nkankan ti awọn yoku, pẹlupẹlu awọn alufa, ko ṣe ni mimojuto Apoti yii. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe ko ki i ṣe ọmọ Isiraẹli nipa ibi, o ni irufẹ iriri iṣoriire ati ojurere lati ọdọ Ọlọrun ti awọn miran ko ni.

Njẹ ki wa ni o ṣe yatọ? A ko le mọ titi igba ti a o fi duro ni iwaju itẹ Ọlọrun. Ṣugbọn o damiloju pe ohun yowu ti o ṣe tọ ọ wa nipasẹ ifihan lati ọdọ Ọlọrun ni. Nigba ti o si ṣe, o fun ni gbogbo iyatọ aye yi.

Nibakanna, ti Ọlọrun ba le fi sinu ọkan wa awọn ifihan ohun ti a nilo lati ṣe lati ni iriri aluyọ ti o lagbara ni ibikibi ti a ti nilo rẹ ninu aye wa, nkan ti yoo tẹle yoo ya ati awa ati awọn ti o wa ni ayika wa lẹnu, ti a ba ṣiṣẹ le lori. Ki a tilẹ sọ otitọ, eyi yoo fun wa ni ẹri ti ko wọpọ jẹ. Nitorina, dipo ti a o fi ma gbiyanju lati ṣe awọn nkan ti awọn miran n ṣe, bi o ti wu ki o dara to, nṣe ni ki a kọ lati ma gbadura si Ọlọrun lati fun wa ni awọn ifihan nkan ti o yẹ ki a ṣe ni pato lati le tayọ ati lati le ṣoriire bi o ti tọ laye yi. Idi si ni pe nkan ti o ṣiṣẹ fun awọn miran le ma ṣiṣẹ fun wa. Njẹ ki a gba ojurere lati gba irufẹ awọn ifihan wọnyi, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ ibukun.

Copyright © 2025, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 08146472876)

Ó ní láti ṣe ǹkankan tí ó yàtọ̀ | Láti ọwọ́: J.O. Lawal | Ọjọ́: Belu 26, 2025 | Àtẹ̀léra: Látorí tábìlì Pásítọ̀ | Nọ́múbà: Vol. 14, No. 27 Read More »